Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 15

O Lè Gbádùn Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ

O Lè Gbádùn Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ

“Kí olúkúlùkù ènìyàn . . . rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”—ONÍWÀÁSÙ 3:13.

1-3. (a) Báwo ni iṣẹ́ ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn? (b) Kí ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa iṣẹ́ ṣíṣe, àwọn ìbéèrè wo la sì máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí?

IṢẸ́ ṣíṣe kì í dùn mọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn nínú lóde òní. Ibi iṣẹ́ máa ń sú wọn láti lọ, torí pé iṣẹ́ tí wọ́n ń fojoojúmọ́ ṣe kì í ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò. Kí làwọn tí nǹkan rí báyìí lára wọn lè ṣe kí wọ́n lè fẹ́ràn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, kí wọ́n sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ ọ̀hún?

2 Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ní èrò tó dára nípa iṣẹ́ àṣekára. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀bùn ni iṣẹ́ àtàwọn èrè tó ń tibẹ̀ wá jẹ́ fún wa. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Oníwàásù 3:13) Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì fẹ́re fún wa ni Jèhófà, ó fẹ́ ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ tá à ń ṣe, ó sì fẹ́ ká jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wa. Tá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, a ní láti máa fojú tí Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ wò ó, ká sì fàwọn ìlànà rẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ sọ́kàn.—Ka Oníwàásù 2:24; 5:18.

3 Àwọn ìbéèrè mẹ́rin tá a máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí rèé: Báwo la ṣe lè gbádùn iṣẹ́ àṣekára? Àwọn iṣẹ́ wo ni Kristẹni tòótọ́ ò gbọ́dọ̀ ṣe? Báwo la ṣe lè ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ojúṣe tá a ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni? Iṣẹ́ tó sì ṣe pàtàkì jù lọ wo la ní láti ṣe? Ká tó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ àwọn òṣìṣẹ́ kára méjì tí kò sírú  wọn láyé àti lọ́run yẹ̀ wò, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi.

ÒṢÌṢẸ́ TÓ GA JÙ LỌ ÀTI ÀGBÀ ÒṢÌṢẸ́ NÁÀ

4, 5. Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òṣìṣẹ́ kára ni Jèhófà?

4 Jèhófà ni Òṣìṣẹ́ Gíga Jù Lọ. Jẹ́nẹ́sísì 1:1 sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn tí Ọlọ́run parí ṣíṣẹ̀dá àwọn ohun tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó wo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ó sì rí i pé wọ́n “dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Lọ́rọ̀ kan, Ọlọ́run nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nínú àwọn ohun tó dá sáyé. Kò sí àníàní pé Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀” rí ìdùnnú tó kọyọyọ nínú jíjẹ́ òṣìṣẹ́ kára.—1 Tímótì 1:11.

5 Òṣìṣẹ́ kára ni Ọlọ́run wa, kò sì dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, Jésù sọ pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí.” (Jòhánù 5:17) Kí ni Baba rẹ̀ ń ṣe látọdún yìí wá? Ó dájú pé kò dáwọ́ dídáàbò bo ìran èèyàn dúró, ó sì ń bójú tó wọn látorí ìtẹ́ rẹ̀ lọ́run. Ó ti ṣẹ̀dá “àwọn ohun tuntun” ìyẹn àwọn Kristẹni tó fẹ̀mí yàn láti jọba pẹ̀lú Jésù lọ́run. (2 Kọ́ríńtì 5:17) Kò dáwọ́ iṣẹ́ dúró láti rí i pé gbogbo ìlérí tó ti ṣe fún ìran èèyàn nímùúṣẹ, káwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun. (Róòmù 6:23) Ó dájú pé inú Jèhófà ń dùn sí àbájáde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọ̀kẹ́ àìmọye ló ti fìfẹ́ hàn sí ìwàásù nípa Ìjọba rẹ̀, bí Ọlọ́run sì ṣe ń fa àwọn èèyàn wọ̀nyí ni wọ́n ń tún ìwà ara wọn ṣe kí wọ́n lè dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.—Jòhánù 6:44.

6, 7. Àwọn àkọsílẹ̀ wo ló fi hàn pé ọjọ́ ti pẹ́ tí Jésù ti ń ṣiṣẹ́ kára?

6 Ọjọ́ ti pẹ́ tí Jésù náà ti jẹ́ òṣìṣẹ́ kára. Kó tó wá sáyé, ó ti sìn gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run nínú ṣíṣẹ̀dá gbogbo ohun tó wà “ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Òwe 8:22-31; Kólósè 1:15-17) Nígbà tó sì wà lórí ilẹ̀ ayé, kò fìgbà kan dáwọ́ dúró láti máa ṣiṣẹ́ kára. Ọmọdé ṣì ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ iṣẹ́ ilé kíkọ́, kò sì pẹ́ táwọn èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí í  pè é ní “káfíńtà.” * (Máàkù 6:3) Iṣẹ́ àṣekára niṣẹ́ káfíńtà, ó sì gba kéèyàn lọ́pọlọ, pàápàá láyé ìgbà yẹn tí kò sí ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń lagi, tí kò sí ilé ìtajà ńláńlá, tí kò sì sáwọn ẹ̀rọ oníná. Ṣó o lè fojú inú yàwòrán Jésù níbi tó ti ń wá igi tó fẹ́ lò, bóyá ó tiẹ̀ máa ní láti lọ gégi lóko, tá á sì gbé e lọ síbi tó bá ti fẹ́ lò ó? Àbí kẹ̀, ṣó o lè fojú yàwòrán ẹ̀ níbi tó ti ń kọ́lé, tó ń figi rólé, tó ń ṣe ilẹ̀kùn tó sì ń kan àga, tábìlì àtàwọn èlò tí wọ́n figi ṣe tó máa ń wà nínú ilé? Ó dájú pé Jésù alára mọ irú ìtẹ́lọ́rùn téèyàn máa ń ní téèyàn bá fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ àṣekára.

7 Jésù yàtọ̀ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run. Iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tó ṣe pàtàkì jù lọ ni Jésù gbájú mọ́ fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀. Torí ìfẹ́ ọkàn tó ní láti bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ó máa ń tètè dìde nílẹ̀, ó máa ń wàásù di alẹ́, kì í sì í fàkókò ṣòfò. (Lúùkù 21:37, 38; Jòhánù 3:2) “Ó ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:1) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà ni Jésù rìn, lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, ó ní láti rin àwọn ọ̀nà eléruku kó lè wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀.

8, 9. Báwo ni Jésù ṣe gbádùn iṣẹ́ àṣekára tó ṣe?

8 Ṣé Jésù gbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ ni! Ó fún irúgbìn òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì fi pápá tó funfun fún kíkórè sílẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti wá dé bá. Iṣẹ́ Ọlọ́run fún Jésù lókun ó sì tẹ́ ẹ lọ́rùn débi pé ó yááfì oúnjẹ kó lè ṣe iṣẹ́ náà dójú àmì. (Jòhánù 4:31-38) Wo bí ọkàn rẹ̀ ṣe máa balẹ̀ tó nígbà tó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé tó sì rídìí láti ròyìn fún Bàbá  rẹ̀ pé: “Mo ti yìn ọ́ lógo ní ilẹ̀ ayé, ní píparí iṣẹ́ tí ìwọ ti fún mi láti ṣe.”—Jòhánù 17:4.

9 Jèhófà àti Jésù ló jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára jù lọ ní ti ká gbádùn iṣẹ́ àṣekára. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló ń mú ká “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfésù 5:1) Ìfẹ́ tá a sì ní fún Jésù ló ń mú ká máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Ní báyìí, ẹ jẹ́ káwa náà wá gbé bá a ṣe lè gbádùn iṣẹ́ àṣekára yẹ̀ wò.

BÁ A ṢE LÈ GBÁDÙN IṢẸ́ ÀṢEKÁRA

O lè gbádùn iṣẹ́ àṣekára, bó o bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò

10, 11. Kí ló lè mú ká lẹ́mìí pé nǹkan á dáa lẹ́nu iṣẹ́ wa?

10 Ó ní ipa tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ń kó nígbèésí ayé Kristẹni kọ̀ọ̀kan. Gbogbo wa la fẹ́ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn àti ìfọ̀kànbalẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa, àmọ́ èyí lè ṣòro gan-an tó bá lọ jẹ́ pé iṣẹ́ tá ò kúndùn là ń ṣe. Báwo la wá ṣe lè gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wa nírú ipò yìí?

11 Nípa níní ẹ̀mí pé nǹkan á dáa. Kì í ṣe gbogbo ìgbà la lè fọwọ́ ara wa yan ohun tá a bá fẹ́ ṣùgbọ́n a lè mú ara wa bá ipò tá a bá bá ara wa mu. Tá a bá ń fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo iṣẹ́ wò ó, á rọrùn fún wa láti ní ẹ̀mí pé nǹkan á dáa lẹ́nu iṣẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jẹ́ olórí ìdílé, máa ronú pé iṣẹ́ tó ò ń ṣe bó ti wù kó kéré tàbí kó nira tó, ló ń jẹ́ kó o lè gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ. Ojú kékeré sì kọ́ ni Ọlọ́run fi ń wo ọ̀rọ̀ gbígbọ́ bùkátà àwọn ará ilé rẹ. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé ọ̀ràn ẹnikẹ́ni tó bá kọ̀ láti gbọ́ bùkátà ìdílé ẹ̀ “burú ju tẹni tó sẹ́ Jèhófà lọ.” (1 Tímótì 5:8; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Tó o bá ń ní in lọ́kàn pé iṣẹ́ tó ò ń ṣe ló ń jẹ́ kó o lé àfojúsùn kan bá, ìyẹn bíbójú tó ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé ẹ lọ́wọ́, wàá máa ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ tó ò ń ṣe dé ìwọ̀n àyè kan, wàá mọ ìdí tó o fi ń ṣiṣẹ́, ìyẹn sì lè máà yé àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́.

12. Kí làwọn èrè tó wà nídìí kéèyàn jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn tí kì í purọ́?

12 Nípa jíjẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn tí kì í purọ́. Ìbùkún téèyàn  máa rí tó bá ń ṣiṣẹ́ kára tó sì jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn ò láfiwé. Àwọn agbanisíṣẹ́ máa ń mọyì àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ kára tí wọ́n sì jẹ́ aláápọn. (Òwe 12:24; 22:29) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, a tún gbọ́dọ̀ máa fòótọ́ ṣiṣẹ́ wa, a ò gbọ́dọ̀ máa jí owó, àwọn ohun èlò tá a fi ń ṣiṣẹ́ tàbí ká máa fàkókò iṣẹ́ ṣe nǹkan tara wa. (Éfésù 4:28) Bá a ṣe rí i ní orí tó ṣáájú, èrè tó wà nídìí kéèyàn máa fòótọ́ ṣiṣẹ́ ò kéré rárá. Ó ṣeé ṣe káwọn agbanisíṣẹ́ fọkàn tán òṣìṣẹ́ tó ń fòótọ́ bá wọn lò. Bóyá àwọn agbanisíṣẹ́ wa mọyì iṣẹ́ àṣekára tá à ń ṣe tàbí wọn ò mọyì ẹ̀, a máa ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó máa ń wá látinú níní “ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí” àti mímọ̀ pé  à ń múnú Ọlọ́run tá a nífẹ̀ẹ́ dùn.—Hébérù 13:18; Kólósè 3:22-24.

13. Kí ni ìwà rere tá a bá ń hù níbi iṣẹ́ lè yọrí sí?

13 Nípa jíjẹ́ kó dá wa lójú pé ìwà wa lè fògo fún Ọlọ́run. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà gíga Kristẹni níbi iṣẹ́, ó dájú pé àwọn èèyàn á máa kíyè sí i. Kí nìyẹn lè yọrí sí? A lè tipa bẹ́ẹ̀ “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́.” (Títù 2:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni, ìwà rere wa lè jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé ìsìn tiwa yàtọ̀, èyí sì lè jẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń jọ́sìn túbọ̀ máa wù wọ́n. Ìwọ ronú lórí bó ṣe máa rí lára ẹ tí ọ̀kan lára àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ bá tìtorí ìwà rere rẹ fìfẹ́ hàn sí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Ohun kan tún ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ: Kò sí ohun tó ń mú kíṣẹ́ gbádùn mọ́ni tó kéèyàn mọ̀ pé ìwà rere òun ń fògo fún Jèhófà ó sì ń múnú rẹ̀ dùn.—Ka Òwe 27:11; 1 Pétérù 2:12.

BÁ A ṢE LÈ FỌGBỌ́N YAN IṢẸ́ TÁ A FẸ́ ṢE

14-16. Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu nípa iṣẹ́ tá a máa ṣe, àwọn ìbéèrè pàtàkì wo la gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò?

14 Bíbélì ò ṣòfin ṣèyí-má-ṣèyẹn tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo iṣẹ́ la lè ṣe o. Ìwé Mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti yan iṣẹ́ tó ń mérè wá, tó dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, tó sì buyì kúnni, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gba àwọn iṣẹ́ tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. (Òwe 2:6) Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu nípa iṣẹ́ tá a máa ṣe, àwọn ìbéèrè méjì tó ṣe pàtàkì wà tá a gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò.

15 Ṣé iṣẹ́ tí mo fẹ́ ṣe yìí lè túmọ̀ sí ṣíṣe ohun kan tí Bíbélì sọ pé kò dáa? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé olè jíjà, irọ́ pípa àti yíyá ère kò dáa. (Ẹ́kísódù 20:4; Ìṣe 15:29; Éfésù 4:28; Ìṣípayá 21:8) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ gba iṣẹ́ tó máa mú wa hu irú àwọn ìwà yìí. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ò ní jẹ́ ká gba iṣẹ́ tí ò ní jẹ́ ká pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́.—Ka 1 Jòhánù 5:3.

16 Ṣé iṣẹ́ tí mo fẹ́ ṣe yìí ò ní sọ mí dẹni tó ń lọ́wọ́ sí ìwàkiwà  tàbí tó ń sún àwọn ẹlòmíì hùwàkiwà? Àpẹẹrẹ kan rèé. Kò kúkú sóhun tó burú téèyàn bá ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò. Àmọ́ tí Kristẹni kan bá ríṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò ní ilé ìwòsàn tí wọ́n dìídì dá sílẹ̀ láti máa ṣẹ́yún ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má máa bá wọn ṣẹ́yún ní tààràtà, síbẹ̀, ṣé iṣẹ́ tó ń ṣe ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń ṣẹ́yún yẹn ò ní fi í hàn bí ẹni tí ò róhun tó burú nínú oyún ṣíṣẹ́, ìyẹn ìwà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kò dára? (Ẹ́kísódù 21:22-24) Torí  pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ìwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu.

17. (a) Àwọn kókó wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò tá a bá fẹ́ pinnu irú iṣẹ́ tó yẹ ká ṣe? (Wo  àpótí tó wà lójú ìwé 177.) (b) Báwo ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó máa múnú Ọlọ́run dùn?

17 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè nípa irú iṣẹ́ tá a lè ṣe la máa lè dáhùn tá a bá fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì méjèèjì tá a jíròrò ní ìpínrọ̀ 15 àti 16. Yàtọ̀ sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí, àwọn kókó kan tún wà tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò tá a bá fẹ́ pinnu irú iṣẹ́ tó yẹ ká ṣe. * A ò lè retí pé kí ẹrú olóòótọ́ pèsè àwọn ìlànà tó máa bá oríṣiríṣi ipò tó lè jẹ yọ mu. Ibí gan-an la ti nílò ìfòyemọ̀. Bá a ṣe kà á ní Orí 2, a ní láti dá ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa  kíkọ́ bá a ṣe lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò nínú ohun gbogbo tá a bá ń ṣe. Tá a bá tipa báyìí kọ́ “agbára ìmòye” wa nípa “lílò,” ẹ̀rí ọkàn wa á ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tínú Ọlọ́run dùn sí, èyí á sì jẹ́ ká lè dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.—Hébérù 5:14.

BÓ O ṢE LÈ FI IṢẸ́ OÚNJẸ ÒÒJỌ́ SÍ ÀYÈ RẸ̀

18. Kí nìdí tí kò fi rọrùn láti ṣàwọn ìpinnu tó máa jẹ́ ká ṣèfẹ́ Ọlọ́run?

18 ‘Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó le koko láti bá lò’ tá a wà yìí, kò rọrùn láti máa fìgbà gbogbo ṣàwọn ìpinnu tó máa jẹ́ ká ṣèfẹ́ Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:1) Kò sì tún rọrùn rárá láti wá iṣẹ́ tó dáa ṣe kó má sì bọ́ mọ́ni lọ́wọ́. Àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé ká ṣiṣẹ́ kára ká lè gbọ́ bùkátà ìdílé. Àmọ́ tá ò bá ṣọ́ra, wàhálà ibi iṣẹ́ tàbí ẹ̀mí mo-gbọ́dọ̀-dọlọ́rọ̀ táwọn èèyàn ayé ní lè wọ̀ wá lẹ́wù tá ò fi ní rójú ráyè fáwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́. (1 Tímótì 6:9, 10) Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò bá a ṣe lè fi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ sí àyè tó yẹ kó wà ká lè ráyè gbọ́ tàwọn “ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.

19. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní kíkún, àǹfààní wo nìyẹn sì lè ṣe fún wa?

19 Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìkù síbì kan. (Ka Òwe 3:5, 6) Àbí Ọlọ́run ò tó ẹni tó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé ni? Ó ṣáà bìkítà nípa wa. (1 Pétérù 5:7) Ó mọ ohun tá a nílò ju àwa fúnra wa lọ, ọwọ́ rẹ̀ ò sì kúrú jù láti pèsè wọ́n fún wa. (Sáàmù 37:25) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká fetí sílẹ̀ nígbà tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rán wa létí pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí [Ọlọ́run] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’” (Hébérù 13:5) Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún ló lè jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run lágbára láti pèsè àwọn kòṣeémánìí ìgbésí ayé fún wa. Tá a bá nígbàgbọ́ kíkún pé Jèhófà máa pèsè ohun tá a bá nílò fún wa, a ò ní máa  ṣàníyàn ju bó ti yẹ lọ torí pé a fẹ́ gbọ́ bùkátà àwọn ará ilé wa. (Mátíù 6:25-32) A ò ní jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ gba iṣẹ́ ìsìn Jèhófà mọ́ wa lọ́wọ́, ká lè máa ráyè lọ sáwọn ìpàdé ká sì máa wàásù ìhìn rere.—Mátíù 24:14; Hébérù 10:24, 25.

20. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

 20 Ẹ jẹ́ kí ojú yín mú ọ̀nà kan. (Ka Mátíù 6:22, 23) Jíjẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan túmọ̀ sí pé ká má ṣe jura wa lọ. Àfojúsùn kan ṣoṣo làwọn Kristẹni tójú wọn bá mú ọ̀nà kan máa ń ní, ìyẹn sì ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Tójú wa bá mú ọ̀nà kan, a ò ní jẹ́ kí lílé iṣẹ́ olówó ńlá kiri gbà wá lọ́kàn, a ò sì ní máa wá ayé gbẹ̀fẹ́ kiri lójú méjèèjì. Ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká máa lépa àwọn nǹkan ìgbàlódé táwọn tó ń polówó á máa jẹ́ ká rò pé tá ò bá ní wọn, inú wa ò lè dùn. Òótọ́ ibẹ̀ sì ni pé nǹkan tuntun ò ní yéé jáde. Báwo la ṣe lè ṣe é tá ò fi ní ṣe jura wa lọ? Kò ní dáa ká máa di ẹrù gbèsè ru ara wa. Ṣọ́ra fún kíkó àwọn nǹkan tó ń náni lówó tó sì ń gbani lákòókò jọ. Fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú “ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ.” (1 Tímótì 6:8) Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti má ṣe jura ẹ lọ.

21. Kí nìdí tó fi yẹ ká lóhun tá ó máa lé, kí ló sì yẹ ká fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa?

21 Jẹ́ káwọn nǹkan tẹ̀mí jẹ ẹ́ lógún, má sì jẹ́ kí wọ́n bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Nígbà tá a ti mọ̀ pé a ò ní àkókò tó pọ̀ tó, ó yẹ ká láwọn nǹkan tá a ó máa lé. Torí tá ò bá ṣọ́ra, àwọn nǹkan tí kò pọn dandan máa gba àkókò tó yẹ ká fi ṣàwọn nǹkan pàtàkì lọ́wọ́ wa. Kí ló wá yẹ ká fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa? Lóde òní, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní ilé ìwé gíga lọ̀pọ̀ ń lépa, kí wọ́n lè rí iṣẹ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n rí towó ṣe láyé yìí. Àmọ́ Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Bó ṣe yẹ kó rí gan-an nìyẹn, Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ káwa Kristẹni fi ṣáájú nígbèésí ayé wa. Bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa, àwọn ohun tá a yàn láti ṣe, àwọn àfojúsùn wa àti àwọn ohun tá à ń lépa láyé gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run àti ṣíṣe ìfẹ́  Ọlọ́run ló jẹ wá lógún kì í ṣe àwọn nǹkan tara, lílọ síléèwé tàbí wíwáṣẹ́.

BÁ A ṢE LÈ MÁA ṢIṢẸ́ KÁRA LÓDE Ẹ̀RÍ

Tá a bá jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù jẹ wá lógún, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

22, 23. (a) Kí ni olórí iṣẹ́ àwọn Kristẹni tòótọ́, báwo la sì ṣe lè fi hàn pé iṣẹ́ yẹn ṣe pàtàkì sí wa? (Wo  àpótí tó wà lójú ìwé 180.) (b) Kí lo pinnu láti ṣe nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́?

22 Mímọ̀ tá a mọ̀ pé àkókò òpin là ń gbé jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká gbájú mọ́ olórí iṣẹ́ àwa Kristẹni, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Bíi ti Jésù, ẹni tá à ń wò fi ṣàpẹẹrẹ, iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mílà yìí làwa náà ń ṣe lójú méjèèjì báyìí. Báwo la ṣe lè fi hàn pé iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì sí wa? Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn Ọlọ́run ló ń fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe gẹ́gẹ́ bí akéde nínú ìjọ. Àwọn kan sì ti ṣètò ara wọn láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà tàbí míṣọ́nnárì. Àwọn òbí kan rí i pé níní àfojúsùn tẹ̀mí ṣe pàtàkì, torí náà wọ́n fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe àfojúsùn wọn. Ṣáwọn tó ń fìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run máa ń gbádùn iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe? Gbogbo ẹnu la fi lè sọ pé, bẹ́ẹ̀ ni! Fífi tọkàntọkàn sin Jèhófà lọ̀nà tó dájú téèyàn lè gbà rí ayọ̀, ìtẹ́lọ́rùn àti ìbùkún rẹpẹtẹ.—Ka Òwe 10:22.

23 Púpọ̀ nínú wa ló ní láti fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ká lè gbọ́ bùkátà ìdílé. Má gbàgbé pé Jèhófà fẹ́ ká gbádùn iṣẹ́ àṣekára. Tá a bá ń hùwà lọ́nà tó fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ la fi ń wò ó, tá a sì ń fàwọn ìlànà rẹ̀ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ sílò, ó dájú pé a máa nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nídìí iṣẹ́ wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ gba iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù mọ́ wa lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Tá a bá fi iṣẹ́ yìí ṣe àfojúsùn wa, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìyẹn á sì jẹ́ ká lè dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 6 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí káfíńtà ni orúkọ tí wọ́n fi máa ń pe “ẹni tó ń fi igi kọ́lé, tó ń figi kan ilé, tó ń kan àga tàbí tó ń figi ṣe àwọn ohun èlò míì.”

^ ìpínrọ̀ 17 Fún àlàyé síwájú sí i lórí irú iṣẹ́ tó yẹ ká gbà láti ṣe, wo Ilé Ìṣọ́ April 15, 1999, ojú ìwé 28 sí 30, àti January 15, 1983, ojú ìwé 22.