Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’

Ìwé yìí máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa fi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé rẹ, èyí á sì jẹ́ kí o dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà níyànjú pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó dúró nínú ìfẹ́ Baba rẹ̀.

ORÍ 1

“Èyí Ni Ohun Tí Ìfẹ́ fún Ọlọ́run Túmọ̀ Sí”

Bíbéli fi gbólóhùn kan ṣàlàyé bí a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.

ORÍ 2

Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan má dà á láàmú síbẹ̀ kí ẹ̀rí ọkàn ẹni náà má mọ́ lójú Ọlọ́run?

ORÍ 3

Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tí Ọlọ́run Fẹ́ràn

Jèhófà máa ń yan àwọn tó fẹ́ fi ṣe ọ̀rẹ́, ó yẹ kí àwa náà yan àwọn tí a fẹ́ kó di ọ̀rẹ́ wa.

ORÍ 4

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ?

Ìwé Mímọ́ sọ àwọn ọ̀nà pàtàkì mẹ́ta ní ìgbésí aye wa tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn.

ORÍ 5

Bá A Ṣe Lè Ya Ara Wa Sọ́tọ̀ Kúrò Nínú Ayé

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àwọn ọ̀nà márùn-ún tá a gbọ́dọ̀ gbà ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé.

ORÍ 6

Bó O Ṣe Lè Yan Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé

Àwọn ìbéèrè mẹ́ta tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n yan eré ìnàjú.

ORÍ 7

Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Lo Fi Ń Wò Ó?

Ǹjẹ́ nǹkan míì wà tí èèyàn lè ṣe láti fi hàn pé ẹ̀mí ṣe pàtàkì yàtọ̀ sí pé kí èèyàn má pààyàn?

ORÍ 8

Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Mọ́ Tónítóní

Bíbélì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn àṣà tó lè sọ ẹ́ di aláìmọ́ ní ojú Jèhófà.

ORÍ 9

“Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè”

Ní ọdọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni ló ń dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè. Báwo lo ṣe lè yẹra fún pàkúté yìí?

ORÍ 10

Ìgbéyàwó Jẹ́ Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Wa

Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó tó máa yọrí sí rere? Tó o bá ti ṣègbéyàwó, kí lo lè ṣe tí ìgbéyàwó rẹ a fi wà pẹ́?

ORÍ 11

“Ẹ Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Ní Ọlá”

Wo àwọn ìbéèrè mẹ́fà tó o lè fi ṣe àyẹ̀wò ara rẹ, èyí tó máa jẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ dára sí i.

ORÍ 12

Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”

Ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè gbé àwọn èèyàn ró, ó sì lè gbé wọn ṣubú? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí o ṣe lè lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ lọ́nà tí Jèhófà fẹ́.

ORÍ 13

Àwọn Ayẹyẹ Tí Inú Ọlọ́run Ò Dùn Sí

Àwọn ọdún àtàwọn ayẹyẹ kan wà tí àwọn èèyàn rò pé àwọn fi ń bọlá fún Ọlọ́run àmọ́ tí inú Ọlọ́run ò dùn sí.

ORÍ 14

Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo

Ohun kan wà tí o ní láti kọ́kọ́ ṣe tí o bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí àwọn èèyàn.

ORÍ 15

O Lè Gbádùn Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ

Ka ìdáhùn àwọn ìbéèrè márùn-ún kan tó máa jẹ́ kí o lè mọ̀ bóyá kí o ṣe irú iṣẹ́ kan tàbí kí o má ṣe é.

ORÍ 16

Kọjú Ìjà sí Èṣù Àtàwọn Ọgbọ́n Àlùmọ̀kọ́rọ́yí Rẹ̀

A mọ̀ pé Sátánì ní agbára lóòótọ́, àmọ́ a kò jẹ́ kí ìyẹn máa dẹ́rù bà wá. Kí nìdí?

ORÍ 17

“Gbígbé Ara Yín Ró Lórí Ìgbàgbọ́ Yín Mímọ́ Jù Lọ”

Àwọn ohun mẹ́ta tó o lè ṣe tí ìgbàgbọ́ rẹ á fi máa lágbára sí i, tí wàá sì lè máa dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

ÀFIKÚN

Ọwọ́ Tó Yẹ Ká Fi Mú Ẹni Tí Wọ́n Bá Yọ Lẹ́gbẹ́

Ṣé ó yẹ kéèyàn jáwọ́ pátápátá lọ́rọ̀ ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́?

ÀFIKÚN

Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí Obìnrin Máa Borí, Kí sì Nìdí?

Bíbélì sọ àwọn ohun mẹ́ta tó máa jẹ́ kó o mọ ìdáhùn.

ÀFIKÚN

Kíkí Àsíá, Dídìbò àti Sísin Ìlú Ẹni

Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí?

ÀFIKÚN

Àwọn Ìpín Tó Tara Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Wá, Àtàwọn Ọ̀nà Kan Tí Wọ́n Ń Gbà Ṣiṣẹ́ Abẹ

Tó o bá ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí, kò ní ṣòro fún ẹ láti gba ìtọ́jú tó yẹ.

ÀFIKÚN

Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Rẹ

Báwo lo ṣe lè jáwọ́ nínú ìwà àìmọ́ yìí?

ÀFIKÚN

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀ àti Ìpínyà

Ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì, ìgbà wo ni ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ lè fẹ́ ẹlòmíì?

ÀFIKÚN

Bá A Ṣe Lè Máa Yanjú Aáwọ̀ Nínú Ọ̀ràn Ìṣòwò

Ǹjẹ́ Kristẹni kan lè pe arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́?