Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 7

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

1. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù ni Ọba tọ́ sí?MÁÀKÙ 1:40-42.

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan ní ọ̀run. Òun ló máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, á sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run. Ìròyìn ayọ̀ lọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. Ìjọba Ọlọ́run máa tó ṣe gbogbo ohun tí àwọn èèyàn ń fẹ́ kí ìjọba rere ṣe fún wọn. Ó máa mú kí gbogbo èèyàn tó wà láyé wà níṣọ̀kan.Ka Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10; 24:14.

Ìlú kì í wà láìní olórí. Jèhófà ti yan Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run.Ka Ìṣípayá 11:15.

2. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù ni Ọba tọ́ sí?

Ọmọ Ọlọ́run ni Ọba tọ́ sí torí pé ó jẹ́ onínúure, ohun tó tọ́ ló sì máa ń ṣe nígbà gbogbo. (Jòhánù 1:14) Yàtọ̀ síyẹn, ó lágbára láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nítorí pé láti ọ̀run ni yóò ti máa ṣàkóso ayé. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí i dìde, ó lọ sí ọ̀run ó sì jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà. (Hébérù 10:12, 13) Nígbà tó yá, Ọlọ́run fún un láṣẹ pé kí ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso.Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14.

3. Àwọn wo ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù?

Àwọn kan tí Bíbélì pè ní àwọn “ẹni mímọ́” yóò ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. (Dáníẹ́lì 7:27) Àwọn àpọ́sítélì Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ni àwọn ẹni mímọ́ tí Ọlọ́run kọ́kọ́ yàn. Títí di àkókò wa yìí, Jèhófà ṣì ń yan àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́. Bí i ti Jésù, Ọlọ́run ń jí wọn dìde gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí.Ka Jòhánù 14:1-3; 1 Kọ́ríńtì 15:42-44.

 Àwọn mélòó ló máa lọ sí ọ̀run? Jésù pè wọ́n ní “agbo kékeré.” (Lúùkù 12:32) Iye wọn máa wá jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. Àwọn pẹ̀lú Jésù jọ máa ṣàkóso ayé.Ka Ìṣípayá 14:1.

4. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso?

Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọdún 1914. * Ohun tí Jésù kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn tó di Ọba ni pé ó lé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀run wá sí ayé. Inú bí Sátánì gan-an, ó sì wá ń dá wàhálà sílẹ̀ ní gbogbo ayé. (Ìṣípayá 12:7-10, 12) Látìgbà yẹn, ìṣòro tó ń bá aráyé fínra ti wá kọjá àfẹnusọ. Ogun, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìsẹ̀lẹ̀ wà lára “àmì” tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé pátá.Ka Lúùkù 21:7, 10, 11, 31.

5. Kí lohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?

Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe kárí ayé, Ìjọba Ọlọ́run ti ń mú kí ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè wà níṣọ̀kan. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọlọ́kàn tútù èèyàn ti ń fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkoso Jésù. Ìjọba Ọlọ́run máa dáàbò bò wọ́n nígbà tó bá pa ayé búburú yìí run. Torí náà, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ jọlá Ìjọba Ọlọ́run ní láti máa ṣègbọràn sí Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run.Ka Ìṣípayá 7:9, 14, 16, 17.

Láàárín ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún kan, Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ fún aráyé. Gbogbo ayé yóò di Párádísè. Níkẹyìn, Jésù yóò dá Ìjọba náà pa dà fún Baba rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:24-26) Ǹjẹ́ ẹnì kan wà tó máa wù ẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún?Ka Sáàmù 37:10, 11, 29.

 

^ ìpínrọ̀ 6 Tó o bá fẹ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe tọ́ka sí ọdún 1914, wo ojú ìwé 215 sí 218 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?