ORÍṢIRÍṢI ọlọ́run ni àwọn èèyàn ń jọ́sìn. Àmọ́ Ìwé Mímọ́ kọ́ni pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. Ọlọ́run tòótọ́ yìí yàtọ̀ gedegbe, ó ju ohun gbogbo lọ, ó ti wà ṣáájú ohun gbogbo, yóò sì máa wà títí ayé. Òun ló dá ohun gbogbo ní ọ̀run àti ayé, òun ló sì dá àwa èèyàn. Nítorí náà, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló yẹ kí á máa sìn.

Ọlọ́run fún wòlíì Mósè ní Òfin pé kí ó fún àwọn èèyàn rẹ̀, Òfin náà jẹ́ “ọ̀rọ̀ tí a tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì sọ”

Ọlọ́run ní orúkọ oyè tó pọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpọ́nlé rẹ̀, àmọ́ orúkọ kan ṣoṣo péré ni orúkọ rẹ̀ gangan. Orúkọ yẹn ni JÈHÓFÀ. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù, ni ó rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” (Ẹ́kísódù 3:15) Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà tí orúkọ yìí, Jèhófà, fara hàn nínú Ìwé Mímọ́. Ohun tí Sáàmù 83:18 sọ nípa Ọlọ́run ni pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

Orúkọ Ọlọ́run wà nínú ìwé àtijọ́ kan tó ń jẹ́ Àkájọ Ìwé Òkun Òkú

Kò sí èèyàn kankan tó fojú rí Ọlọ́run rí. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Ìwọ kò lè rí ojú mi, nítorí pé kò sí ènìyàn tí ó lè rí mi kí ó sì wà láàyè síbẹ̀.” (Ẹ́kísódù 33:20) Ọ̀run ni Ọlọ́run ń gbé, àwa èèyàn kò lè fi ojú wa rí i. Ó lòdì láti ṣe ère tàbí àwòrán tàbí àmì tàbí ohunkóhun mìíràn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ Ọlọ́run, kò sì tọ̀nà láti máa gbàdúrà sí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run fi rán Mósè wòlíì rẹ̀, ó pàṣẹ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” (Ẹ́kísódù 20:2-5) Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run tún fi iṣẹ́ rán wòlíì Aísáyà pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún àwọn ère fífín.”—Aísáyà 42:8.

Àwọn èèyàn kan gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ wọ́n gbà pé kò sẹ́ni tó lè mọ̀ ọ́n àti pé Ọlọ́run kò ṣeé sún mọ́. Wọ́n gbà pé kàkà kí a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ṣe ló yẹ ká máa sá fún un. Kí lèrò tìrẹ? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ jẹ Ọlọ́run lógún? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ lè mọ Ọlọ́run lóòótọ́, débi pé wàá sún mọ́ ọn dáadáa? Jẹ́ ká wo àwọn ìwà dáadáa tí Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run ní.