Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’

 ORÍ 5

Bá A Ṣe Lè Ya Ara Wa Sọ́tọ̀ Kúrò Nínú Ayé

Bá A Ṣe Lè Ya Ara Wa Sọ́tọ̀ Kúrò Nínú Ayé

“Ẹ kì í ṣe apá kan ayé.”—JÒHÁNÙ 15:19.

1. Kí ni Jésù tẹnu mọ́ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn lórí ilẹ̀ ayé?

NÍ ALẸ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀rọ̀ tó sọ fi hàn pé bí nǹkan ṣe máa rí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú jẹ ẹ́ lógún gan-an ni. Ó tiẹ̀ fi ọ̀ràn náà sínú àdúrà tó gbà sí Baba rẹ̀, ó ní: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:15, 16) Nínú ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá yìí, Jésù fi hàn pé òun ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn òun, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n rí bí ọ̀rọ̀ tó ti kọ́kọ́ sọ fáwọn kan lára wọn lálẹ́ ọjọ́ yẹn ti ṣe pàtàkì tó, nígbà tó wí pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Dájúdájú, Jésù kà á sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé!

2. “Ayé” wo ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

2 Nígbà tí Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “ayé,” ohun tó ní lọ́kàn ni gbogbo aráyé tí wọ́n ti sọra wọn dàjèjì sí Ọlọ́run, tí Sátánì ń ṣàkóso lé lórí, tí wọ́n sì ti di ẹrú ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àti ẹ̀mí ìgbéraga tó ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. (Jòhánù 14:30; Éfésù 2:2; 1 Jòhánù 5:19) Ká sòótọ́, “ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé [yẹn] jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Àmọ́, báwo ni gbogbo àwọn tó ń fẹ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe lè wà nínú ayé, síbẹ̀ kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú rẹ̀? A máa gbé ọ̀nà márùn-ún tí wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò, ìyẹn ni pé kí wọ́n fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi ń ṣàkóso lé lórí, kí wọ́n má sì ṣe lọ́wọ́ sí ètò òṣèlú; kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ayé máa darí àwọn; kí  wọ́n máa wọṣọ níwọ̀ntúnwọ̀nsì kí wọ́n sì máa múra lọ́nà tó bójú mu; kí wọ́n jẹ́ kí ojú àwọn mú ọ̀nà kan; kí wọ́n sì gbé ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí wọ̀.

BÁ A ṢE LÈ FARA MỌ́ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN KÁ MÁ SÌ DÁ SÍ ÈTÒ ÒṢÈLÚ

3. (a) Ojú wo ni Jésù fi wo ètò òṣèlú nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tá a fẹ̀mí yàn ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀? (Fi àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé kún un.)

3 Dípò kí Jésù bá wọn dá sí ètò òṣèlú nígbà tó wà láyé, iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ló gbájú mọ́, ìyẹn Ìjọba tí Ọlọ́run máa gbé kalẹ̀ lókè ọ̀run èyí tí Jésù máa ṣàkóso lé lórí gẹ́gẹ́ bí Ọba. (Dáníẹ́lì 7:13, 14; Lúùkù 4:43; 17:20, 21) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n mú Jésù lọ síwájú Gómìnà Róòmù náà, Pọ́ńtíù Pílátù, ó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa fífi hàn pé Kristi àti Ìjọba rẹ̀ làwọn fara mọ́, tí wọ́n sì ń kéde Ìjọba náà fún gbogbo ayé. (Mátíù 24:14) Ìyẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Nítorí náà, àwa jẹ́ ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi . . . gẹ́gẹ́ bí àwọn adípò fún Kristi, àwa bẹ̀bẹ̀ pé: ‘Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́.’” *2 Kọ́ríńtì 5:20.

4. Ọ̀nà wo ni gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ ń gbà fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run làwọn fara mọ́? (Wo  Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Tí Wọn Ò Dá Sí Ọ̀ràn Òṣèlú.)

4 Nítorí pé àwọn ikọ̀ máa ń ṣojú fún ọba tàbí orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ òkèèrè, wọn kì í dá sí ọ̀ràn abẹ́lé tó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá rán wọn lọ; ohun tí wọ́n bá bá lọ ni wọ́n máa ń gbájú mọ́. Àmọ́, àwọn ikọ̀ máa ń gbẹnu sọ fún orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ń ṣojú fún. Bí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tá a fẹ̀mí yàn, tí ‘ẹ̀tọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí aráàlú ń bẹ ní ọ̀run’ náà ṣe rí nìyẹn. (Fílípì 3:20)  Kódà, ọpẹ́lọpẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ń fìtara ṣe, ìyẹn ló ti mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” Kristi lọ́wọ́ láti “padà bá Ọlọ́run rẹ́.” (Jòhánù 10:16; Mátíù 25:31-40) Àwọn tí wọ́n ràn lọ́wọ́ yìí ló wá ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú ikọ̀ fún Kristi, ní ti pé wọ́n ń ṣètìlẹ́yìn fáwọn  arákùnrin Jésù tá a fẹ̀mí yàn. Gẹ́gẹ́ bí agbo kan tó ń fi ìṣọ̀kan gbẹnu sọ fún Ìjọba Mèsáyà náà, àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì kì í lọ́wọ́ sí ètò òṣèlú lọ́nà èyíkéyìí.—Ka Aísáyà 2:2-4.

5. Báwo ni ìjọ Kristẹni ṣe yàtọ̀ sí Ísírẹ́lì ìgbàanì, ọ̀nà wo ni wọ́n sì ń gbà fi hàn pé àwọn yàtọ̀?

5 Àwa Kristẹni tòótọ́ kì í dá sí ọ̀ràn ìṣèlú nítorí pé ti Kristi là ń ṣe. Àmọ́ kì í ṣe nítorí ìyẹn nìkan o. Ohun kan ni pé ọ̀rọ̀ wa ò dà bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì, tí Ọlọ́run yan ibi tí wọ́n á máa gbé fún. Apá kan ẹgbẹ́ ará kárí ayé làwa jẹ́. (Mátíù 28:19; 1 Pétérù 2:9) Nítorí náà, bá a bá ń dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ní orílẹ̀-èdè tá à ń gbé, a ò ní lómìnira àtimáa sọ̀rọ̀ fàlàlà mọ́ tá a bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, á sì ṣòro fún wa láti máa wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. (1 Kọ́ríńtì 1:10) Síwájú sí i, àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, tí Ọlọ́run pàṣẹ fún wa pé ká fẹ́ràn la ó máa bá jà nígbà ogun. (Jòhánù 13:34, 35; 1 Jòhánù 3:10-12) Ìyẹn ló fà á tí Jésù fi sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe gbé idà sókè sí ẹnikẹ́ni. Ó tiẹ̀ tún sọ fún wọn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn.—Mátíù 5:44; 26:52; wo àpótí náà, “ Ṣé Mò Ń Dá sí Ọ̀ràn Òṣèlú?

6. Kí ni yíyà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run gbọ́dọ̀ mú kó o máa ṣe fún Késárì?

6 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, Ọlọ́run la ya ara wa sí mímọ́ fún, kì í ṣe ẹ̀dá èèyàn, àjọ táwọn èèyàn dá sílẹ̀, tàbí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí. Ìwé 1 Kọ́ríńtì 6:19, 20 sọ pé: “Ẹ kì í ṣe ti ara yín, nítorí a ti rà yín ní iye kan.” Nítorí náà, báwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bá ń san ohun ti “Késárì” fún un nípa fífún un ní ọlá tí í ṣe tirẹ̀, tí wọ́n ń sanwó orí, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún un bó ṣe tọ́, a jẹ́ pé lọ́nà kan, wọ́n ń fi “àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run” nìyẹn. (Máàkù 12:17; Róòmù 13:1-7) Lára àwọn ohun tó sì tún jẹ́ ti Ọlọ́run ni ìjọsìn wọn, ìfẹ́ àtọkànwá tí wọ́n ní sí Ọlọ́run àti bí wọ́n ṣe ń ṣègbọràn sí i láìyẹsẹ̀. Bó bá pọn dandan, wọ́n ṣe tán láti kú nítorí ti Ọlọ́run.—Lúùkù 4:8; 10:27;Ka Ìṣe 5:29; Róòmù 14:8.

 BÁ Ò ṢE NÍ JẸ́ KÍ “Ẹ̀MÍ AYÉ” MÁA DARÍ WA

7, 8. Kí ni “ẹ̀mí ayé,” báwo ló sì ṣe ń “ṣiṣẹ́” nínú ẹni?

7 Ọ̀nà míì táwọn Kristẹni máa ń gbà ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé ni pé wọn kì í jẹ́ kí ẹ̀mí búburú ayé darí àwọn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.” (1 Kọ́ríńtì 2:12) Ó sọ fáwọn ará Éfésù pé: “Ẹ ti rìn ní àkókò kan rí ní ìbámu pẹ̀lú . . . ayé yìí, ní ìbámu pẹ̀lú olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.”—Éfésù 2:2, 3.

8 “Afẹ́fẹ́,” tàbí ẹ̀mí ayé, jẹ́ agbára tí kò ṣeé fojú rí, tí ń fipá múni ṣe nǹkan, èyí tó máa ń mú kéèyàn fẹ́ láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, tó sì ń gbé “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” lárugẹ. (1 Jòhánù 2:16; 1 Tímótì 6:9, 10) “Ọlá àṣẹ” ẹ̀mí yìí ń darí aráyé ní ti pé ìwàkiwà tó ń gbé lárugẹ máa ń fa àwọn èèyàn mọ́ra, ó máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́, kì í súni bọ̀rọ̀, àti pé ó délé dóko bí afẹ́fẹ́. Síwájú sí i, bó bá bẹ̀rẹ̀ sí í “ṣiṣẹ́” nínú ẹnì kan, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni onítọ̀hún á bẹ̀rẹ̀ sí hùwà tí kò bá ìlànà Ọlọ́run mu, ìyẹn àwọn ìwà bí ìmọtara-ẹni-nìkan, ìgbéraga, kí ìwọra máa múni ṣe jura ẹni lọ, ìwà aṣèyówùú àti títàpá sí àṣẹ. * Ní kúkúrú ṣá, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ẹ̀mí ayé máa ń mú kéèyàn fìwà jọ Èṣù.—Jòhánù 8:44; Ìṣe 13:10; 1 Jòhánù 3:8, 10.

9. Àwọn ọ̀nà wo ni ẹ̀mí ayé lè gbà wọ ọkàn àti àyà wa?

9 Ṣé ẹ̀mí ayé lè ta gbòǹgbò nínú ọkàn àti àyà rẹ? Bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ ìyẹn á rí bẹ́ẹ̀ kìkì tó bá ṣẹlẹ̀ pé o kò wà lójúfò mọ́. (Ka Òwe 4:23) Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ báyìí ni ẹ̀mí náà máa ń wọlé síni lára, bóyá nípasẹ̀ àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tí wọ́n fojú jọ ẹni rere àmọ́ tó jẹ́ pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Ẹ̀mí tí èṣù ń gbé lárugẹ yẹn tún lè gbà ẹ́ lọ́kàn bó o bá ń ka àwọn ìwé tí kò yẹ, bó o bá ń wo àwòrán oníhòòhò tàbí tó o bá ń tẹ́tí sáwọn apẹ̀yìndà lórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì, bó o bá ń ṣeré ìnàjú tí kò gbámúṣé, tó o sì nífẹ̀ẹ́ sáwọn eré ìdárayá táwọn tó ń bára wọn díje ti máa ń figa gbága. Tàbí nípasẹ̀  ẹnì yòówù tàbí ohunkóhun tó ń gbé èrò Sátánì tàbí ti ayé tó wà lábẹ́ ìdarí rẹ̀ lárugẹ.

10. Kí la lè ṣe tí ẹ̀mí ayé ò fi ní rí wa gbé ṣe?

10 Kí la lè ṣe tí ẹ̀mí ayé tó máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́ yìí ò fi ní rí wa gbé ṣe ká bàa lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run? Ohun tá a lè ṣe ò ju pé ká máa ṣe àwọn ohun ti Jèhófà ti pèsè fún wa láti mú àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ sunwọ̀n sí i, ká sì tún máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kó máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wa. Agbára  Jèhófà ju ti Èṣù tàbí ayé olubi tí Sátánì ń ṣàkóso lé lórí lọ fíìfíì. (1 Jòhánù 4:4) Torí náà, kò sí ohun tó dà bíi ká máa gbàdúrà sí Jèhófà ká bàa lè sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí!

BÁ A ṢE LÈ JẸ́ KÍ AṢỌ ÀTI ÌMÚRA WA MÁA WÀ NÍWỌ̀NTÚNWỌ̀NSÌ

11. Ipa wo ni ẹ̀mí ayé ti ní lórí ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà wọṣọ?

11 A lè fi aṣọ tí ẹnì kan ń wọ̀, bó ṣe ń múra àti bó ṣe mọ́ tónítóní sí, mọ irú ẹ̀mí tó ń darí rẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn èèyàn ò wọṣọ bí ọmọlúwàbí mọ́, ìyẹn ló mú kí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí tẹlifíṣọ̀n kan sọ pé, bó pẹ́ bó yá a ò ní mọ̀yàtọ̀ láàárín aṣẹ́wó àti ẹni tí kì í ṣe aṣẹ́wó mọ́. Kódà, àwọn ọmọbìnrin tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún pàápàá ti ń wọ ìwọ̀kuwọ̀. Ìwé ìròyìn kan tiẹ̀ sọ pé: “Ṣíṣí ló kù tí wọ́n ń ṣí ara sílẹ̀ báyìí, wọ́n ti gbé ìtìjú tà pátápátá.” Àṣà míì tó gbòde ni pé kí wọ́n máa múra wúruwùru lọ́nà tó fi hàn pé kò sí ẹni tó jọ wọ́n lójú, lọ́nà tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn àti bí aláìnítìjú.

12, 13. Àwọn ìlànà wo ló yẹ ká máa tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ pinnu aṣọ tá ó máa wọ̀ àti bá ó ṣe máa múra?

12 Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ohun tó dáa ni pé ká máa múra bí ọmọlúwàbí, ìyẹn ni pé kí aṣọ wa má máa rí wúruwùru, kó mọ́ tónítóní, kó bójú mu, kó sì bá ibi tá à ń wọ̀ ọ́ lọ mu. Ní gbogbo ìgbà, ó yẹ kí ìrísí wa máa fi “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú” hàn, tá a bá wá fi “àwọn iṣẹ́ rere” kún un, á jẹ́ èyí tó bójú mu fún ẹnikẹ́ni, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, “tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé [òun] ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.” Àmọ́ ṣá o, pípe àfiyèsí sí ara wa kọ́ ló jẹ wá lógún, bí kò ṣe pé ‘ká dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.’ (1 Tímótì 2:9, 10; Júúdà 21) Bẹ́ẹ̀ ni, a fẹ́ ká máa wọṣọ lọ́nà tó dára jù lọ, ìyẹn ni pé kó jẹ́ ti “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà . . . , èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.”—1 Pétérù 3:3, 4.

13 Tún fi sọ́kàn pẹ̀lú pé ohun tá a bá fi aṣọ wa rán àti ọ̀nà tá a bá gbà múra lè nípa lórí ojú táwọn míì á fi máa wo ìjọsìn tòótọ́. Tá a bá lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tá a tú sí “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà,”  láti ṣàpèjúwe ìwà téèyàn ń hù, ó máa ń ní èrò ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, ìpayà, gbígba tẹlòmíràn rò àti bíbọ̀wọ̀ fún èrò ẹlòmíràn. Nítorí náà, ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ́ àfojúsùn wa ni pé kí ọ̀nà yòówù tó bá wù wá láti máa gbà wọṣọ má ṣe máa da ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a fẹ́ láti máa bọlá fún Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ ká sì máa fi hàn pé a jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, tó ń ṣe “ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 4:9; 10:31; 2 Kọ́ríńtì 6:3, 4; 7:1.

Ṣé ìrísí mi ń bọlá fún orúkọ Jèhófà?

14. Àwọn ìbéèrè wo la gbọ́dọ̀ bí ara wa nípa ìrísí wa àti ìmọ́tótó ara?

14 Aṣọ wa, ìmúra wa, àti bá a ṣe ń mọ́ tónítóní sí túbọ̀ ṣe pàtàkì nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí tàbí nígbà tá a bá ń lọ sípàdé ìjọ. Máa bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn èèyàn ń wò mí bákan nítorí ìrísí mi àti ìmọ́tótó ara? Ṣé kì í mú kí ará tì wọ́n? Ṣé ohun tó dáa lójú ara mi lórí ọ̀ràn yìí ni mo kà sí pàtàkì ju pé kí n tóótun láti bójú tó ojúṣe èyíkéyìí nínú ìjọ?’—Sáàmù 68:6; Fílípì 4:5; 1 Pétérù 5:6.

15. Kí nìdí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò fi to òfin sílẹ̀ bẹẹrẹbẹ nípa aṣọ, ìmúra àti ìmọ́tótó ara?

15 Bíbélì ò to òfin sílẹ̀ bẹẹrẹbẹ fáwọn Kristẹni nípa aṣọ, ìmúra àti ìmọ́tótó ara. Kò wu Jèhófà pé kó fi òmìnira wa dù wá, yálà òmìnira tá a ní láti yan ohun tá a fẹ́ tàbí láti lo agbára ìrònú wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa, ká máa ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì, ká sì tipa “lílò kọ́ agbára ìwòye [wa] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò  tọ́.” (Hébérù 5:14) Lékè gbogbo rẹ̀, ó fẹ́ kí ìfẹ́ máa darí wa, ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ìfẹ́ fún aládùúgbò. (Ka Máàkù 12:30, 31) Èyí á wá jẹ́ ká gbà pé ọ̀pọ̀ aṣọ ló wà tá a lè wọ̀, lónírúurú ọ̀nà, láì kọjá àyè wa. A lè rí ẹ̀rí èyí nínú bí ogunlọ́gọ̀ èèyàn aláyọ̀ tó ń sin Jèhófà ṣe máa ń wọ onírúurú aṣọ tó rẹwà, níbikíbi tí wọ́n bá pé jọ sí lórí ilẹ̀ ayé.

BÁ A ṢE LÈ JẸ́ KÍ OJÚ WA “MÚ Ọ̀NÀ KAN”

16. Báwo ni ẹ̀mí ayé ṣe ta ko ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

16 Ẹ̀mí ayé kún fún ẹ̀tàn, ó sì ń sún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn láti gbà pé owó àtàwọn nǹkan tówó lè rà ló lè mú kéèyàn láyọ̀. Àmọ́, Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò fọwọ́ sí i pé kéèyàn máa ṣẹ́ra ẹ̀ níṣẹ̀ẹ́ tàbí kó máa fi ohun tó dára du ara ẹ̀, ó kọ́ni  pé àwọn tó máa rí ìyè tí wọ́n sì máa ní ojúlówó ayọ̀ làwọn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” àtàwọn tí ojú wọ́n bá “mú ọ̀nà kan,” ìyẹn ni àwọn tí wọn kì í ṣe jura wọn lọ, àmọ́ tí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. (Mátíù 5:3; 6:22, 23) Bí ara rẹ pé: ‘Ṣé lóòótọ́ ni mo gba ohun tí Jésù fi kọ́ni gbọ́, àbí èrò “baba irọ́” ló ń darí mi? (Jòhánù 8:44) Kí ni ọ̀rọ̀ ẹnu mi, àfojúsùn mi, àwọn nǹkan tí mo fi sí ipò àkọ́kọ́ àti ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbé ayé mi fi hàn pé mo jẹ́?’—Lúùkù 6:45; 21:34-36; 2 Jòhánù 6.

17. Mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn àǹfààní táwọn tí ojú wọn bá mú ọ̀nà kan máa ń gbádùn.

17 Jésù sọ pé: “A [ń] fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àǹfààní táwọn tí ojú wọ́n mú ọ̀nà kan ń gbádùn. Wọ́n máa ń rí ìtura gidi gbà bí wọ́n ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 11:29, 30) Wọn kì í kó àníyàn lé àyà, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ gbara wọn lọ́wọ́ ìdààmú ọkàn àti àìbalẹ̀ àyà. (Ka 1 Tímótì 6:9, 10) Torí pé wọ́n jẹ́ kí ìwọ̀nba tọ́rọ́ kọ́bọ̀ tó ń wọlé tẹ́ àwọn lọ́rùn, wọ́n ń rí àkókò tó pọ̀ sí i láti máa fi gbọ́ ti ìdílé wọn àti láti máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni bíi tiwọn. Èyí sì lè jẹ́ kí wọ́n máa rí oorun sùn dáadáa. (Oníwàásù 5:12) Wọ́n ń rí ayọ̀ tó pọ̀ gbà nínú fífúnni lọ́nà èyíkéyìí tí wọ́n bá lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 20:35) Wọ́n sì ń “ní ìrètí púpọ̀ gidigidi” àti àlàáfíà pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àtọkànwá. (Róòmù 15:13; Mátíù 6:31, 32) Ìbùkún tí kò ṣeé fowó rà mà lèyí o!

BÁ A ṢE LÈ GBÉ “Ẹ̀KÚNRẸ́RẸ́ ÌHÁMỌ́RA OGUN” WỌ̀

18. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ọ̀tá wa, ọ̀nà tó ń gbà ṣọṣẹ́ àti irú ìjà tó ń bá wa jà?

18 Àwọn tó bá dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tún máa ń rí ààbò tẹ̀mí gbà, ìyẹn ni pé Sátánì tó fẹ́ láti bẹ́gi dínà ayọ̀ àwọn Kristẹni, tí kò sì fẹ́ kí wọ́n jogún ìyè àìnípẹ̀kun ò ní lè dí wọn lọ́wọ́ sísin Ọlọ́run. (1 Pétérù 5:8) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí  àwọn alákòóso, lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Ọ̀rọ̀ náà “gídígbò” túmọ̀ sí pé ìjà ojúkojú ni Sátánì ń bá wa jà, kò sì rọrùn láti ríbi sá sí. Síwájú sí i, gbólóhùn náà, “àwọn alákòóso,” “àwọn aláṣẹ” àti “àwọn olùṣàkóso ayé” fi hàn pé ńṣe ni Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ dìídì kóra jọ láti bá wa fà á.

19. Ṣàpèjúwe ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí táwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ gbé wọ̀.

19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ àwa ẹ̀dá, tó sì níbi tí agbára wá mọ, a ṣì lè borí nínú ìjà tí Sátánì ń bá wa jà. Lọ́nà wo? Nípa gbígbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” wọ̀. (Éfésù 6:13) Bí Éfésù 6:14-18 ṣe ṣàpèjúwe ìhámọ́ra ogun náà rèé: “Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in pẹ̀lú abẹ́nú yín tí a fi òtítọ́ dì lámùrè, kí ẹ sì gbé àwo ìgbàyà ti òdodo wọ̀, àti pẹ̀lú ẹsẹ̀ yín tí a fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ̀ ní bàtà. Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ tẹ́wọ́ gba àṣíborí [tàbí, ìrètí] ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lẹ́sẹ̀ kan náà, pẹ̀lú gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.”

20. Báwo ni ipò tiwa ṣe yàtọ̀ sí tọmọ ogun tó ń gbébọn?

20 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló pèsè ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí yìí, kò ní já wa kulẹ̀, ìyẹn bá a bá ń gbé e wọ̀ nígbà gbogbo. Àmọ́, ìjà tàwa Kristẹni ò dà bíi tàwọn ọmọ ogún tó ń gbébọn, tí wọ́n máa ń ráyè sinmi nígbà tí ogun bá dáwọ́ dúró. Sátánì ò ní dẹ́kun àtimáa bá wa ja ìjà àjàkú akátá títí tí Ọlọ́run á fi pa ayé Èṣù yìí run tá á sì sọ gbogbo àwọn ẹ̀mí burúkú sínú ọ̀gbun. (Ìṣípayá 12:17; 20:1-3) Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́ bó o bá ń bá àwọn àìlera kan tàbí àwọn èrò òdì kan fà á, torí pé gbogbo wá gbọ́dọ̀ ‘lu ara wa kíkankíkan’ ká tó lè máa sin Jèhófà nìṣó láìyẹsẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 9:27) Kódà, ìgbà tó bá dà bíi pé a ò ní ìṣòro kankan gan-an ni kò yẹ kí ọkàn wa balẹ̀!

21. Ọ̀nà kan ṣoṣo wo la lè gbà borí nínú ogun tẹ̀mí tá à ń jà?

 21 Síwájú sí i, a ò lè dá ogun yìí jà ká sì ṣẹ́gun. Ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù fi rán wa létí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà “ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.” Lẹ́sẹ̀ kan náà, a gbọ́dọ̀ máa fetí sí Jèhófà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká sì máa pé jọ pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ “ọmọ ogun,” torí pé a jọ ń ja ìjà náà ni! (Fílémónì 2; Hébérù 10:24, 25) Ó dájú pé gbogbo ẹni tó bá ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí á borí nínú ogun náà. Kì í wá ṣèyẹn nìkan, á tún ṣeé ṣe fún wọn láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn bí ẹnikẹ́ni bá fìwọ̀sí lọ̀ wọ́n.

GBÁRA DÌ LÁTI GBÈJÀ ÌGBÀGBỌ́ RẸ

22, 23. (a) Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa gbára dì nígbà gbogbo láti gbèjà ìgbàgbọ́ wa, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa? (b) Kókó wo la máa jíròrò nínú orí tó kàn?

22 Jésù sọ pé: “Nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, . . . ni ayé fi kórìíra yín.” (Jòhánù 15:19) Nítorí èyí, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa múra tán láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn kí wọ́n sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. (Ka 1 Pétérù 3:15) Bí ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo mọ ohun tó fà á táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ti gbogbo èèyàn nígbà míì? Bó bá wa di pé kí ń ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tí gbogbo aráyé ń ṣe, ǹjẹ́ ó dá mi lójú kedere pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì àti ẹrú olóòótọ́ sọ lórí ọ̀ràn náà? (Mátíù 24:45; Jòhánù 17:17) Bá a bá sì yọwọ́ pé màá fẹ́ ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tàwọn míì nítorí àtiṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà, ǹjẹ́ inú mi máa ń dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?’—Sáàmù 34:2; Mátíù 10:32, 33.

23 Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Èṣù tún máa ń dán wa wò láwọn ọ̀nà míì tó ṣòroó fura sí bó bá dọ̀ràn pé ká ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé. Bí àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Èṣù máa ń gbìyànjú láti fi eré ìnàjú tan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wọnú ayé lọ. Báwo la ṣe lè yan eré ìnàjú tó gbámúṣé tó máa tù wá lára tí kò sì ní pa ẹ̀rí ọkàn wa lára? Kókó tá a máa gbé yẹ̀ wò nínú orí tó kàn nìyẹn.

^ ìpínrọ̀ 3 Látìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Pẹ́ńtíkọ́sì, lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ fìdí múlẹ̀, ni Kristi ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lórí ìjọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tá a fẹ̀mí yàn, tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. (Kólósè 1:13) Nígbà tó di ọdún 1914, Ọlọ́run gbé àṣẹ lé Kristi lọ́wọ́ láti máa ṣàkóso lórí “ìjọba ayé.” Nítorí èyí, àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn pẹ̀lú ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ tí ń ṣojú fún Ìjọba Mèsáyà.—Ìṣípayá 11:15.

^ ìpínrọ̀ 8 Wo Reasoning From the Scriptures àti Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1994, ojú ìwé 14. Àwa Ẹlẹrìí Jèhófà la ṣe wọ́n.