Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’

 ORÍ 4

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ?

“Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.”—1 PÉTÉRÙ 2:17.

1, 2. (a) Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ? (b) Àwọn ìbéèrè wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?

ǸJẸ́ o ti ṣàkíyèsí ohun tí ọmọ kékeré kan ṣe nígbà táwọn òbí ẹ̀ ní kó ṣe ohun kan tí kò wù ú? Ó ṣeé ṣe kó o rí i pé ńṣe lọmọ náà rúnjú pọ̀. Ó gbọ́ ohùn bàbá rẹ̀, ó sì mọ̀ pé ó yẹ kóun pa àṣẹ bàbá òun mọ́. Àmọ́, pẹ̀lú bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ yìí, kò kàn ṣáà fẹ́ ṣe nǹkan yẹn ni. Ká sòótọ́, báwa náà ṣe máa ń ṣe nígbà míì nìyẹn.

2 Kì í fi gbogbo ìgbà rọrùn láti bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ. Ṣáwọn ìgbà kan wà tó máa ń ṣòro fún ẹ láti bọ̀wọ̀ fáwọn tó láṣẹ lórí ẹ dé ìwọ̀n àyè kan? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kì í ṣèwọ nìkan lọ̀ràn náà kàn. Àkókò tí bíbọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dàwátì là ń gbé. Síbẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fáwọn tó láṣẹ lé wa lórí. (Òwe 24:21) Ká sòótọ́, a ò lè sọ pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá ò bá bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Ó di dandan ká bi ara wa léèrè pé: Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ? Kí nìdí tí Jèhófà fi ní ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí Jèhófà? Paríparì ẹ̀ ni pé, àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?

ÌDÍ TÓ FI ṢÒROÓ ṢE

3, 4. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ṣe bẹ̀rẹ̀, kí sì nìdí tí àìpé fi máa ń mú kó ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?

3 Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì tó fi lè ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn  tó wà nípò àṣẹ. Àkọ́kọ́ ni pé, àìpé ẹ̀dá ń dà wá láàmú, èkejì sì ni pé àìpé kan náà ò yé da àwọn tó wà nípò àṣẹ láàmú. Ọjọ́ ti pẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti bẹ̀rẹ̀, ìyẹn nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Ọlọ́run lọ́gbà Édẹ́nì. Èyí fi hàn pé ọ̀tẹ̀ ló bí ẹ̀ṣẹ̀. Látìgbà yẹn títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ìfẹ́ láti ṣòtẹ̀ máa ń wà lọ́kàn wa ṣáá.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; 3:1-7; Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12.

4 Nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ìgbéraga àti ẹmi àwa la wà ńbẹ̀, máa ń tètè wọ̀ wá lẹ́wù, àmọ́ tó bá di pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ekukáká la fi ń ṣèyẹn, àfi ká ṣiṣẹ́ kára ká sì gbìyànjú láti ní in. Tá a bá tiẹ̀ ti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láti àwọn ọdún yìí wá pàápàá, tá ò bá sọ́ra, ó ṣeé ṣe ká di alágídí ká sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Fi àpẹẹrẹ ti Kórà ṣe àríkọ́gbọ́n; ó fòótọ́ inu dúró ti àwọn èèyàn Jèhófà nígbà ìṣòro. Síbẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ipò ńlá fún ara rẹ̀, àìnítìjú ẹ̀ sì sún un láti ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè ẹni tó jẹ́ ọlọ́kàn-tútù jù lọ nígbà ayé ẹ̀. (Númérì 12:3; 16:1-3) Tún ronú lórí ohun tí Ùsáyà Ọba ṣe, ìgbéraga ló jẹ́ kó wọ tẹ́ńpìlì lọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó jẹ́ ojúṣe àwọn àlùfáà. (2 Kíróníkà 26:16-21) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí jẹ palaba ìyà nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù. Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ àti ìránnilétí ni ìwàkiwà tí wọ́n hù jẹ́ fún gbogbo wa. A ní láti borí ìgbéraga tó ń jẹ́ kó ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ.

5. Báwo làwọn ẹ̀dá aláìpé ṣe ṣi ipò wọn lò?

5 Yàtọ̀ síyẹn, ìwà táwọn ẹ̀dá aláìpé tó wà ní ipò àṣẹ máa ń hù tún ń jẹ́ kó ṣòro fáwọn èèyàn láti bọ̀wọ̀ fún wọn. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló rorò bí ataare, wọ́n ṣàìdáa sáwọn èèyàn, wọn ò sì gba tẹlòmíì rò rárá. Àní, ìtàn ti fi hàn pé ọ̀pọ̀ ló ti lo agbára wọn nílòkulò. (Ka Oníwàásù 8:9) Bí àpẹẹrẹ, ẹni rere ni Sọ́ọ̀lù, onírẹ̀lẹ̀ èèyàn sì ni nígbà tí Jèhófà fi í jọba. Àmọ́, ó jẹ́ kí owú àti ìgbéraga wọ òun lẹ́wù; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fòòró Dáfídì, ọkùnrin olóòótọ́ yẹn. (1 Sámúẹ́lì 9:20, 21; 10:20-22; 18:7-11) Láìpẹ́ sígbà yẹn ni Dáfídì jọba, ó sì wá wà lára àwọn ọba tó ṣe dáadáa jù ní Ísírẹ́lì, àmọ́  òun náà ṣi agbára rẹ̀ lò. Ó fèrú gba ìyàwó Ùráyà ará Hítì, ó sì ní kí wọ́n fi ọkùnrin aláìmọwọ́ mẹsẹ̀ yìí síbi tí ogun tí gbóná janjan kó lè kú sójú ogun. (2 Sámúẹ́lì 11:1-17) Bó ṣe máa ń rí nìyẹn, àìpé ẹ̀dá ni kì í jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́ bí wọ́n bá wà nípò. Táwọn tó wà nípò ò bá tún lọ bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, ṣe ni nǹkan máa bà jẹ́ ráúráú. Nígbà tí àgbà òṣèlú kan nílùú Britain ń ṣàlàyé báwọn póòpù Kátólíìkì ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn nílé lóko, ó ní: “Ńṣe nipò máa ń gunni, bá a bá sì gbé èèyàn sípò, gàràgàrà nipò á máa gùn-ún.” Pẹ̀lú òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí lọ́kàn wa, ẹ jẹ́ ká wá ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ALÁṢẸ?

6, 7. (a) Kí ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ń sún wa láti ṣe, kí sì nìdí tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti máa tẹrí ba, báwo la sì ṣe lè fi hàn pé à ń ṣe bẹ́ẹ̀?

6 Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, tá a ní sáwọn ọmọnìkejì wa àtèyí tá a ní sára wa ni olórí ìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a fẹ́ múnú Jèhófà dùn torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ka Òwe 27:11; Máàkù 12:29, 30) A mọ̀ dájú pé látìgbà tí Sátánì ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà lọ́gbà Édẹ́nì, tí ọ̀pọ̀ tó ń tẹ̀ lé e sì ti pa ìṣàkóso Jèhófà tì, ni ìbéèrè ti wà nípa bóyá Jèhófà gan-an laláṣẹ àgbáyé àti pé bóyá ó tiẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé. Àmọ́, a láyọ̀ láti kọ́wọ́ ti ipò tí Jèhófà wà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Tọkàntọkàn la fi máa fẹ́ ṣe ti Jèhófà tá a bá ka àwọn ọ̀rọ̀ tó fakíki tó wà nínú Ìṣípayá 4:11. Ó dá wa lójú gbangba gbàǹgbà pé Jèhófà gan-an ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Olùṣàkóso àgbáyé! À ń fi hàn nínú ìwà wa ojoojúmọ́ pé a fọwọ́ sí ìṣàkoso Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ.

7 Ọ̀wọ̀ tá a ní fún Ọlọ́run yìí yẹ kó sún wa láti ṣègbọràn sí i, ká sì tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló jẹ́ kó máa yá wa lára láti gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Síbẹ̀, àwọn ìgbà kan máa ń wà tó máa ń ṣòro fún wa láti ṣègbọràn. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, bíi ti ọmọ kékeré tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan, àwa náà ní láti kọ́  bá a ṣe lè máa tẹrí ba. Ẹ jẹ́ ká rántí pé Jésù pàápàá ṣe ìfẹ́ inú Baba rẹ̀ nígbà tí kò rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ fún Baba rẹ̀ pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.”—Lúùkù 22:42.

8. (a) Kí ni títẹríba fún àṣẹ Jèhófà sábà máa ń túmọ̀ sí lóde òní, kí ló sì jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wò ó? (b) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti fetí sí ìmọ̀ràn ká sì gba ìbáwí? (Wo “ Fetí Sí Ìmọ̀ràn Kí O Sì Gba Ìbáwí.”)

8 Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lónìí; Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn èèyàn tó ń ṣojú fún un lórí ilẹ̀ ayé ló ń lò láti bá wa sọ̀rọ̀. Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, tá a bá ti ń bọ̀wọ̀ fáwọn tí Jèhófà yàn sípò tàbí àwọn tó fàyè gbà láti máa ṣàkóso wa, à ń fi hàn pé à ń tẹrí ba fún àṣẹ Jèhófà nìyẹn. Tá a bá lọ ṣọ̀tẹ̀ sáwọn èèyàn tó ń ṣojú fún Jèhófà pẹ́nrẹ́n, bóyá tá a kọ̀ láti gba ìmọ̀ràn àti ìbáwí tí wọ́n fún wa láti inú Ìwé Mímọ́, inú Ọlọ́run ò ní dùn sí wa o. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kùn sí Mósè tí wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i, Jèhófa sọ pé òun gan-an ni wọ́n kùn sí, òun sì ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí.—Númérì 14:26, 27.

9. Kí nìdí tí ìfẹ́ tá a ní sáwọn ọmọnìkejì wa fi máa sún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà ní ipò àṣẹ? Ṣàkàwé.

9 Ohun tó tún ń jẹ́ ká bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ni ìfẹ́ tá a ní sí ọmọnìkejì wa. Lọ́nà wo? Ó dáa ná, ká sọ pé o jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan. Kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó o wà tó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ogun, o gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn sójà tó kù, o gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sáwọn òfin ọmọ ẹgbẹ́, o sì gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fáwọn ọ̀gá ẹ. Tó o bá lọ fojú pa àwọn ètò tó ti wà nílẹ̀ rẹ́ tó o sì ṣọ̀tẹ̀ sẹ́gbẹ́, àfàìmọ̀ kó o má kó àwọn sójà tó kù sínú ewu. Òótọ́ ni pé jàǹbá táwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ayé yìí ti fà kò kéré rárá. Àmọ́, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà kì í yé rere ṣe. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà ni Bíbélì pé Ọlọ́run ní “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” (1 Sámúẹ́lì 1:3) Òun ni Olórí ẹgbàágbèje àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára. Nígbà míì, Jèhófà máa ń pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun. (Sáàmù 68:11; Ìsíkíẹ́lì 37:1-10) Tá a bá lọ ń ṣọ̀tẹ̀ sáwọn èèyàn tí Jèhófà fi ṣe olórí wa, ṣe kì í ṣe pé ńṣe la fẹ́  kó àwọn tá a jọ jẹ́ ọmọ ogun Jèhófà sínú ewu báyìí? Tí Kristẹni kan bá ṣọ̀tẹ̀ sáwọn alàgbà, ó lè fi tiẹ̀ kó bá àwọn tó kù nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 12:14, 25, 26) Bẹ́ẹ̀ náà ni tí ọmọ kan bá ṣọ̀tẹ̀ nínú ìdílé, ó lè fi tiẹ̀ kó bá agbo ìdílé lápapọ̀. Nítorí náà ìfẹ́ tá a ní sáwọn ọmọnìkejì wa láá jẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ká sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.

10, 11. Báwo ni fífẹ́ láti jàǹfààní tó tọ́ sí wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ?

10 A tún máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ torí a mọ̀ pé tiwa náà ni wọ́n ń ṣe. Gbogbo ìgbà tí Jèhófà bá ní ká bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ló máa ń sọ àǹfààní tó máa tìdí ẹ̀ yọ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ní káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu kí wọ́n lè pẹ́ láyé, káyé wọ́n sì lè dùn bí oyin. (Diutarónómì 5:16; Éfésù 6:2, 3) Ó ní ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà ìjọ torí tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. (Hébérù 13:7, 17) Ó tún ní ká máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ ìlú nítorí ààbò wa.—Róòmù 13:4.

 11 Ó dájú pé bá a ṣe mọ ìdí tí Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa ṣègbọràn á ràn wá lọ́wọ́ láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Ẹ jẹ́ ká wá gbé bá a ṣe lè bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ láwọn ọ̀nà pàtàkì mẹ́ta yẹ̀ wò.

BÁ A ṢE LÈ FỌ̀WỌ̀ HÀN NÍNÚ ÌDÍLÉ

12. Ojúṣe wo ni Jèhófà fún ọkọ àtàwọn bàbá nínú ìdílé, báwo sì ni ọkùnrin kan ṣe lè ṣe ojúṣe yẹn?

12 Jèhófà fúnra rẹ̀ ló dá ètò ìdílé sílẹ̀. Ó sì ṣètò rẹ̀ lọ́nà tó fi máa ṣàṣeyọrí, nítorí pé ó jẹ́ Ọlọ́run ètò. (1 Kọ́ríńtì 14:33) Ó gbé àṣẹ lé àwọn ọkọ àtàwọn bàbá lọ́wọ́ láti máa wakọ̀ ìdílé. Ọkọ gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún Kristi Jésù tó jẹ́ Olórí rẹ̀ nípa títẹ̀lé ọ̀nà tí Jésù gbà lo ipò orí rẹ̀ lórí ìjọ. (Éfésù 5:23) Èyí fi hàn pé ọkọ gbọ́dọ̀ mọsẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, ó sì gbọ́dọ̀ ṣe é bó ṣe yẹ; èyí ò wá sọ ọkọ di apàṣẹwàá tàbí òǹrorò ẹ̀dá, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ń sọ ọ́ di ẹni tó ń fìfẹ́ báni lò, tó ń fọgbọ́n hùwà, tó sì ń gba tàwọn ẹlòmíì rò. Ọkọ gbọ́dọ̀ máa rántí pé ipò orí òun kì í ṣe ti ọ̀gá pátápátá, àmọ́ pé abẹ́ àṣẹ Jèhófà lòún wà.

Bàbá tó jẹ́ Kristẹni máa ń fara wé bí Kristi ṣe lo ipò orí rẹ̀

13. Báwo ni ìyá tàbí aya ṣe lè ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé lọ́nà tó máa múnú Jèhófà dùn?

13 Olùrànlọ́wọ́ ni ìyá tàbí aya jẹ́ lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ ẹ̀. Òun náà ní àṣẹ tiẹ̀ nínú ilé torí Bíbélì sọ nípa “òfin ìyá.” (Òwe 1:8) Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àṣẹ tiẹ̀ wulẹ̀ ń kín ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ni. Aya tó jẹ́ Kristẹni  ní láti máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ nípa ríràn án lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé. Kò gbọ́dọ̀ máa fojú tẹ́ńbẹ́lú ọkọ ẹ̀, kò gbọ́dọ̀ máa fọgbọ́n àyínìke gba tọwọ́ ọkọ ẹ̀ tàbí kó wá gba ipò orí mọ́ ọkọ lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kó máa gbárùkù tì í, kó sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀. Nígbà tí ìpinnu ọkọ rẹ̀ ò bá tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó lè fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé èrò tiẹ̀, síbẹ̀ ó gbọ́dọ̀ máa tẹrí ba fún un. Tí ọkọ rẹ̀ ò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti máa bọ̀wọ̀ fún un, síbẹ̀ bí aya yìí bá ń tẹrí ba fọ́kọ ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ìwà rẹ̀ sún un láti fẹ́ mọ Jèhófà.—Ka 1 Pétérù 3:1.

14. Báwo làwọn ọmọ ṣe lè múnú Jèhófà àtàwọn òbí wọn dùn?

14 Táwọn ọmọ bá ń gbọ́ràn sí bàbá wọn lẹ́nu tí wọn ò sì ṣá àṣẹ màmá wọn tì, wọ́n á máa múnú Jèhófà dùn. Wọ́n á mú ìyìn wá bá àwọn òbí wọn, inú bàbá àti màmá wọn á sì máa dùn. (Òwe 10:1) Láwọn ìdílé tí òbí kan ti ń dá àwọn ọmọ tọ́, àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí òbí wọn lẹ́nu nítorí àsìkò yìí gan-an ló nílò ìtìlẹ́yìn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn. Àwọn ìdílé tí bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ bá ti ń ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run  fún wọn, máa ń láyọ̀, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀. Èyí sì máa ń buyì kún Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó dá ìdílé sílẹ̀.—Éfésù 3:14, 15.

BÁ A ṢE LÈ FỌ̀WỌ̀ HÀN NÍNÚ ÌJỌ

15. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn nínú ìjọ pé à ń bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Jèhófà? (b) Àwọn ìlànà wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sáwọn tó ń múpò iwájú? (Wo “ Ẹ Jẹ́ Onígbọràn Sí Àwọn Tí Ń Mú Ipò Iwájú.”)

15 Jèhófà ti yan Ọmọ rẹ̀ ṣorí ìjọ Kristẹni. (Kólósè 1:13) Jésù náà ti wá yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa bójú tó ohun táwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé nílò tó bá dọ̀ràn ìjọsìn. (Mátíù 24:45-47) Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣojú fún ẹrú yìí. Bíi tàwọn ìjọ tó wà nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, lónìí àwọn alàgbà máa ń gba ìtọ́ni àti ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní tààràtà tàbí látọwọ́ àwọn aṣojú wọn, irú bí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. Tí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá ń gbọ́ tàwọn alàgbà, Jèhófà là ń ṣègbọràn sí.—Ka 1 Tẹsalóníkà 5:12; Hébérù 13:17.

16. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń yan àwọn alàgbà sípò?

16 Àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kì í ṣe ẹni pípé. Aláìpé ni gbogbo wa. Síbẹ̀ “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” làwọn alàgbà jẹ́. Jèhófà ló fún wa láwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí, kí wọ́n lè ran ìjọ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. (Éfésù 4:8) Ẹ̀mí mímọ́ ló ń yan àwọn alàgbà sípò. (Ìṣe 20:28) Lọ́nà wo? Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọlọ́run ń béèrè nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí. (1 Tímótì 3:1-7, 12; Títù 1:5-9) Kódà àwọn alàgbà tó gbé arákùnrin kan yẹ̀ wò bóyá ó kúnjú ìwọ̀n máa ń gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà.

17. Kí nìdí táwọn Kristẹni obìnrin fi máa ń bo orí wọn nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ojúṣe kan nínú ìjọ?

17 Àwọn ìgbà kan máa ń wà tí kì í sáwọn alàgbà tàbí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ láti bójú tó àwọn ojúṣe tó yẹ kí wọ́n bójú tó, irú bíi dídarí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá.  Láwọn àkókò wọ̀nyí, àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi lè bójú tó àwọn ojúṣe wọ̀nyẹn. Tí ò bá wá sàwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi níbẹ̀, àwọn arábìnrin tó tóótun lè bójú tó àwọn ojúṣe wọ̀nyẹn. Àmọ́, nígbà tí obìnrin bá ń bójú tó ojúṣe tó yẹ kí arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi bójú tó, ó gbọ́dọ̀ bo orí rẹ̀. * (1 Kọ́ríńtì 11:3-10) Èyí ò wá túmọ̀ sí pé a tẹ àwọn obìnrin mẹ́rẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún wọn láǹfààní láti bọ̀wọ̀ fún ètò ipò orí tí Jèhófà gbé kalẹ̀ nínú ìdílé àti nínú ìjọ pẹ̀lú.

BÁ A ṢE LÈ BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ALÁṢẸ ÌLÚ

18, 19. (a) Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé àwọn ìlànà tó wà nínú Róòmù 13:1-7? (b) Báwo la ṣe ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ìlú?

18 Tọkàntọkàn làwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Róòmù 13:1-7. (Ka.) Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, wàá rí i pé àwọn ìjọba ìlú ni “àwọn aláṣẹ onípò gíga” tó wà nínú rẹ̀ túmọ̀ sí. Bí Jèhófà bá ṣì fàyè gba àwọn èèyàn wọ̀nyí láti máa ṣàkóso, wọ́n á ṣì máa ṣàwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó, wọ́n á máa rí sí i pé àwọn nǹkan wà létòletò, wọ́n á sì máa pèsè àwọn nǹkan tá a nílò dé ìwọ̀n tí agbára wọ́n mọ. À ń fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ìlú tá a bá ń pa àwọn òfin ìlú mọ́. Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé à ń san owó orí èyíkéyìí tá a bá jẹ wọ́n, ká kọ àwọn ìsọfúnni tó bá yẹ sínú àwọn ìwé tí ìjọba bá ní ká fọwọ́ sí, ká sì máa pa àwọn òfin tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ mọ́, pàápàá èyí tó bá kan ìdílé, iṣẹ́ tàbí àwọn ohun ìní wa. Àmọ́ ṣá o, táwọn aláṣẹ ìlú bá ní ká fi ti Ọlọ́run sílẹ̀ ká wá gbọ́ tàwọn, a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi tàwọn àpọ́sítélì ìgbaanì la ṣe máa dáhùn, wọ́n ní: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:28, 29; wo àpótí náà “ Àṣẹ Ta Ló Yẹ Kí N Tẹ̀ Lé?

19 A tún máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ìlú nípa bá a ṣe  ń hùwà sáwọn èèyàn. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé àwọn aṣojú ìjọba gan-an la fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá àwọn aṣojú ìjọba kan sọ̀rọ̀ nígbà ayé ẹ̀, àwọn bíi Hẹ́ródù Àgírípà Ọba àti Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kì í ṣe ọmọlúwàbí èèyàn rárá, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù fi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n. (Ìṣe 26:2, 25) Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ló yẹ ká máa tẹ̀ lé tá a bá ń bá àwọn èèkàn lára àwọn aṣojú ìjọba sọ̀rọ̀ títí kan àwọn ọlọ́pàá. Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ pàápàá gbọ́dọ̀ máa fi irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn sáwọn olùkọ́ wọn, àwọn ọ̀gá ilé ìwé àtàwọn òṣìṣẹ́ míì níléèwé wọn. Òótọ́ ni pé kì í ṣàwọn tó gba tiwa nìkan là ń bọ̀wọ̀ fún; a tún máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó tiẹ̀ ń ṣàìdáa sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàápàá. Ó yẹ kí gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ máa rí i nínú ìwà wa pé a ka àwọn èèyàn sí.—Ka Róòmù 12:17, 18; 1 Pétérù 3:15.

20, 21. Àǹfààní wo la máa rí gbà tá a bá ń fi tọkàntọkàn bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?

20 Ẹ jẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.” (1 Pétérù 2:17) Inú àwọn èèyàn á máa dùn sí wa tí wọ́n bá mọ̀ pé à ń bọ̀wọ̀ fún wọn látọkàn wá. Má gbàgbé pé ànímọ́ yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dàwátì. Nítorí náà, tá a bá fi ànímọ́ yìí wọ ara wa láṣọ, a jẹ́ pé ńṣe là ń ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa; ó ní ká jẹ́ “kí ìmọ́lẹ̀ [wa] máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà [wa], kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba [wa] tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 5:16.

21 Nínú ayé oníwà wíwọ́ yìí, àwọn tó lọ́kàn rere ń wá síbi tí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí wà. Nítorí náà, fífi ọ̀wọ̀ hàn nínú ìdílé, nínú ìjọ, láàárín àwọn ẹlẹgbẹ́ wa níléèwé àti níbi iṣẹ́ àti fífi hàn sáwọn aláṣẹ ìlú lè sún wọn láti wá bá wa rìn nínú ìmọ́lẹ̀. Èyí á mà dáa gan-an o! Tí nǹkan ò bá tiẹ̀ wá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan dájú. Bá a ṣe ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ń dùn mọ́ Jèhófà Ọlọ́run nínú, ó sì ń jẹ́ ká dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá gbáà lèyí!

^ ìpínrọ̀ 17 Àfikún tó wà “Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí Obìnrin Máa Borí, Kí sì Nìdí?” ṣàlàyé àwọn ọ̀nà mélòó kan tá a lè gbà fi ìlànà yìí sílò.