JÈHÓFÀ Ọlọ́run ti dá àwọn áńgẹ́lì sí ọ̀run tipẹ́tipẹ́ kí ó tó dá ayé. Àmọ́ nígbà tó yá, áńgẹ́lì kan bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà láti ṣi àwọn ẹ̀dá Ọlọ́run lọ́nà kí wọ́n lè máa jọ́sìn òun dípò Ọlọ́run. Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló sì yẹ kí ẹ̀dá máa jọ́sìn. Ìwà àìdáa tí áńgẹ́lì yìí hù ló fi sọ ara rẹ̀ di Sátánì (Ṣaitani) tó túmọ̀ sí “Alátakò,” ìyẹn ẹni tó ń ta ko Ọlọ́run. Kí ni àwọn nǹkan tí Sátánì ṣe láti ta ko Ọlọ́run?

Sátánì lo ejò láti ṣi Éfà lọ́nà

Sátánì ṣi Éfà lọ́nà, ó mú kí ó ṣe àìgbọràn sí Ọlọ́run. Ó fi ẹ̀tàn sọ fún Éfà pé bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe sọ pé kí Éfà má ṣe jẹ èso ọ̀kan lára àwọn igi tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì yẹn, ńṣe ló fi ohun tó dára dù ú. Sátánì wá fi ọ̀dájú pe Ọlọ́run ní òpùrọ́, ó sì fi ẹ̀tàn sọ pé kí Éfà kọ ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí Sátánì sọ rèé: “Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú [èso igi yẹn] ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:5) Éfà fi àìmọ̀kan gba àwọn irọ́ Sátánì gbọ́. Nítorí náà, kò tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run. Éfà sì mú kí Ádámù náà rú òfin Ọlọ́run. Láti ìgbà náà títí di báyìí ni Sátánì ti ń fìtínà gbogbo àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo. Ó sì ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà títí di òní yìí. Báwo ni Sátánì ṣe ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà?

Ìgbàgbọ́ Tí Kì Í Ṣe Ti Òdodo Gbilẹ̀

Sátánì lo ìbọ̀rìṣà àtàwọn òfin àti àṣà èèyàn láti fi ṣi àwọn èèyàn lọ́nà

Sátánì lo ìbọ̀rìṣà àti àwọn òfin àti àṣà àwọn èèyàn láti ṣi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà kúrò nínú ìgbàgbọ́ òdodo. Jésù tó jẹ́ Mèsáyà sọ fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó wà nígbà yẹn pé Ọlọ́run kò gba ìjọsìn wọn, nítorí pé wọ́n ń fi “àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni bí ẹ̀kọ́.” (Mátíù 15:9) Nígbà tí orílẹ̀-èdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ tí wọn kò gba Mèsáyà, Ọlọ́run kọ àwọn náà. Jésù sọ fún wọn pé: “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mátíù 21:43) Bí àwọn tó ń tẹ̀ lé Jésù ṣe di àwọn tí Ọlọ́run yàn, tó sì fi sí ipò àrà ọ̀tọ̀ nìyẹn.

Sátánì wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà láti ṣi àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yìí lọ́nà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ó ṣì wọ́n lọ́nà lóòótọ́? Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, ó lo ohun kan láti fi ṣe àkàwé rẹ̀. Nínú àkàwé yẹn, ọkùnrin kan gbin àlìkámà sínú oko kan. Lẹ́yìn náà, ọ̀tá rẹ̀ wá gbin èpò sí àárín àlìkámà rẹ̀ yẹn. Ọkùnrin náà fi àlìkámà àti èpò náà sílẹ̀ kí wọ́n jọ dàgbà títí di ìgbà ìkórè. Nígbà ìkórè, wọ́n ya èpò kúrò lára àlìkámà, wọ́n da èpò sínú iná. Wọ́n sì kó àlìkámà sínú àká, ìyẹn ibi ìkó-nǹkan-pamọ́-sí.

Jésù wá ṣàlàyé ohun tí àkàwé náà túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Jésù fúnra rẹ̀ ni Afúnrúgbìn náà. Ó sọ pé: “Ní ti irúgbìn àtàtà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ìjọba náà; ṣùgbọ́n àwọn èpò ni àwọn ọmọ ẹni burúkú náà, ọ̀tá tí ó sì fún wọn ni Èṣù. Ìkórè ni ìparí ètò àwọn nǹkan, àwọn áńgẹ́lì sì ni akárúgbìn.” (Mátíù 13:38, 39) Jésù sọ pé àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn òun ló dà bí àlìkámà náà. Àmọ́ Sátánì wá mú àwọn ayédèrú ọmọ ẹ̀yìn wá sí àárín àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù, bí ìgbà téèyàn gbin èpò sí àárín àlìkámà. Bó ṣe di pé ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn ayédèrú ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú nìyẹn gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Àwọn ayédèrú ọmọ ẹ̀yìn yìí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run kò fẹ́. Irú ẹ̀kọ́ bíi pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan, tí wọ́n fi ń sọ pé Ọlọ́run mẹ́ta ló pa pọ̀ di Ọlọ́run kan. Àwọn ayédèrú ọmọ ẹ̀yìn yìí tún bẹ̀rẹ̀ sí í  lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà, wọ́n sì ń dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Ìwọ̀nba àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn díẹ̀ ni kò yà kúrò nínú ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni.

Ọlọ́run Kò Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Òdodo Pa Rẹ́

Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣàlàyé, tó bá yá àyípadà kan máa wáyé. Àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run yóò ya àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo sọ́tọ̀, kí Ọlọ́run lè pa wọ́n run. Ìgbà yẹn ló máa rọrùn láti dá àwọn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀. Ní ìkẹyìn, Ọlọ́run yóò wá pa Sátánì Èṣù tó jẹ́ olórí ọ̀tá ìgbàgbọ́ òdodo run. Ó dájú pé ìgbàgbọ́ òdodo ló máa lékè!

Àmọ́ báwo lo ṣe lè dá àwọn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀ lóde òní? Ìbéèrè yìí ló tún kàn tá a máa dáhùn.

Àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń wá àwọn èèyàn tó fẹ́ láti ní ìgbàgbọ́ òdodo