Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 6

Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

1. Ìròyìn ayọ̀ wo ló wà nípa àwọn tó ti kú?

Nígbà tí Jésù máa fi dé sí Bẹ́tánì nítòsí Jerúsálẹ́mù, ó ti di ọjọ́ kẹrin tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lásárù ti kú. Jésù tẹ̀ lé Màríà àti Màtá tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n ẹni tó kú náà lọ sí ibi tí wọ́n sin ín sí. Kò pẹ́, èrò ti pé jọ. Wo bí inú Màtá àti Màríà ti máa dùn tó nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde!Ka Jòhánù 11:21-24, 38-44.

Màtá ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìròyìn ayọ̀ kan wà nípa àwọn tó ti kú. Ó mọ̀ pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde láti tún pa dà máa gbé lórí ilẹ̀ ayé.Ka Jóòbù 14:14, 15.

2. Ipò wo ni àwọn òkú wà?

Ọlọ́run sọ fún Ádámù pé: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” —JẸ́NẸ́SÍSÌ 3:19.

Erùpẹ̀ ni Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá àwa èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; 3:19) A kì í ṣe ẹ̀dá ẹ̀mí tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀. Ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara ni wá, torí náà kò sí ohun kankan lára wa tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn tá a bá kú. Tá a bá ti kú ọpọlọ wa parí iṣẹ́ nìyẹn, a kò tún lè ronú mọ́. Fún ìdí yìí, Lásárù kò sọ pé òun rí ohunkóhun nígbà tóun kú, torí pé ẹni tó ti kú kò mọ ohunkóhun mọ́.Ka Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5, 6, 10.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń dá àwọn èèyàn lóró nínú iná lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú? Níwọ̀n bí Bíbélì ti jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun, ó ṣe kedere pé ẹ̀kọ́ èké ni ẹ̀kọ́ nípa iná ọ̀run àpáàdì, ńṣe ni àwọn tó sì ń fi irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ni ń ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́. Ohun ìríra gbáà ló jẹ́ lójú Ọlọ́run pé kéèyàn máa joró nínú iná.Ka Jeremáyà 7:31.

 3. Ǹjẹ́ àwọn òkú lè bá wa sọ̀rọ̀?

Àwọn òkú ò lè sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò lè gbọ́ràn. (Sáàmù 115:17) Àmọ́ àwọn áńgẹ́lì kan burú, wọ́n sì lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ẹni tó kú náà ló ń sọ̀rọ̀. (2 Peter 2:4) Jèhófà kò fẹ́ kí á máa wá bá a ṣe máa bá òkú sọ̀rọ̀.Ka Diutarónómì 18:10, 11.

4. Àwọn wo ni Ọlọ́run máa jí dìde?

Àìmọye àwọn èèyàn tó ti kú tí wọ́n wà nínú ibojì ni Ọlọ́run máa jí pa dà sáyé. Kódà Ọlọ́run máa jí àwọn kan tí kò mọ Ọlọ́run tí wọ́n sì ti hùwà búburú kí wọ́n tó kú.Ka Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15.

Àwọn tí Ọlọ́run bá jí dìde máa ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run kí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù nípa ṣíṣègbọràn sí i. (Ìṣípayá 20:11-13) Àwọn tó bá ṣe rere lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí wọn dìde máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.Ka Jòhánù 5:28, 29.

5. Kí ni àjíǹde jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?

Bí Ọlọ́run ṣe rán Ọmọ rẹ̀ pé kí ó wá kú nítorí wa ló jẹ́ kí ìrètí wà fún àwọn òkú. Torí náà, àjíǹde kọ́ wa pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó jẹ́ onínúure. Nígbà tí àwọn òkú bá jíǹde, ta ló ń wù ẹ́ gan-an pé kó o rí?Ka Jòhánù 3:16; Róòmù 6:23.