Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ẹ̀yin Ará Ọ̀wọ́n Tá A Jọ Jẹ́ Akéde Ìjọba Ọlọ́run:

FOJÚ inú wò ó pé o jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn. Láàárọ̀ Friday October 2, 1914, o jókòó sí àyè rẹ ní gbọ̀ngàn ìjẹun ti ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Ẹ̀ ń retí kí Arákùnrin C. T. Russell wọlé. Lójijì ilẹ̀kùn gbọ̀ngàn ìjẹun ṣí, Arákùnrin Russell sì wọlé. Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń ṣe, ó kọ́kọ́ dákẹ́ díẹ̀, ó wá fi ẹ̀rín músẹ́ kí ìdílé Bẹ́tẹ́lì, ó ní “Mo kí gbogbo yín, ẹ káàárọ̀ o.” Àmọ́ dípò kó lọ jókòó sí àyè rẹ̀ níbi tí wọ́n ti máa ń darí ìjọsìn òwúrọ̀, ńṣe ló pàtẹ́wọ́ tó sì ṣe ìfilọ̀ amóríyá kan pé: “Àkókò Àwọn Kèfèrí ti dópin; àwọn ọba wọn ti lo ìgbà wọn kọjá!” O ò lè pa ayọ̀ rẹ mọ́ra torí ó ti pẹ́ tó o ti ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ yìí! Inú gbogbo yín dùn gan-an, lẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ́wọ́ bíi pé kẹ́ ẹ máà dáwọ́ dúró.

Ọdún gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ti kọjá látìgbà tí Arákùnrin Russell ti sọ ọ̀rọ̀ amóríyá yẹn. Àwọn nǹkan wo ni Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe látìgbà yẹn? Kò  lóǹkà! Nípasẹ̀ Ìjọba tí Jèhófà gbé kalẹ̀ yìí, ó ti ń yọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ó sì ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Lọ́dún 1914, àwọn èèyàn Jèhófà ò ju ẹgbẹ̀rún bíi mélòó kan lọ, àmọ́ ní báyìí wọ́n ti lé ní mílíọ̀nù méje àtààbọ̀. Àwọn ọ̀nà wo lo ti gbà jàǹfààní nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ń fún wa?

Lóde òní, àwọn ará sábà máa ń sọ pé, “Kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run ti Jèhófà wà lórí ìrìn!” bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé láti ọdún 1914 ni kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run ti Jèhófà, tó ń ṣàpẹẹrẹ apá ti ọ̀run, èyí tí a kò lè fojú rí lára ètò Rẹ̀ ti ń yára rìn ní kánmọ́kánmọ́. Wàá rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tó o bá fara balẹ̀ ka ìwé yìí. Torí ká lè wàásù ìhìn rere kárí ayé, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ti lo onírúurú ọ̀nà láti fi wàásù, wọ́n lo ìwé ìròyìn, wọ́n gbé ìsọfúnni káàkiri ìgboro, wọ́n ṣe àfihàn àwòrán àti sinimá, wọ́n ṣe káàdì tí wọ́n fi ń jẹ́rìí, wọ́n lo ẹ̀rọ giramafóònù, wọ́n wàásù lórí rédíò, kódà wọ́n lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.

A rí ìbùkún Jèhófà lórí iṣẹ́ náà, torí pé ní báyìí, à ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn wa tó fani mọ́ra ní èdè tó lé ní àádọ́rin lé lẹ́gbẹ̀ta [670], àwọn ìwé ìròyìn yìí kì í sì í ṣe títa. Àwọn ará tó fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn ń ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ilé tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ń lò, yálà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù àti láwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù. Nígbà tí àjálù bá sì ṣẹlẹ̀, àwọn ará wa ọ̀wọ́n lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń yára lọ ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ará tí a “bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà” làwọn lóòótọ́.—Òwe 17:17.

Láwọn ìgbà míì, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn míì tó kórìíra wa máa ń fi òfin “dáná ìjàngbọ̀n,” àmọ́ ńṣe ni gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe lòdì sí wa ń yọrí sí “ìlọsíwájú ìhìn rere,” èyí sì ń gbé ìgbàgbọ́ wa ró.—Sm. 94:20; Fílí. 1:12.

Inú wa dùn pé àwa àti ẹ̀yin jọ jẹ́ “ará ilé,” a sì jọ ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. A nífẹ̀ẹ́ gbogbo yín gan-an ni. Àdúrà wa ni pé kí ìsọfúnni tó wà nínú ìwé yìí mú kẹ́ ẹ túbọ̀ mọyì ogún tẹ̀mí yín ju ti ìgbàkígbà rí lọ.—Mát. 24:45.

Ire o,

Àwa arákùnrin yín,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà