Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ǹjẹ́ ó wù ọ́ láti rí bí àwọn ìlérí Ìjọba náà yóò ṣe ṣẹ?

 APÁ 7

Àwọn Ìlérí Ìjọba Ọlọ́run—Ó Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Ọ̀tun

Àwọn Ìlérí Ìjọba Ọlọ́run—Ó Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Ọ̀tun

 O KÁ èso ápù ńlá kan tó pọ́n gan-an lára ẹ̀ka rẹ̀. O kọ́kọ́ fara balẹ̀ gbọ́ òórùn dídùn rẹ̀ tó ń tá sánsán ná kó o tó fi sínú apẹ̀rẹ̀ táwọn ápù yòókù wà. O ti ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀, ṣùgbọ́n kò rẹ̀ ọ́, ṣe lo tiẹ̀ ṣì fẹ́ ṣe díẹ̀ sí i. Ìyá rẹ wà níbi igi ápù míì nítòsí, ó ń fi ìdùnnú ṣiṣẹ́, tí òun àtàwọn tẹbí-tọ̀rẹ́ tí wọ́n wá bá a kórè sì jọ ń ṣàwàdà bí wọ́n ṣe ń báṣẹ́ lọ. Ìyá rẹ wá dà bí ọ̀dọ́, ó sì ń ta kébékébé bó o ṣe mọ̀ ọ́n nígbà tó o wà lọ́mọdé láyé ìgbà yẹn. Àfi bíi pé òun kọ́ lo rí bó ṣe ń darúgbó nínú ayé tó ti kọjá lọ tipẹ́tipẹ́ yẹn. Kódà o mọ ìgbà tó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn títí ara rẹ̀ fi di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. O di ọwọ́ rẹ̀ mú nígbà tó fi máa mí kanlẹ̀ tó sì kù, o sì sunkún nígbà tí wọ́n ń sin òkú rẹ̀. Àmọ́ òun rèé láàyè báyìí, àtàwọn èèyàn míì náà, ara gbogbo wọn sì le pọ́nkí!

A mọ̀ dájú pé ọjọ́ ń bọ̀ tí nǹkan yóò rí báyìí. A mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé àwọn ìlérí Ọlọ́run kì í yẹ̀. Ní apá yìí, a ó wo bí àwọn kan lára àwọn ìlérí Ìjọba náà yóò ṣe ṣẹ láìpẹ́ yìí, tí yóò sì yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. A ó tún wo díẹ̀ lára àwọn ìlérí Ìjọba náà tó mórí ẹni yá gágá tí yóò ṣẹ lẹ́yìn náà. Inú wa yóò dùn gan-an ni láti wà níbẹ̀ nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso gbogbo ayé yìí, tí ó ń sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!