Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 4

Kí Nìdí Tí A Fi Ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun?

Kí Nìdí Tí A Fi Ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun?

Orílẹ̀-èdè Kóńgò (Kinshasa)

Orílẹ̀-èdè Rùwáńdà

Àjákù ìwé Symmachus rèé tó ní Sáàmù 69:31, níbi tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn, ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta tàbí ìkẹrin Sànmánì Kristẹni

Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi lo oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì, tí a tẹ̀ wọ́n jáde tí a sì pín wọn káàkiri. Nígbà tó yá, a rí i pé ó yẹ ká ṣe ìtumọ̀ míì tó máa túbọ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́” bí Ọlọ́run ṣe fẹ́. (1 Tímótì 2:3, 4) Nítorí náà, ní ọdún 1950 a bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lápá kọ̀ọ̀kan ní èdè tó bóde mu. A ti túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó péye tí kò sì lábùkù sí èdè tí ó lé ní àádóje [130].

A nílò Bíbélì kan tó máa tètè yé àwọn èèyàn. Èdè máa ń yí pa dà, ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló sì ṣòro lóye torí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ye àwọn èèyàn tàbí àwọn ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn kò lò mọ́. Bákan náà, a ti ṣàwárí àwọn àdàkọ Ìwé Mímọ́ tó túbọ̀ péye tó jẹ́ ti ayé àtijọ́ tó sún mọ́ Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ, ìyẹn sì ti jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn èdè Hébérù, Árámáíkì àti èdè Gíríìkì tí wọn fi kọ Bíbélì.

A nílò ìtumọ̀ Bíbélì tí kò bomi la ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn atúmọ̀ Bíbélì kò gbọ́dọ̀ yí ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí pa dà, ńṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe ìtumọ̀ tí kò lábùkù tó sì bá Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ mu. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ni kò lo orúkọ náà, Jèhófà, tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run.

A nílò Bíbélì kan tó fi ògo fún Ẹni tó ni ín. (2 Sámúẹ́lì 23:2) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán ìsàlẹ̀ yìí, a ti dá orúkọ náà, Jèhófà pa dà sínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, bó ṣe wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000 ] ìgbà nínú Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ fọwọ́ kọ. (Sáàmù 83:18) Nítorí a ti fara balẹ̀ ṣe ìwádìí fún ọ̀pọ̀ ọdún kí a tó gbé Bíbélì yìí jáde, ó dùn-ún kà ó sì jẹ́ kí èrò Ọlọ́run ṣe kedere. Yálà Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wà ní èdè rẹ tàbí kò sí, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ka Ọ̀rọ̀ Jèhófà lójoojúmọ́.—Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:2, 3.

  • Kí nìdí tá a fi pinnu pé a nílò ìtumọ̀ Bíbélì míì?

  • Kí ló yẹ kí gbogbo ẹni tó bá fẹ mọ ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣe lójoojúmọ́?

Mọ Púpọ̀ Sí I

IṢẸ́ ÌTẸ̀WÉ

A Fi Iṣẹ́ Títúmọ̀ “Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìkéde Ọlọ́wọ̀ Ti Ọlọ́run” Síkàáwọ́ Wọn—Róòmù 3:2

Láti ọ̀pọ̀ ọdún títí di báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi ọ̀pọ̀ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe ìtúmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì òde òní?

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè kojú àwọn ìṣòro rẹ? Kí nìdí tó o fi lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀?