Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’

 ÀFIKÚN

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀ àti Ìpínyà

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀ àti Ìpínyà

Jèhófà ò fẹ́ káwọn tó gbéra wọn níyàwó dalẹ̀ ara wọn. Nígbà tí Jèhófà ń so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pọ̀, ó wí pé: “Ọkùnrin . . . yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” Nígbà tó ṣe, Jésù Kristi sọ gbólóhùn yìí kan náà, ó sì fi kún un pé: “Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan  má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Mátíù 19:3-6) Nítorí èyí, Jèhófà àti Jésù ń wo ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ètò táá máa wà títí lọ, àyàfi bí ọkọ tàbí aya bá kú. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló fìdí ìgbéyàwó múlẹ̀, ìkọ̀sílẹ̀ kúrò lóun téèyàn á fọwọ́ kékeré mú. Kódà, Jèhófà kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu.—Málákì 2:15, 16.

Kí nìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí tọkọtaya fi lè kọra wọn sílẹ̀? Ohun kan ni pé Jèhófà kórìíra panṣágà àti àgbèrè. (Jẹ́nẹ́sísì 39:9; 2 Sámúẹ́lì 11:26, 27; Sáàmù 51:4) Ó tiẹ̀ kórìíra àgbèrè débi pé ó gbà kí tọkọtaya torí ẹ̀ kọra wọn sílẹ̀. (Bó o bá fẹ́ ka ohun tí àgbèrè túmọ̀ sí, wo Orí 9, ìpínrọ̀ 7, níbi tá a ti ṣàlàyé àgbèrè.) Jèhófà fún ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ bá dalẹ̀ láǹfààní láti yàn bóyá á ṣì máa bá a gbé tàbí ó máa fẹ́ láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Mátíù 19:9) Torí náà, bí ọkọ tàbí aya ẹni tó dalẹ̀ náà bá yàn láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò ṣe ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí. Síbẹ̀, ìjọ Ọlọ́run ò fi dandan gbọ̀n lé e pé kí ẹnikẹ́ni kọra wọn sílẹ̀. Kódà, lábẹ́ àwọn ipò kan, ọkọ tàbí aya ẹni tó dalẹ̀ náà ṣì lè fẹ́ máa gbé pẹ̀lú rẹ̀, pàápàá bó bá ronú pìwà dà látọkàn wá. Bó ti wù kó rí ṣá, àwọn tí wọ́n nídìí tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti kọra wọn sílẹ̀ gbọ́dọ̀ dá pinnu ohun tí wọ́n á ṣe, kí wọ́n sì fara mọ́ ibi tọ́ràn náà bá já sí.—Gálátíà 6:5.

Lábẹ́ àwọn ipò kan tó le koko, àwọn Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn á pínyà tàbí káwọn kọ ọkọ tàbí aya àwọn sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣe àgbèrè. Lábẹ́ irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé kí ẹni tó pínyà yẹn “wà láìlọ́kọ [tàbí, láìláya], bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀” náà. (1 Kọ́ríńtì 7:11) Irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ kò lómìnira láti tún fẹ́ ẹlòmíì. (Mátíù 5:32) Gbé àwọn ipò líle koko díẹ̀ táwọn kan ti torí ẹ̀ pínyà yẹ̀ wò.

Mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọ́ bùkátà ìdílé. Ìdílé kan lè tòṣì, kí wọ́n má sì láwọn ohun kòṣeémánìí, torí pé ọkọ ò pèsè ohun tó yẹ fún wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára rẹ̀ gbé e láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún . . . àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Bírú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ bá kọ̀ láti yí ìwà rẹ̀ padà, aya ní láti pinnu bóyá ó yẹ kóun fẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́, káwọn sì pínyà, kóun àtàwọn  ọmọ má bàa máa ráágó. Àmọ́ ṣá o, àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ gbé ẹ̀sùn èyíkéyìí tí Kristẹni kan bá mú wá pé ọkọ òun ò pèsè jíjẹ, mímu àti aṣọ fún ìdílé rẹ̀ yẹ̀ wò dáádáá. Bí ọkọ bá kọ̀ láti bójú tó ìdílé rẹ̀, ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́ o.

Lílù ní àlùbami. Báwọn tó fẹ́ra wọn sílé bá ń lura wọn bí ẹní lu bàrà, ẹni tọ́wọ́ ìyà náà ń dùn lè di aláàárẹ̀ tàbí kí ìwàláàyè rẹ̀ wà nínú ewu. Bí ẹni tó ń lu ẹnì kejì rẹ̀ bá jẹ́ Kristẹni, àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀ràn náà wò. Kéèyàn máa bínú fùfù, kó sì máa ṣe ohun tó lè pa ẹlòmíì lára, lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́.—Gálátíà 5:19-21.

Mímú kó nira láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Ọkọ tàbí aya lè máa ṣe ohun tó máa mú kó nira fún ẹnì kejì rẹ̀ láti máa kópa nínú ìjọsìn tòótọ́ tàbí kó tiẹ̀ máa fipá mú un láti rú òfin Ọlọ́run láwọn ọ̀nà kan. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ ìjọsìn rẹ̀ di akúrẹtẹ̀ ní láti pinnu bóyá ọ̀nà tó dára jù lọ fóun láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn” ni pé kóun fẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́, kóun sì pínyà pẹ̀lú ẹnì kejì òun.—Ìṣe 5:29.

Nínú gbogbo ọ̀ràn tí ìṣòro tó légbá kan bá ti wáyé bí irú èyí tó wà lókè yìí, ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ fi dandan lé e pé kí ẹni tọ́ràn kàn pínyà tàbí kó máa bá a yí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó lóye òtítọ́ jinlẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ onítọ̀hún àtàwọn alàgbà lè ṣaájò kí wọ́n sì fi Bíbélì gbà wọ́n nímọ̀ràn, wọn ò lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín ọkọ àti aya. Ojú Jèhófà nìkan ló tó o. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ohun tó ń bọlá fún Ọlọ́run tàbí ètò ìgbéyàwó bí Kristẹni tó jẹ́ aya tàbí ọkọ bá ń ṣe àbùmọ́ àwọn ìṣòro tó ń wáyé nínú ilé wọn torí àtilè pínyà kí wọ́n sì máa gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Béèyàn bá dọ́gbọ́n sí i kóun àti ẹnì kejì rẹ̀ lè pínyà, ojú Jèhófà tó o, bó ti wù kó gbìyànjú láti fọ̀rọ̀ náà pa mọ́ tó. Àní sẹ́, “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Àmọ́, bó bá jẹ́ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ léwu gan-an, kí ẹnikẹ́ni má ṣe wá ẹ̀sùn sí Kristẹni èyíkéyìí lẹ́sẹ̀, bó bá parí ẹ̀ sí pé káwọn kúkú pínyà. Ó ṣe tán, “gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run.”—Róòmù 14:10-12.