Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ o rò pé . . .

 • ohun tó wà lọ́kàn èèyàn ni?

 • àbí àkànlò èdè?

 • àbí ìjọba kan ní ọ̀run?

 OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé.”—Dáníẹ́lì 2:44, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

“A fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.”Aísáyà 9:6, Bíbélì Mímọ́.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ BÍBÉLÌ YẸN LÈ ṢE FÚN Ẹ

 • Ìjọba òdodo kan tó máa ṣe ìwọ fúnra rẹ láǹfààní.—Aísáyà 48:17, 18.

 • Nínú ayé tuntun, gbogbo èèyàn máa ní ìlera tó jí pépé, wọ́n á sì láyọ̀. —Ìṣípayá 21:3, 4.

 ǸJẸ́ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

 • Jésù jẹ́ ká rí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí àwọn èèyàn sì máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:9, 10) Jésù ṣe ohun tó jẹ́ ká rí bí Ọlọ́run ṣe máa dáhùn àdúrà yẹn.

  Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì jí àwọn òkú dìde! (Mátíù 15:29-38; Jòhánù 11:38-44) Nítorí pé Jésù ló máa jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó jẹ́ ká rí ohun tí Ìjọba náà máa ṣe fún àwọn èèyàn abẹ́ Ìjọba rẹ̀.Ìṣípayá 11:15.

 • Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí jẹ́ ẹ̀rí pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó dé. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé kí Ìjọba Ọlọ́run tó mú kí àlàáfíà jọba lórí ilẹ̀ ayé, ogun, ìyàn àti ìmìtìtì ilẹ̀ máa kó ìdààmú bá aráyé.Mátíù 24:3, 7.

  Ohun tá à ń fojú ara wa rí tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ayé báyìí nìyẹn. Torí náà, ó dá wa lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo ìṣòrò yìí.

 RÒ Ó WÒ NÁ

Báwo ni ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé SÁÀMÙ 37:29 àti AÍSÁYÀ 65:21-23.