Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 13

Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?

Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?

1. Ṣé gbogbo ẹ̀sìn ló dára?

Àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo wà nínú gbogbo ìsìn. Ìròyìn ayọ̀ ló jẹ́ pé Ọlọ́run ń rí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àìmọye ìwà burúkú ni àwọn èèyàn ti hù lórúkọ ìsìn. (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4; 11:13-15) Àwọn ìròyìn tó ń jáde fi hàn pé, kódà àwọn ẹ̀sìn kan ń lọ́wọ́ nínú ìpániláyà, ìpẹ̀yàrun, ogun àti híhùwà àìdáa sí àwọn ọmọdé. Ẹ wo bí àwọn nǹkan yìí á ṣe máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn olóòótọ́ ọkàn tó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run!Ka Mátíù 24:3-5, 11, 12.

Ńṣe ni ìsìn tòótọ́ ń fògo fún Ọlọ́run àmọ́ ìsìn èké kò mú inú Ọlọ́run dùn. Ìsìn èké ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ tí kò sí nínú Bíbélì, títí kan àwọn ẹ̀kọ́ tí kì í ṣe òótọ́ nípa Ọlọ́run àti nípa ipò tí àwọn òkú wà. Àmọ́, Jèhófà fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa òun.Ka Ìsíkíẹ́lì 18:4; 1 Tímótì 2:3-5.

2. Ìròyìn ayọ̀ wo ló wà nípa ìsìn?

Ohun kan ni pé àwọn ẹ̀sìn èké tí wọ́n sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àmọ́ tó jẹ́ pé ayé Sátánì ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ kò lè tan Ọlọ́run jẹ. (Jákọ́bù 4:4) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pe gbogbo ẹ̀sìn èké ní “Bábílónì Ńlá.” Bábílónì ni orúkọ ìlú ìgbàanì kan tí ẹ̀sìn èké ti bẹ̀rẹ̀ ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú ìparun bá àwọn ẹ̀sìn tó ń tan àwọn èèyàn jẹ, tó sì ń ni àwọn èèyàn lára, òjijì ni ìparun náà máa dé.Ka Ìṣípayá 17:1, 2, 5, 16, 17; 18:8.

Ìròyìn ayọ̀ náà kò tíì tán. Jèhófà kò gbàgbé àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n wà nínú àwọn ẹ̀sìn èké kárí ayé. Ọlọ́run ti ń kó wọn jọ sí ojú kan ní ti pé ó ń kọ́ wọn ní òtítọ́.Ka Míkà 4:2, 5.

 3. Kí ló yẹ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ṣe?

Ẹ̀sìn tòótọ́ ń mú kí àwọn èèyàn wà níṣọ̀kan

Jèhófà ń bójú tó àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti ohun tó dára. Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò nínú ìsìn èké. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run múra tán láti ṣàtúnṣe kí wọ́n lè mú inú Ọlọ́run dùn.Ka Ìṣípayá 18:4.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, nígbà tí àwọn olóòótọ́ ọkàn gbọ́ ìròyìn ayọ̀ látẹnu àwọn àpọ́sítélì, inú wọn dùn gan-an ni. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà ìgbésí ayé tuntun látọ̀dọ̀ Jèhófà, ọ̀nà ìgbésí ayé tó ń múnú ẹni dùn, tó nítumọ̀ tó sì ń mú kéèyàn nírètí. Àpẹẹrẹ rere ni wọ́n jẹ́ fún wa lónìí, torí pé wọ́n fi hàn pé àwọn mọyì ìròyìn ayọ̀ náà nípa fífi Jèhófà ṣe ẹni àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn.Ka 1 Tẹsalóníkà 1:8, 9; 2:13.

Tọwọ́tẹsẹ̀ ni Jèhófà ń gba kí àwọn tó bá jáde kúrò nínú ẹ̀sìn èké dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀, tí wọ́n dà bí ìdílé rẹ̀. Tó o bá wá sọ́dọ̀ Jèhófà, wàá di ọ̀rẹ́ rẹ̀, wàá di ara ìdílé tí ìfẹ́ wà láàárín wọn, ìyẹn àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà, wàá sì tún rí ìyè àìnípẹ̀kun.Ka Máàkù 10:29, 30; 2 Kọ́ríńtì 6:17, 18.

4. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú kí gbogbo ayé láyọ̀?

Ìròyìn ayọ̀ ló jẹ́ pé Ọlọ́run máa pa ìsìn èké run. Kárí ayé ni àwọn èèyàn máa rí ìtura. Ìsìn èké kò tún ní ṣi àwọn èèyàn lọ́nà mọ́ láé, aráyé ò sì ní pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ mọ́. Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ni gbogbo èèyàn tó wà láyé yóò máa sin.Ka Ìṣípayá 18:20, 21; 21:3, 4.