OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Jèhófà ń ṣètò àwọn èèyàn rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé

1, 2. Àyípadà wo ló dé bá ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ní January 1895, báwo ló sì ṣe rí lára àwọn ará?

NÍGBÀ tí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onítara kan tó ń jẹ́ John A. Bohnet gba Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n pè ní Zion’s Watch Tower, ti January 1895, ohun tó rí mú inú rẹ̀ dùn gan-an ni. Àwòrán tuntun tó fani mọ́ra ló wà lára èèpo ìwé ìròyìn náà, àwòrán ilé atọ́nà ọkọ̀ òkun kan. Ó dúró digbí bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjì líle ń jà. Iná tó wà lórí ilé atọ́nà ọkọ̀ òkun náà sì tànmọ́lẹ̀ rekete sójú sánmà. Àkọlé ìfilọ̀ tó wà nínú ìwé ìròyìn náà nípa àwòrán tuntun náà sọ pé, “Ìwé Ìròyìn Wa Wọ Aṣọ Tuntun.”

2 Ohun tí Arákùnrin Bohnet rí yìí wú u lórí débi pé ó kọ lẹ́tà kan sí Arákùnrin Russell. Ó sọ nínú lẹ́tà náà pé: “Inú mi dùn láti rí aṣọ tuntun lára ILÉ ÌṢỌ́ wa. Ó dára gan-an ni.” Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John H. Brown, tóun náà jẹ́ olóòótọ́ kọ̀wé nípa èèpo ìwé ìròyìn náà pé: “Ó fani mọ́ra gan-an ni. Ìpìlẹ̀ tó lágbára tí Ilé Ìṣọ́ náà dúró lé lórí ṣì wà digbí bó tiẹ̀ jẹ́ pé omi òkun tó ń ru gùdù àti ìjì líle ń rọ́ lù ú.” Àwòrán tuntun tó wà lára èèpo ìwé ìròyìn yìí ni àyípadà táwọn ará kọ́kọ́ kíyè sí lọ́dún yẹn, àmọ́ òun kọ́ ni àyípadà kan ṣoṣo tó wáyé. Nígbà tó di oṣù November, wọ́n gbọ́ pé àyípadà pàtàkì kan tún ti wáyé. Ó gbàfiyèsí pé, ó tún ní í ṣe pẹ̀lú òkun tó ń ru gùdù níbi tí ìjì líle ti ń jà.

3, 4. Ìṣòro wo ni Ilé Ìṣọ́ November 15, 1895 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àyípadà ńlá wo la sì kéde?

3 Àpilẹ̀kọ gígùn kan tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 1895 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan, ó ní: Ìṣòro ńlá kan wà tó dà bí ẹ̀fúùfù líle tí kò jẹ́ kí àlááfíà jọba láàárín ẹgbẹ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn arákùnrin ń bá ara wọn jiyàn lórí ẹni tó yẹ kó jẹ́ aṣáájú nínú ìjọ. Kí àwọn ará bàa lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti ṣàtúnṣe ohun tó ń fa ìpínyà àti ẹ̀mí ìbánidíje yẹn, àpilẹ̀kọ́ náà fi ètò Ọlọ́run wé ọkọ̀ òkun. Lẹ́yìn náà, a wá ṣàlàyé láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé àwọn tó ń mú ipò iwájú ni kò ṣe ojúṣe wọn láti múra àwọn tó wà nínú ètò Ọlọ́run tó dà bí ọkọ̀ òkun sílẹ̀ de ìgbà tí ìjì líle máa jà. Kí ló yẹ kí wọ́n ṣe?

4 Àpilẹ̀kọ náà sọ pé ńṣe ni ọ̀gá atukọ̀ òkun tó bá mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ máa rí i dájú pé àwọn ẹ̀wù amúniléfòó àtàwọn nǹkan míì tó lè  gbẹ̀mí àwọn èèyàn là wà nínú ọkọ̀ àti pé àwọn ọmọ iṣẹ́ rẹ̀ ti múra sílẹ̀ kí wọ́n bàa lè la ìjì tó ń bọ̀ já. Bákan náà, ó yẹ káwọn tó ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run rí i dájú pé wọ́n múra gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ sílẹ̀ kí wọ́n bàa lè yanjú àwọn ìṣòro tó dà bí ìjì líle. Kí èyí bàa lè ṣeé ṣe, àpilẹ̀kọ náà kéde àyípadà ńlá kan. Ó ní láti ìgbà yẹn lọ, “kí wọ́n yan àwọn alàgbà nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan” láti máa “‘ṣe àbójútó’ agbo.”—Ìṣe 20:28.

5. (a) Kí nìdí tí ètò àkọ́kọ́ tá a ṣe pé kí àwọn alàgbà wà nínú ìjọ fi jẹ́ ìtẹ̀síwájú tó bọ́ sákòókò? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

5 Ètò àkọ́kọ́ tá a ṣe pé kí àwọn alàgbà wà nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìtẹ̀síwájú tó bọ́ sákòókò, tó mú kí àwọn ìjọ dúró digbí, tó sì jẹ́ kí nǹkan máa lọ bó ṣe yẹ. Ó mú kí àwọn ará wa lè la Ogun Àgbáyé Kìíní yẹn já. Láàárín ọ̀pọ̀ ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn àyípadà tá a ṣe nínú ètò Ọlọ́run ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa jọ́sìn Jèhófà bó ṣe yẹ. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wo ló sọ̀rọ̀ nípa àyípadà yìí? Àwọn àyípadà wo ni ìwọ náà ti rí nínú ètò Ọlọ́run? Báwo làwọn àyípadà náà ṣe ṣe ọ́ láǹfààní?

‘Èmi Yóò Yan Àlàáfíà Ṣe Àwọn Alábòójútó Rẹ’

6, 7. (a) Kí ni ìtúmọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà 60:17? (b) Kí ni “àwọn alábòójútó” àti “àwọn tí ń pínṣẹ́” tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn fi hàn?

6 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i ní Orí 9 ìwé yìí, Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà máa bù kún àwọn èèyàn rẹ̀, ní ti pé wọ́n á máa pọ̀ sí i. (Aísá. 60:22) Àmọ́, Jèhófà tún ṣèlérí pé òun á ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan náà pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin; dájúdájú, èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” (Aísá. 60:17) Kí ni ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn? Báwo ló sì ṣe kàn wá lóde òní?

Àwọn àyípadà tó wáyé kì í ṣe àyípadà búburú sí rere, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àyípadà rere sí èyí tó tún dára sí i

7 Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà máa fi ohun kan rọ́pò òmíràn. Àmọ́, kíyè sí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kò sọ̀rọ̀ nípa àyípadà búburú sí rere, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àyípadà rere sí èyí tó tún dára sí i. Tí wúrà bá rọ́pò bàbà, ìtẹ̀síwájú ló jẹ́, bákàn náà sì lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú àwọn nǹkan tó kù tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn. Torí náà, ńṣe ni Jèhófà lo àpèjúwe yìí láti sàsọtẹ́lẹ̀ pé ipò àwọn èèyàn òun á máa dára sí i ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Irú ìtẹ̀síwájú wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ? Torí pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ̀rọ̀ nípa “àwọn alábòójútó” àti “àwọn tí ń pínṣẹ́,” èyí fi hàn pé ńṣe ni Jèhófà á máa mú kí ìtẹ̀síwájú ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nínú ọ̀nà tí à ń gbà bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run àti ọ̀nà tí à ń gbà ṣètò wọn.

8. (a) Ta ló ń mú kí àwọn ìtẹ̀síwájú tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣeé ṣe? (b) Báwo la ṣe ń jàǹfààní látinú àwọn ìtẹ̀síwájú yìí? (Tún wo àpótí náà, “ Ó Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Gba Ìbáwí.”)

8 Ta ló ń mú kí ìtẹ̀síwájú yìí ṣeé ṣe? Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò mú wúrà wá, . . . Èmi yóò mú fàdákà wá, . . . Èmi yóò sì yan àlàáfíà.” Kò sí àní-àní pé, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń mú kí ìtẹ̀síwájú máa wáyé nínú bá a ṣe ṣètò àwọn ìjọ, kì í ṣe agbára èèyàn rárá. Látìgbà tí Jèhófà sì ti fi Jésù jọba ló ti ń lo Ọmọ rẹ̀ yìí láti mú kí àwọn ìtẹ̀síwájú yìí máa wáyé. Báwo la ṣe ń jàǹfààní látinú àwọn àyípadà yìí? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan náà yìí tún sọ pé àwọn ìtẹ̀síwájú yìí máa yọrí sí “àlàáfíà” àti “òdodo.” Bí a bá ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, tá a sì ń ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, àlàáfíà máa jọba láàárín  wa, ìfẹ́ òdodo tá a ní á sì mú ká máa sin Jèhófà, ẹni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “Ọlọ́run àlááfíà.”—Fílí. 4:9.

9. Tí ètò àti ìṣọ̀kan bá máa wà nínú ìjọ, kí ló yẹ kó jẹ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀, kí sì nìdí?

9 Pọ́ọ̀lù tún sọ nípa Jèhófà pé: “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” (1 Kọ́r. 14:33) Kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù kò fi ètò ṣe ìdàkejì rúdurùdu, àmọ́ àlááfíà ló fi ṣe ìdàkejì rẹ̀. Kí nìdí? Ohun kan ni pé: Wíwà létòlétò kò fi dandan túmọ̀ sí pé nǹkan máa yọrí sí àlàáfíà. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan lè wà létòlétò bí wọ́n ṣe ń yan lọ sójú ogun, àmọ́ wíwà létòlétò wọn kò lè yọrí sí àlááfíà bí kò ṣe ogun. Torí náà, ó yẹ kí àwa Kristẹni fi òótọ́ pàtàkì kan sọ́kàn, ìyẹn ni pé: Ètò tàbí àwùjọ èyíkéyìí tí kò bá ti fi àlàáfíà ṣe ìpìlẹ̀ rẹ̀, bó pẹ́ bó yá, ó máa wó lulẹ̀ ni. Àlàáfíà Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá, torí pé ó máa ń mú kí nǹkan wà létòlétò, mìmì kan ò sì ní lè mi irú ètò bẹ́ẹ̀. A mà dúpẹ́ o, pé “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà” ló ń darí ètò tá a wà nínú rẹ̀, òun ló sì ń mú kó máa tẹ̀ síwájú! (Róòmù 15:33) Àlàáfíà Ọlọ́run ni ìpìlẹ̀ ètò tá à ń jàǹfààní rẹ̀ yìí àti ojúlówó ìṣọ̀kan tá à ń gbádùn, a sì mọyì ètò àti ìṣọ̀kan yìí gan-an nínú àwọn ìjọ Kristẹni kárí ayé.—Sm. 29:11.

10. (a) Àwọn ìtẹ̀síwájú wo ló wáyé nínú ètò Ọlọ́run nígbà yẹn lọ́hùn-ún? (Wo àpótí náà, “ Bí Ìtẹ̀síwájú Ṣe Bá Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Ṣe Iṣẹ́ Àbójútó.”) (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò báyìí?

10 Àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “ Bí Ìtẹ̀síwájú Ṣe Ń Bá Iṣẹ́ Àbójútó” ṣàlàyé díẹ̀ nípa àwọn àǹfààní tí àwọn àyípadà tó wáyé nínú ètò Ọlọ́run mú wá àti bó ṣe mú kí nǹkan wà létòlétò nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Àmọ́, àwọn àyípadà láti ‘bàbà sí wúrà’ wo ni Jèhófà ti tipasẹ̀ Ọba wa mú wá lóde òní? Báwo làwọn àyípadà yẹn ṣe túbọ̀ mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan jọba nínú àwọn ìjọ wa kárí ayé? Báwo làwọn àyípadà yìí ṣe ń mú kó o lè máa sin “Ọlọ́run àlàáfíà” nìṣó?

Bí Kristi Ṣe Ń Darí Ìjọ

11. (a) Àyípadà wo ló wáyé lẹ́yìn ìwádìí kan tó jinlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́? (b) Kí ni àwọn arákùnrin tó para pọ̀ di ìgbìmọ̀ olùdarí pinnu láti ṣe?

11 Láti ọdún 1964 sí 1971, ìgbìmọ̀ olùdarí ṣèwádìí kan tó jinlẹ̀ nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára ohun tí ìwádìí yẹn dá lé ni, bá a ṣe ṣètò àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. * A kẹ́kọ̀ọ́ pé ìgbìmọ̀ alàgbà ló ń bójú tó àwọn ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, dípò kó jẹ́ alàgbà tàbí alábòójútó kan ṣoṣo. (Ka Fílípì 1:1; 1 Tímótì 4:14.) Nígbà tí ìgbìmọ̀ olùdarí wá lóye kókó yẹn dáadáa, wọ́n wá gbà pé Ọba wọn Jésù ló ń tọ́ wọn sọ́nà tí wọ́n fi lè máa tẹ̀ síwájú nínú bí wọ́n ṣe ń ṣètò àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn arákùnrin tó para pọ̀ di ìgbìmọ̀ olùdarí náà sì pinnu pé àwọn á máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọba náà. Kíákíá ni wọ́n ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa ìyànsípò àwọn alàgbà. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àyípadà tí wọ́n ṣe láwọn àkókò kan lẹ́yìn ọdún 1970?

12. (a) Àyípadà wo ló wáyé nínú ìgbìmọ̀ olùdarí? (b) Ṣàlàyé bá a ṣe ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí báyìí. (Wo àpótí náà, “ Bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Jẹ Mọ́ Ìjọba Ọlọ́run,” lójú ìwé 130.)

12 Inú ìgbìmọ̀ olùdarí ni àyípadà àkọ́kọ́ ti wáyé. Ṣáájú àkókò yẹn, àwọn arákùnrin méje tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró náà ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ aláṣẹ àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Lọ́dún 1971, àwọn arákùnrin mẹ́rin míì di ara ìgbìmọ̀ olùdarí, tí iye wọn fi wá jẹ́ mọ́kànlá, àmọ́ wọn kì í ṣe ará ẹgbẹ́ aláṣẹ àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania  mọ́. Kò sí ẹnì kankan lára àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí tó ka ara rẹ̀ sí pàtàkì ju ẹlòmíì lọ. Ṣe ni ipò alága ìgbìmọ̀ náà máa ń yí po lọ́dọọdún láàárín ara wọn bí orúkọ wọn ṣe tò tẹ̀ léra wọn, lọ́nà a, b, d.

13. (a) Ètò wo là ń tẹ̀ lé láti ọdún 1932 sí 1972? (b) Kí ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe lọ́dún 1972?

13 Inú ìjọ ni àyípadà kejì ti wáyé. Lọ́nà wo? Láti ọdún 1932 sí 1972, arákùnrin kan ṣoṣo ló máa ń ṣe àbójútó ìjọ. Ṣáájú ọdún 1936, olùdarí iṣẹ́ ìsìn la máa ń pe arákùnrin tá a yàn náà. Nígbà tó yá, a yí orúkọ yẹn pa dà sí ìránṣẹ́ ìjọ, lẹ́yìn náà a tún wá yí i pa dà sí alábòójútó ìjọ. Àwọn arákùnrin tá a yàn sípò máa ń fìtara bójú tó ipò tẹ̀mí agbo Ọlọ́run. Alábòójútó ìjọ ló máa ń ṣe ìpinnu tó bá kan ìjọ láìjẹ́ pé ó fi tó àwọn ìránṣẹ́ tó kù nínú ìjọ létí. Àmọ́ lọ́dún 1972, Ìgbìmọ̀ Olùdarí múra sílẹ̀ láti ṣe àyípadà mánigbàgbé kan. Àyípadà wo nìyẹn?

14. (a) Ètò wo la bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun ní October 1, 1972? (b) Báwo ni olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà ní Fílípì 2:3 sílò?

14 Dípò tó fi máa jẹ́ pé arákùnrin kan ṣoṣo ló máa jẹ́ alábòójútó ìjọ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, a bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn arákùnrin míì tí wọ́n tóótun níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ là kalẹ̀ láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Àwọn ló máa para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà tí yóò máa ṣe àbójútó ìjọ kọ̀ọ̀kan. October 1, 1972 la bẹ̀rẹ̀ ètò yìí. Lóde òní, olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kì í wo ara rẹ̀ bí ẹni tó ṣe pàtàkì ju àwọn alàgbà tó kù lọ, àmọ́ ńṣe ló máa ń ka ara  rẹ̀ sí “ẹni tí ó kéré jù.” (Lúùkù 9:48) Ìbùkún ńlá ni àwọn arákùnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ fún ẹgbẹ́ ará kárí ayé!—Fílí. 2:3.

Ó ṣe kedere pé ńṣe ni Ọba wa ń fi ọgbọ́n pèsè àwọn olùṣọ́ àgùntàn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àkókò tó tọ́

15. (a) Àwọn ọ̀nà wo ló gbà ṣàǹfààní bá a ṣe ní ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà nínú àwọn ìjọ? (b) Kí ló fi hàn pé Ọlọ́gbọ́n ni Ọba wa?

15 Ìtẹ̀síwájú pàtàkì ló jẹ́ bá a ṣe ṣètò pé ká máa pín ojúṣe ìjọ láàárín àwọn alàgbà. Wo ọ̀nà mẹ́ta tí èyí gbà ṣàǹfààní: Ọ̀nà àkọ́kọ́, kò sí bí ojúṣe alàgbà kan ṣe lè pọ̀ tó nínú ìjọ, ètò yẹn ń mú kí gbogbo àwọn alàgbà máa fi sọ́kàn pé Jésù ni Orí ìjọ. (Éfé. 5:23) Ọ̀nà kejì, Òwe 15:22 sọ pé: “Àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” Bí àwọn alàgbà ṣe ń jíròrò àwọn ọ̀ràn tó kan ipò tẹ̀mí ìjọ, tí wọ́n sì ń ronú pa pọ̀ lórí àwọn àbá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń mú wá, èyí á mú kí wọ́n dorí ìpinnu tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. (Òwe 27:17) Jèhófà máa ń bù kún irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀, ó sì máa ń mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí. Ọ̀nà kẹta, bó ṣe jẹ́ pé àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i tó tóótun ló ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà báyìí nínú ètò Ọlọ́run, àwọn ará ìjọ lè máa rí àbójútó tó yẹ, kí àwọn alàgbà yìí sì lè máa ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ wọn. (Aísá. 60:3-5) Tiẹ̀ rò ó wò ná, ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27,000] ló wà kárí ayé lọ́dún 1971, àmọ́ ó ti ròkè sí ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́fà [113,000] lọ́dún 2013! Ó ṣe kedere pé ńṣe ni Ọba wa ń fi ọgbọ́n pèsè àwọn olùṣọ́ àgùntàn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àkókò tó tọ́.—Míkà 5:5.

 “Kí Ẹ Di Àpẹẹrẹ fún Agbo”

16. (a) Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà? (b) Ọwọ́ wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi mú ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù pé ‘máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn’?

16 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nígbà táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣẹ̀ṣẹ̀ kóra jọ, àwọn alàgbà mọ̀ dáadáa pé ojúṣe àwọn ló jẹ́ láti ran àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa sin Ọlọ́run nìṣó. (Ka Gálátíà 6:10.) Lọ́dún 1908, àpilẹ̀kọ kan jáde nínú Ilé Ìṣọ́ tó dá lé ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù pé: “Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jòh. 21:15-17) Nínú àpilẹ̀kọ yẹn a sọ fún àwọn alàgbà pé: “Ó ṣe pàtàkì pé ká fi ojúṣe tí Ọ̀gá wa gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká máa bójú tó agbo rẹ̀ sípò àkọ́kọ́. Ó sì yẹ ká rí i gẹ́gẹ́ bí àǹfààní ńláǹlà pé à ń bọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa a sì ń bójú tó wọn.” Lọ́dún 1925, a tún rán àwọn alàgbà létí nínú àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ kan bí iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ti ṣe pàtàkì tó. Àpilẹ̀kọ yẹn sọ lápá kan pé: “Ọlọ́run ló ni ìjọ rẹ̀, . . . gbogbo àwọn tó bá wà ní ipò àbójútó nínú ìjọ ló sì máa jíhìn fún Ọlọ́run nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà bójú tó àwọn ará.”

17. Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn alábòójútó ti rí gbà kí wọ́n lè di olùṣọ́ àgùntàn tó tóótun?

17 Báwo ni ètò Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lè tẹ̀ síwájú láti ‘irin sí fàdákà’? Ohun tí wọ́n ń ṣe ni pé, wọ́n ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ọdún 1959 ni ìgbà àkọ́kọ́ tá a ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn alábòójútó. Ọ̀kan lára àwọn kókó tí wọ́n jíròrò ní ilé ẹ̀kọ́ náà ni “Ẹ Máa Fún Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Láfiyèsí.” A gba àwọn alàgbà níyànjú pé kí wọ́n “ṣètò bí wọ́n á ṣe máa lọ bẹ àwọn akéde wò nílé wọn.” A tún ṣàlàyé oríṣiríṣi ọ̀nà táwọn olùṣọ́ àgùntàn lè gbà ṣe ìbẹ̀wò tó ń gbéni ró. Lọ́dún 1966, a tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kan, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí a ti ṣe àwọn àtúnṣe kan sí ilé ẹ̀kọ́ náà. Kókó ọ̀rọ̀ tí ilé ẹ̀kọ́ náà dá lé ni, “Ohun Tó Mú Kí Iṣẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Ṣe Pàtàkì Tó Bẹ́ẹ̀.” Kí ni àwọn kókó pàtàkì tí wọ́n ṣàlàyé ní apá yìí? Wọ́n sọ fún àwọn tó ń mú ipò iwájú pé “kí wọ́n máa fìfẹ́  bójú tó agbo Ọlọ́run, lẹ́sẹ̀ kan náà, kí wọ́n rí i pé wọ́n fún agbo ilé wọn láfiyèsí, kí wọ́n sì máa ṣe déédéé lóde ẹ̀rí.” Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a tún ti ṣètò àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ mìíràn sí i fún àwọn alàgbà. Kí ni àbájáde àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ètò Jèhófà ń fún àwọn alàgbà látìgbàdégbà yìí? Lóde òní, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin tó tóótun ló wà nínú àwọn ìjọ Kristẹni, tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí.

Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Philippines lọ́dún 1966

18. (a) Iṣẹ́ bàǹtàbanta wo la gbé lé àwọn alàgbà lọ́wọ́? (b) Kí nìdí tí Jèhófà àti Jésù fi nífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára?

18 Jèhófà ló ṣètò àwọn alàgbà nípasẹ̀ Ọba wa, Jésù, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta kan. Iṣẹ́ wo nìyẹn? Iṣẹ́ náà ni pé, kí wọ́n darí àwọn àgùntàn Ọlọ́run la àkókò tó léwu jù lọ nínú ìtàn ìran èèyàn tá a wà yìí já. (Éfé. 4:11, 12; 2 Tím. 3:1) Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára, torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tó sọ pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín . . . tinútinú . . . , pẹ̀lú ìháragàgà . . . , kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pét. 5:2, 3) Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára ọ̀pọ̀ ọ̀nà táwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn gbà jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo àti bí wọ́n ṣe ń mú kí àlàáfíà àti ayọ̀ jọba nínú ìjọ.

Bí Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run Lóde Òní

19. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí alàgbà kan bá bá wa ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí?

19 Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni pé, àwọn alàgbà máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará ìjọ. Lúùkù tó jẹ́ ọkàn lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ pé: “Ó ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run. Àwọn méjìlá náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.” (Lúùkù 8:1) Bí Jésù ṣe wàásù pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn alàgbà òde òní ṣe ń fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn lóde ẹ̀rí. Wọ́n gbà pé báwọn ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn ń mú kí ẹ̀mí rere túbọ̀  máa gbilẹ̀ sí i nínú ìjọ. Báwo ni ohun táwọn alàgbà ń ṣe yìí ṣe rí lára àwọn ará ìjọ? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jeannine, tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin [80] ọdún sọ pé: “Tí mo bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú alàgbà lóde ẹ̀rí, àǹfààní ńlá ló máa ń jẹ́ fún mi láti bá alàgbà náà sọ̀rọ̀ kí n sì túbọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa.” Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Steven, tó ti tó ẹni ọdún márùndínlógójì [35] sọ pé: “Tí alàgbà kan bá bá mi ṣiṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, mo gbà pé ńṣe ni alàgbà yẹn fẹ́ ràn mí lọ́wọ́. Tí mo bá sì gba irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, ó máa ń fún mi láyọ̀ gan-an ni.”

Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń wá àgùntàn tó sọ nù rí, bẹ́ẹ̀ làwọn alàgbà ṣe máa ń sapá láti wá àwọn tó ti ṣáko lọ kúrò nínú ìjọ

20, 21. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ olùṣọ́ àgùntàn inú àkàwé Jésù? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àpótí náà, “ Ìbẹ̀wò Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ Tó Sèso Rere.”)

20 Ọ̀nà kejì ni pé, ètò Jèhófà ti kọ́ àwọn alàgbà láti máa fìfẹ́ hàn sí àwọn tó bá ti ṣáko lọ nínú ìjọ. (Héb. 12:12) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn alàgbà ran àwọn aláìlera nípa tẹ̀mí lọ́wọ́, báwo ló sì ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é? A máa rí ìdáhùn nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa olùṣọ́ àgùntàn àti àgùntàn tó sọ nù. (Ka Lúùkù 15:4-7.) Nígbà tí olùṣọ́ àgùntàn inú àkàwé yẹn kíyè sí i pé àgùntàn kan ti sọ nù, ńṣe ló wá àgùntàn náà lọ, àfi bíi pé àgùntàn kan ṣoṣo tó ní nìyẹn. Báwo làwọn Kristẹni alàgbà òde òní ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ olùṣọ́ àgùntàn yẹn? Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé àgùntàn tó sọ nù yẹn ṣì ṣeyebíye lójú olùṣọ́ àgùntàn yẹn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé àwọn tó ti ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣì ṣeyebíye lójú àwọn alàgbà. Ojú àgùntàn tó sọ nù ni wọ́n fi ń wo àwọn aláìlera nípa tẹ̀mí, wọn kì í ronú pé ọ̀rọ̀ wọn ti kọjá àtúnṣe. Bákan náà, bó ṣe jẹ́ pé ńṣe ni olùṣọ́ àgùntàn yẹn pinnu láti ‘wá ọ̀kan tí ó sọnù lọ títí tó fi rí i,’ bẹ́ẹ̀ náà làwọn alàgbà ṣe máa ń lo ìdánúṣe láti wá àwọn aláìlera nípa tẹ̀mí lọ, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́.

21 Kí ni olùṣọ́ àgùntàn inú àkàwé yẹn ṣe nígbà tó rí àgùntàn náà? Ó rọra gbé e nílẹ̀, ó “gbé e lé èjìká rẹ̀,” ó sì dá a pa dà sínú agbo àgùntàn rẹ̀. Bákan náà, tí alàgbà kan bá sọ àwọn ọ̀rọ̀ àtọkànwá tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹnì kan tó jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí jẹ ẹ́ lógún, alàgbà yẹn lè tipa ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbé e dìde, kó sì mú kó pa dà sínú ìjọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Victor nílẹ̀ Áfíríkà nìyẹn, nígbà tó kúrò nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Fún ọdún mẹ́jọ tí mo fi kúrò nínú ìjọ, àwọn alàgbà ṣì ń bá a nìṣó láti ràn mí lọ́wọ́.” Ohun kan wà tó wọ arákùnrin yìí lọ́kàn jù lọ. Ó ṣàlàyé pé: “Lọ́jọ́ kan, alàgbà kan tó ń jẹ́ John tá a jọ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ mi, ó sì fi àwọn fọ́tò kan tá a jọ yà nígbà tá a wà nílé ẹ̀kọ́ náà hàn mí. Ohun tí mo rí yìí wá rán mi létí ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tí mo ti gbádùn sẹ́yìn, débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí láti ní irú ayọ̀ tí mo máa ń ní nígbà tí mò ń sin Jèhófà.” Kò pẹ́ lẹ́yìn tí John ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Victor tí Victor fi pa dà sínú ìjọ. Ní báyìí, ó tún ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà pa dà. Kò sí àní-àní pé bí àwọn alàgbà ṣe ń fìfẹ́ bójú tó ìjọ ń mú kí àwọn ará túbọ̀ máa láyọ̀.—2 Kọ́r. 1:24. *

 Àbójútó Tá A Mú Sunwọ̀n Sí I Ń Mú Kí Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Túbọ̀ Wà Níṣọ̀kan

22. Báwo ni òdodo àti àlàáfíà ṣe ń mú kí ìṣọ̀kan túbọ̀ gbilẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni? (Tún wo àpótí náà, “ Ó Yà Wá Lẹ́nu Gan-an.”)

22 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀, Jèhófà sàsọtẹ́lẹ̀ pé òdodo àti àlááfíà á máa pọ̀ sí i láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Aísá. 60:17) Ńṣe ni àwọn nǹkan méjèèjì yìí máa ń mú kí ìṣọ̀kan ìjọ túbọ̀ máa lagbára. Láwọn ọ̀nà wo? Tó bá kan ti òdodo, ‘Ọlọ́run, Jèhófà kan ṣoṣo ni.’ (Diu. 6:4) Àwọn ìlànà òdodo kan náà ni Jèhófà fi ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ nínú gbogbo ìjọ kárí ayé. Ọ̀kan náà ni àwọn ìlànà rẹ̀ nípa ohun tó dára àti ohun tó burú, wọn ò sì yàtọ̀ nínú “gbogbo ìjọ àwọn ẹni mímọ́.” (1 Kọ́r. 14:33) Torí náà, ọ̀nà kan ṣoṣo tí nǹkan fi lè máa lọ dáadáa nínú ìjọ ni pé kí àwọn ará máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Ní ti àlááfíà, kì í ṣe pé Ọba wa fẹ́ ká máa wà ní àlàáfíà nìkan ni, ó tún fẹ́ ká jẹ́ “ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” (Mát. 5:9) Torí náà, à ń “lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà.” A máa ń lo ìdánúṣe láti yanjú àwọn èdèkòyédè tó lè wáyé láàárín wa. (Róòmù 14:19) À ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan túbọ̀ máa gbilẹ̀ nínú ìjọ.—Aísá. 60:18.

23. Kí ni àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbádùn lóde òní?

23 Nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní November 1895, tó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tá a kéde nínú Ilé Ìṣọ́ pé àwọn alàgbà á máa wà nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, àwọn alàgbà tá a yàn sípò náà sọ ohun kan tó wù wọ́n látọkàn wá. Kí lohun náà? Ohun tó ń wù wọ́n lọ́kàn, tí wọ́n sì ń gbà ládùúrà ni pé kí ìṣètò tuntun yìí mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run “tètè wá ní ìṣọ̀kan ti ìgbàgbọ́.” Pẹ̀lú ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀ ọdún yìí wá, ọkàn wa kún fún ọpẹ́ bá a ṣe ń rí i pé àwọn ìtẹ̀síwájú tí Jèhófà ń tipasẹ̀ Ọba wa mú wá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ń mú ká lè máa sin Jèhófà níṣọ̀kan. (Sm. 99:4) Èyí ti mú kí gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà kárí ayé máa yọ̀ ṣìnkìn bá a ṣe ń rìn “nínú ẹ̀mí kan náà,” tá à ń tẹ̀ lé “ipasẹ̀ kan náà,” tá a sì ń sin “Ọlọ́run àlàáfíà” ní “ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”—2 Kọ́r. 12:18; ka Sefanáyà 3:9.

^ ìpínrọ̀ 11 A tẹ àbájáde ìwádìí jíjinlẹ̀ yẹn sínú ìwé Aid to Bible Understanding.