Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 7

Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù​—Gbogbo Ọ̀nà La Fi Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn

Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù​—Gbogbo Ọ̀nà La Fi Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Àwọn èèyàn Ọlọ́run ń lo onírúurú ọ̀nà láti fi mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ju ti àtẹ̀yìn wá lọ

1, 2. (a) Ọgbọ́n wo ni Jésù lò kó lè bá ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn kan sọ̀rọ̀? (b) Báwo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi olóòótọ́ ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Kí nìdí?

OGUNLỌ́GỌ̀ èèyàn kóra jọ yí Jésù ká ní etí òkun kan, àmọ́ Jésù wọ ọkọ̀ ojú omi kan, ó sì sún díẹ̀ sínú agbami náà. Kí nìdí? Ó mọ̀ pé ohùn òun máa ròkè dáadáa lórí omi, ìyẹn á sì jẹ́ kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó wà níbẹ̀ lè gbọ́ ọ̀rọ̀ òun ketekete.—Ka Máàkù 4:1, 2.

2 Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà tí a bí Ìjọba Ọlọ́run àti ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi olóòótọ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, wọ́n ń lo onírúurú ọ̀nà tuntun tó dóde láti fi tan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn. Lábẹ́ ìdarí Ọba Ìjọba Ọlọ́run, àwa èèyàn Ọlọ́run ń lo ọ̀nà àtinúdá, a sì ń yí ọwọ́ pa dà bí ipò àwọn nǹkan ṣe ń yí pa dà àti bí ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun ṣe ń dóde. A fẹ́ mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ tó bó bá ti lè ṣeé ṣe tó kí òpin tó dé. (Mát. 24:14) Wo díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí a ti gbà mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn níbi yòówù kí wọ́n máa gbé. Kí ìwọ náà wá ronú nípa àwọn ọ̀nà tó o lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àwọn tó tan ìhìn rere náà kálẹ̀ láyé ìgbà yẹn.

Bí A Ṣe Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Ọ̀pọ̀ Rẹpẹtẹ Èèyàn

3. Kí ló dun àwọn ọ̀tá òtítọ́ nípa bí a ṣe ń lo àwọn ìwé ìròyìn?

3 Àwọn ìwé ìròyìn. Arákùnrin Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ti ń tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde láti ọdún 1879, wọ́n ń tan ìhìn Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́ ó da bíi pé láàárín ọdún mẹ́wàá ṣáájú 1914, Kristi darí àwọn nǹkan lọ́nà tí ìhìn rere náà á fi túbọ̀ lè dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn sí i. Ọdún 1903 làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé náà bẹ̀rẹ̀. Lọ́dún yẹn, Ọ̀mọ̀wé E.  L.  Eaton tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwùjọ àwọn àlùfáà ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì kan ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania pe Charles Taze Russell níjà lọ́pọ̀ ìgbà pé kó jẹ́ káwọn pàdé ní gbangba láti jọ wá sọ tẹnu àwọn lórí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Eaton sọ nínú ìwé tó kọ sí Russell pé: “Mo ronú pé tí a bá jọ pàdé tí kálukú wa sì sọ èrò tirẹ̀ níwájú gbogbo ènìyàn lórí díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí èrò àwa méjèèjì kò ti dọ́gba . . . yóò ṣe àwọn aráàlú láǹfààní púpọ̀.” Russell àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ náà gbà pé àwọn aráàlú á nífẹ̀ẹ́ sí i, torí náà wọ́n ṣètò pé kí wọ́n gbé àwọn ìjiyàn náà jáde nínú ìwé ìròyìn kan tó gbajúmọ̀ tó ń jẹ́ The Pittsburgh Gazette. Àwọn èèyàn fẹ́ràn àpilẹ̀kọ tó ń jáde nínú ìwé ìròyìn yìí gan-an, àlàyé òtítọ́ Bíbélì tí Russell ń ṣe sì wú wọn lórí débi pé àwọn olóòtú ìwé ìròyìn náà sọ pé àwọn á kúkú máa gbé àwọn àsọyé tí Russell ń sọ jáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ ò ri pé ibi tí ọ̀rọ̀ yìí wá já sí máa dun àwọn ọ̀tá òtítọ́ gan-an!

Nígbà tó fi máa di ọdún 1914, ó ju ẹgbàá [2,000] ìwé ìròyìn lọ tó ń gbé àwọn ìwàásù Russell jáde

4, 5. Ànímọ́ wo ni Russell ní? Báwo làwọn tó ń mú ipò iwájú ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

4 Láìpẹ́, àwọn ìwé ìròyìn míì náà fẹ́ máa gbé àwọn àsọyé Russell jáde. Nígbà tó fi máa di ọdún 1908, Ilé Ìṣọ́ ròyìn pé àwọn “ìwé ìròyìn mọ́kànlá” ló ń gbé àwọn ìwàásù rẹ̀ yìí jáde déédéé. Àmọ́ o, àwọn arákùnrin tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ìwé ìròyìn dáadáa gba Russell nímọ̀ràn pé tó bá kó àwọn ọ́fíìsì Society kúrò ní ìlú Pittsburgh lọ sí ìlú míì tó gbajúmọ̀ jùyẹn lọ, àwọn ìwé ìròyìn táá máa gbé àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì yẹn jáde yóò túbọ̀ pọ̀ sí i. Russell gbé ìmọ̀ràn náà àti àwọn nǹkan míì tó wé mọ́ ọn yẹ̀ wò dáadáa, ó wá kó àwọn ọ́fíìsì náà lọ sí Brooklyn, ní ìlú New York, lọ́dún 1909. Kí wá ni àbáyọrí rẹ̀? Oṣù mélòó kan péré lẹ́yìn tí wọ́n kó lọ síbẹ̀, ó tó irínwó [400] ìwé ìròyìn tó ń gbé àwọn àsọyé Russell jáde, ọ̀pọ̀ àwọn ìwé ìròyìn míì sì túbọ̀ ń kún wọn lẹ́yìn náà. Nígbà tó fi máa di ọdún 1914 tí Ọlọ́run gbé Ìjọba náà kalẹ̀, ó ju ẹgbàá [2,000] ìwé ìròyìn lọ tó ń gbé àwọn ìwàásù Russell àtàwọn àpilẹ̀kọ rẹ̀ jáde ní èdè mẹ́rin!

5 Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kọ́ wa? Ẹ̀kọ́ náà ni pé, á dára kí àwọn tó ní àṣẹ déwọ̀n àyè kan nínú ètò Ọlọ́run lónìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Russell yìí. Lọ́nà wo? Ní ti pé tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, kí wọ́n máa gba ìmọ̀ràn àwọn míì náà yẹ̀ wò.—Ka Òwe 15:22.

6. Ipa wo ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí a ń gbé jáde nínú ìwé ìròyìn ní lórí ẹnì kan?

6 Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Ìjọba náà tó ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn yẹn yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà. (Héb. 4:12) Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń jẹ́ Ora Hetzel, tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1917, jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ èèyàn tó kọ́kọ́ tipa irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ora sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo wọlé ọkọ, mo lọ kí màmá mi ní ìlú Rochester, ní ìpínlẹ̀ Minnesota. Nígbà tí mo débẹ̀, mo rí i pé wọ́n ń gé àwọn àpilẹ̀kọ kan lára ìwé ìròyìn kan. Àṣé àwọn ìwàásù Russell ni wọ́n ń gé. Màmá mi wá sọ àwọn nǹkan tí wọ́n kọ́ nínú àwọn ìwàásù náà fún mi.” Ora gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yẹn gbọ́, ó sì jẹ́ olóòótọ́ olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run fún nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún.

7. Kí nìdí tí àwọn tó ń múpò iwájú fi tún ọ̀rọ̀ lílo àwọn ìwé ìròyìn láti fi tan ìhìn rere kálẹ̀ gbé yẹ̀ wò?

7 Lọ́dún 1916, ìṣẹ̀lẹ̀ méjì pàtàkì kan mú kí àwọn tó ń múpò iwájú tún ọ̀rọ̀ lílo àwọn ìwé ìròyìn láti fi tan ìhìn rere kálẹ̀ gbé yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Ogun Ńlá tó ń jà nígbà náà jẹ́ kó ṣòro láti rí àwọn ohun èlò ìtẹ̀wé rà. Lọ́dún 1916, ìròyìn tó wá láti ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìwé ìròyìn ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ ìṣòro tí wọ́n ní, ó ní: “Àwọn ìwé ìròyìn tó lé ní ọgbọ̀n [30] péré ló ń gbé àwọn Ìwàásù náà jáde ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ó sì ṣeé ṣe kí iye àwọn ìwé ìròyìn yìí dín kù gan-an láìpẹ́ torí owó bébà tó túbọ̀ ń wọ́n sí i.” Ìṣẹ̀lẹ̀ kejì ni ikú Arákùnrin Russell ní October 31, 1916. Ìyẹn ló fà á tí Ilé Ìṣọ́ December 15, 1916, lédè Gẹ̀ẹ́sì fi kéde pé: “Ní báyìí tí Arákùnrin Russell ti kú, ìwàásù tó ń jáde [nínú àwọn ìwé ìròyìn] yóò dáwọ́ dúró pátápátá.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò  gbé ìwàásù jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn mọ́, àwọn ọ̀nà míì tí à ń lò, irú bíi sinimá Photo-Drama of Creation, ìyẹn àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá, ń kẹ́sẹ járí nìṣó lọ́nà tó ga.

8. Akitiyan wo ni wọ́n ṣe kí wọ́n tó lè ṣe sinimá àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá?

8 Fífi àwòrán sinimá hàn. Nǹkan bí ọdún mẹ́ta ni Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ fi ṣiṣẹ́ lórí sinimá àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá, wọ́n sì wá gbé e jáde lọ́dún 1914. (Òwe 21:5) Bí wọ́n ṣe ṣe ohun tí wọ́n pè ní àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí ni pé, wọ́n fi ọgbọ́n àrà ọ̀tọ̀ gbé ohùn jáde pa pọ̀ mọ́ àwọn àwòrán tó ń rìn, wọ́n sì fi àwọn àwòrán aláwọ̀ mèremère tí wọ́n ṣe sórí gíláàsì kún un, wọ́n wá ń fi hàn gẹ́gẹ́ bíi sinimá lára ògiri. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló kópa nínú àṣefihàn àwọn ìtàn inú Bíbélì, tí wọ́n sì ń ya fọ́tò wọn. Wọ́n tiẹ̀ lo àwọn ẹranko náà nínú rẹ̀. Ìròyìn kan lọ́dún 1913 sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹranko tó wà lọ́gbà ẹranko ńlá kan ni wọ́n lò láti fi ṣe Sinimá tó ní ohùn làwọn ibi tó kan Nóà nínú ìtàn ìṣẹ̀dá ayé náà.” Ní ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwòrán aláwọ̀ mèremère tí wọ́n yà sórí gíláàsì tí wọ́n lò nínú sinimá náà, àwọn ayàwòrán lọ́kùnrin lóbìnrin láti ìlú London, New York, Paris àti Filadẹ́fíà ló fọwọ́ kun àwọn àwòrán náà lọ́kọ̀ọ̀kan pátá.

9. Kí nìdí tí wọ́n fi náwó nára tó bẹ́ẹ̀ sí ṣíṣe sinimá àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò náà?

9 Kí nìdí tí wọ́n fi náwó nára tó bẹ́ẹ̀ sí ṣíṣe sinimá àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá náà? Ìpinnu kan táwọn ará ṣe ní ọ̀wọ́ àpéjọ àgbègbè tó wáyé lọ́dún 1913 sọ ọ́. Ó lọ báyìí pé: “Àwọn ìwé ìròyìn ilẹ̀ Amẹ́ríkà ń ṣe àṣeyọrí tí kò lẹ́gbẹ́ nínú bí wọ́n ṣe ń fi àwọn àwòrán ẹ̀fẹ̀ àti àwòrán míì tí wọ́n ń yà sí àwọn abala ìwé ìròyìn wọn darí èrò àwọn aráàlú. Àwọn sinimá tó ní àwòrán tó ń rìn sì wọ́pọ̀, wọ́n sì tún ṣeé lò lóríṣiríṣi ọ̀nà. Èyí mú kó ṣe kedere pé wọ́n wúlò gan-an. Torí náà, a gbà gbọ́ pé ìyẹn jẹ́ ìdí tó fi tọ́ kí àwa, oníwàásù àti olùkọ́ni ní ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú, fi tọkàntara fọwọ́ sí lílo sinimá aláwọ̀ mèremère àti àwòrán tí ẹ̀rọ ń fi hàn lára ògiri, pé ó jẹ́ ohun tó múná dóko tó sì dára kí àwọn ajíhìnrere àti olùkọ́ni máa lò.”

Apá òkè: Inú ibi tí wọ́n ti ń gbé sinimá àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò jáde; apá ìsàlẹ̀: Àwọn gíláàsì tí wọ́n ya àwòrán àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò sí

10. Báwo ni ibi tí wọ́n ti wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò ṣe pọ̀ tó?

10 Jálẹ̀ ọdún 1914, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń fi àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò náà hàn ní ọgọ́rin [80] ìlú. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ èèyàn tó wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà. Ní ọdún yẹn kan náà, wọ́n fi àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò náà hàn ní orílẹ̀-èdè Denmark, Finland, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Jámánì, New Zealand, Norway, Ọsirélíà, Sweden àti Switzerland. Wọ́n ṣe ẹ̀dà sinimá yìí tí kò fi bẹ́ẹ̀ gùn, tí kò sì ní àwòrán tó ń rìn, kí wọ́n máa lò ó láwọn ìlú kéékèèké. Wọ́n pe ẹ̀dà yìí ní “Eureka Drama,” èyí tó túmọ̀ sí àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìjagunmólú. Owó tí wọ́n fi ṣe é kò tó ti àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò tó kún rẹ́rẹ́, ó sì túbọ̀ rọrùn láti gbé kiri. Nígbà tó fi máa di ọdún 1916, wọ́n ti túmọ̀ àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò yìí tàbí ti àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìjagunmólú sí èdè Armenian, Dano-Norwegian, Faransé, Gíríìkì, Italian, Jámánì, Polish, Sípáníìṣì àti Swedish.

During 1914, the “Photo-Drama” was shown in packed auditoriums

11, 12. Ipa wo ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò ní lórí ọ̀dọ́kùnrin kan? Àpẹẹrẹ wo ló fi lélẹ̀?

11 “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Faransé ní ipa tó ga lórí ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Charles Rohner. Charles sọ pé: “Wọ́n fi àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí hàn ní ìlú mi Colmar, tó wà lágbègbè Alsace, lórílẹ̀-èdè Faransé. Látìbẹ̀rẹ̀ ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí sì ti wú mi lórí gan-an torí bó ṣe ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì lọ́nà tó ṣe kedere.”

12 Bí Charles ṣe ṣèrìbọmi nìyẹn, tó sì wọṣẹ́ alákòókò-kíkún lọ́dún 1922. Ara iṣẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ yàn fún un ni pé kó wà lára àwọn táá máa fi sinimá àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá han àwọn èèyàn ní ilẹ̀ Faransé. Ohun tí Charles sọ nípa iṣẹ́ rẹ̀ yìí ni pé: “Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni wọ́n yàn fún mi. Wọ́n ní kí n máa ta gòjé, wọ́n tún fi mí ṣe ìránṣẹ́ ìnáwó àti ìránṣẹ́ ìwé. Wọ́n sì tún ní kí n máa mú kí àwùjọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀. A máa ń pín ìwé ní àkókò ìsinmi. Àá yan apá kọ̀ọ̀kan gbọ̀ngàn náà fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan. Olúkúlùkù wọn á kó ìwé rẹpẹtẹ dání, wọ́n á lọ fún gbogbo ẹni tó wà níbi tí a pín wọn sí. A tún máa ń gbé tábìlì tí ìwé kún orí rẹ̀ síbi ẹnu ọ̀nà àbáwọlé gbọ̀ngàn náà.” Lọ́dún 1925, ètò Ọlọ́run ní kí Charles wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn, ìlú New York. Wọ́n ní kó máa ṣe olùdarí ẹgbẹ́ akọrin níbi ilé iṣẹ́ rédíò tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ tí wọ́n ń pè ní WBBR. Tí a bá ronú lórí àpẹẹrẹ rere Arákùnrin Rohner, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mo ṣe tán láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yòówù kí wọ́n yàn fún mi kí ìhìn rere Ìjọba náà lè máa tàn káàkiri?’—Ka Aísáyà 6:8.

13, 14. Báwo la ṣe lo rédíò láti fi tan ìhìn rere káàkiri? (Tún wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “ Àwọn Ètò Orí Rédíò WBBR” àti “ Àpéjọ Àgbègbè Mánigbàgbé.”)

13 Rédíò. Láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1929, a ò fi bẹ́ẹ̀ lo sinimá àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá mọ́, rédíò ló tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tó lòde láti máa fi tan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run káàkiri. Ní April 16, 1922, Arákùnrin Rutherford gbóhùn sáfẹ́fẹ́ láti ilé iṣẹ́ rédíò ti Metropolitan Opera House ní ìlú Philadelphia, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, ìyẹn sì ni ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀ níbẹ̀. Wọ́n fojú bù ú pé ó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] èèyàn tó gbọ́ àsọyé náà, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé.” Ọdún 1923 ni wọ́n kọ́kọ́ gbé apá kan ọ̀rọ̀ àpéjọ àgbègbè jáde lórí rédíò. Àwọn tó ń múpò iwájú wá pinnu pé ó máa bọ́gbọ́n mu pé ká kọ́ ilé iṣẹ́ rédíò tiwa, yàtọ̀ sí pé à ń lo àwọn ilé iṣẹ́ rédíò tí wọ́n fi ń ṣòwò. Erékùṣù Staten, ní ìlú New York la kọ́ ilé iṣẹ́ rédíò wa yìí sí, orúkọ rẹ̀ lábẹ́ òfin sì ni WBBR. February 24, 1924, la kọ́kọ́ gbóhùn sáfẹ́fẹ́ níbẹ̀.

Ní 1922, àwọn tá a fojú bù pé wọ́n tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] ló gbọ́ àsọyé náà, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé,” lórí rédíò

14 Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ December 1, 1924, lédè Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàlàyé ìdí tí a fi ń lo rédíò WBBR, ó ní: “A gbà gbọ́ pé nínú gbogbo ọ̀nà tá a ti ń lò bọ̀ látẹ̀yìn, rédíò ni ìnáwó rẹ̀ ṣì kéré jù, òun ló sì wúlò jù láti fi tan ọ̀rọ̀ òtítọ́ káàkiri.” Ó sì wá sọ pé: “Bí Olúwa bá rí i pé ó tọ́ ká tún kọ́ àwọn ilé iṣẹ́ rédíò míì láti máa fi tan òtítọ́ káàkiri, yóò pèsè owó rẹ̀ lọ́nà tó dára lójú rẹ̀.” (Sm. 127:1) Nígbà tó fi máa di ọdún 1926, ilé iṣẹ́ rédíò mẹ́fà ni àwa èèyàn Jèhófà ti ní. Méjì lára ilé iṣẹ́ rédíò náà wà ní Amẹ́ríkà, ìyẹn ilé iṣẹ́ rédíò WBBR ní ìlú New York àti ilé iṣẹ́ rédíò WORD nítòsí ìlú Chicago. Mẹ́rin tó kù sì wà ní ìlú Alberta ní Kánádà, British Columbia, Ontario àti Saskatchewan.

15, 16. (a) Kí ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ní ilẹ̀ Kánádà ṣe nípa àwọn ètò orí rédíò tí a ń gbé jáde? (b) Báwo ni ìwàásù orí rédíò àti ìwàásù àtilé dé ilé ṣe ń ti ara wọn lẹ́yìn?

15 Àmọ́ àwọn aṣáájú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń kíyè sí bí a ṣe ń gbé òtítọ́ Bíbélì sáfẹ́fẹ́ lọ́nà tó gbòòrò yìí. Arákùnrin Albert Hoffman, tó mọ̀ nípa iṣẹ́ tí à ń ṣe nílé iṣẹ́ rédíò tó wà ní ìgbèríko Saskatchewan lórílẹ̀-èdè Kánádà, sọ pé: “Àwọn èèyàn púpọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ nípa àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì [ìyẹn orúkọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ nígbà yẹn]. A fi àwọn ètò orí rédíò yìí jẹ́rìí fáwọn èèyàn gan-an títí di ọdún 1928 tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ àwọn aláṣẹ nípa wa, tó fi wá di pé gbogbo ilé iṣẹ́ rédíò tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń lò ní ilẹ̀ Kánádà kò tún rí ìwé àṣẹ gbà mọ́.”

16 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé iṣẹ́ rédíò wa ní Kánádà kógbá sílé, a ṣì ń gbé àsọyé Bíbélì sáfẹ́fẹ́ lórí àwọn rédíò tí wọ́n fi ń ṣòwò. (Mát. 10:23) Kí àwọn èèyàn lè jàǹfààní àwọn ètò orí rédíò yìí dáadáa, Ilé Ìṣọ́ àti The Golden Age (tí à ń pè ní Jí! báyìí) ń tẹ orúkọ àwọn ilé iṣẹ́ rédíò tí a sanwó fún tó ń gbé òtítọ́ Bíbélì sáfẹ́fẹ́ jáde, kí àwọn akéde  tó ń wàásù láti ilé dé ilé lè máa sọ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa tẹ́tí sí àwọn àsọyé náà lórí ìkànnì rédíò tó wà ládùúgbò wọn. Ipa wo nìyẹn ní lórí àwọn èèyàn? Ipa wo nìyẹn ní lórí àwọn èèyàn? Ìwé Bulletin ti January 1931 sọ pé: “Àwọn ètò orí rédíò yìí ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù àtilé délé túbọ̀ rọrùn gan-an fún àwọn ará láti ṣe. Ọ̀pọ̀ ìròyìn la ti gbọ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn èèyàn kan tẹ́tí sí ètò orí rédíò wa, àwọn àsọyé Arákùnrin Rutherford tí wọ́n sì gbọ́ níbẹ̀ jẹ́ kó yá wọn lára láti gba àwọn ìwé tí a fi lọ̀ wọ́n.” Ìwé Bulletin wá sọ pé ètò orí rédíò tí à ń ṣe àti iṣẹ́ ìwàásù àtilé dé ilé jẹ́ “ọ̀nà méjì pàtàkì tí ètò Olúwa gbà ń tan òtítọ́ kálẹ̀.”

17, 18. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò nǹkan yí pa dà, báwo ni rédíò ṣì ṣe ń kó ipa pàtàkì?

17 Láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1939, wọ́n gbógun ti lílò tí à ń lo àwọn ilé iṣẹ́ rédíò tí a sanwó fún. Torí náà, nígbà tí ọdún 1937 ń parí lọ, àwọn èèyàn Jèhófà yíwọ́ pa dà láti fi bá bí ipò nǹkan ṣe ń lọ mu. Wọn ò lo àwọn ilé iṣẹ́ rédíò tí wọ́n ń sanwó fún mọ́, wọ́n túbọ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù àtilé délé. * Àmọ́ ṣá o, rédíò ṣì ń kó ipa pàtàkì nínú títan ọ̀rọ̀ Ìjọba náà kiri láwọn ibi jíjìnnàréré àti ní àwọn apá ibi kan láyé tí ọ̀rọ̀ ìṣèlú kò jẹ́ kí àwọn aráàlú lè bá àwọn orílẹ̀-èdè míì lájọṣe. Bí àpẹẹrẹ, ilé iṣẹ́ rédíò kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Berlin, ní ilẹ̀ Jámánì máa ń gbé àwọn àsọyé Bíbélì sáfẹ́fẹ́ déédéé láti ọdún 1951 sí ọdún 1991, kí àwọn tó ń gbé ní àwọn apá ibi tí wọ́n mọ̀ sí Ìlà Oòrùn Jámánì tẹ́lẹ̀ lè máa gbọ́ ìhìn Ìjọba náà. Láti ọdún 1961 sí ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, ilé iṣẹ́ rédíò kan tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ ní ilẹ̀ Suriname tó wà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù ń gbé ètò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún jáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi tan ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì kálẹ̀. Láti ọdún 1969 sí 1977, ó ju àádọ́ta lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún [350] ètò orí rédíò tí wọ́n gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè gbé e sáfẹ́fẹ́. Ohun tí wọ́n pe ọ̀wọ́ ètò tí wọ́n ń ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì yẹn ni “Gbogbo Ìwé Mímọ́ Ni Ó Ṣàǹfààní.” Ọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́sàn-án [291] ilé iṣẹ́ rédíò ló ń gbé ètò náà sáfẹ́fẹ́ ní ìpínlẹ̀ méjìdínláàádọ́ta [48] lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́dún 1996, ilé iṣẹ́ rédíò kan ní ìlú Apia tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Samoa ní Gúúsù Òkun Pàsífíìkì máa ń gbé ètò kan jáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. “Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Rẹ Lórí Bíbélì” ni orúkọ ètò náà.

18 Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún ogún ń parí lọ, a kó fi rédíò kó ipa pàtàkì mọ́ nínú títan ìhìn rere kálẹ̀. Àmọ́, ẹ̀rọ ìgbàlódé míì dóde tó mú kó ṣeé ṣe láti tan ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tá ò tíì rí irú ẹ̀ rí láyé.

19, 20. Kí nìdí ti àwa èèyàn Jèhófà fi ń lo ìkànnì wa jw.org? Báwo ló ṣe wúlò tó? (Tún wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “ JW.ORG.”)

19 Ẹ̀rọ Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìṣirò ti ọdún 2013 fi hàn pé àwọn èèyàn tó dín díẹ̀ ní bílíọ̀nù mẹ́ta ló ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìdajì èèyàn inú ayé. Àwọn kan fojú bù ú pé nǹkan bí bílíọ̀nù méjì èèyàn ló máa ń fi ẹ̀rọ alágbèéká bíi fóònù tó lágbára àti ẹ̀rọ tí wọ́n ń pè ní tablet lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Iye àwọn tó ń lò ó sì ń pọ̀ sí i kárí ayé. Ṣùgbọ́n ní báyìí, ilẹ̀ Áfíríkà làwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lórí ẹ̀rọ alágbèéká ti túbọ̀ ń pọ̀ sí i jù, torí pé níbẹ̀, àwọn èèyàn tó ju àádọ́rùn-ún [90] mílíọ̀nù lọ ló ní ètò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ń sanwó fún, tí wọ́n ń lò lórí ẹ̀rọ alágbèéká wọn. Ìtẹ̀síwájú wọ̀nyí ti mú kí ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà ń gba ìsọfúnni yí pa dà gan-an.

20 Láti ọdún 1997 làwa èèyàn Jèhófà ti ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì yìí tó jẹ́ ọ̀nà téèyàn lè gbà mú ìsọfúnni dé ọ̀dọ̀ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Ní 2013, a bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì náà jw.org, ó sì wà ní ọ̀ọ́dúnrún [300] èdè. A kó ìsọfúnni tó dá lórí Bíbélì síbẹ̀, tí àwọn èèyàn lè wà jáde ní èdè tó ju ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta [520] lọ. Lójoojúmọ́, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógójì o lé ẹgbàárùn [750,000] ìbẹ̀wò lọ́kan-kò-jọ̀kan làwọn èèyàn ń ṣe sórí ìkànnì wa yìí. Lóṣooṣù, yàtọ̀ sí wíwa fídíò jáde láti wò, ó ju mílíọ̀nù mẹ́ta odindi ìwé, mílíọ̀nù mẹ́rin odindi ìwé ìròyìn àti mílíọ̀nù méjìlélógún ohun àtẹ́tígbọ́ táwọn èèyàn ń wà jáde níbẹ̀.

21. Ẹ̀kọ́ wo lo kọ́ nínú ìrírí tí a sọ nípa Sina?

21 Ìkànnì yìí ti wá di ọ̀nà kan pàtàkì tó múná dóko tí a gbà ń tan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀, àní ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2013, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sina dé ibi ìkànnì jw.org wa, ó sì tẹ orílé iṣẹ́ wa tó wà ní Amẹ́ríkà láago, pé òun fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì. Kí nìdí tí pípè tó pè fi ṣàrà ọ̀tọ̀? Ìdí ni pé Mùsùlùmí ni Sina, ó sì ń gbé ní abúlé àdádó kan lórílẹ̀-èdè kan tí ìjọba kò ti fi bẹ́ẹ̀ gba iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè. Bí Sina ṣe wá pè yìí, a ṣètò pé kí Ẹlẹ́rìí kan máa bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ láti Amẹ́ríkà. Kámẹ́rà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ń lò láti fi rí ara wọn tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan Lẹ́kọ̀ọ́

22, 23. (a) Ǹjẹ́ a ti fi àwọn ọ̀nà tí a gbà ń mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn rọ́pò iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé? (b) Báwo ni Ọba wa ṣe bù kún ìsapá wa?

22 Kò sí èyíkéyìí lára àwọn ọ̀nà tí a ti lò láti fi mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tá a fẹ́ kó rọ́pò iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé. Ì báà jẹ́ ìwé ìròyìn, sinimá àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò, àwọn ètò orí rédíò tàbí ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn èèyàn Jèhófà ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀. Jésù ò kàn máa wàásù fún àwùjọ èèyàn rẹpẹtẹ nìkan, ṣe ló gbájú mọ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Lúùkù 19:1-5) Jésù tún dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kí àwọn náà lè máa ṣe bíi tirẹ̀, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n máa sọ. (Ka Lúùkù 10:1, 8-11.) Bí a ṣe sọ ní Orí 6, àwọn tó ń múpò iwájú máa ń rọ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé ká máa wàásù fáwọn èèyàn lójúkojú.—Ìṣe 5:42; 20:20.

23 Ọgọ́rùn-ún ọdún kan lẹ́yìn tí a bí Ìjọba Ọlọ́run, àwọn akéde tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ ló ń kópa tó jọjú nínú kíkọ́ àwọn èèyàn nípa àwọn ète Ọlọ́run. Láìsí àní-àní, Ọba wa ti fìbùkún sí àwọn ọ̀nà tá a lò láti fi fọn rere Ìjọba náà. Bí a ṣe máa rí i ní orí tó kàn, Ọba náà ti tún pèsè àwọn ohun èlò tá a nílò ká lè tan ìhìn rere náà kálẹ̀ dé gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti ahọ́n.—Ìṣí. 14:6.

^ ìpínrọ̀ 17 Lọ́dún 1957, àwọn tó ń múpò iwájú ti èyí tó kẹ́yìn nínú ilé iṣẹ́ rédíò wa, ìyẹn WBBR ní ìlú New York.