Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀

 APA 6

Torí Kí Ni Ọlọ́run Ṣe Dá Ilẹ̀ Ayé??

Torí Kí Ni Ọlọ́run Ṣe Dá Ilẹ̀ Ayé??

ỌLỌ́RUN dá ilẹ̀ ayé, ó fi ṣe ibùgbé tó dára gan-an fún àwa èèyàn. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”—Sáàmù 115:16.

Kí Ọlọ́run tó dá ọkùnrin àkọ́kọ́ tó ń jẹ́ Ádámù (Adama), ó ti kọ́kọ́ ya ibi kékeré kan sọ́tọ̀ nínú ayé, ibẹ̀ ń jẹ́ Édẹ́nì. Ó ṣe ọgbà ìdẹ̀ra kan tó lẹ́wà síbẹ̀. Ìwé Mímọ́ sọ pé Édẹ́nì yìí ni odò tó ń jẹ́ Yúfírétì àti èyí tó ń jẹ́ Tígírísì (ìyẹn Hídẹ́kẹ́lì) ti ṣàn jáde. * Àwọn èèyàn gbà pé àgbègbè ibi tí ọgbà Édẹ́nì yìí wà láyé ìgbà yẹn ni a ń pè ní ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Tọ́kì lóde òní. Èyí fi hàn dájú pé ọgbà ìdẹ̀ra tó ń jẹ́ Édẹ́nì yìí ti wà rí lórí ilẹ̀ ayé yìí.

Ọlọ́run dá Ádámù, ó sì fi í sínú ọgbà Édẹ́nì “láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:15) Nígbà tó yá, Ọlọ́run dá ìyàwó fún Ádámù, orúkọ rẹ̀ ni Éfà (Hawawu). Ọlọ́run wá pa àṣẹ fún Ádámù àti Éfà pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ó ṣe kedere pé, Ọlọ́run “kò wulẹ̀ dá [ayé] lásán, [ṣe ni] ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.”—Aísáyà 45:18.

Àmọ́, Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin Ọlọ́run. Nítorí náà, Ọlọ́run lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Bó ṣe di pé èèyàn kò gbé inú Párádísè mọ́ nìyẹn. Ṣùgbọ́n, àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ṣe pọ̀ ju ìyẹn lọ. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

Ṣé Jèhófà wá pa ohun tó sọ pé òun fẹ́ ṣe nípa ilẹ̀ ayé tì ni, ìyẹn bó ṣe fẹ́ kí ilẹ̀ ayé jẹ́ Párádísè tí àwọn èèyàn aláyọ̀ yóò máa gbé? Rárá o! Ọlọ́run sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” (Aísáyà 55:11) Ó dájú pé Ọlọ́run yóò mú kí Párádísè tún pa dà wà lórí ilẹ̀ ayé!

Báwo ni ìgbé ayé wa ṣe máa rí nínú Párádísè? Wo àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Ìwé Mímọ́, èyí tó wà ní ojú ìwé méjì tó tẹ̀ lé èyí.

^ ìpínrọ̀ 4 Ìwé Mímọ́ sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14 pé: “Odò kan wà tí ń ṣàn jáde láti Édẹ́nì láti bomi rin ọgbà náà, ibẹ̀ ni ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí pínyà, ó sì di ohun tí a lè pè ní ẹ̀ka mẹ́rin. Orúkọ èyí èkíní ni Píṣónì . . . Orúkọ odò kejì sì ni Gíhónì . . . Orúkọ odò kẹta sì ni Hídẹ́kẹ́lì [tàbí Tígírísì]; òun ni èyí tí ó lọ sí ìlà-oòrùn Ásíríà. Odò kẹrin sì ni Yúfírétì.” Ní òde òní kò sí èèyàn tó mọ odó tó ń jẹ́ Píṣónì àti èyí tó ń jẹ́ Gíhónì, kò sì sí ẹni tó mọ ojú ibi tí odò méjèèjì yìí wà.