Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’

 ORÍ 2

Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere

Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere

“Di ẹ̀rí-ọkàn rere mú.”—1 PÉTÉRÙ 3:16.

1, 2. Kí nìdí tí ohun èlò atọ́nisọ́nà fi jẹ́ kòṣeémáàní fáwọn arìnrìn-àjò, báwo la sì ṣe lè fi wé ẹ̀rí ọkàn?

AWAKỌ̀ òkun kan ń tukọ̀ lórí agbami òkun; arìnrìn-àjò kan ń rìn ní aṣálẹ̀ kan; awakọ̀ òfuurufú kan ń fò ní gbalasa òfuurufú tó lọ salalu. Bí gbogbo àwọn tá a sọ yìí bá fẹ́ débi tí wọ́n ń lọ, ǹjẹ́ o mọ ohun kan tó jẹ́ kòṣeémáàní fún wọn? Gbogbo wọ́n gbọ́dọ̀ ní ohun èlò atọ́nisọ́nà, irú bíi kọ́ńpáàsì tó wà lójú ìwé yìí, kí wọ́n má bàa ṣìnà, pàápàá táwọn ohun èlò atọ́nisọ́nà ìgbàlódé míì ò bá sí.

2 Kọ́ńpáàsì tẹ́ ẹ̀ ń wò yìí dà bí aago kékeré kan. Bó bá ń ṣiṣẹ́ dáadáa, bí èyíkéyìí nínú àwọn arìnrìn-àjò tá a sọ lókè yìí bá lò ó, ó dájú pé ó máa gúnlẹ̀ láyọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ohun èlò atọ́nisọ́nà, a lè fi kọ́ńpáàsì yìí wé ẹ̀bùn tó ṣeyebíye tí Jèhófà fún wa, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn. (Jákọ́bù 1:17) Bí kò bá sí ẹ̀rí  ọkàn, kò sí ohun táá máa tọ́ wa sọ́nà. Tá a bá lò ó bó ṣe yẹ, ó lè jẹ́ ká mọ ibi tá à ń lọ, kò sì ní jẹ́ ká kúrò lójú ọ̀nà tó tọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ohun tí ẹ̀rí ọkàn jẹ́, ká sì ṣàlàyé bó ṣe ń ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn ìyẹn la máa wá jíròrò àwọn kókó wọ̀nyí: (1) Bá a ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, (2) ìdí tó fi yẹ ká máa gba tàwọn ẹlòmíì rò bí ẹ̀rí ọkàn wọn bá fàyè gbà wọ́n láti ṣe ohun kan àti (3) bí ẹ̀rí ọkàn rere ṣe lè ṣe wá láǹfààní.

OHUN TÍ Ẹ̀RÍ ỌKÀN JẸ́ ÀTI BÓ ṢE Ń ṢIṢẸ́

3. Nínú èdè Gíríìkì tí wọ́n kọ́kọ́ fi kọ Bíbélì, kí ni “ẹ̀rí ọkàn” túmọ̀ sí ní olówuuru, ohun mìíràn wo táwa èèyàn fi yàtọ̀ sáwọn ohun ẹlẹ́mìí yòókù lórí ilẹ̀ ayé lèyí sì ń tọ́ka sí?

3 Nínú èdè Gíríìkì tí wọ́n kọ́kọ́ fi kọ Bíbélì, “ẹ̀rí ọkàn” túmọ̀ ní olówuuru sí “ìmọ̀ àjùmọ̀ní tàbí ìmọ̀ tó wà lọ́kàn ẹni.” Ohun táwa èèyàn fi yàtọ̀ sáwọn ohun ẹlẹ́mìí yòókù lórí ilẹ̀ ayé ni agbára tí Ọlọ́run fún wa láti mọ ara wa. Ìdí nìyẹn tá a fi lè yẹ ohun tó wà lọ́kàn wa wò láti mọ̀ bóyá ohun tó tọ́ là ń ṣe tàbí ohun tí kò tọ́. Bí ọlọ́pàá inú tàbí adájọ́ ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe ń ṣiṣẹ́. Ó máa ń yẹ ohun tá à ń ṣe, ìwà wa àti ohun tá a bá fẹ́ ṣe wò. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́ tàbí kó kì wá nílọ̀ ká má bàa ṣèpinnu tí kò tọ́. Lẹ́yìn náà, ó lè yìn wá tá a bá ṣèpinnu tó fọgbọ́n yọ tàbí kó máa dá wa lẹ́bi tá a bá ṣèpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání.

4, 5. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Ádámù àti Éfà ní ẹ̀rí ọkàn, kí ló ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n tàpá sófin Ọlọ́run? (b) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé ọjọ́un tẹ́tí sí ẹ̀rí ọkàn wọn?

4 Gbàrà tí Ọlọ́run ti dá èèyàn látìbẹ̀rẹ̀ ló ti dá ẹ̀rí ọkàn mọ́ wọn. A mọ̀ pé Ádámù àti Éfà ní ẹ̀rí ọkàn. Ìdí ni pé ojú tì wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:7, 8) Pé ẹ̀rí ọkàn wọn ń dà wọ́n láàmú kò yí ẹ̀ṣẹ̀ wọn padà. Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sófin Ọlọ́run ni. Èyí fi hàn pé ṣe ni wọ́n fúnra wọn yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run tí wọ́n sì di ọ̀tá rẹ̀. Wọn ò ṣàìmọ ohun tí wọ́n tọrùn bọ̀ torí ẹni pípé ni wọ́n nígbà náà, ọ̀rọ̀ wọn sì ti kọjá àtúnṣe.

 5 Ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá aláìpé ni kò ṣe bíi ti Ádámù àti Éfà torí pé wọ́n máa ń tẹ́tí sí ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn bá sọ. Bí àpẹẹrẹ, Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́, sọ pé: “Mo ti di ìṣẹ̀tọ́ mi mú, èmi kì yóò sì jẹ́ kí ó lọ; ọkàn-àyà mi kì yóò ṣáátá mi fún èyíkéyìí nínú àwọn ọjọ́ mi.” * (Jóòbù 27:6) Jóòbù máa ń kọbi ara sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. Ó máa ń tẹ́tí sí i, ó sì máa ń jẹ́ kó darí ìwà tó ń hù àti ìpinnu tó ń ṣe. Abájọ tó fi lè sọ tọkàntọkàn pé ẹ̀rí ọkàn òun ò ṣáátá òun, ìyẹn ni pé kò da òun láàmú, àti pé kò dá òun lẹ́bi. Ọ̀nà tí ẹ̀rí ọkàn Dáfídì gbà ṣiṣẹ́ yàtọ̀ sí ti Jóòbù. Lẹ́yìn tí Dáfídì hùwà àìlọ́wọ̀ sí Sọ́ọ̀lù, ẹni tí Jèhófà fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí ọba, ńṣe ni “ọkàn-àyà Dáfídì ń gbún un ṣáá.” (1 Sámúẹ́lì 24:5) Ẹ̀rí ọkàn Dáfídì tó ń dá a lẹ́bi yẹn ṣe é láǹfààní torí ó jẹ́ kó mọ̀ pé kò yẹ kóun tún dá irú ẹ̀ láṣà mọ́.

6. Kí ló fi hàn pé ẹ̀rí ọkàn jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn?

6 Ṣé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nìkan ni Jèhófà dá ẹ̀rí ọkàn mọ́ ni? Gbọ́ ohun tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ, ó ní: “Nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn-àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, a ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí a ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.” (Róòmù 2:14, 15) Èyí fi hàn pé nígbà míì, ẹ̀rí ọkàn àwọn tí kò mọ àwọn òfin Jèhófà pàápàá máa ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó bá ìlànà Ọlọ́run mu.

7. Kí nìdí tí ẹ̀rí ọkàn fi lè ṣiṣẹ́ ségesège láwọn ìgbà míì?

7 Àmọ́ ṣá o, ẹ̀rí ọkàn máa ń ṣiṣẹ́ gbòdì nígbà míì. Kí ló  fà á? Jẹ́ ká tibi àpèjúwe ohun èlò atọ́nisọ́nà tá a sọ lẹ́ẹ̀kan yẹn wò ó ná. Bí wọ́n bá fi sẹ́gbẹ̀ẹ́ irin tútù, ó lè jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ségesège. Bí wọ́n bá sì lo òun àti ìwé atọ́nisọ́nà tí kò péye pa pọ̀, ó lè ṣi èèyàn lọ́nà. Báwa náà bá lọ jẹ́ kí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan gbà wá lọ́kàn pẹ́nrẹ́n, ẹ̀rí ọkàn wa lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ségesège. Tá ò bá sì wá fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, a lè má mọ̀yàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, pàápàá tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Ká sòótọ́, ẹ̀rí ọkàn wa ò lè ṣiṣẹ́ dáadáa tá ò bá jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa darí wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀rí-ọkàn mi . . . ń jẹ́rìí pẹ̀lú mi nínú ẹ̀mí mímọ́.” (Róòmù 9:1) Báwo la wá ṣe lè rí i dájú pé ọ̀nà tí ẹ̀rí ọkàn wa ń gbà ṣiṣẹ́ kò ta ko ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà? Àfi ká yáa kọ́ ọ.

BÁ A ṢE LÈ KỌ́ Ẹ̀RÍ ỌKÀN WA

8. (a) Báwo ni ọkàn-àyà ṣe lè kó èèràn ran ẹ̀rí ọkàn, kí ló sì yẹ kó jẹ wá lógún tá a bá fẹ́ ṣèpinnu? (b) Kí nìdí tí wíwulẹ̀ ní ẹ̀rí ọkàn tí kò dani láàmú ò fi tó fún Kristẹni? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

8 Báwo lo ṣe máa ń ṣàwọn ìpinnu tá a gbé ka ẹ̀rí ọkàn? Àwọn kan wà tó dà bíi pé ohun tó bá ṣáà ti wá sí wọn lọ́kàn ni wọ́n máa ń ṣe. Wọ́n lè wá sọ pé: “Kò da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú.” Ohun tó bá wu ọkàn-àyà láti ṣe ló máa ń fẹ́ ṣe, ìyẹn sì lè ran ẹ̀rí ọkàn. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremáyà 17:9) Nítorí náà, ohun tó wu ọkàn-aya láti ṣe kọ́ ló yẹ kó jẹ wá lógún, bí kò ṣe ohun tó máa múnu Jèhófà Ọlọ́run dùn. *

9. Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe kan ẹ̀rí ọkàn wa?

 9 Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ là ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti kọ́ tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, ìpinnu yẹn máa fi hàn pé a ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn àti pé ìfẹ́ inú wa kọ́ là ń ṣe. Àpẹẹrẹ ẹnì kan rèé. Nehemáyà, tó jẹ́ gómìnà tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́, lẹ́tọ̀ọ́ láti máa gba owó orí àtàwọn ìṣákọ́lẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn ará ìlú Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ló dé tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kó fẹ́ dáwọ́ lé ohunkóhun tó lè múnú bí Jèhófà nípa níni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára. Ó sọ pé: “Èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tìtorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (Nehemáyà 5:15) Ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn, ìyẹn ìbẹ̀rù àtọkànwá tí ò ní jẹ́ ká ṣe ohunkóhun tó máa bí Baba wa ọ̀run nínú. Irú ìbẹ̀rù tó ń fọ̀wọ̀ hàn bẹ́ẹ̀ á jẹ́ ká máa wo ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ká tó ṣèpinnu èyíkéyìí.

10, 11. Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló dá lórí ọtí mímu, báwo sì ni Ọlọ́run ṣe lè tọ́ wa sọ́nà ká lè fi àwọn ìlànà náà sílò?

10 Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ nípa ọtí mímu yẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ nínú wa ló máa ń ṣèpinnu yálà kóun mutí tàbí kóun má mutí, láwọn ibi àríyá. Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ ká mọ ohun tí ọtí mímu ní nínú. Àwọn ìlànà wo ló ṣàlàyé ọ̀ràn yìí nínú Bíbélì? Ká sòótọ́, Bíbélì ò sọ pé mímu ọtí níwọ̀nba burú, ńṣe ló wulẹ̀ ń fògo fún Jèhófà olùpèsè wáìnì. (Sáàmù 104:14, 15) Àmọ́, Bíbélì dẹ́bi fún mímu ọtí àmujù àti ṣíṣẹ̀fẹ̀ rírùn nídìí ọtí. (Lúùkù 21:34; Róòmù 13:13) Bíbélì tún fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì ni mímu ọtí lámujù jẹ́, torí ńṣe ló kà á mọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì bíi panṣágà àti àgbèrè. *1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

11 Irú àwọn ìlànà báwọ̀nyí làwa Kristẹni lè fi máa tọ́ ẹ̀rí ọkàn wa tó sì máa jẹ́ ká lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Nítorí náà, tá a bá fẹ́ ṣèpinnu nípa ọtí mímu níbi  àríyá, ẹ jẹ́ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè bí: ‘Irú ayẹyẹ wo ni wọ́n pè mí sí? Ṣé kò ní kọjá bó ṣe yẹ, kó wá di àríyá aláriwo? Kí lèrò èmi alára nípa ọtí mímu? Ṣé mo máa ń hára gàgà láti mutí, ṣé mo ti sọ ọ́ di ọlọ́run, ṣé mo fi ń pàrònú rẹ́ àbí ńṣe ni mo fi ń ṣakin? Ṣé mo lè pinnu ìgbà tó yẹ kí n dánu dúró?’ Bá a ṣe ń ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì wọ̀nyí àtàwọn ìbéèrè tó ṣeé ṣe kó jẹ yọ, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà fún ààbò Jèhófà. (Ka Sáàmù 139:23, 24) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń bẹ Jèhófà pé kó máa fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ dáàbò bò wá. A tún ń dá ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ láti máa ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àmọ́, ohun kan ṣì wà tó yẹ ká máa gbé yẹ̀ wò tá a bá fẹ́ ṣèpinnu.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA GBÉ OHUN TÍ Ẹ̀RÍ ỌKÀN ÀWỌN ẸLÒMÍÌ BÁ SỌ YẸ̀ WÒ?

Ẹ̀rí ọkàn tá a ti fi Bíbélì kọ́ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pinnu bóyá kó o mutí tàbí kó o má mutí

12, 13. Kí nìdí tí ohun tí ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni fàyè gbà fi yàtọ̀ síra, ojú wo ló sì yẹ ká máa fi wo ìyàtọ̀ yìí?

12 Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu nígbà míì tó o bá rí i pé ẹ̀rí ọkàn Kristẹni kan fàyè gba ohun kan tí ẹ̀rí ọkàn Kristẹni mìíràn sì ta kò ó. Ohun tó wu ẹnì kan lè máà wu ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, ní ti ọ̀ràn mímutí níbi àríyá, ẹnì kan lè máà rí ohun tó burú nínú bíbá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mélòó kan mutí níwọ̀nba; lójú ẹlòmíì sì rèé, ìwà ìbàjẹ́ gbáà ló jẹ́. Kí nìdí tí irú ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ fi wà, báwo nìyẹn sì ṣe lè kan àwọn ìpinnu tá à ń ṣe?

13 Ohun tó mú káwọn èèyàn yàtọ̀ síra ò lóǹkà. Bí wọ́n ṣe tọ́ kálukú wa dàgbà yàtọ̀ síra gan-an ni. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ṣì lè máa rántí àwọn ìwà tó kù díẹ̀ káàtó tí wọ́n ti hù sẹ́yìn, wọ́n sì lè máà tíì borí ẹ̀ pàápàá. (1 Àwọn Ọba 8:38, 39) Bí àyè ọtí mímu bá yọ, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á fẹ́ láti ṣọ́ra. Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá bá ẹ lálejò, ó ṣeé ṣe kí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ má fàyè gbà á láti mutí. Tírú ẹ̀ bá wá ṣẹlẹ̀, ṣé kò ní bí ẹ nínú báyìí? Àbí ṣe lo tiẹ̀ máa fi dandan lé e? Ó dájú pé o ò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Yálà o mọ ohun tó fà á tí kò fi mutí tàbí o kò mọ̀ ọ́n,  tí kò sì wù ú kó ṣàlàyé fún ẹ, ó yẹ kí ìfẹ́ ará sún ẹ láti gba tiẹ̀ rò.

14, 15. Ọ̀nà wo ní ẹ̀rí ọkàn àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà yàtọ̀ síra, kí sì ni Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú láti ṣe?

14 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí i pé ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní yàtọ̀ síra gan-an ni. Nígbà yẹn, ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni kan ò gbà wọ́n láyè láti jẹ àwọn oúnjẹ kan táwọn kan ti fi rúbọ sí òrìṣà. (1 Kọ́ríńtì 10:25) Àmọ́ ní ti Pọ́ọ̀lù ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò ṣe é ní nǹkan kan láti jẹ irú àwọn oúnjẹ tí wọ́n ṣì máa tà lọ́jà bẹ́ẹ̀. Ní tiẹ̀, òrìṣà ò já mọ́ nǹkan kan; ó mọ̀ pé oúnjẹ tí Jèhófà dá, tó sì jẹ́ pé òun ló ni ín, kò lè jẹ́ tàwọn òrìṣà láéláé. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù lóyé pé àwọn kan ò fara mọ́ èrò tóun ní yẹn. Ó ṣeé ṣe káwọn kan lára wọn ti jẹ́ abọ̀rìṣà pọ́ńbélé kí wọ́n tó di Kristẹni. Ní tiwọn gbogbo ohun tó bá ti ní í ṣe pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà ló máa ń bí wọn nínú. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe wá yanjú ọ̀ràn náa?

15 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí àwa tí a ní okun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun, kí a má sì máa ṣe bí ó ti wù wá. Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” (Róòmù 15:1, 3) Pọ́ọ̀lù ronú pé ńṣe ló yẹ ká máa fi ohun tó jẹ àwọn ará wa lógún ṣáájú tiwa bí Kristi ti ṣe. Nígbà tó wá ń ṣàlàyé ọ̀ràn tó jẹ mọ́ èyí, Pọ́ọ̀lù sọ pé òun tiẹ̀ lè má fẹnu kan ẹran mọ́ tó bá jẹ́ pé ìyẹn ló máa mú kí ìránṣẹ́ kan tó ṣeyebíye, ẹni tí Kristi kú fún kọsẹ̀.—Ka 1 Kọ́ríńtì 8:13; 10:23, 24, 31-33.

16. Kí nìdí táwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gba ohun kan kò fi gbọ́dọ̀ máa dẹ́bi fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn bá fàyè gbà á?

16 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà wọ́n láti ṣe ohun kan ò gbọ́dọ̀ máa dẹ́bi fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn tiwọn fàyè gbà á, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fi dandan lé e pé kí wọ́n máa ṣe bíi tàwọn. (Ka Róòmù 14:10) Ká sòótọ́, ara tiwa alára ló yẹ ká máa fi ẹ̀rí ọkàn wa yẹ̀ lọ́wọ́ wò, kò yẹ ká máa fi tanná wo  ohun táwọn ẹlòmíì ń ṣe. Rántí pé Jésù ti fìgbà kan sọ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” (Mátíù 7:1) Gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ ní láti ṣọ́ra ká má bàa dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ẹ̀rí ọkàn kálukú. Ńṣe ló yẹ ká máa wá ọ̀nà láti nífẹ̀ẹ́ ara wa ká sì jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìjọ, ká máa gbé ara wa ró, ká má sì máa fọ̀rọ̀ èké bara wa jẹ́.—Róòmù 14:19.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍNÚ KÉÈYÀN NÍ Ẹ̀RÍ ỌKÀN RERE

Ẹ̀rí ọkàn rere lè tọ́ wa sọ́nà tó yẹ láyé, ó sì lè fún wa láyọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn

17. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀rí ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí?

17 Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ di ẹ̀rí-ọkàn rere mú.” (1 Pétérù 3:16) Ẹ̀bùn tí ò láfiwé ni ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Ó yàtọ̀ sí ẹ̀rí ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Pọ́ọ̀lù  firú ẹ̀rí ọkàn bẹ́ẹ̀ wé èyí “tí [wọ́n] ti sàmì sí . . . gẹ́gẹ́ bí pé pẹ̀lú irin ìsàmì.” (1 Tímótì 4:2) Irin ìsàmì dà bí irin gbígbóná táwọn alágbẹ̀dẹ fi ń ṣiṣẹ́, téèyàn bá sì gbé e lé ara ńṣe lara ọ̀hún máa bó yànmàkàn, tá á dégbò, tó bá sì yá ńṣe ló máa gíràn-án. Ẹ̀rí ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn ti kú, ìyẹn ni pé ó ti gíràn-án débi pé kò kì wọ́n nílọ̀ mọ́, kì í dá wọn lẹ́bi tí wọ́n bá hùwà tí kò tọ́, gbogbo nǹkan ló sì máa ń gbà láìjanpata. Àwọn kan tiẹ̀ wà tí wọn ò fẹ́ mọ ẹ̀bi wọn lẹ́bi mọ́.

18, 19. (a) Kí ló lè jẹ́ àǹfààní kí ẹ̀rí ọkàn gúnni ní kẹ́ṣẹ́? (b) Kí la lè ṣe tí ẹ̀rí ọkàn wa bá ṣì ń dà wá láàmú lẹ́yìn tá a ti ronú pìwà dà?

18 Ká sòótọ́, bí ẹ̀rí ọkàn wa bá ti ń gún wa ní kẹ́ṣẹ́, ó lè jẹ́ pé ńṣe ló ń sọ fún wa pé a ti ṣàṣìṣe. Tó bá jẹ́ pé irú ìmọ̀lara  bẹ́ẹ̀ ló mú kí ẹnì kan ronú pìwà dà, Ọlọ́run lè dárí jì í bó bá tiẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ tó lé kenkà pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀rí ọkàn Ọba Dáfídì gún un ní kẹ́ṣẹ́ nígbà tó dẹ́ṣẹ̀ kan tó burú jáì, síbẹ̀ Ọlọ́run dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà látọkàn wá. Bó ṣe kórìíra ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, tó sì pinnu láti máa pa àwọn òfin Jèhófà mọ́ ló jẹ́ kó tètè rí i pé ‘ẹni rere ni Jèhófà ó sì ṣe tán láti dárí jini.’ (Sáàmù 51:1-19; 86:5) Tí ẹ̀rí ọkàn wa bá ṣì ń gún wa ní kẹ́ṣẹ́ lẹ́yìn tá a ti ronú pìwà dà tí Ọlọ́run sì ti dárí jì wá ńkọ́?

19 Nígbà míì, ẹ̀rí ọkàn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan lè máa dá a lẹ́bi ṣáá, tá á sì máa nà án lẹ́gba ní gbogbo ìgbà lẹ́yìn tó ti ronú pìwà dà. Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, àwa la máa pa ọkàn-àyà tó ń dá wa lẹ́bi yẹn lẹ́nu mọ́ nípa jíjẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà tóbi ju ìmọ̀lára èyíkéyìí téèyàn lè ní lọ. A ní láti gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ká gbára lé agbára rẹ̀ láti dárí jini, ká sì ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti ní irú ìgbàgbọ́ kan náà. (Ka 1 Jòhánù 3:19, 20) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ máa ń jẹ́ kí ọkàn èèyàn balẹ̀, ó máa ń jẹ́ kára tuni, ó sì máa ń fúnni ní irú ayọ̀ tó ṣọ̀wọ́n láyé tá a wà yìí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì nígbà kan rí lọkàn wọn ti balẹ̀ báyìí, wọ́n sì ti ń fi ẹ̀rí ọkàn rere sin Jèhófà Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 6:11.

20, 21. (a) Kí nìdí tá a fi tẹ ìwé yìí? (b) Òmìnira wo làwa Kristẹni ń jàǹfààní ẹ, báwo ló sì ṣe yẹ ká lò ó?

20 Ìdí tá a fi tẹ ìwé yìí ni pé kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀, kó o sì ní ẹ̀rí ọkàn rere ní àkókò ráńpẹ́ tó kù kí ayé búburú Sátánì tó ń dà wá láàmú yìí kógbá sílé. Ó dájú pé ìwé yìí ò lè ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn òfin àtàwọn ìlànà tí wàá nílò fún onírúurú ìṣòro tó bá ń jẹ yọ lójoojúmọ́. Má sì retí pé gbogbo òfin nípa àwọn ọ̀ràn tá a gbé ka ẹ̀rí ọkàn lo máa rí kà nínú ìwé yìí o. Ńṣe la wulẹ̀ ṣe é láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí bó o ṣe lè tipasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fífi í sílò kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ kó lè máa fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.  Àwọn “òfin Kristi” ò dà bí Òfin Mósè torí pé ẹ̀rí ọkàn àti ìlànà làwọn tó ń tẹ̀ lé òfin Kristi ń gbé ohun tí wọ́n ń ṣe kà, kì í ṣe àwọn òfin tó wà lákọọ́lẹ̀. (Gálátíà 6:2) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fún àwọn Kristẹni ní òmìnira tí kò láfiwé. Síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rán wa létí pé a ò gbọ́dọ̀ lo òmìnira yẹn bíi “bojúbojú fún ìwà búburú.” (1 Pétérù 2:16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni irú òmìnira bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ ká láǹfààní àgbàyanu láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

21 Bó o ti ń ronú lórí ọ̀nà tó dáa jù láti fàwọn ìlànà Bíbélì sílò tàdúràtàdúrà kó o tó pinnu ohun tó o máa ṣe, wàá rí i pé àwọn ètò tó o ṣe nígbà tó o kọ́kọ́ mọ Jèhófà lo tún ń padà tẹ̀ lé báyìí. Wàá sì “tipasẹ̀ lílò” kọ́ “agbára ìwòye” rẹ. (Hébérù 5:14) Àǹfààní gbáà ni ẹ̀rí ọkàn rẹ tó o ti fi Bíbélì kọ́ máa jẹ́ fún ẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bíi ti ohun èlò atọ́nisọ́nà tó máa ń jẹ́ kí arìnrìn àjò mọ ibi tó yẹ kóun gbà, ẹ̀rí ọkàn rẹ á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣe àwọn ìpinnu tó máa múnú Baba rẹ ọ̀run dùn. Wàá sì lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 5 Kò sí ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀rí ọkàn,” nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àmọ́, àpẹẹrẹ Jóòbù tá a mẹ́nu kàn níhìn-ín fi hàn pé àwọn èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn. Ọ̀rọ̀ náà “ọkàn-àyà” sábà máa ń túmọ̀ sí ẹni tá a jẹ́ ní inú. Èyí fi hàn pé Jóòbù tẹ́tí sí apá pàtàkì kan lára ẹni tó jẹ́ ní inú, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. Iye ìgbà tá a lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ẹ̀rí ọkàn” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó ọgbọ̀n.

^ ìpínrọ̀ 8 Bíbélì fi hàn pé wíwulẹ̀ ní ẹ̀rí ọkàn tí kò dani láàmú ò tó. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èmi kò ní ìmọ̀lára ohunkóhun lòdì sí ara mi. Síbẹ̀, nípa èyí, a kò fi mí hàn ní olódodo, ṣùgbọ́n ẹni tí ń wádìí mi wò ni Jèhófà.” (1 Kọ́ríńtì 4:4) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹ̀rí ọkàn àwọn tó ń ṣenúnibíni sáwa Kristẹni lè ṣàì dá wọn lẹ́bi torí wọ́n lè ronú pé ohun tínú Ọlọ́run dùn sí làwọn ń ṣe. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lójú Ọlọ́run, kó má sì da àwa fúnra wa láàmú.—Ìṣe 23:1; 2 Tímótì 1:3.

^ ìpínrọ̀ 10 Ọ̀pọ̀ dókítà ló ti sọ pé kò ṣeé ṣe fáwọn ọ̀mùtípara láti mutí níwọ̀nba; béèyàn bá ní kí wọ́n mutí “níwọ̀nba” bí ìgbà téèyàn ní kí wọ́n má mutí mọ́ ni.