Kíkí àsíá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé títẹrí ba fún àsíá tàbí kíkí i, èyí tó sábà máa ń jẹ́ nígbà tí orin orílẹ̀-èdè bá ń lọ lọ́wọ́, jẹ́ ìjọsìn táwọn èèyàn fi ń fògo fún Orílẹ̀-èdè àtàwọn aṣáájú gẹ́gẹ́ bi olùgbàlà, dípò Ọlọ́run. (Aísáyà 43:11; 1 Kọ́ríńtì 10:14; 1 Jòhánù 5:21) Ọ̀kan lára irú àwọn aṣáájú bẹ́ẹ̀ ni Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì ìgbàanì. Káwọn èèyàn bàa lè mọ bí ọba alágbára gíga yìí ṣe lọ́lá tó àti bó ṣe nítara fún ìjọsìn tó, ó gbé ère gàgàrà kan kalẹ̀, ó sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn olùgbé Bábílónì pé nígbà tí orin kan tá a lè fi wé orin orílẹ̀-èdè bá ń lọ lọ́wọ́, kí wọ́n tẹrí ba fún un. Àmọ́, àwọn Hébérù mẹ́ta, ìyẹn Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, kọ̀ láti tẹrí ba fún ère náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè yọrí sí ikú fún wọn.—Dáníẹ́lì, orí 3.

Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Carlton Hayes ṣe sọ nípa àkókò tá à ń gbé yìí, “àsíá ti di àmì ìgbàgbọ́ tó ṣe pàtàkì àti ohun ìjọsìn kan ṣoṣo tí gbogbo àwọn tó ní ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ń wárí fún. Àwọn ọkùnrin á ṣí fìlà wọn bí wọ́n bá ń gbé àsíá kọjá lọ; àwọn akéwì ti kọ ọ̀pọ̀ ewì láti fi júbà rẹ̀, àwọn ọmọdé sì máa ń kọrin kí i.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tún ní “àwọn ọjọ́ mímọ́” tiẹ̀, irú bí Ọjọ́ Kẹrin Oṣù July lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó tún ní àwọn “ẹni mímọ́ àtàwọn akọni” tiẹ̀; ó sì ní “àwọn tẹ́ńpìlì,” tàbí ojúbọ. Nígbà ayẹyẹ kan tó wáyé lórílẹ̀-èdè Brazil, olórí àwọn ọmọ ogun kan jẹ́wọ́ pé: “À ń tẹrí ba fún àsíá a sì ń jọ́sìn rẹ̀ . . . gẹ́gẹ́ bá a ṣe ń jọ́sìn Ilẹ̀ Baba wa.” Bó ṣe rí nìyẹn, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana tiẹ̀ sọ nígbà kan pé “bí àgbélébùú ṣe jẹ́ mímọ́ náà ni àsíá jẹ́ mímọ́.”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tá à ń sọ yìí tiẹ̀ ṣàlàyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé orin  orílẹ̀-èdè “jẹ́ ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà fi bí ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè ṣe rí lára wọn hàn, wọ́n á máa bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọ́run máa fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè àwọn tàbí àwọn tó ń ṣàkóso àwọn.” Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ò gba wèrè mẹ́sìn bí wọ́n bá ń fojú ìjọsìn wo kíkí àsíá àti kíkọ orin orílẹ̀-èdè. Kódà, nígbà tí ìwé The American Character ń ṣàlàyé lórí bí àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń lọ síléèwé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe kọ̀ láti tẹrí ba fún àsíá tàbí bí wọ́n ṣe kọ̀ láti búra pé orílẹ̀-èdè làwọn á máa gbárùkù tì, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ẹjọ́ tó ti wáyé ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti wá mú kó ṣe kedere báyìí pé ìjọsìn gbáà ni gbogbo ààtò ojoojúmọ́ tó rọ̀ mọ́ kíkí tàbí títẹrí ba fún àsíá jẹ́.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Jèhófà kì í lọ́wọ́ sáwọn ààtò ìsìn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ táwọn ẹlòmíì ní láti pinnu pé àwọn fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọn kì í tàbùkù sí àsíá tó jẹ́ àmì orílẹ̀-èdè, wọ́n sì máa ń wo ìjọba tó bá wà nípò gẹ́gẹ́ bí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” pé wọ́n jẹ́ “òjíṣẹ́ Ọlọ́run.” (Róòmù 13:1-4) Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pé ká máa gbàdúrà “nípa àwọn ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní ipò gíga.” Ohun tó sì fà á tá a fi fẹ́ máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé “kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ àti ìwà àgbà.”—1 Tímótì 2:2.

Dídìbò láti yan àwọn olóṣèlú sípò. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í sọ pé káwọn míì má dìbò. Wọn kì í fẹ̀hónú hàn nígbà ìdìbò, wọ́n sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ táwọn èèyàn bá yàn sípò. Síbẹ̀, wọn kì í lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìṣèlú orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé. (Mátíù 22:21; 1 Pétérù 3:16) Kí ni Kristẹni kan gbọ́dọ̀ ṣe láwọn ilẹ̀ tó bá ti pọn dandan pé káwọn aráàlú dìbò tàbí láwọn ibi tí wọn kì í ti í gbà lẹ́yọ fáwọn tí kò bá lọ síbi tí wọ́n gbé àpótí ìbò sí? Bí Kristẹni kan bá rántí pé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò bá wọn dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà, bóun náà bá bára ẹ̀ nírú ipò bẹ́ẹ̀, ó lè pinnu pé òun á bá wọn dé ibi tí wọ́n gbé àpótí ìbò sí, bí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá yọ̀ǹda fún un pé kó lọ. Àmọ́ ṣá o, ó gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má bàa ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé kò dáa. Ó gbọ́dọ̀ fàwọn ìlànà mẹ́fà wọ̀nyí sọ́kàn:

  1.   Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù “kì í ṣe apá kan ayé.”—Jòhánù 15:19.

  2. Kristi àti Ìjọba Ọlọ́run làwọn Kristẹni ń ṣojú fún.—Jòhánù 18:36; 2 Kọ́ríńtì 5:20.

  3. Ìmọ̀ àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ṣọ̀kan, ìfẹ́ bíi ti Kristi ló sì so àwọn tó jẹ́ ara ìjọ pọ̀.—1 Kọ́ríńtì 1:10; Kólósè 3:14.

  4. Àwọn tó bá lọ́wọ́ sí yíyan aṣojú kan sípò máa pín nínú ohun tó bá ṣe.—Ṣàkíyèsí àwọn ìlànà tó wà nínú àkọsílẹ̀ inú 1 Sámúẹ́lì 8:5, 10-18 àti 1 Tímótì 5:22.

  5. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń béèrè fún ọba tí wọ́n lè máa fojú rí, ńṣe ni Jèhófà wò ó bíi pé wọ́n ti kọ Òun sílẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 8:7.

  6. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ bí wọ́n bá ń báwọn èèyàn tí èrò wọn yàtọ̀ síra nípa ètò òṣèlú sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 24:14; 28:19, 20; Hébérù 10:35.

Sísin orílẹ̀-èdè. Láwọn ilẹ̀ kan, Ìjọba máa ń béèrè pé káwọn tí kò bá fẹ́ wọṣẹ́ ológun wá sin orílẹ̀-èdè wọn fáwọn àkókò kan. Bírú ọ̀ràn yìí bá dojú kọ wá, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà nípa rẹ̀, ó sì ṣeé ṣe ká jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀, ká wá ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti kọ́ mu.—Òwe 2:1-5; Fílípì 4:5.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé ká “jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso, láti gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo, . . . láti jẹ́ afòyebánilò.” (Títù 3:1, 2) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, a lè bí ara wa láwọn ìbéèrè wọ̀nyí: ‘Bí mo bá gbà láti ṣiṣẹ́ sin ìlú, ǹjẹ́ ìyẹn á mú kí n lọ́wọ́ sí ètò ìṣèlú àbí ó máa mú kí n lọ́wọ́ nínú ìsìn èké?’ (Míkà 4:3, 5; 2 Kọ́ríńtì 6:16, 17) ‘Ǹjẹ́ ṣíṣe irú iṣẹ́ yìí á mú kó ṣòro fún mi láti máa ṣe ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni àbí kò ní jẹ́ kí n lè ṣe ojúṣe náà mọ́?’ (Mátíù 28:19, 20; Éfésù 6:4; Hébérù 10:24, 25) ‘Àti pé, bí mo bá gbà láti sin orílẹ̀-èdè mi, ǹjẹ́ iṣẹ́ tí wọ́n á fún mi ṣe á fàyè sílẹ̀ fún mi láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi máa tẹ̀ síwájú, bóyá kí n máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún?’—Hébérù 6:11, 12.

Lẹ́yìn tí Kristẹni kan bá ti ṣe àwọn àgbéyẹ̀wò yìí, bó bá wá  pinnu tọkàntọkàn pé òun á sin orílẹ̀-èdè tàbí ìlú òun dípò kí wọ́n rán òun lọ sẹ́wọ̀n, àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tó ṣe. (Róòmù 14:10) Àmọ́ ṣá o, bó bá sọ pé kò wu òun láti sin orílẹ̀-èdè tàbí ìlú òun, a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tirẹ̀ pẹ̀lú.—1 Kọ́ríńtì 10:29; 2 Kọ́ríńtì 1:24.