Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 16

Bí A Ṣe Ń Pàdé Pọ̀ Láti Jọ́sìn

Bí A Ṣe Ń Pàdé Pọ̀ Láti Jọ́sìn

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Bí ìpàdé wa ti ṣe pàtàkì tó àti bó ṣe bẹ̀rẹ̀

1. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn kóra jọ, ìrànlọ́wọ́ wo ni wọ́n rí gbà, kí sì nìdí tí wọ́n fi nílò rẹ̀?

KÉTÉ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kóra jọ láti gba ara wọn níyànjú. Àmọ́, ńṣe ni wọ́n ti ilẹ̀kùn mọ́rí torí pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn ọ̀tá wọn. Ẹ wo bí ìbẹ̀rù wọn ṣe pòórá nígbà tí Jésù fara hàn láàárín wọn tó sì sọ pé: “Ẹ gba ẹ̀mí mímọ́”! (Ka Jòhánù 20:19-22.) Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tún kóra jọ, Jèhófà sì tú ẹ̀mí mímọ́ sórí wọn. Bó ṣe di pé wọ́n rí okun gbà nìyẹn o fún iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n máa ṣe lọ́jọ́ iwájú!—Ìṣe 2:1-7.

2. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń fún wa lágbára, kí sì nìdí tá a fi nílò rẹ̀? (b) Kí nìdí tí Ìjọsìn Ìdílé fi ṣe pàtàkì? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé àti àpótí náà, “ Ìjọsìn Ìdílé,” lójú ìwé 175.)

2 Irú ìṣòro kan náà bíi ti àwọn ará wa ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní là ń dojú kọ. (1 Pét. 5:9) Nígbà míì, ìbẹ̀rù èèyàn ni ìṣòrò àwọn kan lára wa. Nítorí náà, a nílò agbára látọ̀dọ̀ Jèhófà tá a bá fẹ́ máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó. (Éfé. 6:10) Àwọn ìpàdé wa ni Jèhófà sì fi ń pèsè èyí tó pọ̀ jù nínú agbára náà fún wa. Ní báyìí, a láǹfààní láti máa lọ sí àwọn ìpàdé méjì tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ìyẹn Ìpàdé fún Gbogbo Èèyàn, Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, àti ìpàdé tá a máa ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ tá à ń pè ní Ìgbésí Ayè áti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni. * A tún máa ń pé jọ ní ìgbà mẹ́rin míì lọ́dún, ìyẹn àpéjọ àgbègbè kan, àpéjọ àyíká méjì àti Ìrántí Ikú Kristi. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lọ sí gbogbo ìpàdé? Báwo ni àwọn ìpàdé wa tòde òní ṣe bẹ̀rẹ̀? Kí sì ni ọwọ́ tá a fi mú àwọn ìpàdé náà ń fi hàn nípa wa?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Pàdé Pọ̀?

3, 4. Kí ni Jèhófà pàṣẹ pé kí àwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣe? Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan.

3 Ó pẹ́ tí Jèhófà ti pàṣẹ pé kí àwọn èèyàn rẹ̀ máa pé jọ láti jọ́sìn òun. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní Òfin. Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sì wà lára Òfin náà kí ìdílé kọ̀ọ̀kan bàa lè máa jọ́sìn Ọlọ́run kí wọ́n sì máa gba ìtọ́ni látinú Òfin náà. (Diu. 5:12; 6:4-9) Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ lé àṣẹ yẹn, ó fún ìdílé wọn lókun, orílẹ̀-èdè wọn lápapọ̀ sì lágbára nípa tẹ̀mí, ó sì tún jẹ́ mímọ́. Àmọ́, nígbà tí wọ́n kò tẹ̀ lé Òfin náà, tí wọ́n pa àṣẹ rẹ̀ tì, irú bíi pípàdé déédéé fún ìjọsìn Jèhófà, wọ́n pàdánù ojú rere Ọlọ́run.—Léf. 10:11; 26:31-35; 2 Kíró. 36:20, 21.

 4 Tún wo àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀. Ó máa ń lọ sí sínágọ́gù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ọjọ́ Sábáàtì. (Lúùkù 4:16) Lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò ṣíwọ́ pípàdé déédéé bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kò sí lábẹ́ òfin Sábáàtì. (Ìṣe 1:6, 12-14; 2:1-4; Róòmù 14:5; Kól. 2:13, 14) Láwọn ìpàdé yẹn, kì í ṣe ìtọ́ni àti ìṣírí nìkan làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń gbà, wọ́n tún máa ń fi àdúrà wọn, ìdáhùn wọn àtàwọn orin rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run.—Kól. 3:16; Héb. 13:15.

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń pàdé pọ̀ láti fún ara wọn lókun àti ìṣírí

5. Kí nìdí tá a fi ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún? (Tún wo àpótí náà, “ Àwọn Àpéjọ Ọdọọdún Tó Ń Mú Káwọn Èèyàn Ọlọ́run Wà Níṣọ̀kan,” lójú ìwé 176.)

5 Lọ́nà kan náà, nígbà tá a bá lọ sáwọn ìpàdé wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ àwọn àpéjọ àyíká, àti àpéjọ àgbègbè tá à ń ṣe lọ́dọọdún, à ń fi hàn pé a kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run, à ń rí okun gbà nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, a sì ń gbé àwọn míì ró bá a ṣe ń sọ ohun tá a gbà gbọ́. Ní pàtàkì, a láǹfààní láti fi àdúrà wa, àwọn ìdáhùn wa àtàwọn orin wa jọ́sìn Jèhófà. Lóòótọ́, bí a ṣe ṣètò àwọn ìpàdé wa yàtọ̀ sí tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, síbẹ̀ àwọn ìpàdé wa yìí náà ṣe pàtàkì. Báwo ni àwọn ìpàdé wa tòde òní ṣe bẹ̀rẹ̀?

Àwọn Ìpàdé Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ Tó Ń Mú Ká Ní “Ìfẹ́ àti Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà”

6, 7. (a) Kí ni àwọn ìpàdé wa wà fún? (b) Báwo ni àwọn ìpàdé yìí ṣe yàtọ̀ síra ní àwùjọ kọ̀ọ̀kan?

6 Nígbà tí Arákùnrin Charles Taze Russell bẹ̀rẹ̀ sí í wá òtítọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó rí i pé ó pọn dandan láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń wá òtítọ́ bíi tirẹ̀. Ní ọdún 1879, Arákùnrin Russell kọ̀wé pé: “Èmi àtàwọn míì ní ìlú Pittsburgh ti dá kíláàsì Bíbélì kan sílẹ̀ láti máa wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ jáde, ọjọ́ Sunday la sì máa ń pàdé.” Wọ́n rọ àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn Zion’s  Watch Tower, ìyẹn Ilé Ìṣọ́, láti máa pàdé. Nígbà tó máa fi di ọdún 1881, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpàdé ní ìlú Pittsburgh, ìpínlẹ̀ Pennsylvania, ní gbogbo ọjọ́ Sunday àti Wednesday. Ilé Ìṣọ́ ti November 1895 lédè Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé àwọn ìpàdé náà wà fún “Pípéjọ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ìfẹ́ àti ìdàpọ̀” àti pé kí àwọn tó ń wá sípàdé lè máa fún ara wọn ní ìṣírí.—Ka Hébérù 10:24, 25.

7 Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, bí àwùjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ̀ọ̀kan ṣe ṣètò àwọn ìpàdé náà àti iye ìgbà tí wọ́n ń ṣe é yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ àwùjọ kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 1911 sọ pé: “Ó kéré tán, a máa ń ṣe ìpàdé márùn-ún lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.” Wọ́n máa ń ṣe àwọn ìpàdé yẹn lọ́jọ́ Monday, Wednesday àti Friday, wọ́n sì máa ń ṣèpàdé ní ẹ̀ẹ̀méjì lọ́jọ́ Sunday. Lẹ́tà míì tó wá látọ̀dọ̀ àwùjọ kan nílẹ̀ Áfíríkà tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 1914 sọ pé: “À ń ṣe ìpàdé lẹ́ẹ̀mejì lóṣù, ó ń bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Friday, á sì parí lọ́jọ́ Sunday.” Àmọ́, nígbà tó yá, wọ́n wá ṣètò àwọn ìpàdé náà lọ̀nà tá a gbà ń ṣe é lónìí. Ní ṣókí, ẹ jẹ́ ká wo bí ìpàdé kọ̀ọ̀kan ṣe bẹ̀rẹ̀.

8. Àwọn àkòrí wo ni àwọn àsọyé fún gbogbo èèyàn dá lé ní ìbẹ̀rẹ̀?

8 Ìpàdé fún Gbogbo Èèyàn. Lọ́dún 1880, ìyẹn ọdún tó tẹ̀ lé ọdún tí Arákùnrin Russell bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower jáde, ó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ìwàásù káàkiri. (Lúùkù 4:43) Bí Arákùnrin Russell ṣe ń lọ káàkiri, ó fi àwòkọ́ṣe ìpàdé kan lélẹ̀ tó wá di Ìpàdé fún Gbogbo Èèyàn tá à ń ṣe báyìí. Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ ń kéde ìrìn àjò náà, ó sọ pé Arákùnrin Russell “yóò láyọ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa ìpàdé fún gbogbo èèyàn lórí àkòrí náà, ‘Àwọn ohun tí ó tan mọ́ Ìjọba Ọlọ́run.’” Lọ́dún 1911, lẹ́yìn tí àwọn kíláàsì tàbí àwọn ìjọ ti fìdí múlẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan, a rọ kíláàsì kọ̀ọ̀kàn láti rán àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tó dáńgájíá lọ sáwọn àgbègbè ìtòsí láti sọ ọ̀wọ́ àsọyé mẹ́fà tó dá lórí àwọn àkòrí irú bí ìdájọ́ àti ìràpadà. Ní ìparí àsọyé kọ̀ọ̀kan, wọ́n á sọ orúkọ ẹni tó máa sọ àsọyé lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e àti àkòrí àsọyé náà.

9. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, ọ̀nà wo ni Ìpàdé fún Gbogbo Èèyàn gbà yí pa dà, báwo lo ṣe lè máa ti ìpàdé yìí lẹ́yìn?

9 Lọ́dún 1945, Ilé Ìṣọ́ kéde pé Ìpàdé fún Gbogbo Èèyàn máa bẹ̀rẹ̀ kárí ayé. Ó máa ní ọ̀wọ́ àsọyé Bíbélì mẹ́jọ tó dá lórí “àwọn ìṣòro ti àkókò yìí tó jẹ́ kánjúkánjú.” Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tá a yàn fi lo àwọn àkòrí tí ẹrú olóòótọ́ fún wọn, àmọ́ wọ́n tún ń lo àkòrí táwọn fúnra wọn yàn. Ṣùgbọ́n lọ́dún 1981, a sọ fún gbogbo àwọn olùbánisọ̀rọ̀ láti gbé àsọyé wọn ka ìwé àsọyé tí wọ́n fún gbogbo ìjọ. * Títí di ọdún 1990, àwọn ìwé àsọyé fún gbogbo èèyàn kan gbà kí alásọyé jẹ́ kí àwùjọ lóhùn sí àsọyé náà tàbí kí wọ́n ṣe àṣefihàn. Àmọ́ lọ́dún 1990 yẹn, wọ́n yí ìtọ́ni náà pa dà, pé ṣe ni ká máa sọ ọ́ ní àsọyé láìpe àwùjọ pé kí wọ́n dá sí i. Nígbà tó di January 2008  àtúnṣe míì wáyé. Wọ́n sọ àsọyé di ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú dípò ìṣẹ́jú márùnlélógójì [45] tó jẹ́ tẹ́lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyípadà ti bá ọ̀nà tá a gbà ṣètò àsọyé náà, àsọyé fún gbogbo èèyàn tá a múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa ṣì ń gbé ìgbàgbọ́ wa ró nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa oríṣiríṣi ohun tó jẹ ti Ìjọba Ọlọ́run. (1 Tím. 4:13, 16) Ṣé o máa ń fi ìtara pe àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ àtàwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí láti wá gbọ́ àwọn àsọyé wa tó ṣe pàtàkì tá a gbé ka Bíbélì?

10-12. (a) Àwọn àtúnṣe wo la ti ṣe sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara rẹ?

10 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Lọ́dún 1922, àwọn arákùnrin tí a mọ̀ sí arìnrìn-àjò ìsìn, ìyẹn àwọn òjíṣẹ́ tí Watch Tower Society rán lọ si àwọn ìjọ láti máa sọ àsọyé kí wọ́n sì máa múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù, dábàá pé kí wọ́n máa ṣe ìpàdé kan déédéé láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. A gba àbá yìí wọlé. Níbẹ̀rẹ̀, àwọn ìjọ máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní àárín ọ̀sẹ̀ tàbí ní ọjọ́ Sunday.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, Gánà,1931

11 Ilé Ìṣọ́ June 15, 1932, lédè Gẹ̀ẹ́sì, pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe ìpàdé náà. Àpilẹ̀kọ náà tọ́ka sí bí wọ́n ṣe máa ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní Bẹ́tẹ́lì, ó wá sọ pé arákùnrin kan ni kó máa darí ìpàdé náà. Arákùnrin mẹ́ta lè jókòó sí àwọ́n àga iwájú nínú ìpàdé, kí wọ́n máa pín àwọn ìpínrọ̀ náà kà láàárín ara wọn. Nígbà yẹn, àwọn àpilẹ̀kọ kò ní àwọn ìbéèrè tá a tẹ̀ sórí ìwé, torí náà, wọ́n ní kí olùdarí sọ fún àwùjọ pé kí wọ́n fa ìbéèrè yọ látinú àpilẹ̀kọ tí wọ́n ń jíròrò lọ́wọ́. Lẹ́yìn yẹn, á wá pe àwọn èèyàn nínú àwùjọ náà láti dáhùn àwọn ìbéèrè náà. Bí ọ̀rọ̀ náà bá ń fẹ́ àlàyé sí i, wọ́n ní kí olùdarí ṣe “àlàyé kúkúrú tó yéni yékéyéké.”

12 Níbẹ̀rẹ̀, wọ́n gbà kí ìjọ kọ̀ọ̀kan yan ẹ̀dà tó wù wọ́n nínú ìwé ìròyìn náà láti fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, èyí tí àwọn tó pọ̀ jù nínú ìjọ  bá fẹ́ ni wọ́n sì máa lò. Àmọ́, Ilé Ìṣọ́ April 15, 1933, lédè Gẹ̀ẹ́sì, dábàá pé kí gbogbo ìjọ máa lo ìwé ìròyìn tó dé kẹ́yìn. Lọ́dún 1937, ìtọ́ni kan wá jáde pé kí wọ́n máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́jọ́ Sunday. Nígbà tó yá, wọ́n tún ṣe àwọn àtúnṣe kan sí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe ìpàdé náà, èyí tí wọ́n ṣàlàyé sínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 1942, lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀nà yẹn là ń tẹ̀ lé títí dòní olónìí. Àkọ́kọ́, ìwé ìròyìn náà sọ pé àwọn ìbéèrè á máa wà ní ìsàlẹ̀ ojú ìwé kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, àwọn ìbéèrè náà sì ni kí wọ́n máa lò. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé ìpàdé náà kò gbọ́dọ̀ ju wákàtí kan lọ. Ó tún gba àwọn tó ń dáhùn níyànjú pé kí wọ́n máa dáhùn ní “ọ̀rọ̀ ti ara wọn” dípò tí wọ́n á fi máa kà á jáde látinú ìpínrọ̀. Títí di bá a ṣe ń sọ yìí, Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ṣì ni ọ̀nà pàtàkì kan tí ẹrú olóòótọ́ fi ń pèsè oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Mát. 24:45) Á dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Ṣé mo sì máa ń gbìyànjú láti dáhùn tó bá ṣeé ṣe?’

13, 14. Báwo ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ ṣe bẹ̀rẹ̀, kí lo sì máa ń gbádùn nínú ìpàdé yìí?

13 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Láàárín ọdún 1893 sí 1896, lẹ́yìn tí a ti mú àwọn ìdìpọ̀ ìwé Millennial Dawn mélòó kan jáde, Arákùnrin H. N. Rahn, tó jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń gbé nílùú Baltimore, ìpínlẹ̀ Maryland, nílẹ̀ Amẹ́ríkà, dábàá ṣíṣe ìpàdé tí wọ́n ń pé ní “Dawn Circles” (Ẹgbẹ́ Ìmọ́lẹ̀ Òwúrọ̀ Tó Ń Para Pọ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì) kí wọ́n lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Níbẹ̀rẹ̀, ṣe ni wọ́n ń ṣe ìpàdé yìí láti fi gbìyànjú ẹ̀ wò, ilé àdáni ni wọ́n sì ti sábà máa ń ṣe é. Àmọ́, nígbà tó fi máa di September 1895, wọ́n ti ń ṣe ìpàdé Dawn Circles dáadáa ní ọ̀pọ̀ ìlú lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ oṣù yẹn dábàá pé kí gbogbo àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ máa ṣe ìpàdé náà. Ó sọ pé ẹni tó bá ń darí ìpàdé náà ní láti jẹ́ ẹni tó mọ̀wé kà dáadáa. Kó máa ka gbólóhùn kan, kó sì dúró kí àwùjọ ṣàlàyé. Lẹ́yìn tó bá ti ka àwọn gbólóhùn kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìpínrọ̀ kan tán tí wọ́n sì ti jíròrò wọn, kó wá ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n yàn síbẹ̀. Tí wọ́n bá parí orí ìwé kan, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwùjọ náà máa wá sọ ohun tó rí kọ́ ní ṣókí.

14 Orúkọ ìpàdé yìí ti yí pa dà láwọn ìgbà mélòó kan. Nígbà kan, wọ́n pè é ní Berean Circles for Bible Study, ìyẹn tọ́ka sí àwọn ará Bèróà tí wọ́n fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́. (Ìṣe 17:11) Nígbà tó yá, ó yí pa dà di Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ní báyìí, à ń pè é ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, odindi ìjọ ló sì máa ń pàdé pọ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kì í ṣe àwùjọ kan ní ilé àdáni mọ. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, oríṣiríṣi ìwé ńlá àti ìwé pẹlẹbẹ la ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú ìpàdé yìí, títí kan àwọn àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ pàápàá. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni a ti rọ gbogbo àwọn tó ń wá sí ìpàdé náà láti máa lóhùn sí ìpàdé yìí. Ìpàdé náà ti mú ká túbọ̀ ní ìmọ̀ Bíbélì. Ǹjẹ́ o máa ń múra  ìpàdé yìí sílẹ̀ déédéé, ṣé o sì máa ń dáhùn dáadáa ní ìpàdé yìí débi tó bá ṣeé ṣe fún ọ tó?

15. Kí nìdí tá a fi dá Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀?

15 Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Arákùnrin Carey Barber tó ń sìn ní orílé-iṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York nígbà yẹn sọ pé, “Ní alẹ́ Monday, February 16, 1942, gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì Brooklyn ni a pè láti forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ tá a wá mọ̀ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.” Arákùnrin Barber tó wá dí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí nígbà tó yá ṣàlàyé ilé ẹ̀kọ́ náà pé ó jẹ́ “ọ̀kan lára ọ̀nà tó ta yọ jù lọ tí Jèhófà gbà ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò lóde òní.” Ilé ẹ̀kọ́ náà kẹ́sẹjárí gan-an torí pé ó mú kí àwọn arákùnrin túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì túbọ̀ mọ bá a ṣe ń wàásù. tó fi jẹ́ pé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1943, ètò Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ìjọ kárí ayé ní ìwé pẹlẹbẹ Course in Theocratic Ministry (Ìlànà Ẹ̀kọ́ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run). Ilé Ìṣọ́ June 1,  1943, lédè Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé a dá Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ kó lè ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ láti “kọ́ ara wọn kí wọ́n lè di ẹlẹ́rìí tó túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ pípolongo Ìjọba náà.”—2 Tím. 2:15.

16, 17. Ṣé bá a ṣe máa mọ̀rọ̀ọ́ sọ nìkan ni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ń kọ́ wa? Ṣàlàyé.

16 Níbẹ̀rẹ̀, ó nira gan-an fún ọ̀pọ̀ láti máa sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ ńlá. Clayton Woodworth, Jr., tí bàbá rẹ̀ wà lára àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n pẹ̀lú Arákùnrin Rutherford lọ́dún 1918 láìjẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀, sọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára òun nígbà tó kọ́kọ́ dara pọ̀ mọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà lọ́dún 1943. Arákùnrin Woodworth sọ pé: “Ó ṣòro fún mi láti sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. Ó máa ń ṣe mi bíi pé ahọ́n mi ń gùn sí i, itọ́ ẹnu mi máa ń gbẹ́ pátápátá, ohùn mi á sì bẹ̀rẹ̀ sí í há tàbí kó tún ròkè jù nígbà míì.” Àmọ́ nígbà tí ọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀ mọ́ Clayton lẹ́nu dáadáa, wọ́n fún un ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti máa sọ àsọyé. Kì í ṣe béèyàn ṣe ń mọ̀rọ̀ọ́  sọ nìkan ní Ilé ẹ̀kọ́ náà kọ́ ọ, ó tún kọ́ ọ ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa gbára lé Jèhófà. Ó sọ pé: “Mo wá mọ̀ pé kì í ṣe ẹni tó ń sọ̀rọ̀ náà ló ṣe pàtàkì. Tó bá múra sílẹ̀ dáadáa tó sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, inú àwọn èèyàn tó ń gbọ́ ọ á dùn, wọ́n á sì rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.”

17 Lọ́dún 1959, wọ́n ní kí àwọn arábìnrin máa forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Arábìnrin Edna Bauer rántí ìfilọ̀ tí wọ́n ṣe ní àpéjọ tó lọ. Ó sọ pé: “Mo rántí pé inú àwọn arábìnrin dùn jọjọ. Ní báyìí, wọ́n ti fún wa láǹfààní tó pọ̀ sí i.” Láwọn ọdún tó ti kọjá, ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ti forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tí Jèhófà sì ti kọ́ wọn. Lóde òní, à ń gba irú ìdálẹ̀kọ́ yìí ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ tá à ń ṣe.—Ka Aísáyà 54:13.

18, 19. (a) Báwo la ṣe ń gba ìtọ́ni nípa iṣẹ́ ìwàásù wa lóde òní? (b) Kí nìdí tá a fi ń kọrin láwọn ìpàdé wa? (Wo àpótí náà “ Kíkọ Òtítọ́ Lórin.”)

18 Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní 1919, wọ́n máa ń ṣe ìpàdé láti ṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá. Nígbà yẹn, kì í ṣe gbogbo ará ìjọ ló máa ń wà nípàdé náà, kìkì àwọn tó máa ń pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ń wà níbẹ̀. Ní èyí tó pọ̀ jù nínú ọdún 1923, ẹ̀ẹ̀kan lóṣù ni wọ́n máa ń ṣe Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, gbogbo àwọn tó sì wà ní kíláàsì tàbí ìjọ ló ní láti wá síbẹ̀. Nígbà tó máa di ọdún 1928, wọ́n rọ àwọn ìjọ pé kí wọ́n máa ṣe Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lọ́dún 1935, Ilé Ìṣọ́ rọ gbogbo ìjọ pé kí wọ́n gbé Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn náà ka ìsọfúnni tó wà nínú ìwé Director (tí wọ́n ń pè ní Informant nígbà tó yá, tó tún wá di Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa). Kò pẹ́ tí ìpàdé yìí fi wá di apá tá à ń ṣe nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan déédéé.

19 Lóde òní, a máa ń gba ìtọ́ni nípa bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ tá à ń ṣe. (Mát. 10:5-13) Tó o bá kúnjú ìwọ̀n láti gba ẹ̀dà ìwé ìpàdé, ṣé o máa ń kà á, ṣé o sì máa ń lo àbá tó wà nínú rẹ̀ bó o ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù?

Ìpàdé Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Lọ́dún

Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹn máa ń kóra jọ lọ́dọọdún láti ṣe Ìrántí Ikú Jésù (Wo ìpínrọ̀ 20)

20-22. (a) Kí nìdí tá a fi ń rántí ikú Jésù? (b) Àǹfààní wo lo máa ń rí gbà bó o ṣe ń lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún?

20 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe ìrántí ikú òun títí òun á fi dé. Bíi ti Ìrékọjá, ọdọọdún là ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi. (1 Kọ́r. 11:23-26) Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń wá sí ìpàdé yìí lọ́dọọdún. Ó máa ń rán àwọn ẹni àmì òróró létí àǹfààní tí wọ́n ní pé wọ́n jẹ́ ajùmọ̀jogún nínú Ìjọba Ọlọ́run. (Róòmù 8:17) Bákan náà, ó ń mú kí àwọn àgùntàn mìíràn ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọba Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n sì dúró ṣinṣin sí i.—Jòh. 10:16.

21 Arákùnrin Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn máa rántí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, wọ́n sì mọ̀ pé ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ló yẹ ká máa ṣe é. Ilé Ìṣọ́ ti April 1880 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ó jẹ́ àṣà ọ̀pọ̀ lára wa fún ọdún mélòó kan ní Pittsburgh níbí láti máa  . . . ṣe Ìrékọjá [Ìrántí] àti láti máa jẹ ohun  ìṣàpẹẹrẹ ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.” Kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àpéjọ pa pọ̀ pẹ̀lú Ìrántí Ikú Jésù. Ọdún 1889 nìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe àkọ́sílẹ̀ iye àwọn èèyàn tó pé jọ. Wọ́n jẹ́ igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [225], àwọn méjìlélógún [22] ló sì ṣèrìbọmi.

22 Lónìí, a kì í ṣe Ìrántí Ikú Jésù pa pọ̀ mọ́ àpéjọ mọ́, àmọ́ a máa ń pe gbogbo èèyàn níbi gbogbo tí à ń gbé láti dara pọ̀ mọ́ wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tàbí ibi tí a háyà. Lọ́dún 2013, ó lé ní mílíọ̀nù mọ́kàndínlógún [19,000,000] tó pé jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Jésù. Ẹ wo àǹfààní ńlá tá a ní láti wá sí Ìrántí náà, yàtọ̀ síyẹn a tún rọ àwọn èèyàn láti wá dara pọ̀ mọ́ wa ní alẹ́ mímọ́ jù lọ yìí! Ṣé o máa ń fi ìtara pe ọ̀pọ̀ tó o lè pè wá sí Ìrántí náà lọ́dọọdún?

Kí Ni Ìṣe Wa Ń Fi Hàn

23. Ojú wo lo fi ń wo pípàdé pọ̀ wa?

23 Àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà kì í wo ìtọ́ni tó fún wọn pé kí wọ́n máa pàdé pọ̀ bí ohun ìnira. (Héb. 10:24, 25; 1 Jòh. 5:3) Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì Ọba nífẹ̀ẹ́ lílọ jọ́sìn nílé Jèhófà. (Sm. 27:4) Ó máa ń gbádùn lílọ síbẹ̀ gan-an pẹ̀lú àwọn èèyàn míì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Sm. 35:18) Ronú nípa àpẹẹrẹ Jésù. Kódà nígbà tó ṣì kéré, ó fẹ́ràn lílọ jọ́sìn ní ilé Bàbá rẹ̀ gan-an.—Lúùkù 2:41-49.

Bó ṣe ń wù wá gan-an láti máa pàdé pọ̀ ń fi hàn pé òótọ́ la gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso

24. Tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé wa, àwọn àǹfààní wo la máa ní?

24 Nígbà tá a bá lọ sáwọn ìpàdé, ṣe là ń fi ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà hàn, a sì ń fi hàn pé a fẹ́ láti máa gbé àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ró. Bákan náà, ó máa ń wù wá gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe máa gbé bí ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn ìpàdé wa, àwọn àpéjọ àti àpéjọ àgbègbè wa la sì ti ń kọ́ irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìpàdé wa ń kọ́ wa ní òye iṣẹ́, ó sì ń fún wa ní okun tí yóò mú lè máa ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe lónìí nìṣó, ìyẹn iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi Ọba àti dídá wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Ka Mátíù 28:19, 20.) Láìsí àní-àní, bó ṣe ń wù wá gan-an láti máa pàdé pọ̀ ń fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ohun gidi sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Ǹjẹ́ ká máa mọyì àwọn ìpàdé wa!

^ ìpínrọ̀ 2 Yàtọ̀ sí àwọn ìpàdé ìjọ tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a rọ ìdílé kọ̀ọ̀kan tàbí ẹnì kọ̀ọ̀kan láti ya àkókò sọ́tọ̀ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìjọsìn ìdílé.

^ ìpínrọ̀ 9 Lọ́dún 2013, ó lé ní ọgọ́sàn-án [180] ìwé àsọyé tá a ní lọ́wọ́.