Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 26

Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?

Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?

Estonia

Orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè

Orílẹ̀-èdè Mòǹgólíà

Orílẹ̀-èdè Puerto Rico

Orúkọ mímọ́ Ọlọ́run la fi ń pe gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, a gbà pé àǹfààní ló jẹ́ láti máa mú kí ilé yìí wà ní mímọ́ tónítóní, kó dùn-ún wò, kó sì wà láìyingin. Ìyẹn sì jẹ́ apá pàtàkì lára ìjọsìn mímọ́ wa. Gbogbo wa la lè kópa nínú iṣẹ́ náà.

Yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó lẹ́yìn ìpàdé. Lẹ́yìn ìpàdé, àwọn arákùnrin àti arábìnrin máa ń fayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní. Wọ́n sì tún máa ń ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó tó pọ̀ látìgbàdégbà. Alàgbà kan tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló máa ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ náà, ó sábà máa ń wo àkọ́sílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ń yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ tó bá wà, irú bíi gbígbálẹ̀, fífi omi tàbí ẹ̀rọ fọ ilẹ̀ tàbí nínu eruku, títo àga, fífọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti bíbu oògùn apakòkòrò sí i, fífọ fèrèsé àti dígí, kíkó pàǹtírí dà nù tàbí ṣíṣe ìmọ́tótó ara ilé àti ríro àyíká. Ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, a máa ń ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ṣíṣe gbogbo iṣẹ́ ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba náà tinú tòde. A máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ wọn láti máa bọ̀wọ̀ fún ibi ìjọsìn wa.—Oníwàásù 5:1.

Yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe àtúnṣe tó bá yẹ. Lọ́dọọdún, a máa ń yẹ tinú tòde Gbọ̀ngàn Ìjọba wò fínnífínní. Àyẹ̀wò yìí máa ń mú ká ṣe iṣẹ́ àtúnṣe déédéé láti mú kí gbọ̀ngàn náà wà láìyingin, tí èyí kì í jẹ́ ká máa ná owó dà nù. (2 Kíróníkà 24:13; 34:10) Gbọ̀ngàn Ìjọba tó mọ́ tónítóní tá a sì tọ́jú dáádáá ni ìbi tó yẹ láti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa. Tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ náà, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọyì ibi ìjọsìn wa. (Sáàmù 122:1) Èyí tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn fojú tó dára wò wá ládùúgbò tá à ń gbé.—2 Kọ́ríńtì 6:3.

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tọ́jú ibi ìjọsìn wa?

  • Àwọn ètò wo la ṣe láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní?