Olùfẹ́ Jèhófà Ọ̀wọ́n:

Jésù sọ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Wo báwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe fúnni níṣìírí tó! Ó dájú gbangba pé a lè mọ òtítọ́ láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” tí èké àti irọ́ ń gbilẹ̀ bí iná ọyẹ́ yìí. (2 Tímótì 3:1) Ṣó o rántí ìgbà tó o kọ́kọ́ mọ̀ pé inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lèèyàn ti lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? O ò rí i bí inú rẹ ṣe dùn tó nígbà náà!

Àmọ́, bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́, kéèyàn sì máa sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíì déédéé ló tún pọn dandan pé kí ìwà tiwa alára bá òtítọ́ tá a fi ń kọ́ni mu. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa á dáhùn ìbéèrè yìí. Ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin pé: “Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 15:10.

Kíyè sí i pé Jésù dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nípa pípa àwọn àṣẹ Bàbá rẹ̀ mọ́. Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn. Ká bàa lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, ó pọn dandan pé ká máa fi òtítọ́ ṣèwà hù lójoojúmọ́. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.”—Jòhánù 13:17.

Nítorí náà, ó dá wa lójú pé ìwé yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fi òtítọ́ ṣèwà hù ní ìgbésí ayé rẹ, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ dúró “nínú ìfẹ́ Ọlọ́run . . . pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.” —Júúdà 21.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà