Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

Apá òsì: Ìpàdé tá a ṣe ní ìta gbangba nílùú London, lórílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì, lọ́dún 1945; Apá ọ̀tún: Àpéjọ àkànṣe lórílẹ̀-èdè Màláwì, nílẹ̀ Áfíríkà, lọ́dún 2012

 APÁ 5

Ètò Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ìjọba Ọlọ́run​—Bí Àwọn Ìránṣẹ́ Ọba Náà Ṣe Ń Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́

Ètò Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ìjọba Ọlọ́run​—Bí Àwọn Ìránṣẹ́ Ọba Náà Ṣe Ń Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́

 O RẸ́RÌN-ÍN músẹ́ sí arákùnrin tó ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle. Arákùnrin náà kò tíì fi bẹ́ẹ̀ dàgbà, inú ìjọ yín ló sì ti wá. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tó máa ṣiṣẹ́ ní àpéjọ àyíká yín. Bó o ṣe ń gbádùn àsọyé rẹ̀, ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí àwa èèyàn Ọlọ́run ń rí gbà ń wú ọ lórí. O rántí ọjọ́ tó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ lórí pèpéle, o sì wá rí i pé ó ti tẹ̀ síwájú gan-an! Àtìgbà tó ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà ló tún ti ń tẹ̀síwájú síi. Láìpẹ́ yìí, òun àti ìyàwó rẹ̀ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Bó o ṣe ń pàtẹ́wọ́ lẹ́yìn tí arákùnrin náà parí àsọyé alárinrin yìí, o wò yíká, o sì ronú nípa àwọn ìtọ́ni tí gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run ń gbà.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí gbogbo èèyàn Ọlọ́run yóò jẹ́ àwọn “tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Aísá. 54:13) Ìgbà ọ̀hún la wà yìí. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wa kò mọ sórí ohun tí à ń kọ́ látinú àwọn ìtẹ̀jáde wa, àmọ́ ó tún kan àwọn ìpàdé, àpéjọ àyíká, àpéjọ àgbègbè àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ń múra wa sílẹ̀ fún àwọn iṣẹ́ kan pàtó nínú ètò Jèhófà. Nínú apá yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe ń jẹ́ kó dá wa lójú hán-ún hán-ún pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso.