Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 11

“Ẹ Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Ní Ọlá”

“Ẹ Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Ní Ọlá”

“Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ.”—ÒWE 5:18.

1, 2. Ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò, kí sì nìdí tá a fi máa gbé e yẹ̀ wò?

ṢÓ O ti ṣègbéyàwó? Bó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni, ṣé ìgbéyàwó rẹ máa ń fún ẹ láyọ̀, àbí ńṣe lò ń fojú winá ìṣòro tó lékenkà? Ṣé àárín ẹ̀yin méjèèjì ṣì gún? Àbí, ńṣe lẹ kàn ń yí gbogbo ẹ̀ mọ́ra wọn torí pé nǹkan ò jọra? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o máa banú jẹ́ pé ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní síra yín tẹ́lẹ̀ ti di tútù. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ó dájú pé wàá fẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ mú ìyìn wá bá Jèhófà, Ọlọ́run tó o fẹ́ràn. Nítorí náà, bọ́rọ̀ ẹ ṣe rí yìí lè mú kí ominú máa kọ ẹ́, kí ẹ̀dùn ọkàn sì máa bá ẹ. Síbẹ̀ náà, má ṣe rò pé kò sọ́nà àbáyọ.

2 Ní báyìí, à ń rí àwọn tọkọtaya Kristẹni tí wọ́n ti ń ṣe dáadáa, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àjọṣe wọn ò dán mọ́rán tẹ́lẹ̀. Síbẹ̀ wọ́n wá bí wọ́n ṣe máa fún àjọṣe wọn lókun. Ó ṣeé ṣe kí ìgbéyàwó tìẹ náà túbọ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn. Lọ́nà wo?

BÓ O ṢE LÈ TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN ÀTI ẸNÌ KEJÌ RẸ

3, 4. Kí nìdí tí àjọṣe tọkọtaya á fi dán mọ́rán sí i bí wọ́n bá ń sapá láti sún mọ́ Ọlọ́run? Ṣàkàwé.

3 Àjọṣe ìwọ àti ẹnì kejì rẹ á túbọ̀ dán mọ́rán tẹ́ ẹ bá sapá láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Kí nìdí? Wo àpèjúwe yìí ná: Fojú inú yàwòrán àpáta ńlá kan tó rí ṣóńṣó lókè, tó sì fẹ̀ ràbàtà nísàlẹ̀. Ọkùnrin kan dúró sí apá ọ̀tún àpáta náà, obìnrin kan sì dúró sí òdì kejì rẹ̀. Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í gun àpáta náà. Àmọ́, nítorí pé àpáta náà fẹ̀ nísàlẹ̀, àwọn méjèèjì ò rí ara wọn. Ṣùgbọ́n, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bí wọ́n  ṣe ń sún mọ́ ibi ṣóńṣó àpáta náà lápá òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ra, kò sì pẹ́ tí ọwọ́ fi kan ọwọ́. Ǹjẹ́ o rí ẹ̀kọ́ tó fini lọ́kàn balẹ̀ tí àpèjúwe yìí fi kọ́ni?

4 A lè fi àwọn ìsapá rẹ láti máa sin Jèhófà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ wé béèyàn ṣe máa ń sapá bó bá fẹ́ gun àpáta. Níwọ̀n bó o ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a lè sọ pé o ti ń sapá gidigidi láti gun àpáta. Àmọ́, bí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ò bá ní àjọṣe tó dán mọ́rán, ó lè jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kálukú yín ti ń pọ́n àpáta náà. Bóyá ẹnì kan lápá ọ̀tún, ẹnì kejì ní òdì kejì. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀, bẹ́ ẹ bá ń pọ́n àpáta náà nìṣó? Òótọ́ ni pé, àlàfo tó pọ̀ gan-an lè kọ́kọ́ wà láàárín yín níbẹ̀rẹ̀. Àmọ́, bẹ́ ẹ bá ṣe ń sapá láti túbọ̀ máa sún mọ́ Ọlọ́run, ìyẹn ni pé tẹ́ ẹ̀ ń gun àpáta náà nìṣó, bẹ́ẹ̀ ni àjọṣe yín á túbọ̀ máa  dán mọ́rán sí i. Ká sòótọ́, sísúnmọ́ Ọlọ́run ló máa jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. Àmọ́, báwo gan-an lẹ ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?

Bí tọkọtaya bá fi ìmọ̀ Bíbélì sílò, àjọṣe wọn á túbọ̀ dán mọ́rán

5. (a) Ọ̀nà wo lèèyàn lè gbà sún mọ́ Jèhófà àti ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó?

5 Ọ̀nà pàtàkì kan tẹ́ ẹ fi lè dà bí ẹni tó ń pọn àpáta ni pé kẹ́ ẹ máa fetí sáwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó. (Sáàmù 25:4; Aísáyà 48:17, 18) Nítorí náà, ṣàyẹ̀wò ìmọ̀ràn àtàtà kan ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu bà. Ó ní: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn.” (Hébérù 13:4) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? A sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “ọlá” fún ohun pàtàkì àti ohun tó ṣeyebíye. Irú ojú tí Jèhófà sì fi ń wo ìgbéyàwó gan-an nìyẹn, ó kà á sí ohun pàtàkì tó ṣeyebíye.

ÌFẸ́ ÀTỌKÀNWÁ FÚN JÈHÓFÀ LÓ YẸ KÓ MÁA SÚN Ẹ ṢE NǸKAN

6. Kí la lè kíyè sí látinú ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà gbé ìmọ̀ràn rẹ̀ nípa ìgbéyàwó kalẹ̀, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fi èyí sọ́kàn?

6 Òótọ́ ni pé, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ti mọ̀ pé ìgbéyàwó ṣeyebíye ó sì jẹ́ mímọ́. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. (Ka Mátíù 19:4-6) Àmọ́ sá o, bó o bá ń fojú winá ìṣòro nínú ìgbéyàwó rẹ báyìí, wíwulẹ̀ mọ̀ pé ìgbéyàwó jẹ́ ohun tó lọ́lá lè máà tó láti sún ìwọ àti ẹnì kejì rẹ láti nífẹ̀ẹ́ ara yín, kẹ́ ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fúnra yín. Kí ló máa wá sún yín láti máa ṣe bẹ́ẹ̀? Fara balẹ̀ kíyè sí bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ̀rọ̀ nípa bíbọlá fúnni. Kò sọ pé, “ìgbéyàwó ọlá”; kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní, “ẹ jẹ́ kí ìgbéyàwó ọlá.” Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó rí, àmọ́ ńṣe ló ń gba àwọn èèyàn níyànjú. * Tó o bá ń fi í sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ ìyànjú lọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí, ìyẹn á túbọ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti padà máa fi ojú iyì wo ẹnì kejì rẹ. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

7. (a) Àwọn àṣẹ inú Ìwé Mímọ́ wo là ń pa mọ́, kí sì nìdí? (b) Àǹfààní wo ló wà nínú ṣíṣègbọràn?

 7 Ronú díẹ̀ ná lórí ojú tó o fi ń wo àwọn àṣẹ míì tó wà nínú Ìwé Mímọ́, irú bí àṣẹ tó ní ká máa sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn tàbí ìṣílétí tó ní ká máa pé jọ pọ̀ déédéé fún ìjọsìn. (Mátíù 28:19; Hébérù 10:24, 25) Ká sòótọ́, ó lè má rọrùn láti pa àwọn àṣẹ wọ̀nyí mọ́. Àwọn tó ò ń wàásù fún lè máa fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́, tàbí kó jẹ́ pé pípésẹ̀ sáwọn ìpàdé kò fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ ẹ́ lọ́run torí pé ọ̀ràn àtijẹ àtimu á ti jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu. Láìka gbogbo èyí sí, ò ń bá a nìṣó láti máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run, o kì í sì í pa ìpàdé jẹ. Kò sẹ́ni tó lè ní kó o má ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, kódà Sátánì pàápàá ò tó bẹ́ẹ̀! Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ àtọkànwá tó o ní fún Jèhófà ló ń mú kó o máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (1 Jòhánù 5:3) Àwọn nǹkan rere wo nìyẹn sì ti yọrí sí? Jíjáde òde ẹ̀rí àti lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ máa ń jẹ́ kó o ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ayọ̀ àtọkànwá torí o mọ̀ pé ìfẹ́ Ọlọ́run lò ń ṣe. Èyí á sì wá tipa bẹ́ẹ̀ sọ agbára rẹ dọ̀tun. (Nehemáyà 8:10) Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ wa?

8, 9. (a) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tó ní ká jẹ́ kí ìgbéyàwó wa ní ọlá, kí sì nìdí? (b) Kókó méjì wo la máa jíròrò báyìí?

8 Bó ṣe jẹ́ pé ìfẹ́ àtọkànwá tó o ní fún Ọlọ́run ló ń mú kó o máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ tó ní ká máa wàásù ká sì máa pàdé pọ̀ mọ́ láìka àwọn ìpèníjà tó ń bá a rìn sí, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á ṣe mú kó o fi ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ sílò pé “kí ìgbéyàwó [rẹ] ní ọlá,” kódà nígbà tó bá dà bíi pé nǹkan ò rọgbọ pàápàá. (Hébérù 13:4; Sáàmù 18:29; Oníwàásù 5:4) Síwájú sí i, bí ipá tó ò ń sà láti máa wàásù kó o sì máa lọ sípàdé ìjọ ṣe ń mú kó o rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa kíyè sí àwọn ohun tó o bá ń ṣe láti mú kí ìgbéyàwó rẹ ní ọlá, yóò sì san ẹ́ lẹ́san rere.—1 Tẹsalóníkà 1:3; Hébérù 6:10.

 9 Nígbà náà, báwo lo ṣe lè mú kí ìgbéyàwó rẹ ní ọlá? O ò gbọ́dọ̀ máa hùwà tó lè kó bá ìgbéyàwó rẹ. Láfikún sí èyí, o gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kí àdéhùn ìgbéyàwó yín yẹ̀.

MÁ ṢE HÙWÀ, MÁ SÌ ṢE SỌ̀RỌ̀ TÓ Ń TÀBÙKÙ SÍ ÌGBÉYÀWÓ

10, 11. (a) Ìwà wo ló máa ń tàbùkù sí ìgbéyàwó? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó?

10 Kristẹni kan tó jẹ́ aya sọ nígbà kan pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi lókun kí n lè fara dà á.” Fara da kí ni? Ó ṣàlàyé pé: “Ńṣe lọkọ mi máa ń nà mí lẹ́gba ọ̀rọ̀. Ó lè máà sí ọgbẹ́ tó ṣe é fojú rí lára mi, àmọ́ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tó máa ń sọ ti dọ́gbẹ́ sí mi lọ́kàn. Ó máa ń sọ pé, ‘Ìnira lo jẹ́ fún mi!’ àti pé ‘O ò tiẹ̀ já mọ́ nǹkan kan!’” Ọ̀rọ̀ ńlá tó ń fẹ́ àbójútó lobìnrin yìí sọ yìí o, ìyẹn bíbú ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó.

11 Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tó ń bani nínú jẹ́ gbáà ni pé káwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni máa rọ̀jò èébú léra wọn lórí, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ dá ọgbẹ́ tí kì í jinná bọ̀rọ̀ síra wọn lọ́kàn! Láìsí àníàní, ìgbéyàwó tí tọkọtaya bá ti ń sọ̀rọ̀ líle síra wọn kì í ṣe ìgbéyàwó tó ní ọlá. Báwo ni ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ti ń ṣe sí lórí ọ̀rọ̀ yìí? Bó o ṣe lè mọ̀ ni pé kó o fìrẹ̀lẹ̀ bi ẹnì kejì rẹ pé, “Báwo làwọn ọ̀rọ̀ mi ṣe máa ń rí lára ẹ ná?” Bí ẹnì kejì rẹ bá nímọ̀lára pé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sábà máa ń fa ọgbẹ́ ọkàn fóun, o gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣàtúnṣe.— Gálátíà 5:15; ka Éfésù 4:31.

12. Báwo ni ìjọsìn ẹnì kan ṣe lè di ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run?

12 Má gbàgbé pé bí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ nínú ìgbéyàwó ṣe ń lo ahọ́n yín kan àjọṣe yín pẹ̀lú Jèhófà. Bíbélì sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan, síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó  ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.” (Jákọ́bù 1:26) Ńṣe ni ìjọsìn rẹ àti ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ jọ ń rìn pa pọ̀. Bíbélì kò ṣètìlẹ́yìn fún èrò náà pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ nílé kò já mọ́ nǹkan kan béèyàn bá ṣáà ti gbà pé Ọlọ́run lòún ń jọ́sìn. Má wulẹ̀ tanra ẹ jẹ. Ọ̀rọ̀ pàtàkì lọ̀rọ̀ yìí o. (Ka 1 Pétérù 3:7) O lè láwọn ẹ̀bùn àbínibí kan, tàbí kó o nítara, àmọ́ tó o bá ń mọ̀ọ́mọ̀ fọ̀rọ̀ líle dọ́gbẹ́ sí ẹnì kejì rẹ lọ́kàn, ò ń tàbùkù sí ìgbéyàwó nìyẹn, Ọlọ́run sì lè ka ìjọsìn rẹ sí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan.

13. Báwo ni ọkọ tàbí aya kan ṣe lè dá ọgbẹ́ sí ẹnì kejì rẹ̀ lọ́kàn?

13 Àwọn tọkọtaya tún ní láti wà lójúfò kí wọ́n má bàa dá ọgbẹ́ ọkàn síra wọn lọ́kàn láwọn ọ̀nà kan ti kò ṣe tààràtà. Gbé àwọn àpẹẹrẹ méjì yìí yẹ̀ wò: Ìyá kan tó ń dá tọ́mọ sábà máa ń fi tẹlifóònù pe arákùnrin kan tó ti gbéyàwó láti béèrè fún ìmọ̀ràn, wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn; arákùnrin kan tó jẹ́ àpọ́n máa ń lo àkókò tó pọ̀ gan-an lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lóde ẹ̀rí pẹ̀lú arábìnrin kan tó ti lọ́kọ. Òótọ́ ni pé àwọn méjèèjì tó ti ṣègbéyàwó tá a mẹ́nu bà nínú àpèjúwe yìí kò ní ohun búburú kankan lọ́kàn; síbẹ̀, ipa wo ni ìwà wọn máa ní lórí ẹnì kejì wọn? Aya kan tó ń kojú irú nǹkan báyìí sọ pé: “Ó máa ń dùn mí gan-an tí n bá rí i pé ọkọ mi ń lo àkókò tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yẹn láti bá arábìnrin míì sọ̀rọ̀ nínú ìjọ. Ó máa ń mú kó ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan lójú ẹ̀.”

14. (a) Ojúṣe tọkọtaya wo ni ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:24 tẹnu mọ́? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

14 A lè lóye ìdí tọ́rọ̀ náà fi máa dun ọkọ tàbí aya yìí àtàwọn míì tí wọ́n bá ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé ẹni tí wọ́n fẹ́ ò fi ìtọ́ni tó ṣe pàtàkì tí Ọlọ́run fún wọn sílò pé: “Ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ . . . yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn tó ti ṣègbéyàwó  ṣì ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn; Ọlọ́run ti fi ìlànà lélẹ̀ pé, ojúṣe wọn sí ẹnì kejì wọn ló ṣe pàtàkì jù lọ. Bákan náà, àwọn Kristẹni fẹ́ràn àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́; síbẹ̀ ojúṣe wọn sí ẹnì kejì wọn làkọ́kọ́. Nítorí náà, báwọn Kristẹni tí wọ́n ti ṣègbéyàwó bá ń ní àjọṣe tó wọra ju bó ṣe yẹ lọ tàbí tí wọ́n ń lo àkókò tó pọ̀ jù pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, pàápàá pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin  tàbí obìnrin bíi tiwọn, ńṣe ni wọ́n ń jin ìgbéyàwó wọn lẹ́sẹ̀. Àbí ohun tó ń fa èdèkòyédè láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ nìyẹn? Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ṣé lóòótọ́ ni mò ń ráyè gbọ́ ti ẹnì kejì mi, tí mo sì ń fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dọ́kàn?’

15. Ní ìbámu pẹ̀lú Mátíù 5:28, kí nìdí táwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó kò fi gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹni tí kì í ṣe ẹnì kejì wọn máa jẹ wọ́n lógún jù?

15 Síwájú sí i, àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, tí wọ́n wá lọ ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin míì jẹ wọ́n lógún ju ti ẹnì kejì wọn lọ ń finá ṣeré ni o. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọkàn àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti ṣègbéyàwó máa ń fà sí ẹlòmíì tí àjọṣe wọn àti tiẹ̀ jọ wọra ju bó ṣe yẹ lọ. (Mátíù 5:28) Ìyẹn sì ti mú kí wọ́n hùwà tó túbọ̀ tàbùkù sí ìgbéyàwó ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ tí wọ́n ní sí onítọ̀hún lọ. Gbọ́ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.

‘KÍ IBÙSÙN ÌGBÉYÀWÓ WÀ LÁÌNÍ Ẹ̀GBIN’

16. Àṣẹ wo ni Pọ́ọ̀lù fúnni lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó?

16 Bí Pọ́ọ̀lù ti ń sọ̀rọ̀ ìyànjú yìí tán pé “kí ìgbéyàwó ní ọlá,” ló ti fi ìkìlọ̀ kún un pé: “Kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) “Ibùsùn ìgbéyàwó” tí Pọ́ọ̀lù lò níhìn-ín túmọ̀ sí ìbálòpọ̀. Ìbálòpọ̀ yìí wà “láìní ẹ̀gbin,” tàbí pé kò lábààwọ́n, kìkì tó bá jẹ́ pé àárín tọkọtaya ló mọ. Nítorí náà, àwọn Kristẹni máa ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí náà pé: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ.”—Òwe 5:18.

17. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ojú tàwọn èèyàn ayé fi ń wò panṣágà nípa lórí àwọn Kristẹni? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jóòbù?

17 Àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn ń tàpá sófin Ọlọ́run. Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ka panṣágà sí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ burú lóde òní. Nítorí náà, àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò àwọn èèyàn nípa lórí ojú tí wọ́n fi ń wo panṣágà. Wọ́n mọ̀ pé, bópẹ́ bóyá, “Ọlọ́run  [ló máa] dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́” kì í ṣe èèyàn. (Hébérù 10:31; 12:29) Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ fara mọ́ èrò Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ yìí. (Ka Róòmù 12:9) Rántí pé Jóòbù baba ńlá náà sọ pe: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú.” (Jóòbù 31:1) Bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n má bàa ṣe ohunkóhun tó lè yọrí sí panṣágà, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fojú wọn wo ìwòkuwò, wọn kì í sì í wo ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn níwò kí wọ́n bá a ṣe panṣágà.—Wo Àfikún, lójú ìwé 219 sí 221.

18. (a) Báwo ni panṣágà ṣe burú tó lójú Jèhófà? (b) Kí ni panṣágà àti ìbọ̀rìṣà fi jọra?

18 Báwo ni panṣágà ṣe burú tó lójú Jèhófà? Òfin Mósè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà. Ní Ísírẹ́lì, panṣágà àti ìbọ̀rìṣà wà lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó máa ń yọrí sí ikú. (Léfítíkù 20:2, 10) Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ẹ̀ṣẹ̀ méjèèjì ló jọra? Wò ó báyìí ná, ọmọ Ísírẹ́lì tó bá ń jọ́sìn òrìṣà ti da májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe jẹ́ pé ọmọ Ísírẹ́lì tó bá ṣe panṣágà ti da májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ̀. Àwọn méjèèjì tó dẹ́ṣẹ̀ yìí ló hùwà ọ̀dàlẹ̀. (Ẹ́kísódù 19:5, 6; Diutarónómì 5:9; ka Málákì 2:14) Nítorí náà, àwọn méjèèjì ló ṣẹ̀ sófin Jèhófà, Ọlọ́run olóòótọ́ tó ṣeé gbíyè lé.—Sáàmù 33:4.

19. Bí ẹnì kan bá ti pinnu pé òun ò ní ṣe panṣágà, kí ló lè ràn án lọ́wọ́, kí sì nìdí?

19 Ká sòótọ́, Òfin Mósè kọ́ ló ń darí àwọn Kristẹni. Àmọ́, táwọn Kristẹni bá ń rántí pé ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni panṣágà ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ìyẹn á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ ìpinnu wọn láti má ṣe lọ́wọ́ sírú àṣà bẹ́ẹ̀. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Gbé ìfiwéra yìí yẹ̀ wò: Ṣé wàá wọ inú Ṣọ́ọ̀ṣì lọ láti kúnlẹ̀ níwájú ère kó o sì gbàdúrà níbẹ̀? Ó dájú pé, wàá sọ pé, ‘Láéláé, mi ò jẹ́ ṣerú ẹ̀!’ Àmọ́ tí wọ́n bá tìtorí ẹ̀ fún ẹ lówó gọbọi ńkọ́? Ńṣe lo máa sọ pé, ‘mi ò jẹ́ dán an wò!’ Bẹ́ẹ̀ ni, Kristẹni tòótọ́ ò jẹ́ ronú àtida Jèhófà nípa jíjọ́sìn  òrìṣà, torí ohun ìríra ló jẹ́. Bákan náà, ohun ìríra ló gbọ́dọ̀ jẹ́ lọ́kàn àwọn Kristẹni láti máa ronú pé àwọn máa da Jèhófà Ọlọ́run wọn àti ẹnì kejì wọn nípa ṣíṣe panṣágà, láìka ohun yòówù tó lè mú kí wọ́n fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ sí. (Sáàmù 51:1, 4; Kólósè 3:5) A ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa mú kí inú Sátánì dùn, àmọ́ tó máa kó ẹ̀gbin bá Jèhófà àti ètò ìgbéyàwó tó jẹ́ mímọ́.

BÍ ÀDÉHÙN ÌGBÉYÀWÓ ṢE LÈ TÚBỌ̀ LÁGBÁRA

20. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìgbéyàwó kan? Ṣàkàwé.

20 Láfikún sí pé o ò ní máa hùwà tó ń tàbùkù sí ìgbéyàwó, àwọn ìgbésẹ̀ wo lo tún lè gbé kó o lè padà máa bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì rẹ? Ìdáhùn rèé, fojú inú wo ìgbéyàwó bí ilé kan. Wá wo àwọn ọ̀rọ̀ onínúure, aájò tó tinú wá àtàwọn ọ̀rọ̀ tó ń buyì kúnni táwọn tọkọtaya máa ń sọ síra wọn bí àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ tó mú kí ilé yẹn rẹwà. Bí ẹ̀yin méjèèjì bá sún mọ́ra yín, ìgbéyàwó yín máa dà bí ilé táwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ sọ di ẹlẹ́wà tó sì fani mọ́ra. Bí ìfẹ́ yín bá ń jó rẹ̀yìn, àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ yẹn ló ń dàwátì yẹn, ìgbéyàwó yín á wá dà bí ilé tó kàn wà gbundúku lásán. Níwọ̀n bó o ti ń fẹ́ láti ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé “kí ìgbéyàwó ní ọlá,” wàá fẹ́ láti ṣe ohun tó máa mú kí nǹkan sunwọ̀n sí i. Ó ṣe tán, o ò jayò pa tó o bá ṣàtúnṣe ohun tó ṣeyebíye tàbí tó o mú un padà bọ̀ sípò. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọgbọ́n ni a ó fi gbé agbo ilé ró, nípa ìfòyemọ̀ sì ni yóò fi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. Nípa ìmọ̀ sì ni àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún yóò fi kún fún gbogbo ohun oníyelórí tí ó ṣeyebíye tí ó sì wuni.” (Òwe 24:3, 4) Gbé béèyàn ṣe lè fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílò nínú ìgbéyàwó yẹ̀ wò.

21. Báwo làwọn tọkọtaya ṣe lè mú kí àjọṣe wọn túbọ̀ máa dán mọ́rán sí i? (Tún wo  àpótí tó wà lójú ìwé 131.)

21 Lára àwọn ‘nǹkan iyebíye’ tó máa ń wà nínú ìdílé  aláyọ̀ ni àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ tòótọ́, ìbẹ̀rù Ọlọ́run, àti ìgbàgbọ́ tó lágbára. (Òwe 15:16, 17; 1 Pétérù 1:7) Wọ́n máa ń jẹ́ kí àjọṣe tọkọtaya dán mọ́rán. Àmọ́ ǹjẹ́ o kíyè sí ọ̀nà táwọn nǹkan iyebíye gbà kún inú iyàrá tí wọ́n sọ nínú òwe tá a mẹ́nu bà lókè yìí? “Nípa ìmọ̀.” Ó dájú pé, ìmọ̀ Bíbélì lágbára láti yí ìrònú àwọn èèyàn padà, kó sì sún wọn láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn bíi tàtẹ̀yìnwá, bí wọ́n bá fi í sílò. (Róòmù 12:2; Fílípì 1:9) Nítorí náà, nígbàkigbà tí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ bá jọ ń ka ẹsẹ Bíbélì, bóyá látinú ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, tàbí látinú àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì nínú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tó sì jẹ mọ ọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó, ńṣe ló dà bíi pé ẹ ń ṣàyẹ̀wò ohun ẹ̀ṣọ́ kan tó lè bu ẹwà kún ilé yín. Bí ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní fún Jèhófà bá ń sún yín láti máa fi ìmọ̀ràn tẹ́ ẹ kà yẹn sílò, ńṣe lẹ̀ ń mú àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ yẹn wọnú “àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún.” Ó sì ṣeé ṣe kẹ́ ẹ tún padà ní àjọṣe tímọ́tímọ́ tó fani lọ́kàn mọ́ra bíi tàtẹ̀yìnwá.

22. Irú ìbàlẹ̀ ọkàn wo la máa ní bá a bá ń sapá láti ṣe ojúṣe tiwa kí àjọṣe wa àti ti ẹnì kejì wa lè dán mọ́rán sí i?

22 Òótọ́ ni pé, ó lè gba ìsapá àti àkókò díẹ̀ kó o tó lè tún àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ wọ̀nyẹn tò sáyè wọn. Síbẹ̀, bó o bá sapá láti ṣe ojúṣe tìẹ, ọkàn ẹ á balẹ̀ dọ́ba torí o mọ̀ pé ò ń ṣègbọràn sí àṣẹ inú Bíbélì pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10; Sáàmù 147:11) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìsapá tó o bá ń fi taratara ṣe láti jẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ ní ọlá máa jẹ́ kó o lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 6 Ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìgbéyàwó yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ tó fi gbani níyànjú.—Hébérù 13:1-5.