Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀFIKÚN

Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí Obìnrin Máa Borí, Kí sì Nìdí?

Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí Obìnrin Máa Borí, Kí sì Nìdí?

Ibo ló ti yẹ kí obìnrin tó jẹ́ Kristẹni máa fi nǹkan borí bó bá dọ̀ràn ìjọsìn, kí sì nìdí? Ẹ jẹ́ ká gbé lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ lórí ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. Ó fún wa ní ìtọ́sọ́nà tá a nílò lórí ọ̀ràn náà ká bàa lè ṣe àwọn ìpinnu tó yẹ, àwọn ìpinnu tó máa fi ọlá fún Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 11:3-16) Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àwọn kókó mẹ́ta tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò: (1) àwọn ìgbòkègbodò tó lè fa kí obìnrin fi nǹkan borí, (2) ibi tó ti yẹ kí obìnrin fi nǹkan borí, àti (3) ohun tó gbọ́dọ̀ mú obìnrin fi nǹkan borí.

Àwọn ìgbòkègbodò tó lè mú kí obìnrin fi nǹkan borí. Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ohun méjì: àdúrà àti sísọ tẹ́lẹ̀. (Ẹsẹ 4, 5) Ńṣe ni ẹni tó bá ń gbàdúrà ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àmọ́, lóde òní, sísọ tẹ́lẹ̀ ni kí ẹnì kan tó jẹ́ oníwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa fi ẹ̀kọ́ tá a gbé karí Bíbélì kọ́ni. Ṣó wá lè jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé kí obìnrin máa bo orí rẹ̀ nígbàkigbà tó bá ń gbàdúrà tàbí tó bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Rárá o. Ibi tí obìnrin bá ti ń gbàdúrà tàbí tó ti ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ló máa pinnu bóyá ó máa borí tàbí kò ní borí.

Ibi tó ti yẹ kí obìnrin fi nǹkan borí. Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ní ibi méjì tá a ti lè retí pé kí obìnrin ṣe àwọn nǹkan kan lọ́kàn, ìyẹn nínú ìdílé àti nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Orí obìnrin ni ọkùnrin . . .  Olúkúlùkù obìnrin tí ń gbàdúrà tàbí tí ń sọ tẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀ dójú ti orí rẹ̀.” (Ẹsẹ 3, 5) Nínú ìdílé, ọkọ ni Jèhófà yàn ṣe orí aya. Bí kì í bá fi ọ̀wọ̀ tó yẹ fún ọkọ tí Ọlọ́run yàn ṣe orí rẹ̀, ó máa dójú tì í bó bá ṣe ojúṣe tí Jèhófà gbé lé ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, bó bá pọn dandan pé kí ìyàwó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi tí ọkọ rẹ̀ wà, ó gbọ́dọ̀ fi nǹkan borí, kó lè fi hàn pé òun gbà pé orí òun ló jẹ́. Yálà ó ti ṣèrìbọmi tàbí kò tíì ṣèrìbọmi, ohun tó yẹ kó ṣe nìyẹn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni olórí ìdílé. * Bákan náà, bó bá ní láti gbàdúrà tàbí kó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, níbi tọ́mọ rẹ̀ ọkùnrin kékeré tó ti ṣèrìbọmi wà, ó ṣì gbọ́dọ̀ borí, kì í ṣe torí pé ọmọ náà jẹ́ olórí ìdílé o, bí kò ṣe torí àṣẹ tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi lọ́wọ́ nínú ìjọ Kristẹni.

Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ibòmíì, ìyẹn ìjọ, nígbà tó sọ pé: “Bí ó bá dà bí ẹni pé ẹnikẹ́ni ń ṣe awuyewuye fún àṣà mìíràn kan, àwa kò ní òmíràn, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ Ọlọ́run kò ní.” (Ẹsẹ 16) Nínú ìjọ Kristẹni, àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi ló máa ń múpò iwájú. (1 Tímótì 2:11-14; Hébérù 13:17) Àwọn ọkùnrin nìkan la máa ń yàn gẹ́gẹ́ bí alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run sì máa ń gbéṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti máa bójú tó agbo. (Ìṣe 20:28) Àmọ́, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ipò nǹkan lè béèrè pé ká ké sí obìnrin tó jẹ́ Kristẹni pé kó wá bójú tó iṣẹ́ tó jẹ́ pé ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi, tó sì kúnjú ìwọ̀n ló yẹ kó bójú tó o. Bí àpẹẹrẹ, ó lè pọn dandan pé kó darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá torí pé ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi tó sì kúnjú ìwọ̀n ò sí níbẹ̀ tàbí kó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ti ṣètò tẹ́lẹ̀ níbi tí ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi wà. Nítorí pé irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára iṣẹ́ tí ìjọ Kristẹni ń bójú tó, ó gbọ́dọ̀ fi nǹkan borí láti fi hàn pé iṣẹ́ tí wọ́n sábà máa ń yàn fún ọkùnrin lòun ń ṣe.

Lọ́wọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn wa ni kò béèrè pé kí obìnrin fi nǹkan borí. Bí àpẹẹrẹ, kò ní borí bó bá ń dáhùn nípàdé ìjọ, bóun àti ọkọ rẹ̀ tàbí arákùnrin míì tó ti ṣèrìbọmi bá ń wàásù láti ilé dé ilé, tó bá ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn  ọmọ rẹ̀ tí wọn ò tíì ṣèrìbọmi tàbí tó bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ ṣáá o, àwọn ìbéèrè míì lè jẹ yọ lórí ọ̀ràn yìí, bí ohun kan ò bá sì dá arábìnrin kan lójú, ó lè ṣe ìwádìí síwájú sí i. * Bọ́rọ̀ náà bá ṣì rú u lójú lẹ́yìn tó ti ṣèwádìí, kò sóhun tó burú níbẹ̀ bó bá fi nǹkan borí.

Ohun tó gbọ́dọ̀ mú obìnrin fi nǹkan borí. Ní ẹsẹ 10, a rí ìdí méjì tí obìnrin tó jẹ́ Kristẹni fi gbọ́dọ̀ fẹ́ láti fi nǹkan borí. Bíbélì sọ pé: “Ó . . . yẹ kí obìnrin ní àmì ọlá àṣẹ ní orí rẹ̀ nítorí àwọn áńgẹ́lì.” Lákọ̀ọ́kọ́, kíyè sí gbólóhùn náà, “àmì ọlá àṣẹ.” Bí obìnrin bá fi nǹkan borí, ńṣe ló ń fi hàn pé òun mọrírì àṣẹ tí Jèhófà ti gbé lé àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi nínú ìjọ lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé òún nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run òun ò sì fẹ́ yẹsẹ̀ nínú títẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Ìdí kejì la rí nínú gbólóhùn tó sọ pé, “nítorí àwọn áńgẹ́lì.” Báwo ni bíbò tí obìnrin bá bo orí ṣe kan àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára wọ̀nyẹn?

Inú àwọn áńgẹ́lì máa ń dùn láti rí i pé gbogbo ẹ̀dá tí Jèhófà dá ló ń bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ̀, lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀dá aláìpé. Ó ṣe tán, àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ máa tẹrí ba fún àwọn ìlànà tí Jèhófà gbé kalẹ̀, ìlànà tí ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì kùnà láti tẹ̀ lé látijọ́. (Júúdà 6) Ní báyìí, àwọn áńgẹ́lì lè rí Kristẹni kan tó jẹ́ obìnrin, àmọ́ tó túbọ̀ nírìírí, tó túbọ̀ nímọ̀, tó sì túbọ̀ lóye ju ọkùnrin kan tó ti ṣèrìbọmi lọ nínú ìjọ; síbẹ̀, tó múra tán láti tẹrí ba fún àṣẹ rẹ̀. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn, tó máa tó di ọ̀kan lára àwọn àjùmọ̀jogún Kristi. Irú obìnrin bẹ́ẹ̀ máa tó wà nípò kan tó máa ga ju tàwọn áńgẹ́lì lọ, á sì ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run. Àpẹẹrẹ àtàtà mà nìyẹn jẹ́ fáwọn áńgẹ́lì láti  máa kíyè sí báyìí o! Dájúdájú, àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ gbáà ni gbogbo àwọn arábìnrin ní láti fi hàn bí wọ́n ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó bí wọ́n ti ń ṣe ohun tí Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ wọn nípa títẹrí ba àti pípa òfin Ọlọ́run mọ́ láìyẹsẹ̀, tí àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ sì ń wò wọ́n!

^ ìpínrọ̀ 3 Kò sídìí tí obìnrin tó jẹ́ Kristẹni á fi máa gbàdúrà sókè níbi tọ́kọ ẹ̀ tó jẹ́ onígbàgbọ́ wà, àyàfi lábẹ́ àwọn ipò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, bíi tí ọkọ bá ya odi nítorí àìsàn.

^ ìpínrọ̀ 2 Bó o bá ń fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ wo Ilé Ìṣọ́ July 15, 2002, ojú ìwé 26 sí 27, àti August 15, 1977, ojú ìwé 489.