Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

Apá òsì: Ọdún 1926 ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì kẹ́yìn; apá ọ̀tún: Àwọn èèyàn kíyè sí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá yàtọ̀

 APÁ 3

Àwọn Ìlànà Ìjọba Ọlọ́run​—Bá A Ṣe Wá Òdodo Ọlọ́run

Àwọn Ìlànà Ìjọba Ọlọ́run​—Bá A Ṣe Wá Òdodo Ọlọ́run

 LẸ́NU àìpẹ́ yìí, o rí i pé aládùúgbò rẹ kan máa ń wo ìwọ àti ìdílé rẹ. Bí o ṣe ń kọjá lọ o juwọ́ sí i, òun náà sì juwọ́ sí ẹ. Ó wá ṣẹ́wọ́ sí ẹ pé kó wá. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ mo lè bí ẹ ní ìbéèrè kan? Kí ló mú kí ẹ dá yàtọ̀?” O wá bi í pé: “Kí lo ní lọ́kàn gan-an?” Ó wá sọ pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, àbí? Ẹ yàtọ̀ sáwọn èèyàn yòókù pátápátá. Ẹ kì í ṣe bí àwọn ẹlẹ́sìn yòókù, torí pé ẹ kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa n ṣe, ẹ kì í sì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú àti ogun. Kò sí ẹnì kankan nínú yín tó ń mu sìgá. Àti pé ìwà ọmọlúwàbí ni ìdílé rẹ máa ń hù. Kí ló mú kí ẹ yàtọ̀ pátápátá?”

O mọ̀ pé ohun tó fà á tá a fi yàtọ̀ ni pé: Ìlànà Ìjọba Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé. Gẹ́gẹ́ bí Ọba, gbogbo ìgbà ni Jésù ń yọ́ wa mọ́. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, èyí sì ń jẹ́ ká dá yàtọ̀ nínú ayé búburú yìí. Nínú apá yìí, a máa rí bí Ìjọba Mèsáyà ṣe ń yọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ́ nípa tẹ̀mí, ní ti àwọn àṣà àtàwọn ìwà kan àti ní ti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètò nǹkan, kí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe lè máa fi ògo fún Jèhófà.