Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 18

Báwo La Ṣe Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ará Wa Tí Àjálù Bá?

Báwo La Ṣe Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ará Wa Tí Àjálù Bá?

Orílẹ̀-èdè Dominican Republic

Orílẹ̀-èdè Japan

Orílẹ̀-èdè Haiti

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣètò ìrànwọ́ tó máa mú ìtura wá fún àwọn ará wa tí àjálù náà bá. Irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń fi hàn pé ìfẹ́ tòótọ́ ló wà láàárín wa. (Jòhánù 13:34, 35; 1 Jòhánù 3:17, 18) Àwọn ọ̀nà wo la máa ń gbà ṣèrànwọ́?

A máa ń fowó ṣèrànwọ́. Nígbà tí ìyàn ńlá mú ní Jùdíà, àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni ní ìlú Áńtíókù fi owó ránṣẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wọ́n ní Jùdíà. (Ìṣe 11:27-30) Lọ́nà kan náà, tá a bá gbọ́ pé nǹkan nira fún àwọn ará wa láwọn apá ibì kan láyé, a máa ń fi owó ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ wa, kí wọ́n lè fi pèsè àwọn nǹkan fún àwọn ará tí nǹkan nira fún gan-an.—2 Kọ́ríńtì 8:13-15.

A máa ń ṣèrànwọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́. Àwọn alàgbà tó bá wà níbi tí àjálù kan ti ṣẹlẹ̀ máa ń wá ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ kàn, láti rí i pé gbogbo wọn wà lálàáfíà. Ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ máa ń ṣètò fún oúnjẹ, omi tó mọ́, aṣọ, ibùgbé àti ìtọ́jú ara. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mọ iṣẹ́ tí wọ́n lè fi ṣàtúnṣe ibi tí àjálù bà jẹ́, máa ń ná owó ara wọn láti lọ ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá tàbí láti tún àwọn ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́ ṣe. Ìṣọ̀kan tá a ní nínú ètò wa àti ìrírí tá a ti ní bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ máa ń jẹ́ kí a lè tètè kóra jọ láti ṣèrànwọ́ nígbà ìṣòro. Bí a ṣe ń ṣèrànwọ́ fún “àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́,” ni a tún ń ṣèrànwọ́ fún àwọn míì tí ó bá ṣeé ṣe, láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí.—Gálátíà 6:10.

A máa ń fi Ìwé Mímọ́ tu àwọn èèyàn nínú. Àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí nílò ìtùnú gan-an. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, a máa ń rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Inú wa máa ń dùn láti sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tí ìdààmú bá, à ń mú un dá wọn lójú pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo àjálù tó ń fa ìrora àti ìjìyà bá aráyé.—Ìṣípayá 21:4.

  • Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa tètè ṣèrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?

  • Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la lè fi sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó yè bọ́ nínú àjálù?