Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀFIKÚN

Bá A Ṣe Lè Máa Yanjú Aáwọ̀ Nínú Ọ̀ràn Ìṣòwò

Bá A Ṣe Lè Máa Yanjú Aáwọ̀ Nínú Ọ̀ràn Ìṣòwò

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jíròrò ọ̀rọ̀ àwọn tó ń mú onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ sílé ẹjọ́ nínú 1 Kọ́ríńtì 6:1-8. Ó dùn ún láti gbọ́ pé àwọn Kristẹni kan ní Kọ́ríńtì “gbójúgbóyà láti lọ sí kóòtù níwájú àwọn aláìṣòdodo.” (Ẹsẹ 1) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé àwọn ìdí gúnmọ́ táwọn Kristẹni kò fi gbọ́dọ̀ máa mú ara wọn lọ sílé ẹjọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n máa yanjú aáwọ̀ nínú ìjọ. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìdí tí ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí yìí fi ṣe pàtàkì ká sì ṣàyẹ̀wò àwọn apá ibi díẹ̀ tí kò gbòòrò dé.

Bí ọ̀rọ̀ ìṣòwò bá da àwa àtàwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa pọ̀, a óò kọ́kọ́ wá bá a ṣe lè yanjú ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí Jèhófà fẹ́, kì í ṣe lọ́nà tó wù wá. (Òwe 14:12) Bí Jésù ṣe fi hàn, ohun tó dáa jù lọ ni pé ká máa tètè yanjú èdè àìyedè kó tó di ńlá. (Mátíù 5:23-26) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé inú máa ń bí àwọn Kristẹni kan débi pé wọ́n máa ń gbé ara wọn lọ sílé ẹjọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀, ó túmọ̀ sí ìpaláyò fún yín pé ẹ ń pe ara yín lẹ́jọ́.” Kí nìdí to fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí pàtàkì kan ni pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè tàbùkù sí ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìjọ àti Ọlọ́run tá à ń sìn. Torí náà, ó yẹ ká fi ìbéèrè Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé: “Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a ṣe àìtọ́ sí ẹ̀yin fúnra yín?”—Ẹsẹ 7.

Pọ́ọ̀lù tún sọ pé Ọlọ́run ti gbé ètò tó dára kalẹ̀ nínú ìjọ nípa bó ṣe yẹ ká máa yanjú aáwọ̀. Àwọn alàgbà jẹ́ Kristẹni tí òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ ti sọ di ọlọgbọ́n, Pọ́ọ̀lù sì sọ pé wọ́n “lè ṣèdájọ́ láàárín àwọn arákùnrin” lórí “àwọn ọ̀ràn ti ìgbésí ayé yìí.” (Ẹsẹ 3-5) Jésù fi hàn pé àwọn aáwọ̀ tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, bí ìfọ̀rọ̀-èké-bani-jẹ́ àti jìbìtì la gbọ́dọ̀ yanjú nípa gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́ta kan: àkọ́kọ́, káwọn tọ́ràn kàn gbìyànjú láti yanjú aáwọ̀ náà láàárín ara wọn; èkejì, bí ìyẹn ò bá ṣiṣẹ́, káwọn méjèèjì mú ẹlẹ́rìí wá; àti ìkẹta, bí ìyẹn náà ò bá ṣiṣẹ́, kí wọ́n fa ọ̀rọ̀ náà lé ìjọ, èyí táwọn alàgbà ń ṣojú fún, lọ́wọ́.—Mátíù 18:15-17.

 Àmọ́ ṣá o, ìyẹn ò fi dandan túmọ̀ sí pé amòfin tàbí oníṣòwò làwọn Kristẹni tó jẹ́ alàgbà, kò sì pọn dandan kí wọ́n ṣe bí amòfin tàbí oníṣòwò. Àwọn kọ́ ló ń ṣòfin táwọn ará á fi máa yanjú èdè àìyedè tó bá wáyé lórí ọ̀ràn ìṣòwò láàárín ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń gbìyànjú láti ran gbogbo àwọn tí ọ̀ràn bá kàn lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, kí wọ́n sì yanjú ọ̀ràn náà ní ìtùnbí ìnùbí. Bó bá jẹ́ àwọn ọ̀ràn tó díjú gan-an, wọ́n lè kàn sí alábòójútó àyíká tàbí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, àwọn ipò míì máa ń wáyé, tó ju èyí tí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù lè ṣiṣẹ́ fún lọ. Kí ni díẹ̀ lára wọn?

Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó wulẹ̀ lè jẹ́ pé ohun tó múni lọ sílé ẹjọ́ ni láti ṣe ohun tó máa tẹ́ tọ̀tún tòsì lọ́rùn táá sì mú kí àlàáfíà jọba. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ohun tí òfin béèrè nìyẹn kéèyàn tó lè gba ìkọ̀sílẹ̀, kí wọ́n tó lè fúnni lẹ́tọ̀ọ́ àbójútó ọmọ, kéèyàn tó lè gba owó ìtìlẹyìn, kí wọ́n tó lè sanwó ìbánigbófò fúnni, kí wọ́n tó lè sọ pé kí báńkì tó wọko gbèsè sanwó fúnni, kí wọ́n sì tó lè fi òǹtẹ̀ lu ìwé ìhágún. Àwọn ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé bí ẹnì kan bá pe arákùnrin lẹ́jọ́, àfi kóun náà yáa pè é lẹ́jọ́ padà kó bàa lè dáàbò bo ara rẹ̀. *

Bí ìgbẹ́jọ́ yìí bá wáyé láìsí ariwo, ó lè má ta ko ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fẹ̀mí rẹ̀ darí Pọ́ọ̀lù láti kọ sílẹ̀. * Síbẹ̀ náà, ohun tí Kristẹni kan gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn ni pé sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ ló ṣe pàtàkì jù lọ. Ìfẹ́ lohun àkọ́kọ́ tá a fi ń dá àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi mọ̀, àti pé “ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5; Jòhánù 13:34, 35.

^ ìpínrọ̀ 2 Lẹ́ẹ̀kan lọ́gbọ̀n, Kristẹni kan lè ṣẹ Kristẹni bíi tiẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì nípa fífipá bá a lò pọ̀, gbígbéjà kò ó, pípa á, tàbí jíjà á lólè. Nínú irú àwọn ọ̀ràn bí èyí, kò lòdì sí ẹ̀kọ́ Kristẹni pé kéèyàn jẹ́ káwọn aláṣẹ gbọ́ nípa rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ẹ̀ lè yọrí sí ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ tàbí bíbá onítọ̀hún ṣẹjọ́ ọ̀daràn.

^ ìpínrọ̀ 8 Bó o bá ń fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ wo Ilé Ìṣọ́ March 15, 1997, ojú ìwé 17 sí 22, àti October 15, 1991, ojú ìwé 25 sí 28.