Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

Apá òsì: Arábìnrin kan ní ìpínlẹ̀ Alabama ní Amẹ́ríkà, ń fi àwo rẹ́kọ́ọ̀dù gbé ìwàásù Arákùnrin Rutherford sétígbọ̀ọ́ ẹnì kan, láàárín ọdún 1936 sí 1939; Apá ọ̀tún: Ilẹ̀ Switzerland

 APÁ 1

Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run​—Pípèsè Oúnjẹ Nípa Tẹ̀mí

Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run​—Pípèsè Oúnjẹ Nípa Tẹ̀mí

 O RÍ i pé inú akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ dùn gan-an bó ṣe wá lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ kà. Ó wá rọra bi ọ́ pé, “Ṣé pé Bíbélì sọ pé a lè gbé nínú Párádísè títí láé, láyé ńbí?” Ẹni tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí rẹ́rìn-ín músẹ́, ó ní, “Ó dáa, kí ni Bíbélì tẹ́ ẹ kà yẹn sọ?” Ọ̀rọ̀ yìí wú akẹ́kọ̀ọ́ náà lórí débi pé ó mirí tìyanutìyanu, ó ní, “Ó yà mí lẹ́nu pé kò tiẹ̀ sẹ́ni tó kọ́ mi nírú nǹkan báyìí rí!” O wá rántí pé ó sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn nígbà àkọ́kọ́ tó máa gbọ́ ọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí? Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run nírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí. Irú ìrírí bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ́ ká tún rántí ẹ̀bùn iyebíye tá a rí gbà, ìyẹn ìmọ̀ òtítọ́! Rò ó wò ná: Báwo ni ẹ̀bùn náà tiẹ̀ ṣe tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́? A máa sọ̀rọ̀ nípa ìbéèrè yẹn ní apá yìí. Bí àwa èèyàn Ọlọ́run ṣe ń rí ìlàlóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ gbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lóòótọ́. Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn báyìí ni Jésù Kristi Ọba Ìjọba náà ti ń rí sí i lójú méjèèjì pé àwa èèyàn Ọlọ́run ń kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́.