Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 14

Kí Nìdí tí Ọlọ́run Fi Ní Ètò Kan?

Kí Nìdí tí Ọlọ́run Fi Ní Ètò Kan?

1. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ṣètò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ bí àwùjọ kan?

Ọlọ́run ṣètò àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, ó sì fún wọn ní àwọn òfin tí wọ́n á máa tẹ̀ lé. Ó pe àwọn èèyàn náà ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ ìjọsìn tòótọ́ àti agbátẹrù ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 147:19, 20) Àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè lè wá tipa bẹ́ẹ̀ jàǹfààní látara Ísírẹ́lì.Ka Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

Ọlọ́run yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ìtàn bí Ọlọ́run ṣe bá wọn lò nígbà àtijọ́ jẹ́ kí a mọ bí èèyàn ṣe lè jàǹfààní téèyàn bá pa òfin Ọlọ́run mọ́. (Diutarónómì 4:6) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn míì lè tipa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá mọ Ọlọ́run tòótọ́. Ka Aísáyà 43:10, 12.

2. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́?

Nígbà tó yá, orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì pàdánù ojú rere Ọlọ́run, Jèhófà sì fi ìjọ Kristẹni rọ́pò wọn. (Mátíù 21:43; 23:37, 38) Ní báyìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ni ẹlẹ́rìí fún Jèhófà dípò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.Ka Ìṣe 15:14, 17.

Jésù ṣètò àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti wàásù kí wọ́n sì sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 10:7, 11; 24:14; 28:19, 20) Ní báyìí, a ti wà ní ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, iṣẹ́ yẹn sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Fun ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn aráyé, Jèhófà mú kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo kóra jọ pọ̀ sínú ẹ̀sìn tòótọ́. (Ìṣípayá 7:9, 10) Ọlọ́run ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́ kí wọ́n lè máa fún ara wọn níṣìírí, kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́. Kárí ayé, wọ́n ń gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan náà ní àwọn ìpàdé wọn.Ka Hébérù 10:24, 25.

 3. Báwo ni ètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti òde òní ṣe bẹ̀rẹ̀?

Láàárín ọdún 1870 sí 1879, àwùjọ kékeré kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàwárí àwọn òtítọ́ Bíbélì kan tó ti dàwátì nínú ẹ̀sìn Kristẹni láti ọjọ́ pípẹ́. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù ṣètò ìjọ Kristẹni láti wàásù, torí náà wọ́n tara bọ iṣẹ́ ìwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Nígbà tó di ọdún 1931, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà.Ka Ìṣe 1:8; 2:1, 4; 5:42.

4. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ìjọ Kristẹni tó wà ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ máa ń jàǹfààní látàrí ìtọ́ni tí wọ́n ń rí gbà látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí tó ń ṣojú fún Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ. (Ìṣe 16:4, 5) Bákan náà ni ọ̀rọ̀ rí lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń jàǹfààní lábẹ́ ìdarí àwọn alàgbà onírìírí tí wọ́n wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi tá a ti ń túmọ̀ àwọn ìwé tá a gbé ka Bíbélì sí èdè tó lé ní ẹgbẹ̀ta [600], tá a ti ń tẹ̀ wọ́n, tá a sì ń pín wọn kiri. Èyí mú kí ó ṣeé ṣe fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí láti pèsè ìtọ́ni àti ìṣírí nípa tẹ̀mí fún àwọn ìjọ tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] kárí ayé. Ní ìjọ kọ̀ọ̀kan, àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, a sì tún lè pè wọ́n ní alábòójútó. Tìfẹ́tìfẹ́ ni àwọn ọkùnrin yìí máa ń bójú tó agbo Ọlọ́run. Ka 1 Pétérù 5:2, 3.

Ọlọ́run ṣètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti wàásù ìròyìn ayọ̀ kí á sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Bíi ti àwọn àpọ́sítélì, a máa ń wàásù láti ilé dé ilé. (Ìṣe 20:20) A tún máa ń kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ètò ṣákálá kan. Ìdílé kan ṣoṣo ni wá, Baba wa sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ńṣe la dà bí ọmọ ìyá, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa. (2 Tẹsalóníkà 1:3) Níwọ̀n bí Jèhófà ti ṣètò àwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n lè wu òun, kí wọ́n sì ran àwọn míì lọ́wọ́, àwọn lá lè pè ní ìdílé tó láyọ̀ jù lọ láyé.Ka Sáàmù 33:12; Ìṣe 20:35.