Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 3

Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Ìròyìn Ayọ̀ Ti Wá Lóòótọ́?

Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Ìròyìn Ayọ̀ Ti Wá Lóòótọ́?

1. Ta ni Òǹṣèwé Bíbélì?

Inú Bíbélì la ti rí ìròyìn ayọ̀ tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29) Àwọn ìwé kéékèèké mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ló para pọ̀ di Bíbélì. Nǹkan bí ogójì [40] olóòótọ́ ọkùnrin ni Ọlọ́run lò láti kọ àwọn ìwé yìí. Mósè ló kọ àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn. Àpọ́sítélì Jòhánù ló kọ ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ọdún sẹ́yìn. Èrò ta ni àwọn tó kọ Bíbélì kọ sílẹ̀? Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti bá àwọn tó kọ Bíbélì sọ̀rọ̀. (2 Sámúẹ́lì 23:2) Èrò Ọlọ́run ni wọ́n kọ sílẹ̀ kì í ṣe tiwọn. Torí náà Jèhófà ni Òǹṣèwé Bíbélì.Ka 2 Tímótì 3:16; 2 Pétérù 1:20, 21.

2. Báwo la ṣe mọ̀ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?

A mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá torí pé ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Kò sí ẹ̀dá èèyàn tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Jóṣúà 23:14) Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la aráyé tó sì máa rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.Ka Aísáyà 42:9; 46:10.

A máa retí pé kí ìwé tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ìwé kan tí kò láfiwé, bọ́rọ̀ sì ṣe rí náà nìyẹn. Ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dà Bíbélì ni wọ́n ti tẹ̀ jáde ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Òótọ́ ni pé ọjọ́ ti pẹ́ tí Bíbélì ti wà, àmọ́ ó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Bákan náà, nǹkan bí ogójì èèyàn tó kọ ìwé náà kò ta ko ara wọn. * Síwájú sí i, Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní, Bíbélì yìí sì tún lágbára láti yí ìgbésí ayé ẹni pa dà sí rere. Àwọn ẹ̀rí yìí ló mú kí ó dá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13.

 3. Kí ni Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gan-an?

Ìròyìn ayọ̀ nípa ohun ribiribi tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé ló wà nínú Bíbélì. Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé bí ẹ̀dá èèyàn ṣe pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé láìpẹ́ sí ìgbà tí Ọlọ́run dá èèyàn, ó sì tún sọ bí ayé ṣe máa pa dà di Párádísè.Ka Ìṣípayá 21:4, 5.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún ní àwọn òfin, ìlànà àti ìmọ̀ràn nínú. Láfikún, ìtàn nípa bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn èèyàn lò wà nínú Bíbélì, ìtàn yìí sì jẹ́ kí á mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Nígbà náà, Bíbélì lè jẹ́ kó o mọ Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé bó o ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.Ka Sáàmù 19:7, 11; Jákọ́bù 2:23; 4:8.

4. Báwo lo ṣe lè lóye ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?

Ìwé yìí máa jẹ́ kó o lóye ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lọ́nà tí Jésù máa ń gbà mú kí àwọn èèyàn lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù máa ń tọ́ka sí ọ̀kan-ò-jọ̀kan ẹsẹ Bíbélì, ó sì máa ń ṣàlàyé “ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.”Ka Lúùkù 24:27, 45.

Kò sí ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra bí ìròyìn ayọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn èèyàn kan wà tí wọn kì í fẹ́ gbọ́ ìròyìn ayọ̀, ó tiẹ̀ máa ń bí àwọn míì nínú. Má tìtorí ìyẹn sọ pé o ò ní kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Ó ṣe pàtàkì pé kó o mọ Ọlọ́run tó o bá máa rí ìyè àìnípẹ̀kun.Ka Jòhánù 17:3.

 

^ ìpínrọ̀ 7 Wo ìwé pẹlẹbẹ tá a pè ní, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn.