Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 8

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?

1. Báwo ni ìwà ibi ṣe bẹ̀rẹ̀?

Àkókò tí Ọlọ́run fi gba àwọn èèyàn láyè láti ṣàkóso ara wọn ti pọ̀ tó láti fi hàn pé èèyàn kò lè yanjú ìṣòro aráyé

Ìwà ibi bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Sátánì pa irọ́ àkọ́kọ́. Áńgẹ́lì pípé ni Sátánì nígbà tí Ọlọ́run dá a, àmọ́ ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.’ (Jòhánù 8:44) Ó jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ máa fà sí ohun tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, ó fẹ́ kí àwọn èèyàn máa jọ́sìn òun dípò Ọlọ́run. Sátánì parọ́ fún Éfà obìnrin àkọ́kọ́ náà, ó sì mú kí ó ṣègbọràn sí òun dípò kí ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ádámù dara pọ̀ mọ́ Éfà, òun náà sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ìpinnu tí Ádámù ṣe yọrí sí ìjìyà àti ikú.Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 19.

Nígbà tí Sátánì ń tan Éfà láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ńṣe ni Sátánì ń dáná ọ̀tẹ̀ sí ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run tàbí sí ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ẹni Gíga Jù Lọ. Èyí tó pọ̀ jù nínú aráyé ló ti dara pọ̀ mọ́ Sátánì tí wọn kò sì fẹ́ kí Ọlọ́run máa ṣàkóso àwọn. Nípa bẹ́ẹ̀, Sátánì ti wá di “olùṣàkóso ayé.”Ka Jòhánù 14:30; 1 Jòhánù 5:19..

2. Ṣé àbùkù wà nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá?

Gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ló jẹ́ pípé. Àtèèyàn àtàwọn áńgẹ́lì tí Ọlọ́run dá ló lè yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run láìyẹhùn. (Diutarónómì 32:4, 5) Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá àwa èèyàn ni pé, ó fún wa ní òmìnira láti yàn bóyá ká ṣe rere tàbí ká ṣe búburú. Òmìnira yìí fún wa ní àǹfààní láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.Ka Jákọ́bù 1:13-15; 1 Jòhánù 5:3.

3. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà títí di báyìí?

Látìgbà yẹn wá, Jèhófà ti fàyè gba ọ̀tẹ̀ tí wọ́n ṣe sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé wọn ò lè jàǹfààní kankan nínú ìṣàkóso tí òun kò bá lọ́wọ́ sí. (Oníwàásù 7:29; 8:9)  Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà tí ẹ̀dá èèyàn ti wà láyé, ọ̀rọ̀ náà ti wá yé gbogbo èèyàn báyìí. Àwọn ẹ̀dà èèyàn tó jẹ́ alákòóso ti kùnà láti mú ogun, ìwà ọ̀daràn, àìṣẹ̀tọ́ tàbí àìsàn kúrò. Ka Jeremáyà 10:23; Róòmù 9:17.

Ìṣàkóso Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sí ti èèyàn, àwọn tó fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ń jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀. (Aísáyà 48:17, 18) Láìpẹ́, Jèhófà máa pa gbogbo ìjọba èèyàn run. Àwọn èèyàn tó bá gbà pé kí Ọlọ́run máa ṣàkóso àwọn nìkan ni yóò máa gbé láyé.—Aísáyà 11:9.Ka Dáníẹ́lì 2:44.

4. Kí ni sùúrù Ọlọ́run mú kí á lè ṣe?

Sátánì sọ pé ìgbà tá a bá ń rí nǹkan gbà lọ́wọ́ Jèhófà nìkan la máa sin Jèhófà, pé kò sí ẹnì kankan tó máa sin Jèhófà torí pé ó dìídì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ṣé ó wù ẹ́ láti fi hàn pé irọ́ ni ohun tí Sátánì sọ yìí? O lè ṣe bẹ́ẹ̀! Sùúrù Ọlọ́run ń fún gbogbo wa ní àǹfààní láti fi hàn bóyá ìṣàkóso Ọlọ́run la fara mọ́ tàbí ìṣàkóso èèyàn. Bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa ló máa fi èyí tá a fara mọ́ hàn.Ka Jóòbù 1:8-12; Òwe 27:11.

5. Báwo la ṣe lè yan Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Alákòóso wa?

Awọn ohun tá à ń ṣe ló máa fi hàn bóyá a gba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Alákòóso wa

A lè yan Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Alákòóso wa nípa wíwá ìsìn tòótọ́ tí ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ bá Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu, ká sì dara pọ̀ mọ́ ìsìn náà. (Jòhánù 4:23) Láti fi hàn pé a ò fẹ́ kí Sátánì jẹ́ alákòóso wa, àpẹẹrẹ Jésù ló yẹ ká máa tẹ̀ lé, ká má ṣe lọ́wọ́ nínú ìṣèlú àti ogun.Ka Jòhánù 17:14.

Sátánì ń lo agbára rẹ̀ láti mú kí àwọn èèyàn máa wo ìṣekúṣe àti ìwàkiwà bí ohun tí kò burú. Tí a kò bá lọ́wọ́ nínú irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìbátan wa kan lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n gbógun tì wá. (1 Pétérù 4:3, 4) Ọwọ́ wa ni ọ̀rọ̀ kù sí báyìí. Ṣé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run la máa dara pọ̀ mọ́? Ṣé òfin rẹ̀ tó mọ́gbọ́n dání, tó sì fìfẹ́ hàn la máa tẹ̀ lé? Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé a fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì tó sọ pé a ò ní ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ lákòókò ìṣòro. Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 15:33.

Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún aráyé mú kó dá wa lójú pé ìwà ibi àti ìjìyà máa dópin. Àwọn tó lo ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ yìí máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.Ka Jòhánù 3:16.

 

Mọ Púpọ̀ Sí I

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ́ àwa èèyàn. Kí lèrò rẹ? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó fa ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn.