1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ṣe ìgbéyàwó tí ìdílé bá máa láyọ̀?

Ọ̀dọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run aláyọ̀ tó ń fẹ́ kí ìdílé láyọ̀, ni ìròyìn ayọ̀ ti wá. (1 Tímótì 1:11) Òun ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Bí ìdílé bá máa láyọ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ìgbéyàwó lọ́nà tó bá òfin mu, torí pé ó máa jẹ́ kí wọ́n lè pa ọwọ́ pọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn. Àwọn Kristẹni ní láti tẹ̀ lé òfin orílẹ̀-èdè wọn nípa fífi orúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba.Ka Lúùkù 2:1, 4, 5.

Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó? Ó fẹ́ kí ìgbéyàwó dà bí okùn alọ́májàá láàárín ọkọ àti aya. Jèhófà fẹ́ kí tọkọtaya jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. (Hébérù 13:4) Ó kórìíra ìkọ̀sílẹ̀. (Málákì 2:16) Àmọ́, ó gba àwọn Kristẹni láyè pé kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì fẹ́ ẹlòmíì bí ọkọ tàbí aya wọn bá ṣe panṣágà.Ka Mátíù 19:3-6, 9.

2. Báwo ló ṣe yẹ kí tọkọtaya máa ṣe sí ara wọn?

Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin lọ́nà tí wọ́n á fi lè máa ṣèrànwọ́ fún ara wọn nínú ìgbéyàwó. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Ọkọ ni olórí ìdílé, ó yẹ kí ó máa pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa ti ara, kí ó sì máa kọ́ wọn nípa Ọlọ́run. Ó gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ tọkàntara, kó má ṣe jẹ́ pé ti ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀. Tọkọtaya gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Níwọ̀n bí àwọn tọkọtaya ti jẹ́ aláìpé, ohun pàtàkì tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn ni pé kí wọ́n máa dárí ji ara wọn.Ka Éfésù 4:31, 32; 5:22-25, 33; 1 Pétérù 3:7.

3. Ṣé ó yẹ kó o fi ọkọ tàbí aya rẹ sílẹ̀ torí pé kò sí ayọ̀ nínú ìgbéyàwó yín?

Bẹ́ ẹ bá ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó yín, ńṣe ni kí ẹ̀yin méjèèjì sapá gidigidi láti máa fi ìfẹ́ ba ara yín lò. (1 Kọ́ríńtì 13: 4, 5) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò fún tọkọtaya ní ìṣírí pé kí wọ́n pínyà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti yanjú àwọn ìṣòro tó wà nínú ìgbéyàwó.Ka 1 Kọ́ríńtì 7:10-13.

4. Ẹ̀yin ọmọ, kí ni Ọlọ́run fẹ́ kẹ́ ẹ máa ṣe?

Jèhófà fẹ́ kẹ́ ẹ láyọ̀. Ó fún yín ní ìmọ̀ràn tó dára jù tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ gbádùn ìgbà èwe yín. Ó fẹ́ kẹ́ ẹ kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọgbọ́n àti ìrírí àwọn òbí yín. (Kólósè 3:20) Jèhófà tún fẹ́ kẹ́ ẹ rí ayọ̀ nínú ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe fún Ẹlẹ́dàá yín àti fún Ọmọ rẹ̀.Ka Oníwàásù 11:9–12:1; Mátíù 19:13-15; 21:15, 16.

5. Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè mú kí àwọn ọmọ yín láyọ̀?

Ó yẹ kẹ́ ẹ ṣiṣẹ́ kára kẹ́ ẹ lè pèsè oúnjẹ, ibùgbé àti aṣọ fún àwọn ọmọ yín. (1 Tímótì 5:8) Àmọ́, kí àwọn ọmọ yin tó lè láyọ̀, ẹ tún gbọ́dọ̀ kọ́ wọn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. (Éfésù 6:4) Bí ẹ̀yìn fúnra yín bá ń fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, èyí máa mú kí àwọn ọmọ yín rí i pé ó yẹ kí àwọn náà nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ gbé ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ àwọn ọmọ yín kà, ó máa mú kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́.Ka Diutarónómì 6:4-7; Òwe 22:6.

Ara àwọn ọmọ máa ń yá gágá bẹ́ ẹ bá ń yìn wọ́n tẹ́ ẹ sì ń fún wọn níṣìírí. Ó tún ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ máa bá wọn wí, kẹ́ ẹ sì máa tọ́ wọn sọ́nà. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kí wọ́n sá fún ìwà tó lè kó ìbànújẹ́ bá wọn. (Òwe 22:15) Síbẹ̀, ẹ má ṣe fi ìbínú tàbí ìkanra bá wọn wí.Ka Kólósè 3:21.

Ọ̀pọ̀ ìwé ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dìídì ṣe láti ran àwọn òbí àtàwọn ọmọ lọ́wọ́. Àwọn àlàyé tó dá lórí Bíbélì ló wà nínú àwọn ìwé náà.Ka Sáàmù 19:7, 11.