1. Kí nìdí tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà?

Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè mú kí á yẹra fún ohun tó lè fẹ̀mí wa wewu?—SÁÁMÙ 36:9.

Ẹlẹ́dàá wa gbọ́n jù wá lọ. Nítorí pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni, ó ń bójú tó wa gan-an. Bákan náà, kò ní in lọ́kàn pé kí àwa èèyàn máa gbé ìgbé ayé wa láìsí ìtọ́sọ́nà òun. (Jeremáyà 10:23) Torí náà, bó ṣe ṣe pàtàkì pé kí òbí kan tọ́ ọmọ rẹ̀ kékeré sọ́nà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì pé kí Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà. (Aísáyà 48:17, 18) Àwọn ìlànà Bíbélì ló ń jẹ́ ká mọ ìtọ́sọ́nà tó dà bí ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ka 2 Tímótì 3:16.

Àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà ń kọ́ wa ní ọ̀nà téèyàn lè gbà gbé ìgbésí ayé tó dára jù lọ nísinsìnyí, ó sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá wa, ó jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu pé ká mọyì ìtọ́sọ́nà rẹ̀, ká sì máa tẹ̀ lé e. Ka Sáàmù 19:7, 11; Ìṣípayá 4:11.

2. Kí ni ìlànà Bíbélì?

Àwọn ìlànà Bíbélì jẹ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì téèyàn lè lò nínú ipò tó yàtọ̀ síra. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, òfin lè wáyé nítorí ohun kan pàtó. (Diutarónómì 22:8) Ó gba pé kéèyàn ronú jinlẹ̀ gan-an kéèyàn lè mọ bó ṣe máa fi ìlànà kan sílò nínú ọ̀ràn kan pàtó. (Òwe 2:10-12) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run ló mú kí á wà láàyè. A lè lo Ìlànà yìí lẹ́nu iṣẹ́, nínú ilé àti nígbà tá a bá ń rìnrìn àjò. Ìlànà yìí ń mú ká yẹra fún ohunkóhun tó lè fi ẹ̀mí ẹni wewu. Ka Ìṣe 17:28.

3. Àwọn ìlànà méjì wo ló ṣe pàtàkì jù?

Jésù sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìlànà méjì tó ṣe pàtàkì jù. Èyí àkọ́kọ́ sọ nípa ìdí tí àwa èèyàn fi wà láàyè, ìyẹn ni pé ká lè mọ Ọlọ́run, ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì máa fòótọ́ inú sìn ín. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí  ìlànà àkọ́kọ́ yìí máa darí wa nínú gbogbo ìpinnu tá a bá ń ṣe. (Òwe 3:6) Àwọn tó bá ń fi ìlànà yìí sílò máa di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, wọ́n á ní ojúlówó ayọ̀, wọ́n á sì rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ka Mátíù 22:36-38.

Ìlànà kejì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. (1 Kọ́ríńtì 13:4-7) A ń fi ìlànà kejì yìí sílò tá a bá ń hùwà sí àwọn èèyàn bí Ọlọ́run ṣe máa ń ṣe sí wa. Ka Mátíù 7:12; 22:39, 40.

4. Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe ń ṣe wá láǹfààní?

Àwọn ìlànà Bíbélì máa ń jẹ́ kí àwọn ìdílé mọ bí wọ́n ṣe lè gbé pa pọ̀ tìfẹ́tìfẹ́. (Kólósè 3:12-14) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún máa ń dáàbò bo àwọn ìdílé ní ti pé ó jẹ́ kí wọ́n mọ ìlànà míì tó ń ṣeni láǹfààní, ìyẹn ni pé okùn alọ́májàá ni ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́. Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:24.

Tá a bá ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì sílò, àtijẹ àtimu kò ní wọ́n wa, a ò sì ní máa ṣe ohun tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn agbaniṣíṣẹ́ máa ń mọyì àwọn òṣìṣẹ́ tó máa ń fi ìlànà Bíbélì sílò, èyí tó sọ pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ àti aláápọn. (Òwe 10:4, 26; Hébérù 13:18) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún kọ́ wa pé ká ní ìtẹ́lọ́rùn tá a bá ti ní àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémáàní, ká sì ka níní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run sí ohun tó ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan ti ara lọ. Ka Mátíù 6:24, 25, 33; 1 Tímótì 6:8-10.

A máa ní ìlera tó dára tá a bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò. (Òwe 14:30; 22:24, 25) Bí àpẹẹrẹ, téèyàn bá ń ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run tó sọ pé a kò gbọ́dọ̀ mutí ní ìmukúmu, èèyàn ò ní tipa ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí àti jàǹbá. (Òwe 23:20) Jèhófà kò sọ pé ká má ṣe mu ọtí líle, àmọ́ ìwọ̀nba ló sọ pé kí á mu. (Sáàmù 104:15; 1 Kọ́ríńtì 6:10) Àwọn ìlànà Ọlọ́run ń ṣe wá láǹfààní ní ti pé ó jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe ohun tá à ń ṣe nìkan la gbọ́dọ̀ kíyè sí, a tún gbọ́dọ̀ kíyè sí ohun tá à ń rò. (Sáàmù 119:97-100) Síbẹ̀, kì í ṣe tórí pé àwọn ìlànà Ọlọ́run wulẹ̀ ń ṣe wá láǹfààní la fi ń tẹ̀ lé e. À ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé à ń bọlá fún Jèhófà. Ka Mátíù 5:14-16.