Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

 ORÍ 15

Bí A Ṣe Jà fún Òmìnira Láti Lè Máa Sin Jèhófà Láìsí Ìdíwọ́

Bí A Ṣe Jà fún Òmìnira Láti Lè Máa Sin Jèhófà Láìsí Ìdíwọ́

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Bí Kristi ṣe ran àwa ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ ká lè fi orúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin ká sì lo ẹ̀tọ́ tá a ní láti pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́

1, 2. (a) Ẹ̀rí wo lo ní láti fi hàn pé ọmọ Ìjọba Ọlọ́run lo jẹ́ lóòótọ́? (b) Kí nìdí tó fi máa ń pọn dandan fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti jà nígbà míì ká lè ní òmìnira láti máa sin Jèhófà láìsí ìdíwọ́?

ṢÉ ỌMỌ Ìjọba Ọlọ́run ni ọ́? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni, torí pé o jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ̀rí wo lo ní láti fi hàn pé ọmọ Ìjọba Ọlọ́run lo jẹ́ lóòótọ́? Kì í ṣe ìwé àṣẹ ìrìn àjò tàbí oríṣi ìwé míì tí wọ́n ń gbà lọ́dọ̀ ìjọba ni ẹ̀rí náà. Kàkà bẹ́ẹ̀ bó o ṣe ń sin Jèhófà Ọlọ́run ló máa pinnu bóyá o jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run lóòótọ́. Ìjọsìn tòótọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ohun tó o gbà gbọ́ nìkan. Ó tún kan àwọn ohun tí ò ń ṣe, ìyẹn bó o ṣe ń pa àwọn àṣẹ Ìjọba Ọlọ́run mọ́. Ní ti gbogbo àwa tá a jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run, ìjọsìn wa kan gbogbo ohun tí à ń ṣe ní ìgbésí ayé wa, títí kan bí a ṣe ń bójú tó ìdílé wa àti ohun tá a máa ń ṣe tí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìtọ́jú ìṣègùn bá délẹ̀.

2 Àmọ́ àwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ ka bá a ṣe jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọrun sí, wọn ò sì fojú pàtàkì wo àwọn ohun tí Ìjọba Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa. Àwọn ìjọba kan ti gbìyànjú láti dí ìjọsìn wa lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n pa á rẹ́ pátápátá. Nígbà míì, ó máa ń pọn dandan fún àwa ọmọ abẹ́ Ìjọba Kristi pé ká jà fún òmìnira láti lè pa òfin Ìjọba Mèsáyà mọ́ láìsí ìdíwọ́. Àbí ìyẹn yà ọ́ lẹ́nu? Kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ́ Bíbélì, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn Jèhófà ní láti jà fún òmìnira láti lè máa jọ́sìn rẹ̀ láìsí ìdíwọ́.

3. Kí ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ní láti jà fún nígbà ayé Ẹ́sítérì Ayaba?

3 Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Ẹ́sítérì Ayaba, àwọn èèyàn Ọlọ́run jà fitafita nítorí ẹ̀mí wọn. Kí nìdí? Hámánì, èèyànkéèyàn tó jẹ́ Igbá Kejì Ọba sọ fún Ahasuwérúsì Ọba Páṣíà pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù tó wà láwọn àgbègbè tí ọba náà ń ṣàkóso, torí pé “òfin wọn . . . yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn ènìyàn yòókù.” (Ẹ́sít. 3:8, 9, 13) Ǹjẹ́ Jèhófà fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀? Rára o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó bù kún ìsapá Ẹ́sítérì àti Módékáì nígbà tí wọ́n rọ Ọba Páṣíà pé kó má ṣe pa àwọn èèyàn Ọlọ́run.—Ẹ́sít. 9:20-22.

4. Kí la máa jíròrò nínú orí yìí?

4 Lóde òní ńkọ́? Bá a ṣe rí i nínú orí tó ṣáájú, ìgbà míì wà tí àwọn aláṣẹ ayé máa ń ta ko àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nínú orí yìí, a máa jíròrò bí irú àwọn ìjọba bẹ́ẹ̀ ṣe gbìyànjú láti dí ìjọsìn wa lọ́wọ́. A máa sọ̀rọ̀ nípa kókó mẹ́ta tó gbòòrò gan-an: (1) ẹ̀tọ́ tá a ní láti fi orúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin ká sì máa ṣe ìjọsìn lọ́nà tá a fẹ́,  (2) òmìnira tá a ní láti yan ìtọ́jú ìṣègùn tó bá ìlànà Bíbélì mu, àti (3) ẹ̀tọ́ tí àwọn òbí ní láti fi ìlànà Jèhófà kọ́ àwọn ọmọ wọn. Bí a bá ṣe ń jíròrò ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kókó yìí, a máa rí bí àwọn tó fi tọkàntọkàn rọ̀ mọ́ Ìjọba Mèsáyà ṣe jà fitafita láti fi hàn pé wọ́n mọyì bí wọ́n ṣe jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run àti bí Jèhófà ṣe bù kún ìsapá wọn.

Bí A Ṣe Sapá Láti Fi Orúkọ Ẹ̀sìn Wa Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin Ká sì Ní Òmìnira Tó Yẹ

5. Àǹfààní wo ni àwa Kristẹni máa ní tá a bá fi orúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin?

5 Ǹjẹ́ a nílò ká fi orúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dọ̀ ìjọba èèyàn ká tó lè sin Jèhófà? Rárá o! Àmọ́ tá a bá fi orúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ó máa jẹ́ kó rọrùn láti máa ṣe ìjọsìn wa. Bí àpẹẹrẹ, ó máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti máa ṣèpàdé nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa láìsí ìdíwọ́, á sì tún jẹ́ kó rọrùn fún wa láti máa tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì àti láti máa kó wọn wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè, ká sì máa wàásù ìhìn rere fún àwọn aládùúgbò wa fàlàlà. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin, a sì ní òmìnira láti máa ṣe ìjọsìn wa bí àwọn míì tó fi orúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ṣe ní in. Àmọ́ kí làwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ìjọba kan kò gbà láti fi orúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ tàbí tí wọn kò fún wa ní òmìnira tó yẹ?

6. Àwọn ìṣòro wo ló dojú kọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1940 sí 1943 lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà?

6 Orílẹ̀-Èdè Ọsirélíà. Ní ọdún 1940 sí 1943, aláṣẹ orílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé àwọn ohun tá a gbà gbọ́ “jẹ́ ewu” fún gbogbo ìsapá tí àwọn ń ṣe láti jagun. Ni wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lè ṣèpàdé, wọn ò sì lè wàásù ní gbangba. Ìjọba ti Bẹ́tẹ́lì pa, wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. Wọn kò fàyè gba ẹnikẹ́ni láti ní àwọn ìwé wa. Lẹ́yìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Ọsirélíà ti ń ṣe ìjọsìn wọn lábẹ́lẹ̀ fún ọdún mélòó kan, ara tu wọ́n nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ní June 14, 1943, Ilé Ẹjọ́ Gíga ti Ilẹ̀ Ọsirélíà wọ́gi lé ìfòfindè náà.

7, 8. Ṣàlàyé bí àwọn ará wa nílẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe jà fún ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n lè ní òmìnira láti máa sin Jèhófà láìsí ìdíwọ́.

7 Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà. Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ Ìjọba Kọ́múníìsì fi fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó tó wá di ọdún 1991 tí wọ́n gbà pé ká fi orúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Lẹ́yìn tí ìjọba Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí tú ká, Ìjọba Ilẹ̀ Rọ́ṣíà fi orúkọ wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1992. Àmọ́ kò pẹ́ rárá tí inú fi bẹ̀rẹ̀ sí í bí àwọn kan tó ń ṣàtakò wa torí bá a ṣe ń pọ̀ sí i lọ́nà tó yára kánkán, pàápàá àwọn tó ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn alátakò fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilé ẹjọ́ láàárín ọdún 1995 sí 1998. Ní gbogbo ìgbà márààrún, agbẹjọ́rò àwọn tó fẹ̀sùn kàn wá kò rí ẹ̀rí kankan mú wá láti fi hàn pé a jẹ̀bi. Síbẹ̀ àwọn alátakò yìí kò dẹwọ́, wọ́n tún fi ẹ̀sùn kàn wá lórúkọ àwọn aráàlú lọ́dún 1998. Ilé ẹjọ́ kọ́kọ́ dá wa láre, àmọ́ nígbà tí àwọn alátakò yìí pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ilé ẹjọ́ dá wa lẹ́bi ní oṣù May 2001. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í tún ẹjọ́ náà gbọ́ ní  oṣù October 2001. Nígbà tó sì di ọdún 2004, ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n wọ́gi lé orúkọ ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin ní ìlú Moscow kí wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ wa.

8 Bí inúnibíni tó gbóná janjan tún ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. (Ka 2 Tímótì 3:12.) Wọ́n fojú àwọn ará wa rí màbo wọ́n sì hùwà ìkà sí wọn. Wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé wa, wọn kò sì gbà wá láyè láti kọ́ ilé ìjọsìn tàbí ká yá a lò. Ronú nípa bí àwọn ohun tí kò rọgbọ tó wáyé yìí ṣe máa rí lára àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ẹjọ́ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù lọ́dún 2001, a sì tún fi ẹ̀rí púpọ̀ sí i kún un lọ́dún 2004. Nígbà tó di ọdún 2010, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá ẹjọ́ náà. Ilé ẹjọ́ náà rí i kedere pé ẹ̀tanú ìsìn ló mú kí wọ́n fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ó sì wọ́gi lé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà ṣe torí pé kò sí ẹ̀rí kankan láti fi ti àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá lẹ́yìn. Ilé ẹjọ́ náà tún sọ pé torí kí wọ́n lè gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ẹ̀tọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní lábẹ́ òfin ni wọ́n ṣe hùmọ̀ láti fi òfin de iṣẹ́ wa. Ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ yìí ṣe fi ìdí ẹ̀tọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wá múlẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣì ń kọ etí ikún sí ìdájọ́ yìí, bí ilé ẹjọ́ ṣe ń dá wa láre yìí ti jẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórílẹ̀-èdè náà túbọ̀ ní ìgboyà gan-an.

Titos Manoussakis (Wo ìpínrọ̀ 9)

9-11. Báwo ni àwọn èèyàn Jèhófà lórílẹ̀-èdè Gíríìsì ṣe jà fún ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti máa jọ́sìn pa pọ̀? Ibo lọ̀rọ̀ náà sì yọrí sí?

9 Orílẹ̀-Èdè Gíríìsì. Lọ́dún 1983, Arákùnrin Titos Manoussakis gba yàrá kan ní ìlú Heraklion, erékùṣù Crete, kí àwọn ara wa mélòó kan lè máa ṣe ìpàdé níbẹ̀. (Héb. 10:24, 25) Kò pẹ́ sígbà yẹn ni olórí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan lọ fi ẹ̀sùn kàn wá lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọba pé à ń ṣe ìjọsìn nínú yàrá. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ yàtọ̀ sí ti àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì! Ni wọ́n bá fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan Arákùnrin Titos Manoussakis àtàwọn ará wa mẹ́ta míì, wọ́n sì gbé wọn lọ sílé ẹjọ́. Wọ́n bu owó ìtanràn lé wọn, wọ́n sì fi wọ́n sí ẹ̀wọ̀n oṣù méjì. Tọkàntọkàn ni àwọn ará wa fi rọ̀ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, torí náà wọ́n rí i pé ìdájọ́ náà kò ní jẹ́ káwọn ní òmìnira láti máa jọ́sìn Ọlọ́run láìsí ìdíwọ́. Wọ́n bá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí àwọn ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè náà, nígbà tó sì yá, ọ̀rọ̀ náà dé Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.

10 Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dájọ́ náà lọ́dún 1996, ó sì pa àwọn alátakò ìjọsìn tòótọ́ lẹ́nu mọ́. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé, “Ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára ‘ẹ̀sìn táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa’ lábẹ́ òfin ilẹ̀ Gíríìsì.” Ó tún sọ pé ẹjọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ dá náà kò ní jẹ́ kí “ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn yìí lè ní òmìnira láti ṣe ìjọsìn rẹ̀ fàlàlà.” Ilé ẹjọ́ náà fi kún un pé ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì kò ní àṣẹ láti “pinnu bóyá ẹ̀kọ́ ìsìn tàbí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ náà bófin mu tàbí kò bófin mu.” Bí wọ́n ṣe wọ́gi lé ẹjọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ dá lòdì sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn, wọ́n sì túbọ̀ fi ìdí òmìnira tí a ní láti máa ṣe ẹ̀sìn wa múlẹ̀!

 11 Ṣé ẹjọ́ tí a jàre rẹ̀ yìí fòpin sí àtakò tí wọ́n ń ṣe sí wa nílẹ̀ Gíríìsì? Ó ṣeni láàánú pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn ọdún méjìlá gbáko tí irú ọ̀rọ̀ yìí ti wà ní ilé ẹjọ́ ní ìlú Kassandreia, lórílẹ̀-èdè náà, wọ́n fẹnu ọ̀rọ̀ náà jóná lọ́dún 2012. Bíṣọ́ọ̀bù kan ní Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ló fẹ̀sùn kàn wá. Àmọ́ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Orílẹ̀-Èdè Gíríìsì, tó láṣẹ jù lórílẹ̀-èdè náà dá àwa èèyàn Ọlọ́run láre. Nínú ìpinnu tí ìgbìmọ̀ yìí ṣe, wọ́n tọ́ka sí òfin ilẹ̀ Gíríìsì pé ó fún àwọn èèyàn ní òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù wọ́n àti pé kò tọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé ẹ̀sìn wa kì í ṣe ẹ̀sìn táwọn èèyàn mọ̀. Ìgbìmọ̀ náà sọ pé: “Àwọn ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ kì í ṣe nǹkan àṣírí, torí náà ẹ̀sìn táwọn èèyàn mọ̀ délé dóko ni.” Inú ìwọ̀nba àwọn ará tó wà nínú ìjọ Kassandreia dùn gan-an pé wọ́n ti lè máa ṣe ìpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba báyìí.

12, 13. Báwo ni àwọn alátakò lórílẹ̀-èdè Faransé ṣe gbìyànjú láti fi “àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n”? Ibo lọ̀rọ̀ náà sì já sí?

12 Orílẹ̀-Èdè Faransé. Àwọn kan tó ń ṣàtakò àwa èèyàn Ọlọ́run ti dọ́gbọ́n “fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n.” (Ka Sáàmù 94:20.) Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1994 sí 1996, àjọ tó ń bójú tó owó orí lórílẹ̀-èdè Faransé bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò ètò ìnáwó ọ̀kan lára àwọn àjọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè náà, ìyẹn Association Les Témoins de Jéhovah (ATJ). Aṣojú ọ́fíìsì ìjọba tó ń bójú tó ìnáwó sọ ojú abẹ níkòó nípa ibi tí àyẹ̀wò náà lè já sí pé: “Àyẹ̀wò yìí lè mú kí ilé ẹjọ́ ti ọ́fíìsì àwọn tí ọ̀rọ̀ bá kàn pa tàbí kí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n . . . , èyí sì lè ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ ohun tí àjọ náà ń ṣe tàbí kó mú kí wọ́n ṣí kúrò lórílẹ̀-èdè wa.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí ẹ̀sùn èyíkéyìí wé mọ́ wa lẹ́sẹ̀ nínú àyẹ̀wò náà, àjọ tó ń bójú tó owó orí lórílẹ̀-èdè náà bu owó orí tàbùàtabua tó lè ṣòro láti san lu àjọ tí à ń lò lábẹ́ òfin níbẹ̀. Ohun tí wọ́n fẹ́ dọ́gbọ́n ṣe ni pé, wọ́n fẹ́ kí sísan owó orí náà ni àjọ wa lára débi pé a máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà níbẹ̀ pa, a sì máa tà á ká lé rí owó san owóbówó tí wọ́n bù lé wa. Àkóbá kékeré kọ́ ni èyí máa ṣe, àmọ́ àwa èèyàn Ọlọ́run kò jẹ́ kó rẹ̀ wá. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fara mọ́ ìwà ìrẹ́jẹ yìí rárá, nígbà tó sì yá ọ̀rọ̀ náà dé Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù lọ́dún 2005.

13 June 30, 2011 ni wọ́n dá ẹjọ́ náà. Ilé ẹjọ́ sọ pé ẹ̀tọ́ tí àwọn èèyàn ní láti máa ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n kò fàyè gba ìjọba láti máa ṣe òfíntótó àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn àti bí àwọn onísìn ṣe ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ wọn, àyàfi tọ́rọ̀ náà bá burú jáì. Ilé ẹjọ́ tún sọ pé: “Owó orí náà . . . lè ṣàkóbá fún owó tó ń wọlé fún àjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì ní jẹ́ kí àjọ náà lè ran àwọn tó wà lábẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n máa ṣe ẹ̀sìn wọn bó ṣe tọ́ láìsí ìdíwọ́.” Bí ilé ẹjọ́ ṣe dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre nìyẹn o! Inú àwa èèyàn Jèhófà dùn gan-an pé ìjọba ilẹ̀ Faransé dá owó orí tí wọ́n bù lé wa pa dà nígbẹ̀yìngbẹ́yín títí kan èlé orí rẹ̀. Wọ́n sì tún gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí àwọn ilé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa bí ilé ẹjọ́ ṣe pa á láṣẹ.

O lè máa gbàdúrà déédéé fún àwọn tá a jọ jẹ́ ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń jìyà torí pé ilé ẹjọ́ kò ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ wọn bó ṣe tọ́

14. Kí ni ìwọ náà lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wa tó ń jà fún òmìnira láti máa sin Ọlọ́run láìsí ìdíwọ́?

 14 Bíi ti Ẹ́sítérì àti Módékáì nígbà àtijọ́, àwa èèyàn Jèhófà lóde òní jà fún òmìnira láti lè máa jọ́sìn Ọlọ́run wa lọ́nà tó pa láṣẹ fún wa láìsí ìdíwọ́. (Ẹ́sít. 4:13-16) Kí ni ìwọ náà lè ṣe? O lè máa gbàdúrà déédéé fún àwọn tá a jọ jẹ́ ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń jìyà torí pé ilé ẹjọ́ kò ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ wọn bó ṣe tọ́. Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ lè ṣèrànwọ́ púpọ̀ fún àwọn ará wa tí wọ́n ń fojú winá inúnibíni àti ìṣòro tó le gan-an. (Ka Jákọ́bù 5:16.) Ǹjẹ́ Jèhófà máa ń dáhùn irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀? Àwọn ẹjọ́ tá a jàre rẹ̀ fi dá wa lójú pé ó máa ń dáhùn rẹ̀!—Héb. 13:18, 19.

Òmìnira Tá A Ní Láti Yan Ìtọ́jú Ìṣègùn Tó Bá Ìlànà Bíbélì Mu

15. Àwọn kókó pàtàkì wo ni àwa èèyàn Ọlọ́run máa ń fi sọ́kàn nípa lílo ẹ̀jẹ̀?

15 Bí a ṣe sọ nínú Orí Kọkànlá ìwé yìí, àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run ti gba ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere látinú Ìwé Mímọ́ pé kí wọ́n yẹra fún àṣìlò ẹ̀jẹ̀, tó wọ́pọ̀ gan-an lóde òní. (Jẹ́n. 9:5, 6; Léf. 17:11; Ka Ìṣe 15:28, 29.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í gba ẹ̀jẹ̀ sára, a fẹ́ ìtọ́jú ìṣègùn tó dára jù fún ara wa àtàwọn èèyàn wa bí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ kò bá ti ta ko àṣẹ Ọlọ́run. Àwọn ilé ẹjọ́ tí àṣẹ wọn ga jù ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti fara mọ́ ọn pé àwọn èèyàn ní ẹ̀tọ́ láti yan irú ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́ tàbí èyí tí wọn kò fẹ́. Èyí sinmi lórí ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbà láyè àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àmọ́ láwọn ilẹ̀ kan, àwa èèyàn Ọlọ́run ti fojú winá ìṣòro tó le gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan.

16, 17. Irú ìtọ́jú wo ni wọ́n fún arábìnrin wa kan lórílẹ̀-èdè Japan tó yà á lẹ́nu gan-an? Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà rẹ̀?

16 Orílẹ̀-Èdè Japan. Ìyàwó ilé ni Arábìnrin Misae Takeda. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63], ó sì nílò kí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ tó le gan-an fún un. Tọkàntọkàn ni arábìnrin yìí fi rọ̀ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, torí náà ó ṣàlàyé fún dókítà rẹ̀ pé òun kò ní fẹ́ gba ẹ̀jẹ̀ sára. Síbẹ̀, ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, ó yà á lẹ́nu gan-an nígbà tó mọ̀ pé wọ́n ti fa ẹ̀jẹ̀ sí òun lára nígbà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ náà. Ìwàkiwà tí wọ́n hù àti ẹ̀tàn tí wọ́n ṣe yìí ká Arábìnrin Takeda lára gan-an, torí náà, ó fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn àtàwọn dókítà náà lóṣù June 1993. Èèyàn tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, tó sì máa ń sọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni arábìnrin wa yìí, síbẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára gan-an. Ó fìgboyà sọ̀rọ̀ ní ilé ẹjọ́ tí èrò kún fọ́fọ́. Ó lé ní wákàtí kan tó fi wà lórí ìdúró láìka àìlera rẹ̀ sí. Ó kú ní oṣù kan lẹ́yìn tó wá sílé ẹjọ́ kẹ́yìn. Ẹ̀rí fi hàn pé ìgboyà àti ìgbàgbọ́ arábìnrin yìí lágbára gan-an! Ó sọ pé léraléra ni òun máa ń bẹ Jèhófà pé kó bù kún òun lórí ohun tí òun ń jà fún yìí. Ó dá a lójú pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà rẹ̀. Ǹjẹ́ ó rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́?

17 Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Japan dá Arábìnrin Takeda láre ní ọdún kẹta lẹ́yìn tó kú. Ilé ẹjọ́ náà gbà pé bí wọn kò ṣe tẹ̀ lé ohun tí arábìnrin wa sọ tí wọ́n sì fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára kò tọ́ rárá. February 29, 2000 ni wọ́n dá ẹjọ́ náà, ara ohun tí wọ́n sì sọ nínú ìdájọ́ náà ni pé ó yẹ kí wọ́n “bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí kálùkù ní láti pinnu ohun tó bá fẹ́.” Àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ ló jẹ yọ látinú bí  Arábìnrin Takeda ṣe jà fún ẹ̀tọ́ tó ní láti yan irú ìtọ́jú tó fẹ́, tó sì bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ mu. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbogbo ilẹ̀ Japan ti lè fọkàn balẹ̀ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn láìsí ìbẹ̀rù pé wọ́n lè fipá fa ẹ̀jẹ̀ sí wa lára.

Pablo Albarracini (Wo ìpínrọ̀ 18 sí 20)

18-20. (a) Báwo ni ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ṣe fìdí ẹ̀tọ́ tí arákùnrin kan ní múlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà tí wọ́n sì lo ìtọ́ni tó kọ sílẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe fa ẹ̀jẹ̀ sí òun lára? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fi ara wa sí abẹ́ àkóso Kristi, tó bá dọ̀rọ̀ àṣìlò ẹ̀jẹ̀?

18 Orílẹ̀-Èdè Ajẹntínà. Báwo ni àwa ọmọ Ìjọba Ọlọ́run ṣe lè múra sílẹ̀ tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ní láti pinnu irú ìtọ́jú tá a fẹ́ nígbà tí àìlera wa bá le débi pé a kò lè sọ̀rọ̀? A lè máa mú ìwé àṣẹ tá a kọ ohun tá a fẹ́ sí dání bí Arákùnrin Pablo Albarracini ṣe ṣe. Ní oṣù May 2012, ó ṣèèṣì kó sọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ jalè, wọ́n sì yìnbọn lù ú lọ́pọ̀ ìgbà. Ó ti dákú nígbà tí wọ́n fi máa gbé e dé ilé ìwòsàn, kò sì lè ṣàlàyé ohun tó fẹ́ nípa ọ̀rọ̀ ìfàjẹ̀sínilára. Àmọ́ ó mú ìwé ìtọ́ni nípa ìtọ́jú rẹ̀ dání, ìyẹn káàdì téèyàn lè kọ ìtọ́ni sí pé òun ò gbẹ̀jẹ̀, ó sì ti lé ní ọdún mẹ́rin ṣáájú ìgbà yẹn tó ti buwọ́ lù ú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣe é yìí le gan-an, tí àwọn dókítà kan sì sọ pé tí wọ́n ò bá fẹ́ kó kú, ó yẹ kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára, àwọn tó ń tọ́jú rẹ̀ sọ pé ohun tó kọ sínú ìwé yẹn làwọn máa tẹ̀ lé. Àmọ́ bàbá Pablo kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí náà ó lọ gba àṣẹ nílé ẹjọ́ kí wọ́n lè fa ẹ̀jẹ̀ sí ọmọ rẹ̀ lára.

19 Kíá ni agbẹjọ́rò tó ṣojú fún ìyàwó Pablo pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Láàárín wákàtí mélòó kan, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gi lé ìdájọ́ àkọ́kọ́ yẹn, wọ́n sì sọ pé ohun tí aláìsàn náà kọ sínú ìwé ló yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé nílé ìwòsàn. Bàbá Pablo bá gbé ẹjọ́ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti ilẹ̀ Ajẹntínà. Àmọ́ ilé ẹjọ́ yìí kò rí “ẹ̀rí kankan tó lè mú kí wọ́n ṣiyè méjì pé Pablo lo òye, ó ní ohun tó dáa lọ́kàn, wọn kò sì fipá mú un láti kọ [ìtọ́ni tó kọ nípa ìtọ́jú rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe fa ẹ̀jẹ̀ sí òun lára].” Ilé ẹjọ́ sọ pé: “Gbogbo ẹni tó tójú bọ́ tó sì dàgbà tó ló lè sọ ọ̀nà tí òun fẹ́ kí wọ́n gbà tọ́jú òun bí ara òun kò bá yá, ó sì lè fara mọ́ oríṣi ìtọ́jú kan tàbí kó kọ̀ ọ́ . . . Dókítà tó bá ń tọ́jú onítọ̀hùn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni náà.”

Ṣé o ti kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú káàdì tí a fi ń fa ọ̀rọ̀ ìtọ́jú nílé ìwòsàn lé aṣojú ẹni lọ́wọ́?

20 Ó ti pẹ́ tí ara Arákùnrin Albarracini ti yá dáadáa báyìí. Inú òun àti ìyàwó rẹ̀ dùn gan-an pé ó ti kọ ìwé nípa bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tí kò le àmọ́ tó ṣe pàtàkì tó ṣe yìí fi hàn pé ó fi ara rẹ̀ sí abẹ́ àkóso Kristi nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Ṣé ìwọ àti ìdílé rẹ pẹ̀lú ti ṣe bẹ́ẹ̀?

April Cadoreth (Wo ìpínrọ̀ 21 sí 24)

21-24. (a) Ìdájọ́ mánigbàgbé wo ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Kánádà ṣe nípa fífa ẹ̀jẹ̀ sí àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ lára? (b) Ìṣírí wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ lè rí gbà látinú ìrírí yìí?

21 Orílẹ̀-Èdè Kánádà. Àwọn ilé ẹjọ́ sábà máa ń gbà pé àwọn òbí ní ẹ̀tọ́ láti pinnu irú ìtọ́jú tó dára jù tí wọ́n fẹ́ fún àwọn ọmọ wọn nílé ìwòsàn. Ìgbà míì wà táwọn ilé ẹjọ́ tiẹ̀ gbà pé kí àwọn dókítà fara mọ́ ìpinnu tí ọmọ aláìtójúúbọ́ àmọ́ tó ní làákàyè bá ṣe nípa irú ìtọ́jú tó fẹ́. Ohun tó wáyé nínú ọ̀rọ̀ Arábìnrin April Cadoreth nìyẹn. Nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, wọ́n gbé e lọ sílé ìwòsàn nítorí pé ó ń ṣẹ̀jẹ̀ sínú. Ní oṣù mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, ó ti kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú káàdì tí a fi ń fa ọ̀rọ̀ ìtọ́jú nílé ìwòsàn lé aṣojú ẹni lọ́wọ́ pé kí wọ́n má ṣe fa ẹ̀jẹ̀ sí òun lára kódà tí ọ̀ràn  pàjáwìrì bá wáyé. Dókítà tó tọ́jú rẹ̀ dìídì kọ̀ jálẹ̀ láti tẹ̀ lé ohun tí Arábìnrin April kọ sílẹ̀, ó sì lọ gba àṣẹ nílé ẹjọ́ kó lè fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Ó fipá fa ìgò ẹ̀jẹ̀ mẹ́ta tó kún fún sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ sí í lára. Arábìnrin April sọ pé ṣe lọ̀rọ̀ yìí dà bí ìgbà tí wọ́n bá fipá bá èèyàn lò pọ̀.

22 April àtàwọn òbí rẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ilé ẹjọ́. Lẹ́yìn ọdún méjì, ọ̀rọ̀ náà dé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Kánádà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ kò sọ pé kí wọ́n yí òfin tó fàyè gba pé kí wọ́n ṣèpinnu fún ọmọ tí kò tíì tójú bọ́ pa dà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá gbogbo owó tí April ná lórí ẹjọ́ náà pa dà, ó sì dá a láre. Kódà wọ́n ní gbogbo àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ míì tó ní làákàyè, lè máa lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti pinnu irú ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́ nílé ìwòsàn. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé: “Tó bá dọ̀rọ̀ ìtọ́jú nílé ìwòsàn, ó yẹ kí wọ́n máa gba àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọdún mẹ́rìndínlógún [16] láyè láti fi hàn pé wọ́n ní òye tó pọ̀ tó nípa oríṣi ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́ nílé ìwòsàn àti pé àwọn fúnra wọn ló pinnu ohun tí wọ́n fẹ́, kì í ṣe ẹnì kan ló pinnu fún wọn.”

 23 Ẹjọ́ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an torí pé ó dá lórí ohun tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sọ nípa ẹ̀tọ́ tí ọmọ aláìtójúúbọ́ tó ní làákàyè ní lábẹ́ òfin. Kí wọ́n tó dá ẹjọ́ yìí, àwọn ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè Kánádà lè pa àṣẹ nípa irú ìtọ́jú tí wọ́n máa fún ọmọ tí kò tíì pé ọdún mẹ́rìndínlógún, tí wọ́n bá ṣáà ti rí i pé irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ ló máa dáa jù fún ọmọ náà. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dá ẹjọ́ yìí, ilé ẹjọ́ kò tún ní ẹ̀tọ́ mọ́ láti pa àṣẹ tó lòdì sí ohun tí irú ọmọ bẹ́ẹ̀ fẹ́ láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ fún un láǹfààní láti fi hàn pé òun ní làákàyè àti òye tó pọ̀ tó láti yan ohun tí òun fẹ́.

“Inú mi máa ń dùn gan-an pé mo ṣe ìwọ̀nba ohun tí agbára mi ká láti gbé orúkọ Ọlọ́run ga kí n sì mú Sátánì ní òpùrọ́”

24 Ǹjẹ́ ẹjọ́ tó gba ọdún mẹ́ta gbáko yìí ní àǹfààní kankan? April dáhùn pé “Bẹ́ẹ̀ ni!” Ó ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé báyìí, ara rẹ̀ sì ti le dáadáa, ó ní: “Inú mi máa ń dùn gan-an pé mo ṣe ìwọ̀nba ohun tí agbára mi ká láti gbé orúkọ Ọlọ́run ga kí n sì mú Sátánì ní òpùrọ́.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí April yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọ wa lè fìgboyà rọ̀ mọ́ ìpinnu wọn, kí wọ́n sì fi hàn pé àwọn jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìjọba Ọlọ́run.—Mát. 21:16.

Ẹ̀tọ́ Tí Àwọn Òbí Ní Láti Fi Ìlànà Jèhófà Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn

25, 26. Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì lẹ́yìn tí àwọn òbí bá kọ ara wọn sílẹ̀?

25 Ara ojúṣe tí Jèhófà fún àwọn òbí ni pé kí wọ́n fi àwọn ìlànà òun kọ́ àwọn ọmọ wọn. (Diu. 6:6-8; Éfé. 6:4) Ojúṣe yìí kò rọrùn àmọ́ ó lè túbọ̀ ṣòro tí ìkọ̀sílẹ̀ bá wáyé. Èyí lè jẹ́ kí àwọn òbí náà ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń wu òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an pé kó fi àwọn ìlànà Kristẹni tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, àmọ́ kí òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí máà fẹ́ bẹ́ẹ̀. Òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ní láti gbà pé bí òun àti ọkọ tàbí aya rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tiẹ̀ ti kọra sílẹ̀, ọmọ ṣì pa wọ́n pọ̀.

26 Òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè pe ẹjọ́ pé kí wọ́n jẹ́ kí òun kó àwọn ọmọ sọ́dọ̀ kí òun lè fi ìlànà ẹ̀sìn òun kọ́ wọn. Àwọn kan sọ pé ó léwu láti fi ìlànà ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tọ́ ọmọ. Wọ́n lè sọ pé òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí náà kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọ ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àtàwọn ayẹyẹ míì, wọ́n sì lè sọ pé kò ní jẹ́ kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí wọn lára nígbà tí wọ́n bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì kí wọ́n lè “dá ẹ̀mí wọn sí.” Àmọ́ inú wa dùn pé, ohun tí ilé ẹjọ́ gbà pé ó dára jù fún àwọn ọmọ ni wọ́n máa ń wò dípò kí wọ́n máa wo bóyá ẹ̀sìn ọ̀kan nínú àwọn òbí náà léwu tàbí kò léwu. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.

27, 28. Ìdájọ́ wo ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Ìpínlẹ̀ Ohio ṣe nígbà tí àwọn kan mú ẹ̀sùn wá pé fífi ìlànà ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ọmọ lè ṣàkóbá fún un?

27 Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ní ọdún 1992, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Ìpínlẹ̀ Ohio gbọ́ ẹjọ́ tí bàbá kan tí kì i ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú wá pé ìlànà ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìyá ọmọ òun fẹ́ fi kọ́ ọmọ àwọn máa ṣàkóbá fún un. Ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà dá bàbá yìí láre, wọ́n sì gbà pé kó mú ọmọ náà sọ́dọ̀. Wọ́n ní ìyá ọmọ náà, ìyẹn Jennifer Pater lè wá máa wo ọmọ rẹ̀ àmọ́ kò gbọ́dọ̀ “fi ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ọmọ náà, kò sì gbọ́dọ̀ fi hàn án lọ́nàkọnà.” Àṣẹ tí ilé ẹjọ́ yìí pa gbòòrò gan-an débi pé ó lè túmọ̀ sí pé Arábìnrin Pater kò ní lè bá Bobby ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì tàbí nípa ìlànà ìwà  rere! Wo bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe máa rí lára Arábìnrin Jennifer. Ó dùn ún gidigidi, àmọ́ ó ní ọ̀rọ̀ náà kọ́ òun láti máa ní sùúrù, kí òun sì máa dúró de Jèhófà láti yanjú ọ̀rọ̀. Ó ní “Jèhófà kì í fi wá sílẹ̀ nígbà kankan.” Ètò Jèhófà ran agbẹjọ́rò rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Ìpínlẹ̀ Ohio.

28 Ilé ẹjọ́ yìí kò fara mọ́ ìpinnu tí ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà ṣe, ó sọ pé “àwọn òbí ní ẹ̀tọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ní ẹ̀tọ́ láti fi ìlànà ìwà rere àti ti ẹ̀sìn kọ́ wọn.” Ilé ẹjọ́ yìí tún sọ pé àyàfi tí wọ́n bá mú ẹ̀rí wá láti fi hàn pé ìlànà ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ṣàkóbá fún ọmọ kó sì ba ọpọlọ rẹ̀ jẹ́, kò yẹ kí ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà tìtorí ẹ̀sìn, kó wá fòfin de ẹ̀tọ́ tí òbí ní láti mú ọmọ rẹ̀ sọ́dọ̀. Ilé ẹjọ́ kò rí ẹ̀rí kankan láti fi hàn pé àwọn ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ lè ṣe ìpalára fún ọmọ tàbí kó ba ọpọlọ rẹ̀ jẹ́.

Ọ̀pọ̀ ilé ẹjọ́ ti dá àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni láre kí wọ́n lè mú ọmọ wọn sọ́dọ̀

29-31. Kí ló ṣẹlẹ̀ tí wọ́n fi gba ọmọ lọ́wọ́ arábìnrin wa kan lórílẹ̀-èdè Denmark? Ìdájọ́ wo sì ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Denmark ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí?

29 Orílẹ̀-Èdè Denmark. Irú ìṣòro yìí ni Arábìnrin Anita Hansen ní nígbà tí ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́ kó lè mú Amanda, ọmọ wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún méje sọ́dọ̀. Òótọ́ ni pé ilé ẹjọ́ àgbègbè wọn sọ lọ́dún 2000 pé Arábìnrin Hansen ni kó mú ọmọ náà sọ́dọ̀, àmọ́ bàbá ọmọ náà pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ilé ẹjọ́ gíga, wọ́n sì wọ́gi lé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ ṣe. Wọ́n bá sọ pé bàbá ni kó mú ọmọ náà sọ́dọ̀. Ilé ẹjọ́ gíga sọ pé ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn òbí méjèèjì tí kò dọ́gba mú kí ohun tí wọ́n fẹ́ yàtọ̀ síra, torí náà ọ̀dọ̀ bàbá ló máa  dáa jù kí ọmọ wà kí ọ̀rọ̀ lè lójú. Bó ṣe di pé wọ́n gba ọmọ lọ́wọ́ Arábìnrin Hansen nìyẹn torí pé ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà!

30 Gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa ń da Arábìnrin Hansen lọ́kàn rú gan-an nígbà míì débi pé kì í mọ ohun tí ì bá gbàdúrà fún. Ó ní, “Àmọ́ ọ̀rọ̀ inú Róòmù 8:26 àti 27 máa ń tù mí nínú gan-an. Ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé Jèhófà lóye ohun tí mò ń rò. Ojú rẹ̀ kò kúrò lára mi, kò sì ní fi mí sílẹ̀.”—Ka Sáàmù 32:8; Aísáyà 41:10.

31 Arábìnrin Hansen pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Denmark. Ilé ẹjọ́ náà sọ nínú ìdájọ́ rẹ̀ pé: “Ohun tó máa ṣe ọmọ láǹfààní ni olórí ohun tó yẹ kí wọ́n fi pinnu ẹni tí ọmọ máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀.” Síwájú sí i, ilé ẹjọ́ sọ pé irú ọwọ́ tí òbí kọ̀ọ̀kan bá fi mú èdèkòyédè ló yẹ kó pinnu ẹni tí wọ́n máa jẹ́ kó mú ọmọ sọ́dọ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀kọ́ ìsìn àti ìgbàgbọ́” àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìtùnú ńlá gbáà ló jẹ́ fún Arábìnrin Hansen nígbà tí ilé ẹjọ́ sọ pé kí wọ́n dá ọmọ náà pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ torí pé òun ló máa lè ṣe ojúṣe òbí fún un.

32. Báwo ni Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe gba àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe ẹ̀tanú sí wọn?

32 Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù. Nígbà míì, àwọn ẹjọ́ tó dá lórí ẹni tó yẹ kó mú ọmọ sọ́dọ̀ kì í parí sí ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè tọ́rọ̀ náà ti wáyé. Irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ tún máa ń dé Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Nínú irú ẹjọ́ méjì tí ilé ẹjọ́ yìí gbọ́, wọ́n sọ pé àwọn ilé ẹjọ́ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè kan ti jẹ́ kí ẹ̀sìn nípa lórí ìdájọ́ wọn, wọ́n jẹ́ kí ẹjọ́ tí wọ́n dá fún òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n dá fún òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé ẹ̀tanú ni wọ́n ṣe yẹn, torí náà “kí wọ́n má ṣe máa lo ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ẹ̀sìn nìkan láti fi ṣe ìdájọ́.” Abiyamọ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jàǹfààní irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù sọ bí ara ṣe tù ú, ó ní, “Ó máa ń dùn mí gan-an tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn mí pé àkóbá ni mò ń ṣe fún àwọn ọmọ mi, nígbà tó jẹ́ pé ohun tí mo gbà pé ó dára jù lọ ni mò ń gbìyànjú láti ṣe fún wọn bí mo ṣe ń fi ìlànà Kristẹni kọ́ wọn.”

33. Báwo ni àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lè tẹ̀ lé ìlànà inú Fílípì 4:5?

33 Àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ń fẹ̀sùn kàn nílé ẹjọ́ pé wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa fi ìlànà Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ wọn máa ń gbìyànjú láti fi òye bá àwọn èèyàn lò. (Ka Fílípì 4:5.) Bí wọn kò ṣe fojú kéré ẹ̀tọ́ àti ojúṣe tí wọ́n ní láti fi ìlànà Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún gbà pé ọkọ tàbí aya wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ojúṣe tó rí i pé ó yẹ fún àwọn ọmọ náà. Irú ọwọ́ wo ló yẹ kí òbí tó bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú ojúṣe rẹ̀ láti tọ́ ọmọ?

34. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni lóde òní lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn Júù nígbà ayé Nehemáyà?

34 A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nehemáyà. Àwọn Júù ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ṣe àtúnṣe tó yẹ lára odi Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n sì tún un kọ́. Wọ́n mọ̀ pé èyí máa dáàbò bo ìdílé wọn lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè àwọn ọ̀tá tó yí wọn ká. Torí náà, Nehemáyà rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ . . . jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin  yín àti àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn aya yín àti ilé yín.” (Neh. 4:14) Àwọn Júù nígbà yẹn gbà pé ó yẹ kí àwọn jà lóòótọ́. Bákan náà lónìí, àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣiṣẹ́ kára láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà ní ọ̀nà òtítọ́. Wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí kò dára táwọn ọmọ ń rí níléèwé àti ní àdúgbò máa ń fẹ́ nípa lórí wọn. Kódà irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè yọ́ wọnú ilé nípasẹ̀ àwọn orin, ìwé tàbí fídíò. Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe gbàgbé láé pé gbogbo ìgbà ló yẹ kí ẹ máa sapá láti jà fún àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin kí wọ́n lè wà nípò tí wọ́n á fi lè fọkàn balẹ̀ máa dàgbà nípa tẹ̀mí.

Jẹ́ Kó Dá Ọ Lójú Pé Jèhófà Máa Ti Ìjọsìn Tòótọ́ Lẹ́yìn

35, 36. Àwọn àǹfààní wo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rí látinú bá a ṣe ń jà fún ẹ̀tọ́ tá a ní lábẹ́ òfin? Kí lo sì pinnu láti ṣe?

35 Ó dájú pé Jèhófà ti bù kún ìsapá ètò rẹ̀ lóde òní bá a ṣe ń jà fún ẹ̀tọ́ tá a ní láti máa sìn ín láìsí ìdíwọ́. Nígbà tí irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ bá ń lọ lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń lo àǹfààní yìí láti wàásù ní ilé ẹjọ́ àti fún ìlú lápapọ̀. (Róòmù 1:8) Àǹfààní míì tó tún wà nínú àwọn ẹjọ́ tí a jàre rẹ̀ ni pé ó ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú lè máa lo àwọn ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin. Àmọ́ ṣá o, èèyàn Ọlọ́run ni wá, kì í ṣe pé a fẹ́ máa ṣàtúnṣe bí nǹkan ṣe ń lọ láwùjọ; kì í sì í ṣe pé a fẹ́ máa dá ara wa láre. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí ká lè fìdí ìhìn rere múlẹ̀, ká sì mú kí ìjọsìn tòótọ́ túbọ̀ gbèrú ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa ń fẹ́ fìdí ẹ̀tọ́ tá a ní lábẹ́ òfin múlẹ̀ ní ilé ẹjọ́.—Ka Fílípì 1:7.

36 Ẹ má ṣe jẹ́ ká fojú kéré àwọn ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ lára ìgbàgbọ́ àwọn tó ti jà fún òmìnira tá a ní láti lè máa jọ́sìn Jèhófà láìsí ìdíwọ́! Ká jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa dúró sán-ún bíi tiwọn, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń ti iṣẹ́ wa lẹ́yìn, yóò sì máa bá a nìṣó láti fún wa ní agbára ká lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Aísá. 54:17.