OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Àwọn ilé tá à ń kọ́ kárí ayé wúlò fún àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run

1, 2. (a) Kí ló pẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti gbádùn láti máa ṣe? (b) Kí ló ṣe pàtàkì jù lọ lójú Jèhófà?

ỌJỌ́ pẹ́ tí inú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ti máa ń dùn láti kọ́ àwọn ilé tó ń fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ìtara lọ́wọ́ sí kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn, wọ́n sì mú àwọn ohun èlò ìkọ́lé wá lọ́pọ̀lọpọ̀.—Ẹ́kís. 35:30-35; 36:1, 4-7.

2 Jèhófà ò wo ilé táwọn èèyàn rẹ̀ ń kọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù lọ tí wọ́n ń gbà bọlá fún òun, kì í sì í ṣe àwọn ilé náà ló kà sí ohun tó ṣeyebíye jù lọ. (Mát. 23:16, 17) Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ lójú Jèhófà tàbí tó kà sí ẹ̀bùn tó ń bọlá fún un ju ohunkóhun mìíràn lọ, ni bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jọ́sìn rẹ̀, bí wọ́n ṣe múra tán láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń fi ìtara ṣe é. (Ẹ́kís. 35:21; Máàkù 12:41-44; 1 Tím. 6:17-19) Kókó yìí ṣe pàtàkì gan-an ni. Kí nìdí? Ìdí ni pé ilé tá a kọ́ lónìí lè máà sí mọ́ bó bá dọ̀la. Bí àpẹẹrẹ, àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì kò sí mọ́. Àmọ́ bí àwọn ilé yẹn ò tiẹ̀ sí mọ́, Jèhófà ò gbàgbé ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àti iṣẹ́ ribiribi tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin ṣe láti kọ́ àwọn ilé náà.—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58; Hébérù 6:10.

3. Kí la máa ṣàyẹ̀wò nínú orí yìí?

3 Bákan náà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń ṣiṣẹ́ kára lóde òní kí wọ́n lè kọ́ àwọn ibi ìjọsìn. Àwọn ohun tá a sì ti gbé ṣe lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi, Ọba wa kọjá àfẹnusọ! Láìsí àní-àní, Jèhófà ti bù kún ìsapá wa. (Sm. 127:1) Nínú orí yìí, a máa ṣàyẹ̀wò díẹ̀ péré lára àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tá a ti ṣe àti bí wọ́n ṣe bọlá fún Jèhófà. A tún máa gbọ́ ohun tí àwọn tó ti kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà sọ.

Kíkọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba

4. (a) Kí nìdí tá a fi nílò àwọn ibi ìjọsìn púpọ̀ sí i? (b) Kí nìdí tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan pọ̀? (Wo àpótí náà, “ Iṣẹ́ Kíkọ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì —Àtúntò Látàrí Ìyípadà Tó Ń Wáyé.”)

4 Bá a ṣe jíròrò rẹ̀ ní Orí 16, Jèhófà fẹ́ ká máa pé jọ láti jọ́sìn òun. (Héb. 10:25) Kì í ṣe pé àwọn ìpàdé wa ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun nìkan ni wọ́n tún ń mú kí ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ sí i. Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ṣe ń lọ sí òpin bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń mú kí iṣẹ́ náà máa yára kánkán. Látàrí èyí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń rọ́ wá sínú ètò rẹ̀ lọ́dọọdún. (Aísá. 60:22) Bí àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run sì ṣe ń pọ̀ sí i yìí la túbọ̀ ń nílò àwọn ilé tá a ti lè máa tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. A sì tún nílò àwọn ibi ìjọsìn púpọ̀ sí i.

5. Kí nìdí tí orúkọ náà, Gbọ̀ngàn Ìjọba fi bá a mu wẹ́kú? (Tún wo àpótí náà, “ Ṣọ́ọ̀ṣì ‘New Light.’”)

 5 Látìgbà tí àwa èèyàn Jèhófà lóde òní ti bẹ̀rẹ̀ ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti rí i pé ó pọn dandan kí àwọn náà ní ibi ìjọsìn tiwọn. Ó jọ pé ọ̀kan lára irú àwọn ibi ìjọsìn tá a kọ́kọ́ kọ́ ni èyí tí wọ́n kọ́ sí ìpínlẹ̀ West Virginia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1890. Láti ọdún 1931 sí ọdún 1934, àwọn èèyàn Jèhófà kọ́ àwọn gbọ̀ngàn mélòó kan tàbí kí wọ́n ṣe àtúnṣe èyí tó wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní gbogbo ìgbà yẹn, kò sí èyíkéyìí lára àwọn ibi ìjọsìn yẹn tó ni orúkọ kan pàtó. Àmọ́, nígbà tó di ọdún 1935, Arákùnrin Rutherford ṣe ìbẹ̀wò sí erékùṣù Hawaii, níbi tí wọ́n ti ń kọ́ gbọ̀ngàn kan pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun kan. Nígbà tí wọ́n bi Arákùnrin Rutherford pé kí ni káwọn pe ilé náà, ó dá wọn lóhùn pé: “Ǹjẹ́ a ò kúkú ní máa pè é ní ‘Gbọ̀ngàn Ìjọba,’ níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tá à ń ṣe nìyẹn, à ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?” (Mát. 24:14) Ẹ wo bí orúkọ yẹn ṣe bá a mú wẹ́kú! Kì í wá ṣe gbọ̀ngàn yẹn nìkan ló ń jẹ́ orúkọ náà o, kò pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í pe èyí tó pọ̀ jù  lọ lára àwọn ilé táwa èèyàn Jèhófà kárí ayé ti ń ṣèpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

6, 7. Kí ló ti jẹ́ àbájáde bá a ṣe ń yára kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba?

6 Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1970, àwọn ibi tá a ti nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Láti yanjú ìṣòro yìí, àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣètò ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kan tí wọ́n lè gbà máa kọ́ àwọn ilé tó fani mọ́ra, tó ṣeé lò, tí wọ́n á sì kọ́ parí láàárín ọjọ́ díẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọdún 1983, wọ́n ti kọ́ irú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba bẹ́ẹ̀ tó tó igba [200] ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà. Kí iṣẹ́ náà bàa lè máa lọ geerege, àwọn arákùnrin bẹ̀rẹ̀ sí í dá ìgbìmọ̀ ìkọ́lé ẹlẹ́kùnjẹkùn sílẹ̀. Ọ̀nà ìgbàkọ́lé yìí kẹ́sẹ járí gan-an débi pé ní ọdún 1986, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí ètò Ọlọ́run máa lo ìṣètò náà. Ní ọdún 1987, ọgọ́ta [60] Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ló ti wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. * Lọ́dún 1992, wọ́n tún yan àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn sípò ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà, Ọsirélíà, Faransé, Jámánì, Japan, Mẹ́síkò, South Africa àti Sípéènì. Dájúdájú, àwọn ará wa tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ nílò ìtìlẹ́yìn wa, torí pé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe jẹ́ apá kan iṣẹ́ ìsìn mímọ́.

7 Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n yára kọ́ yìí máa ń jẹ́rìí lọ́nà kíkàmàmà fún àwọn èèyàn tó ń gbé ládùúgbò ibi tí wọ́n kọ́ wọn sí. Bí àpẹẹrẹ, àkọlé kan fara hàn nínú ìwé ìròyìn kan ní orílẹ̀-èdè Sípéènì pé, “Ìgbàgbọ́ Ń Ṣí Àwọn Òkè Nídìí.” Nígbà tí ìwé ìròyìn yìí ń sọ̀rọ̀ lórí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí wọ́n yára kọ́ ní ìlú  Martos, ó béèrè pé: “Nínú ayé tó kún fún ìmọtara-ẹni-nìkan yìí, kí ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti onírúurú ẹkùn ìpínlẹ̀ [ní orílẹ̀-èdè Sípéènì] láti fínnúfíndọ̀ rìnrìn-àjò lọ sí ìlú Martos kí wọ́n lè kọ́ ilé kan tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí látàrí bí wọ́n ṣe yára kọ́ ọ, bó ṣe rí rèǹtèrente, tí ohun gbogbo sì wà létòletò?” Láti dáhùn ìbéèrè náà, ìwé ìròyìn yẹn fa ọ̀rọ̀ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ náà yọ pé: “Ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé Jèhófà ń kọ́ àwa èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.”

Ilé Kíkọ́ ní Àwọn Ilẹ̀ Tí Àwọn Ará Ò Ti Fi Bẹ́ẹ̀ Lówó

8. Ìṣètò tuntun wo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí lọ́dún 1999, kí sì nìdí?

8 Bí ọgọ́rùn-ún ọdún ogún ṣe ń parí lọ, àwọn èèyàn ń rọ́ wá sínú ètò Jèhófà ní àwọn ilẹ̀ tí àwọn ará ò ti fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́. Àwọn ìjọ ń sa gbogbo ipá wọn láti kọ́ àwọn ibi ìpàdé. Àmọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ní láti fara da ìfiṣẹ̀sín àti ẹ̀tanú torí pé ńṣe ni àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn rí bí ilé àtijọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ilé ìsìn míì. Àmọ́, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1999, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí ìṣètò kan tó mú kí iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba máa yára kánkán ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Wọ́n ń lò lára ọrẹ tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn ará wa ní àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù, kí “ìmúdọ́gba” lè wà. (Ka 2 Kọ́ríńtì 8:13-15.) Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì ń wá láti orílẹ̀-èdè míì kí wọ́n lè yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́.

9. Iṣẹ́ wo ló dà bí èyí tí kò ní ṣeé ṣe, àmọ́ ibo la bá iṣẹ́ náà dé báyìí?

9 Nígbà tí iṣẹ́ náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ńṣe ló dà bí ohun tí kò ní ṣeé ṣe. Ìròyìn kan sọ ní ọdún 2001 pé ó ju ọ̀ọ́dúnrún lé ní ẹgbàá mẹ́sàn-án [18,300 ] Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a nílò ní  orílẹ̀-èdè méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Àmọ́, pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn ẹ̀mí Ọlọ́run àti Ọba wa Jésù Kristi, ohun gbogbo ni ṣíṣe. (Mát. 19:26) Láàárín nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, láti ọdún 1999 sí ọdún 2013, Gbọ̀ngàn Ìjọba tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti kọ́ lábẹ́ ìṣètò yìí jẹ́ ọ̀kẹ́ kan àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ó dín mọ́kànléláàádọ́jọ [26,849]. * Jèhófà ṣì ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù wa débi pé ní ọdún 2013, àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ṣì nílò ni àwọn orílẹ̀-èdè yẹn jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ààbọ̀ [6,500], àti pé ní báyìí ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba là ń nílò sí i lọ́dọọdún.

Kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àwọn ilẹ̀ tí àwọn ará ò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ ní àwọn ìṣòro tiẹ̀

10-12. Ọ̀nà wo ni iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti gbà bọlá fún orúkọ Jèhófà?

10 Báwo ni àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tá à ń kọ́ yìí ṣe ń bọlá fún orúkọ Jèhófà? Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè ròyìn pé: “Láàárín oṣù kan lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ńṣe ni àwọn tó ń wá sí ìpàdé máa ń di ìlọ́po méjì.” Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ó jọ pé àwọn èèyàn máa ń lọ́ tìkọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ wa àyàfi tí wọ́n bá rí i pé a ní ibi ìjọsìn tó bójú mu. Àmọ́, ní gbàrà tá a bá ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, kì í pẹ́ tó fi ń kún táá tún di pé a nílò òmíràn. Ṣùgbọ́n kì í wulẹ̀ ṣe torí pé ilé náà dùn wò ló ń mú káwọn èèyàn fẹ́ láti wá jọ́sìn Jèhófà. Ojúlówó ìfẹ́ Kristẹni tí àwọn tó ń kọ́ gbọ̀ngàn náà ń fi hàn tún máa ń nípa lórí ojú tí àwọn èèyàn fi ń wo ètò rẹ̀. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.

11 Indonesia. Nígbà tí ọkùnrin kan tó ti ń kíyè sí bí wọ́n ṣe ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan rí i pé ńṣe ni àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ yọ̀ǹda ara wọn, ó sọ pé: “Ó ga o, ẹ̀yin èèyàn yìí ń ṣe bẹbẹ! Mo kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn tínú yín sì ń dùn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ò gba kọ́bọ̀. Mi ò rò pé ẹ̀sìn kankan tún wà tó dà bíi tiyín!”

12 Ukraine. Obìnrin kan tó máa ń gba ibi tí wọ́n ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan kọjá lójoojúmọ́ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn èèyàn náà àti pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba ni wọ́n ń kọ́. Ó sọ pé: “Ẹnu àbúrò mi kan tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo ti kọ́kọ́ gbọ́ nípa wọn. Lẹ́yìn tí mo ti kíyè sí bí wọ́n ṣe ń kọ́lé náà, mo pinnu pé màá dára pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run yìí. Ẹ̀gàn ni hẹ̀, àwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ ara wọn!” Obìnrin yìí gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi ní ọdún 2010.

13, 14. (a) Kí lo ti rí kọ́ nínú ohun tí tọkọtaya kan ṣe lẹ́yìn tí wọ́n ti kíyè sí bí àwọn ará kan ṣe ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba? (b) Kí lo lè ṣe kó o lè rí i dájú pé ibi ìjọsìn yín ń bọlá fún orúkọ Jèhófà?

13 Ajẹntínà. Tọkọtaya kan lọ bá arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ níbì kan tí wọ́n ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Èyí ọkọ sọ pé, “A ti ń kíyè sí yín látìgbà tẹ́ ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé yìí, a sì . . . ti pinnu pé a máa fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run nílé tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ yìí.” Lẹ́yìn náà ló wá béèrè pé, “Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè yẹ lẹ́ni táá máa wá jọ́sìn níbí?” Tọkọtaya náà gbà pé àwọn máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn bí àwọn ará bá gbà láti máa kọ́ gbogbo ìdílé àwọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ará sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.

14 Bóyá o ò sí lára àwọn tó kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tẹ́ ẹ ti ń ṣèpàdé, àmọ́ o ṣì lè ṣe púpọ̀ sí i láti mú kí ibi tẹ́ ẹ ti ń ṣèpàdé ládùúgbò  yín máa bọlá fún orúkọ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, o lè máa fọ̀yàyà ké sí àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ àti àwọn míì tó ò ń bá pàdé lóde ẹ̀rí láti máa wá sí àwọn ìpàdé tá à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. O tún ní àǹfààní láti máa mú kí ibi tẹ́ ẹ ti ń ṣèpàdé wà ní mímọ́ kó o sì máa tún un ṣe. Tó o bá ṣètò tó mọ́yán lórí láti máa ya iye kan sọ́tọ̀, wàá lè máa rí owó fi ṣètọrẹ kí wọ́n lè lò ó fún títọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba yín tàbí kí wọ́n fi kọ́ irú àwọn ibi ìjọsìn bẹ́ẹ̀ sí apá ibòmíì lórí ilẹ̀ ayé. (Ka 1 Kọ́ríńtì 16:2.) Ńṣe ni gbogbo àwọn ìgbòkègbodò yìí ń fìyìn fún orúkọ Jèhófà.

Àwọn Òṣìṣẹ́ Tó Ń “Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn”

15-17. (a) Àwọn wo ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lára iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà? (b) Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí àwọn tọkọtaya tó ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé kárí ayé sọ?

15 Àwọn ará tó wà ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì ni wọ́n máa ń ṣe ọ̀pọ̀ lára iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Àmọ́ o, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa ilé kíkọ́ máa ń ti orílẹ̀-èdè míì wá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn kan lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn yìí ti ṣètò ara wọn lọ́nà tí wọ́n á fi lè lo ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lórílẹ̀-èdè míì láti bá wọn kọ́lé. Àwọn míì sì ti ń sìn láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, wọ́n ń ti ẹnu iṣẹ́ ìkọ́lé kan kọjá lọ sí òmíràn.

Timo ati Lina Lappalainen (Wo ìpínrọ̀ 16)

16 Iṣẹ́ ìkọ́lé ní ilẹ̀ òkèèrè máa ń ní àwọn ìṣòrò tiẹ̀, àmọ́ èrè púpọ̀ wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Timo àti Lina ti lọ bá wọn kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì ní àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Éṣíà, Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Timo sọ pé, “Láti bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ni iṣẹ́ mi ti máa ń yí pa dà lẹ́ẹ̀kan lọ́dún méjì.” Lina, tó fẹ́ Timo ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sẹ́yìn, sọ pé: “Èmi àti Timo ti sìn ní orílẹ̀-èdè mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó máa ń gba  ọ̀pọ̀ ìsapá ó sì máa ń pẹ́ díẹ̀ kí oúnjẹ tuntun, ipò ojú ọjọ́ tó yàtọ̀, èdè tuntun àti ìpínlẹ̀ ìwàásù tuntun tó mọ́ni lára àti kéèyàn tó ní àwọn ọ̀rẹ́ míì.” * Ṣé gbogbo ipá tí wọ́n sà yẹn sèso rere? Lina sọ pé: “Àwọn ìṣòro yẹn ti wá yọrí sí ìbùkún ńláǹlà fún wa. À ń gbádùn ìfẹ́ àti ẹ̀mí àlejò táwọn ará ń fi hàn sí wa, a sì ti rí i pé Jèhófà ń fi ìfẹ́ bójú tó wa. Ìlérí tí Jésù ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú Máàkù 10:29, 30, tún ti ṣẹ sí wa lára. A ti wá ní àwọn arákùnrin, arábìnrin àti ìyá nínú ètò Ọlọ́run ní ìlọ́po ọgọ́rọ̀ọ̀rún.” Timo sọ pé: “Inú wa ń dùn gan-an ni bá a ṣe ń lo ẹ̀bùn wa fún iṣẹ́ tó nítumọ̀ jù lọ, ìyẹn kíkópa nínú mímú àwọn ohun ìní Ọba náà gbòòrò sí i.”

17 Darren àti Sarah, tí wọ́n ti kópa nínú iṣẹ́ ilé kíkọ́ ní ilẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà, Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà, Yúróòpù, Amẹ́ríkà ti Gúúsù àti Gúúsù Pàsífíìkì, gbà pé ohun tí Jèhófà ti ṣe fún àwọn pọ̀ ju ohun tí àwọn yááfì lọ. Láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n ti bá pa dé sí, Darren sọ pé: “Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún mi láti máa bá àwọn ará ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé ṣiṣẹ́. Mo ti wá rí i pé ńṣe ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà dà bí okùn tó yí ayé ká, tó sì so gbogbo wa pọ̀ ṣọ̀kan.” Sarah sọ pé: “Mo ti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́dọ̀ àwọn ará tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tèmi! Bí mo ṣe ń rí ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n yááfì kí wọ́n lè sin Jèhófà ń mú kí n pinnu láti máa fún Jèhófà ni ohun tó dára jù lọ.”

18. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 110:1-3 ṣe ń ní ìmúṣẹ?

18 Dáfídì Ọba sọ tẹ́lẹ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run báyìí máa dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, síbẹ̀ wọ́n máa “fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn” kí wọ́n lè máa ṣe àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Ka Sáàmù 110:1-3.) Gbogbo àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ tá a fi ń ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n ń lọ́wọ́ nínú bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ní ìmúṣẹ. (1 Kọ́r. 3:9) Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì, àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà kárí ayé jẹ́ ẹ̀rí gidi tó fi hàn pé òótọ́ ni Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti máa ṣiṣẹ́ sin Jésù Kristi, Ọba wa bá a ti ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó ń fi ọlá tó tọ́ sí Jèhófà fún un!

^ ìpínrọ̀ 6 Ní ọdún 2013, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n fọwọ́ sí pé kí wọ́n máa bá ìgbìmọ̀ ìkọ́lé ẹlẹ́kùnjẹkùn méjìléláàdóje [132] tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣiṣẹ́ ju ẹgbàá márùndínlọ́gọ́fà [230,000] lọ. Ní orílẹ̀-èdè yẹn, ọdọọdún ni àwọn ìgbìmọ̀ yẹn máa ń ṣe kòkáárí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tó tó márùndínlọ́gọ́rin [75] tí wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ láti ṣe àtúnṣe àwọn gbọ̀ngàn tó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900].

^ ìpínrọ̀ 9 Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a kọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò sí lábẹ́ ìṣètò yìí kò sí lára iye tá a mẹ́nu kàn yìí.

^ ìpínrọ̀ 16 Àwọn òṣìṣẹ́ káyé àti àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn máa ń lo èyí tó pọ̀ jù lára àkókò wọn lẹ́nu iṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́lé, àmọ́ wọ́n tún máa ń kọ́wọ́ ti ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní òpin ọ̀sẹ̀ tàbí ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́.