Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀFIKÚN

Àwọn Ìpín Tó Tara Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Wá, Àtàwọn Ọ̀nà Kan Tí Wọ́n Ń Gbà Ṣiṣẹ́ Abẹ

Àwọn Ìpín Tó Tara Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Wá, Àtàwọn Ọ̀nà Kan Tí Wọ́n Ń Gbà Ṣiṣẹ́ Abẹ

Àwọn ìpín tó tara èròjà ẹ̀jẹ̀ wá. Bí wọ́n bá pín ọ̀kọ̀ọ̀kan èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, ìyẹn sẹ́ẹ̀lì pupa, sẹ́ẹ̀lì funfun, sẹ́ẹ̀lì amẹ́jẹ̀dì àti omi inú ẹ̀jẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ni wọ́n máa ń rí àwọn ìpín kéékèèké míì tó tara èròjà ẹ̀jẹ̀ wá. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìpín sẹ́ẹ̀lì pupa la ti ń rí purotéènì kan tó ń jẹ́ hemoglobin. Wọ́n sì ti fi hemoglobin tí wọ́n mú látara èèyàn tàbí ara ẹranko ṣètọ́jú àwọn aláìsàn tí ẹ̀jẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán lára wọn, tàbí àwọn tí ẹ̀jẹ̀ tó dà nù lára wọn pọ̀.

Omi inú ẹ̀jẹ̀, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àsán omi, ní onírúurú èròjà míì tá a lè rí nínú ará. Omi inú ẹ̀jẹ̀ tún láwọn èròjà tó máa ń mú kí ẹ̀jẹ̀ dì, àwọn èròjà agbóguntàrùn àtàwọn èròjà míì tó ń jẹ́ purotéènì, irú bí albumin. Bí àìsàn bá ń ṣe ẹnì kan, àwọn dókítà lè ní kí wọ́n gún un lábẹ́rẹ́ gamma globulin, tó jẹ́ èròjà kan tó wá látinú omi inú ẹ̀jẹ̀ ẹnì kan tó ní àjẹsára irú àìsàn bẹ́ẹ̀. Àwọn purotéènì kan tún wà nínú sẹ́ẹ̀lì funfun tí wọ́n máa ń lò láti tọ́jú ẹni tó bá ní kòkòrò àrùn lára àti àrùn jẹjẹrẹ.

Ṣó yẹ káwọn Kristẹni gbà kí wọ́n fi ìpín tó wá látara àwọn èròjà ẹ̀jẹ̀ tọ́jú àwọn? Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, torí náà olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ ṣèpinnu tó bá bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu níwájú Ọlọ́run. Àwọn kan lè sọ pé àwọn ò fẹ́ èyíkéyìí lára ìpín tó wá látinú èròjà ẹ̀jẹ̀. Wọ́n sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n ń ronú lórí Òfin tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ mọ́ ẹran, àfi kí wọ́n “dà á jáde sórí ilẹ̀ bí omi.” (Diutarónómì 12:22-24) Àwọn míì sì rèé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò  fẹ́ gbẹ̀jẹ̀ tàbí èyíkéyìí lára àwọn èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, wọ́n lè gbà kí dókítà fi ìpín tó wá látara àwọn èròjà ẹ̀jẹ̀ tọ́jú àwọn. Wọ́n lè máa ronú pé ó níbi tí wọ́n á pín èròjà ẹ̀jẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ dé tí ìpín tó wá látara ẹ̀jẹ̀ náà ò fi ní lè dúró fún ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá alààyè tí wọ́n tara ẹ̀ mú un jáde mọ́.

Bó o bá ń pinnu yálà o máa gba ìpín tó tara àwọn èròjà ẹ̀jẹ̀ jáde tàbí o ò ní gbà á, àwọn ìbéèrè tó o máa gbé yẹ̀ wò nìyí: Ǹjẹ́ mo mọ̀ pé bí mo bá sọ pé mi ò fẹ́ èyíkéyìí nínú ìpín tó wá látara àwọn èròjà ẹ̀jẹ̀, ohun tí mò ń sọ ni pé mi ò fẹ́ irú àwọn oògùn kan tó lè gbógun ti àrùn tàbí èyí tó lè mú kí ẹ̀jẹ̀ dì kí èyí tó máa ṣòfò lára rẹ̀ má bàa pọ̀ jù? Ǹjẹ́ mo lè ṣàlàyé fún dókítà ìdí tí mi ò ṣe fẹ́ láti lo ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ìpín tó wá látara àwọn èròjà ẹ̀jẹ̀?

Àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣiṣẹ́ abẹ. Lára àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ni hemodilution, ìyẹn dída oògùn pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀ àti cell salvage, ìyẹn gbígbe ẹ̀jẹ̀. Ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe hemodilution, ìyẹn dída oògùn pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀ ni pé bí iṣẹ́ abẹ bá ń lọ lọ́wọ́, wọ́n á darí ẹ̀jẹ̀ gba ibòmíì lọ, wọ́n á wá fi oògùn tó ń mú kí ẹ̀jẹ̀ pọ̀ rọ́pò rẹ̀, bí iṣẹ́ abẹ bá parí, wọ́n á dá ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n darí síbòmíì náà padà sínú ara. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe cell salvage, ìyẹn gbígbe ẹ̀jẹ̀, ni pé wọ́n á gbe ẹ̀jẹ̀ tó bá dà nù látojú ọgbẹ́ tàbí nínú ara nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ abẹ, wọ́n á fọ̀ ọ́ tàbí kí wọ́n sẹ́ ẹ, wọ́n á wá dá a padà sínú ara aláìsàn náà. Torí pé bí dókítà kan ṣe ń lo ẹ̀jẹ̀ nígbà tó bá ń ṣiṣẹ́ abẹ yàtọ̀ sí bí dókítà míì ṣe ń lò ó, Kristẹni kan gbọ́dọ̀ wádìí ohun tí dókítà òun fẹ́ láti ṣe.

 Bó o bá fẹ́ ṣèpinnu nípa àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣiṣẹ́ abẹ yìí, bi ara rẹ pé: ‘Bó bá jẹ́ pé wọ́n á fi ẹ̀jẹ̀ mi sínú ohun kan, tí kò sì ní máa lọ yíká nínú ara mi fún àkókò díẹ̀, ǹjẹ́ ẹ̀rí ọkàn mi á gbà mí láyè kí n ṣì máa wo ẹ̀jẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí apá kan ara mi, tí kò fi ni pọ́n dandan pé kí wọ́n “dà á jáde sórí ilẹ̀”?  (Diutarónómì 12:23, 24) Ṣé kò ní da ẹ̀rí ọkàn mi tí mo fi Bíbélì kọ́ láàmú bí wọ́n bá fa ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ lára mi nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ abẹ fún mi, tí wọ́n fọ̀ ọ́, tí wọ́n sẹ́ ẹ, tí wọ́n sì tún wá dá a padà sí mi lára? Ǹjẹ́ mo tiẹ̀ mọ̀ pé bí mo bá sọ pé mi ò fẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ mi tọ́jú mi lọ́nà èyíkéyìí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀jẹ̀ mi fún àyẹ̀wò, wọn ò gbọ́dọ̀ sẹ́ ẹ̀jẹ̀ mi, wọn ò sì gbọ́dọ̀ lo ẹ̀rọ tó ń fa ẹ̀jẹ̀ jáde, táá jẹ́ kí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn wọnú rẹ̀, táá sì tún dá a padà sínú ara?’

Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ọ̀nà tó máa fẹ́ kí wọ́n gbà lo ẹ̀jẹ̀ òun bí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ abẹ fóun. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí náà nìyẹn bí wọ́n bá fẹ́ gba ẹ̀jẹ̀ fún àyẹ̀wò tàbí kí wọ́n da egbòogi pọ̀ mọ́ ọn, kí wọ́n tó dá a padà sínú ara.