Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

Ṣé Wàá Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà?

Ṣé Wàá Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà?

A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìwé yìí láti mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa àti láti mọ̀ nípa iṣẹ́ tí à ń ṣe, kó o sì rí ohun tí ètò wa ń gbé ṣe. A mọ̀ pé ìwé yìí á ti jẹ́ kó o mọ̀ pé àwa là ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà lóde òní. A rọ̀ ẹ́ pé kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run nìṣó, kó o máa sọ ohun tó ò ń kọ́ fún àwọn ará ilé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ yòókù, kó o sì máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ wa déédéé.​—Hébérù 10:23-25.

Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà á jẹ́ kó o túbọ̀ rí bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó. Ìyẹn á wá mú kó o fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti fi hàn pé ìwọ náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòhánù 4:8-10, 19) Àmọ́, báwo lo ṣe lè fi hàn nínú ìgbé ayé rẹ pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Kí nìdí tí títẹ̀lé àwọn ìlànà rẹ̀ fi máa ṣe ọ́ láǹfààní? Kí ló sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú wa? Ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á fẹ́ kí ẹ jọ wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí kí ìwọ àti ìdílé rẹ bàa lè máa “pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, . . . pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.”—Júúdà 21.

A rọ̀ ẹ́ pé kó o máa tẹ̀ síwájú ní ọ̀nà òtítọ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé tó wà nísàlẹ̀ yìí . . .

 

Mọ Púpọ̀ Sí I

BÉÈRÈ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Bíbélì ń ran ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lọ́wọ́ kárí ayé láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ṣé wàá fẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára wọn?

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ

Kí Là Ń Pè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Mọ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀fẹ́ tá à ń ṣe.