Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

 ORÍ 3

Jèhófà Ṣí Ète Rẹ̀ Payá

Jèhófà Ṣí Ète Rẹ̀ Payá

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Jèhófà ń ṣí ète rẹ̀ payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, àmọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ nìkan ló ń ṣí i payá fún

1, 2. Báwo ni Jèhófà ṣe ti ń ṣí ète rẹ̀ nípa aráyé payá?

ÀWỌN òbí tí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn jẹ lógún máa ń jẹ́ kí wọ́n gbọ́ nípa ìjíròrò ọ̀rọ̀ ìdílé wọn. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ ìdílé ni òbí ọlọ́gbọ́n máa ń sọ létí àwọn ọmọ. Ìwọ̀nba ohun tí wọ́n bá rí pé òye àwọn ọmọ náà lè gbé ni wọ́n máa ń sọ fún wọn.

2 Bákan náà, Jèhófà ń ṣí ète rẹ̀ nípa ìdílé aráyé payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Àmọ́ ìgbà tó bá tásìkò lójú rẹ̀ ló máa ń ṣí i payá. Ẹ jẹ́ ká wá ṣe àyẹ̀wò ṣókí nípa bí Jèhófà ṣe ti ń ṣí ète rẹ̀ nípa Ìjọba náà payá bọ̀ látẹ̀yìn wá.

Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Ìjọba Ọlọ́run?

3, 4. Ṣé Jèhófà ti dìídì pinnu gbogbo bí nǹkan ṣe máa rí fún ìran èèyàn látìbẹ̀rẹ̀ ni? Ṣàlàyé.

3 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Ìjọba Mèsáyà kò sí lára ète Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé, kì í ṣe pé Jèhófà ti dìídì pinnu gbogbo bí nǹkan ṣe máa rí fún ìran èèyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ lọ. Ṣe ló dá àwa èèyàn ká lè yan ohun tó wù wá. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tó ń sọ ète rẹ̀ nípa ìran èèyàn fún Ádámù àti Éfà, ó sọ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́n. 1:28) Àmọ́ Jèhófà ní kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà òun nípa ohun tó jẹ́ rere àti búburú. (Jẹ́n. 2:16, 17) Ńṣe ló yẹ kí Ádámù àti Éfà jẹ́ adúróṣinṣin. Ká ní àwọn àti àtọmọdọ́mọ wọn jẹ́ adúróṣinṣin ni, a kò ní nílò Ìjọba Kristi ká tó lè mú ète Ọlọ́run ṣẹ. Àwọn èèyàn pípé ni ì bá kún gbogbo ayé báyìí, tí gbogbo wọn á sì máa jọ́sìn Jèhófà.

4 Àmọ́ Sátánì àti Ádámù àti Éfà wá ṣọ̀tẹ̀. Ìwà ọ̀tẹ̀ wọn kò mú kí Jèhófà pa ète rẹ̀ pé kí àwọn ẹ̀dá èèyàn pípé kún ilẹ̀ ayé tì láìmú un ṣẹ. Ṣe ni Jèhófà wá lo ọ̀nà kan táá jẹ́ kí ète rẹ̀ yìí lè ṣẹ. Ìdí sì ni pé ète Jèhófà kò dà bí ọkọ̀ rélùwéè tó ti lójú ọ̀nà pàtó tó gbọ́dọ̀ gbà kò tó lè débi tó ń lọ, tó sì tún jẹ́ pé àwọn èèyàn lè ṣe ohun tá a mú kó yẹ̀ kúrò ní ipa ọ̀nà tó ń tọ̀. Tí Jèhófà bá ti lè sọ pé nǹkan báyìí lòun fẹ́ ṣe, kò sí ohunkóhun láyé àtọ̀run tó lè ní kí ìfẹ́ rẹ̀ má ṣẹ. (Ka Aísáyà 55:11.)  Bí ìṣòro kan bá tiẹ̀ fẹ́ dí ọ̀nà tí ète rẹ̀ fẹ́ gbà ṣẹ, Jèhófà á gbé e gba ọ̀nà ibòmíì. * (Ẹ́kís. 3:14, 15) Ìgbà tó bá rí pé ó yẹ láti sọ ọ̀nà tuntun tó fẹ́ gbà mú ète rẹ̀ ṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, yóò sọ fún wọn.

5. Kí ni Jèhófà ṣe nípa ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì?

5 Láti wá yanjú ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì yìí, Jèhófà pinnu láti gbé Ìjọba náà kalẹ̀. (Mát. 25:34) Nígbà tó dà bíi pé kò sí ìrètí fún ẹ̀dá èèyàn mọ́ yẹn, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí ohun tó máa lò láti fi mú aráyé pa dà bọ̀ sípò payá, ìyẹn ohun tó máa yanjú wàhálà tí ìwàǹwara Sátánì láti di alákòóso dá sílẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì kùnà. (Jẹ́n. 3:14-19) Àmọ́ ṣá, Jèhófà ò ṣí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa Ìjọba náà payá lẹ́ẹ̀kan náà.

Jèhófà Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣí Ète Rẹ̀ Nípa Ìjọba Náà Payá

6. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe? Àmọ́ kí ni kò sọ?

6 Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ni Jèhófà fi ṣèlérí pé “irú-ọmọ” kan yóò pa ejò náà rẹ́ ráúráú. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15.) Àmọ́ kò sọ àwọn ohun tí a ó fi dá irú ọmọ náà àti irú ọmọ ejò náà mọ̀ nígbà yẹn. Kódà, fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] lẹ́yìn ìgbà náà, Jèhófà ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ míì nípa nǹkan wọ̀nyẹn. *

7. Kí nìdí tí Jèhófà fi yan Ábúráhámù? Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la kọ́ látinú èyí?

7 Nígbà tó yá, Jèhófà yan Ábúráhámù, pé irú ọmọ tí òun ṣèlérí náà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Ìdí tí Jèhófà fi yan Ábúráhámù ni pé ó “fetí sí ohùn [Jèhófà].” (Jẹ́n. 22:18) Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tá a kọ́ látinú èyí ni pé, kìkì àwọn tó bá bẹ̀rù Jèhófà tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un ló máa ń ṣí ète rẹ̀ payá fún.—Ka Sáàmù 25:14.

8, 9. Àwọn kókó pàtàkì wo ni Jèhófà ṣí payá fún Ábúráhámù àti Jékọ́bù nípa irú ọmọ tó ṣèlérí náà?

8 Ìgbà tí Jèhófà tipasẹ̀ áńgẹ́lì bá Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ni Jèhófà kọ́kọ́ ṣí kókó pàtàkì kan nípa irú ọmọ tí òun ṣèlérí yìí payá, ìyẹn ni pé èèyàn ló máa jẹ́. (Jẹ́n. 22:15-17; Ják. 2:23) Ṣùgbọ́n báwo ni ẹ̀dá èèyàn yìí ṣe máa wá pa ejò náà rẹ́? Ta ni ejò náà? Àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣí payá lẹ́yìn ìgbà náà jẹ́ ká mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

9 Jèhófà pinnu pé nípasẹ̀ ọmọ ọmọ Ábúráhámù tó ń jẹ́ Jékọ́bù, tó ní ìgbàgbọ́ gan-an nínú Ọlọ́run, ni irú ọmọ tí òun ṣèlérí náà yóò ti wá. (Jẹ́n. 28:13-22) Jèhófà wá tipasẹ̀ Jékọ́bù sọ ọ́ di mímọ̀ pé Ẹni Tí Ọlọ́run Ṣèlérí náà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Júdà, ọmọ Jékọ́bù. Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ pé àtọmọdọ́mọ Júdà yìí yóò gba “ọ̀pá aládé,” ìyẹn ọ̀pá kúkúrú táá fi hàn pé ọba aláṣẹ ni, àti pé “ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.” (Jẹ́n. 49:1, 10) Ọ̀rọ̀ yẹn ni Jèhófà fi jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹni Tí Ọlọ́run Ṣèlérí náà yóò di alákòóso, ìyẹn ọba.

10, 11. Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣí ète rẹ̀ payá fún Dáfídì àti Dáníẹ́lì?

10 Àádọ́talélẹ́gbẹ̀ta [650] ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Júdà, Jèhófà ṣí ohun púpọ̀ sí i nípa ète rẹ̀ payá fún Dáfídì Ọba tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Júdà. Jèhófà sọ pé Dáfídì jẹ́ “ọkùnrin kan tí ó tẹ́  ọkàn-àyà [òun] lọ́rùn.” (1 Sám. 13:14; 17:12; Ìṣe 13:22) Torí pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run jinlẹ̀ gan-an lọ́kàn Dáfídì, Jèhófà bá a dá májẹ̀mú, ó ṣèlérí fún un pé àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kan yóò jọba títí láé.—2 Sám. 7:8, 12-16.

11 Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Dáníẹ́lì sọ ọdún pàtó tí Ẹni Àmì Òróró tàbí Mèsáyà náà yóò fara hàn lórí ilẹ̀ ayé. (Dán. 9:25) Jèhófà ka Dáníẹ́lì sí “ẹni kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi.” Kí nìdí? Ìdí ni pé Dáníẹ́lì bọ̀wọ̀ fún Jèhófà gan-an, ó sì ń sìn ín láìyẹsẹ̀.—Dán. 6:16; 9:22, 23.

12. Kí ni Jèhófà sọ pé kí Dáníẹ́lì ṣe? Kí nìdí?

12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà tipasẹ̀ Dáníẹ́lì àtàwọn wòlíì míì kọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó jẹ́ irú ọmọ tó ṣèlérí náà nígbà yẹn, kò tíì tó àsìkò lójú Jèhófà pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ohun tó mí sí wọn pé kí wọ́n kọ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Ọlọ́run mú kí Dáníẹ́lì rí ìran nípa bí a ṣe gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀, Jèhófà sọ fún un pé kó fi èdìdì di ìran náà títí dìgbà tí àsìkò á fi tó lójú òun. Tó bá wá dìgbà yẹn, ìmọ̀ tòótọ́ yóò “di púpọ̀ yanturu.”—Dán. 12:4.

Jèhófà tipasẹ̀ àwọn olóòótọ́ èèyàn bíi Dáníẹ́lì kọ ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa Ìjọba Mèsáyà

Jésù Mú Kí Ète Ọlọ́run Ṣe Kedere

13. (a) Ta ni irú ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí náà? (b) Báwo ni Jésù ṣe mú kí òye àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣe kedere?

13 Jèhófà fi hàn kedere pé Jésù ni irú ọmọ tí òun ṣèlérí náà, ìyẹn àtọmọdọ́mọ Dáfídì tí yóò di Ọba. (Lúùkù 1:30-33; 3:21, 22) Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó fi òye ète Ọlọ́run yé aráyé, bí ìgbà tí ìmọ́lẹ̀ tàn sí wọn nípa ète náà. (Mát. 4:13-17) Bí àpẹẹrẹ, Jésù fi ẹni tó jẹ́ “ejò” tí Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15 mẹ́nu kàn hàn kedere, torí ó ní Èṣù ni “apànìyàn” àti “baba irọ́.” (Jòh. 8:44) Jésù fi hàn nínú ìṣípayá tó fi han Jòhánù pé “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì” ni “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà.” * (Ka Ìṣípayá 1:1; 12:9.) Jésù tún fi hàn nínú ìṣípayá kan náà bí òun tóun jẹ́ irú ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà yóò ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ inú ọgbà Édẹ́nì ṣẹ ní kíkún ní ti pé òun yóò pa Sátánì rẹ́ ráúráú.—Ìṣí. 20:7-10.

14-16. Ṣé gbogbo ìgbà làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń fòye mọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtumọ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Jésù ṣí payá fún wọn? Ṣàlàyé.

14 Bí a ṣe sọ ní Orí 1 ìwé yìí, Jésù sọ̀rọ̀ gan-an nípa Ìjọba náà. Àmọ́ sá o, gbogbo ìgbà kọ́ ló ń sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fẹ́ mọ̀ fún wọn. Kódà àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ pàtó kan wà tí Jésù sọ fún wọn, àmọ́ tó jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ kọ́ ló yé wọn, kódà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fòye mọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtumọ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Jésù Ọ̀gá wọn ti ṣí payá tipẹ́tipẹ́. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ ná.

15 Lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni (S.K.), Jésù mú kó ṣe kedere pé ayé ni wọ́n ti máa mú àwọn tí yóò bá Ọba Ìjọba Ọlọ́run ṣàkóso, wọ́n á wá jí wọn dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí lọ sí  ọ̀run. Àmọ́, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kò tètè lóye ohun tó ṣí payá fún wọn yìí. (Dán. 7:18; Jòh. 14:2-5) Ní ọdún yẹn kan náà, Jésù fi àwọn àkàwé sọ ọ́ pé ó ṣì máa pẹ́ lẹ́yìn tí òun bá gòkè re ọ̀run kí Ọlọ́run tó gbé Ìjọba náà kalẹ̀. (Mát. 25:14, 19; Lúùkù 19:11, 12) Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kò lóye kókó pàtàkì yìí náà, wọ́n tún wá bi Jésù lẹ́yìn tó jíǹde pé: “Ìwọ ha ń mú ìjọba padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?” Àmọ́ Jésù pinnu láti má ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé kankan ní àsìkò náà. (Ìṣe 1:6, 7) Jésù tún kọ́ni pé àwọn “àgùntàn mìíràn” yóò wà tí kò ní sí lára “agbo kékeré” tí yóò bá a jọba. (Jòh. 10:16; Lúùkù 12:32) Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kò fi bẹ́ẹ̀ lóye bí àwùjọ méjèèjì yìí ṣe jẹ́. Ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run gbé Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́dún 1914 ló tó wá yé wọn.

16 Jésù ì bá sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó ṣì wà pẹ̀lú wọn láyé, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé wọn kò lè gbà wọ́n mọ́ra. (Jòh. 16:12) Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ṣí payá nípa Ìjọba náà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ṣùgbọ́n kò tíì tó àsìkò tí irú ìmọ̀ tòótọ́ bẹ́ẹ̀ yóò di púpọ̀ yanturu.

Ìmọ̀ Tòótọ́ Di Púpọ̀ Yanturu ní “Àkókò Òpin”

17. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè lóye òtítọ́ nípa Ìjọba náà? Ṣùgbọ́n kí la tún nílò?

17 Jèhófà sọ fún Dáníẹ́lì pé tó bá di “àkókò òpin,” ọ̀pọ̀ yóò “máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́” nípa ète Ọlọ́run yóò sì di púpọ̀ yanturu. (Dán. 12:4) Àwọn tó bá fẹ́ ní ìmọ̀ yẹn gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ní in. Ìwé ìwádìí kan sọ pé ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù tá a pè ní “lọ káàkiri” níbí túmọ̀ sí ni pé kéèyàn fara balẹ̀ ṣe àyẹ̀wò ìwé kan fínnífínní. Ṣùgbọ́n bó ṣe wù ká ṣàyẹ̀wò Bíbélì fínnífínní tó, òtítọ́ nípa Ìjọba náà kò lè yé wa dáadáa àfi tí Jèhófà bá mú kó yé wa.—Ka Mátíù 13:11.

18. Báwo làwọn tó bẹ̀rù Jèhófà ṣe fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀?

18 Bí Jèhófà ṣe ń ṣí ète rẹ̀ nípa Ìjọba náà payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nígbà díẹ̀ ṣáájú ọdún 1914 náà ló ṣe ń ṣí i payá nìṣó ní àkókò òpin yìí. A máa rí i ní Orí 4àti 5 ìwé yìí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ní láti ṣàtúnṣe sí òye wọn nípa àwọn ẹ̀kọ́ kan. Ṣùgbọ́n ṣé bí wọ́n ṣe ń ṣàtúnṣe òye wọn yìí wá fi hàn pé Jèhófà kò sí lẹ́yìn wọn ni? Rárá o! Ó wà lẹ́yìn wọn digbí. Kí nìdí tó fi wà lẹ́yìn wọn? Torí pé àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà yìí ní ànímọ́ méjì kan tó fẹ́ràn ni, ìyẹn ìgbàgbọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀. (Héb. 11:6; Ják. 4:6) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ìgbàgbọ́ pé gbogbo ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Ìwé Mímọ́ yóò ṣẹ pátá. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ní ló sì ń jẹ́ kí wọ́n gbà pé àwọn ti ṣi bí àwọn ìlérí náà ṣe máa ṣẹ ní pàtó lóye. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wọn yìí hàn nínú ohun tí wọ́n sọ nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 1925, lédè Gẹ̀ẹ́sì. Wọ́n ní: “A mọ̀ pé Olúwa ló ń fúnra rẹ̀ túmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti pé yóò túmọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà tó dára lójú rẹ̀, yóò sì jẹ́ nígbà tó bá tásìkò lójú rẹ̀.”

“Olúwa . . . yóò túmọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà tó dára lójú rẹ̀, yóò sì jẹ́ nígbà tó bá tásìkò lójú rẹ̀”

19. Òye wo ni Jèhófà ti wá jẹ́ ká ní báyìí, kí sì nìdí?

19 Nígbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́dún 1914, ìwọ̀nba òye ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ní nípa bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ Ìjọba náà yóò ṣe ṣẹ. (1 Kọ́r. 13:9, 10, 12) Torí pé a ń hára gàgà láti rí i pé àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣẹ, àwọn ìgbà kan wà tó jẹ́ pé ibi tí a fojú sí ọ̀nà kò gbabẹ̀. Ìrírí wa láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ti fi hàn pé ọ̀rọ̀ kan tí Ilé Ìṣọ́ tá a tọ́ka sí níṣàájú tún sọ bọ́gbọ́n mu gan-an ni. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ó jọ pé ohun tó yẹ ká máa fi sọ́kàn ni pé a kò lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ títí dìgbà tó bá ní ìmúṣẹ tàbí ìgbà tó bá ń ṣẹ lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n ní báyìí tí àkókò òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló ti ṣẹ, ọ̀pọ̀ sì ń ṣẹ lọ́wọ́. Torí pé àwa èèyàn Ọlọ́run jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a sì máa ń gba ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà bá fún wa, ó ti jẹ́ ká túbọ̀ ní òye kíkún nípa ète rẹ̀. Ìmọ̀ tòótọ́ sì ti wá pọ̀ yanturu lóòótọ́!

 Àtúnṣe sí Òye Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Táwọn Èèyàn Ọlọ́run Ní Dán Wọn Wò

20, 21. Kí làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe nígbà tí àtúnṣe bá òye wọn, kí làwọn kan kò ṣe?

20 Tí Jèhófà bá ṣe àtúnṣe sí òye òtítọ́ tá a ní, àtúnṣe náà máa ń dán ipò ọkàn wa wò. Ìyẹn ni pé, ǹjẹ́ a ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ táá jẹ́ ká lè gba àwọn àtúnṣe yìí? Irú ìdánwò yìí bá àwọn Kristẹni tó wà láyé ní ìdajì ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé Júù tó jẹ́ Kristẹni ni ọ́ lásìkò náà. O bọ̀wọ̀ fún Òfin Mósè gan-an, ohun ìwúrí sì ni àṣà àti ìṣe orílẹ̀-èdè rẹ jẹ́ fún ọ. O wá gba àwọn lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí látọ̀dọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó ń sọ pé èèyàn kò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́ àti pé Jèhófà ti kọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa ti ara, pé ṣe ló ń kó àwọn Júù àti Kèfèrí jọ pọ̀ báyìí láti sọ wọ́n di Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí. (Róòmù 10:12; 11:17-24; Gál. 6:15, 16; Kól. 2:13, 14) Kí lo máa ṣe?

21 Àwọn Kristẹni tó nírẹ̀lẹ̀ fara mọ́ àlàyé tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti ṣe, Jèhófà sì bù kún wọn. (Ìṣe 13:48) Àwọn míì kọ̀ jálẹ̀, wọn kò fara mọ́ àtúnṣe tó dé bá òye tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀, tinú wọn ni wọ́n fẹ́ máa ṣe. (Gál. 5:7-12) Tí wọn kò bá yí èrò òdì wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí pa dà, àǹfààní bíbá Kristi ṣàkóso á bọ́ lọ́wọ́ wọn.—2 Pét. 2:1.

22. Báwo làwọn àtúnṣe tó ń bá òye wa nípa ète Ọlọ́run ṣe rí lára rẹ?

22 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, Jèhófà ti tún òye wa ṣe nípa Ìjọba náà. Bí àpẹẹrẹ, ó ti jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìgbà tí a máa ya àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tí kò kọbi ara sí ìhìn rere, bí ìgbà tí wọ́n ya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́. Ó tún ti jẹ́ ká mọ ìgbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa pé, ó jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn àkàwé tí Jésù sọ nípa Ìjọba náà àti ìgbà tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró yóò gòkè lọ sọ́run. * Kí ni ìṣarasíhùwà rẹ sí àwọn ìlàlóye yìí? Ṣé ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ ń lágbára sí i ni? Ǹjẹ́ o rí i pé ṣe ni wọ́n jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà túbọ̀ ń kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀ nìṣó? Ẹ̀kọ́ tó kàn nínú ìwé yìí yóò jẹ́ kó túbọ̀ dá ọ lójú ṣáká pé Jèhófà ń ṣí ète rẹ̀ payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 4 Orúkọ Ọlọ́run wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan lédè Hébérù tó túmọ̀ sí “di.” Orúkọ Jèhófà fi hàn pé òun ni Ẹni tí ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run,” ní ojú ìwé 43.

^ ìpínrọ̀ 6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò yẹn lè gùn gan-an lójú àwa èèyàn òde òní, ká má gbàgbé pé nígbà yẹn, ẹ̀mí àwọn èèyàn máa ń gùn gan-an ju ti ìsinsìnyí. Èèyàn mẹ́rin péré látorí Ádámù sí Ábúráhámù, bá ara wọn láyé. Ìyẹn ni pé Lámékì baba Nóà bá Ádámù láyé, Ṣémù ọmọ Nóà bá Lámékì láyé, Ábúráhámù sì bá Ṣémù láyé.—Jẹ́n. 5:5, 31; 9:29; 11:10, 11; 25:7.

^ ìpínrọ̀ 13 Ìgbà méjìdínlógún ni orúkọ náà “Sátánì” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Àmọ́ ó ju ìgbà ọgbọ̀n lọ tí orúkọ náà “Sátánì” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì. Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, torí Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù kò fi bẹ́ẹ̀ pàfiyèsí sí ọ̀rọ̀ nípa Sátánì, bí a ṣe máa dá Mèsáyà mọ̀ ló gbájú mọ́. Ìgbà tí Mèsáyà dé ló wá táṣìírí Sátánì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, tí wọ́n sì wá kọ ọ́ sínú ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì.

^ ìpínrọ̀ 22 Tó o bá fẹ́ ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn àtúnṣe tó bá òye tá a ní tẹ́lẹ̀ yìí, wo àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ wọ̀nyí: October 15, 1995, ojú ìwé 23 sí 28; January 15, 2008, ojú ìwé 20 sí 24; July 15, 2008, ojú ìwé 17 sí 21; July 15, 2013, ojú ìwé 9 sí 14.