Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Apá òsì: Ọlọ́pàá wá mú arákùnrin kan torí pé ó ń wàásù ní ìlú Eindhoven, orílẹ̀-èdè Netherlands, lọ́dún 1945; apá ọ̀tún: Ṣé òfin gbà yín láyè láti máa wàásù níbi tí ò ń gbé?

 APÁ 4

Ìjọba Ọlọ́run Jagun Mólú​—A Fi Ìdí Ìhìn Rere Múlẹ̀ Lọ́nà Òfin

Ìjọba Ọlọ́run Jagun Mólú​—A Fi Ìdí Ìhìn Rere Múlẹ̀ Lọ́nà Òfin

 KÁ SỌ pé lọ́jọ́ kan tí ò ń wàásù láti ilé dé ilé, o gbọ́ ìró fèrè ọkọ̀ ọlọ́pàá tó ń dún kíkankíkan, tó sì ń sún mọ́ tòsí. Bí o ṣe ń bá ẹni tó wà nílé tó kàn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹni tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ ń wo ọkọ̀ ọlọ́pàá náà bó ṣe wá dúró lọ́dọ̀ yín. Ọ̀kan lára wọn sọ̀ kalẹ̀, ó sì bi yín pé: “Ṣé ẹ̀yin méjèèjì lẹ̀ ń lọ sílé àwọn èèyàn, tẹ́ ẹ̀ ń báwọn sọ̀rọ̀ Bíbélì? Àwọn èèyàn ti ń fẹjọ́ yín sùn wá!” O dá wọn lóhùn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, o sì sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?

Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá máa nípa gan-an lórí ibi tọ́rọ̀ yìí máa já sí. Báwo ni ìjọba ṣe ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà látẹ̀yìn wá níbi tí ò ń gbé? Ǹjẹ́ wọ́n gbà wọ́n láyè láti máa ṣe ẹ̀sìn wọn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé akitiyan tí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti ṣe gan-an láti fi “ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin” láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. (Fílí. 1:7) Ibi yòówù kó o máa gbé, ìgbàgbọ́ rẹ máa túbọ̀ lágbára tó o bá ń ronú lórí bí ilé ẹjọ́ ṣe dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre nínú àwọn ẹjọ́ tó ti kọjá. Nínú apá yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ẹjọ́ mánigbàgbé tó wáyé. Àwọn ẹjọ́ tá a jàre rẹ̀ mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìjọba tó ti ń ṣàkóso lóòótọ́ ni Ìjọba Ọlọ́run, torí pé a ò lè ṣe àwọn àṣeyọrí yìí lágbára tiwa!