Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìwé Yìí

Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìwé Yìí

Ìwé yìí máa mú kó o lè fojú ara rẹ̀ rí ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí ní ìparí àwọn ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn kà nínú Bíbélì rẹ sí àwọn ìbéèrè tá a kọ lọ́nà tó dúdú yàtọ̀.

Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, ronú lórí bí wọ́n ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè náà. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn gan-an láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye ohun tí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ń sọ.Ka Lúùkù 24:32, 45.

Àkíyèsí: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ gbogbo ìwé tá a tọ́ka sí nínú ìwé yìí.