Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 5

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ayé Yìí?

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ayé Yìí?

1. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé yìí?

Jèhófà dá ayé yìí fún àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ilé wa ló jẹ́. Nítorí èyí ni Ọlọ́run kò ṣe dá Ádámù àti Éfà sí ọ̀run kí wọ́n máa bímọ síbẹ̀ káwọn èèyàn lè máa gbé ní ọ̀run, nítorí pé ó ti dá àwọn áńgẹ́lì tẹ́lẹ̀ láti máa gbé ní ọ̀run. (Jóòbù 38:4, 7) Kàkà bẹ́ẹ̀, inú Párádísè kan tá à ń pè ní ọgbà Édẹ́nì ni Ọlọ́run fi ọkùnrin àkọ́kọ́ sí pé kó máa gbé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17) Jèhófà fún òun àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ní àǹfààní láti máa wà títí láé lórí ilẹ̀ ayé.Ka Sáàmù 37:29; 115:16.

Ní ìbẹ̀rẹ̀, ọgbà Édẹ́nì nìkan ló jẹ́ Párádísè. Ọlọ́run fẹ́ kí tọkọtaya àkọ́kọ́ náà bímọ, kí wọ́n sì fi àwọn ọmọ wọn kún ilẹ̀ ayé. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n á máa gbé ní gbogbo ayé, wọ́n á sì sọ ayé di Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ayé yìí kò ní pa run láé. Ńṣe ni ayé yìí máa jẹ́ ibùgbé àwa èèyàn títí láé.Ka Sáàmù 104:5.

2. Kí nìdí tí ayé yìí kò fi jẹ́ Párádísè báyìí?

Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, torí náà Jèhófà lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà náà. Bí wọ́n ṣe pàdánù Párádísè nìyẹn, kò sì sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó tíì lè dá a pa dà. Bíbélì sọ pé: “Ilẹ̀ ayé ni a ti fi lé ọwọ́ ẹni burúkú.”—Jóòbù 9:24.Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:23, 24.

Ṣé Jèhófà ti gbàgbé ohun tó ní lọ́kàn fún àwa èèyàn níbẹ̀rẹ̀? Rárá! Ọlọ́run ní agbára tó ju gbogbo agbára lọ. Kò lè kùnà láé. (Aísáyà 45:18) Ó máa rí sí i pé àwọn èèyàn pa dà gbé nínú Párádísè.Ka Sáàmù 37:11, 34.

3. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa dá Párádísè náà pa dà?

Ayé máa pa dà di Párádísè nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run fi jẹ. Nínú ogun kan tó ń jẹ́ Amágẹ́dọ́nì, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá  Ọlọ́run run. Lẹ́yìn náà ni Jésù yóò wá fi Sátánì sẹ́wọ̀n fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún. Ogun yìí kò ní pa àwọn èèyàn Ọlọ́run run torí pé Jésù máa tọ́ wọn sọ́nà á sì dáàbò bò wọ́n. Wọ́n máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.Ka Ìṣípayá 20:1-3; 21:3, 4.

4. Ìgbà wo ni èèyàn ò ní jìyà mọ́?

Ìgbà wo ni Ọlọ́run máa mú ìwà ibi kúrò láyé? Jésù fún wa ní “àmì” kan tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí ń wu ẹ̀mí àwọn èèyàn léwu, èyí sì jẹ́ ká mọ̀ pé “ìparí ètò àwọn nǹkan” la wà báyìí.Ka Mátíù 24:3, 7-14, 21, 22.

Lákòókò ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún tí Jésù fi máa ṣàkóso aráyé látọ̀run wá, ó máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé. (Aísáyà 9:6, 7; 11:9) Yàtọ̀ sí pé Jésù máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba, ó tún máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, èyí á sì mú kó mú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kúrò. Lọ́nà yìí, Ọlọ́run máa tipasẹ̀ Jésù mú àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú kúrò pátápátá.Ka Aísáyà 25:8; 33:24.

5. Àwọn wo ló máa gbé nínú Párádísè tó ń bọ̀?

Ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, wàá rí àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n ní láti ṣe kí wọ́n lè wu Ọlọ́run

Àwọn èèyàn tó ṣègbọràn sí Ọlọ́run ni yóò gbé nínú Párádísè. (1 Jòhánù 2:17) Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ wá àwọn ọlọ́kàn tútù kí wọ́n sì kọ́ wọn ní ohun tí wọ́n máa ṣe láti rí ojú rere Ọlọ́run. Lóde òní, Jèhófà ń kó ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jọ kí wọ́n lè gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀. (Sefanáyà 2:3) Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn èèyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ọkọ, bàbá, aya àti ìyá tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. Àwọn ọmọ àtàwọn òbí wọn ń jọ́sìn pa pọ̀, wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe lè jàǹfààní látinú ìròyìn ayọ̀.Ka Míkà 4:1-4.