1. Ìròyìn wo ló wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn èèyàn máa gbádùn gbígbé lórí ilẹ̀ ayé. Ó dá ayé àti ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ aráyé. Láìpẹ́ sí àkókò yìí, Ọlọ́run máa mú kí ayé dára fún àwọn èèyàn níbi gbogbo. Ó máa mú gbogbo ohun tó ń fìyà jẹ aráyé kúrò pátápátá.Ka Jeremáyà 29:11.

Kò tíì sí ìjọba kankan tó tíì ṣàṣeyọrí láti mú ìwà ipá, àìsàn tàbí ikú kúrò. Àmọ́, kíyè sí ìròyìn ayọ̀ yìí. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú gbogbo ìjọba èèyàn kúrò yóò sì fìdí ìjọba tirẹ̀ múlẹ̀. Àwọn tó bá wà lábẹ́ àkóso ìjọba rẹ̀ yóò gbádùn àlàáfíà àti ìlera tó jí pépé.Ka Aísáyà 25:8; 33:24; Dáníẹ́lì 2:44.

2. Kí nìdí tí ìròyìn ayọ̀ náà fi jẹ́ kánjúkánjú?

Ìgbà tí Ọlọ́run bá pa àwọn èèyàn búburú run nìkan ni ìyà tó ń jẹ aráyé máa dópin. (Sefanáyà 2:3) Ìgbà wo ni èyí máa ṣẹlẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ àwọn ìṣòro tó ńbá aráyé fínra lákòókò wa yìí tẹ́lẹ̀. Àwọn nǹkan búburú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí jẹ́ ká mọ̀ pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ ayé yìí.Ka 2 Tímótì 3:1-5.

3. Kí ló yẹ ká ṣe?

Ó yẹ kí á kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn Bíbélì. Bíbélì dà bí lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ Bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Ó sọ bá a ṣe lè gbádùn ìgbésí ayé wa nísinsìnyí àti bá a ṣe lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Òótọ́ ni pé inú àwọn kan lè má dùn sí ọ pé o fẹ́ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, tó o bá ń ronú nípa ọjọ́ iwájú aláyọ̀ tí Ọlọ́run ṣèlérí fún ọ, o kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí ọ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.Ka Òwe 29:25; Ìṣípayá 14:6, 7.