Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

Kí ni ìròyìn àyọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà á gbọ́? Ìwé yìí dáhùn àwọn ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń béèrè nípa Bíbélì.

Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìwé Yìí

Ìwé yìí á mú kó o gbádùn àtimáa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wo bó o ṣe lè rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tọ́ka sí nínú Bíbélì rẹ.

Kí Ni Ìròyìn Ayọ̀ Náà?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú àti ohun tó yẹ kó o ṣe.

Ta Ni Ọlọ́run?

Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ, ǹjẹ́ ó sì nífẹ̀ẹ́ wa?

Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Ìròyìn Ayọ̀ Ti Wá Lóòótọ́?

Báwo la ṣe mọ̀ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?

Ta Ni Jésù Kristi?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tí Jésù fi kú, ohun tí ìràpadà jẹ́ àti ohun tí Jésù ń ṣe nísinsìnyí.

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ayé Yìí?

Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé àti ìgbà tí ìyà máa dópin àti bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí àti àwọn tó máa gbé nínú lórí ilẹ̀ ayé.

Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a kú? Ṣé a tún lè pa dà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ta ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, kí ni ìjọba náà sì máa ṣe?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?

Báwo ni ìwà ibi ṣe bẹ̀rẹ̀, kí sì nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gbà á títí di báyìí? Ṣé ìyà máa dópin láé?

Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀?

Jèhófà, Ọlọ́run aláyọ̀ fẹ́ kí ìdílé láyọ̀. Ká nípa àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó lè mú kí ọkọ, aya, òbí àtàwọn ọmọ ṣe ojúṣe wọn.

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ẹ̀sìn Tòótọ́?

Ǹjẹ́ ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà? Wo àwọn kókó márùn-ún téèyàn lè fi dá ẹ̀sìn tòótọ́ mọ̀.

Bawo La Ṣe Ń Jàǹfààní Látinú Àwọn Ìlànà Bíbélì?

Jésù ṣàlàyé ìdí tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà àtàwọn ìlànà Bíbélì méjì tó ṣe pàtàkì jù.

Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?

Wò ó bóyá gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́, bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà àti nǹkan míì tó lè mú kó o sún mọ́ Ọlọ́run.

Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?

Ṣé ìgbà kan máa dé tí gbogbo èèyàn á jùmọ̀ máa jọ́sìn Ọlọ́run kan ṣoṣo?

Kí Nìdí tí Ọlọ́run Fi Ní Ètò Kan?

Bíbélì sọ bá a ṣe ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́ àti ìdí tá a fi ṣe é.

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nìṣó?

Báwo ni ohun tó o mọ̀ nípa Ọlọ́run àti nípa Bíbélì ṣe máa ṣe àwọn ẹlòmíì láǹfààní? Báwo ni àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe máa rí?