Orílẹ̀-èdè Faransé

Orílẹ̀-èdè Poland

Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Ìdí nìyẹn tá a fi ń lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti òde òní, títí kan Íńtánẹ́ẹ̀tì fún iṣẹ́ wa. Ìkànnì wa, jw.org, jẹ́ ibi tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó ìsọfúnni nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ wa sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí làwọn ohun tó wà níbẹ̀?

Àwọn ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè. O lè rí ìdáhùn sí díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn èèyàn ti béèrè. Bí àpẹ̀ẹrẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ǹjẹ Ìyà Lè Dópin? àti Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde? wà lórí ìkànnì wa ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600]. Wàá tún rí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun níbẹ̀ ní èdè tó lé ní àádóje [130]. Àwọn ìwé táa fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà wà níbẹ̀, títí kan ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-⁠an? àtàwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. O lè ka ọ̀pọ̀ lára ìwé wọ̀nyí tàbí kó o tẹ́tí sí wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o sì lè wà wọ́n jáde lóríṣiríṣi ètò ìṣiṣẹ́ táwọn èèyàn ń lò bíi MP3, PDF tàbí EPUB. O tiẹ̀ lè tẹ ojú ìwé mélòó kan jáde fún ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ìsọfúnni náà ní èdè rẹ̀! Àwọn fídíò tún wà ní oríṣiríṣi èdè àwọn adití. Àwọn ohun tó o tún lè wà jáde ni Bíbélì kíkà bí ẹni ń ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́, àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn orin aládùn tó o lè gbádùn lákòókò ọwọ́dilẹ̀.

Ìsọfúnni tó jóòótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun míì tá a tún ń gbé sórí ìkànnì wa ni àwọn ìròyìn nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ àti fídíò nípa iṣẹ́ wa karí ayé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìrànwọ́ tá a ṣe fún àwọn tí àjálù bá. O lè rí ìsọfúnni nípa àwọn àpéjọ tó ń bọ̀ àti àdírẹ́sì ibi táwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa wà.

À ń tipa àwọn ìsọfúnni yẹn tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ dé apá ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé. Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo, títí kan ilẹ̀ Antarctica, ló ń jàǹfààní rẹ̀. Àdúrà wa ni pé “kí ọ̀rọ̀ Jèhófà lè máa [yára gbòòrò]” lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé fún ògo Ọlọ́run.—2 Tẹsalóníkà 3:1.

  • Báwo ni ìkànnì wa, jw.org ṣe ń ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

  • Kí lo máa fẹ́ ṣèwádìí nípa rẹ̀ lórí ìkànnì wa?