Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Orílẹ̀-èdè South Korea

Orílẹ̀-èdè Àméníà

Orílẹ̀-èdè Bùrúńdì

Orílẹ̀-èdè Sri Lanka

Ká lè sọ “ìhìn rere” náà fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn,” èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (750) la fi ń tẹ ìwé jáde. (Ìfihàn 14:6) Báwo la ṣe ń ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí? À ń lo àwọn òǹkọ̀wé wa tí wọ́n wà káàkiri ayé àti àwọn atúmọ̀ èdè tó ń fi tọkàn tara ṣiṣẹ́, gbogbo wọn pátá sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Èdè Gẹ̀ẹ́sì la fi ń kọ àwọn ìwé wa ká tó tú u sí àwọn èdè míì. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń bójú tó Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ní orílé-iṣẹ́ wa lágbàáyé. Ẹ̀ka yìí ló ń ṣètò iṣẹ́ àwọn òǹkọ̀wé tó wà ní orílé-iṣẹ́ wa àtàwọn tó wà láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan. Àwọn òǹkọ̀wé wa wá láti àwọn ibi tó yàtọ̀ síra, èyí ń jẹ́ ká lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò fún àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra, ó sì ń jẹ́ kí àwọn èèyàn láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun tí à ń gbé jáde.

A máa ń fi ohun tá a kọ ránṣẹ́ sí àwọn atúmọ̀ èdè. Lẹ́yìn tá a bá ṣàtúnṣe sí ohun tí àwọn òǹkọ̀wé wa kọ, tá a sì fọwọ́ sí i, a máa ń fi ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sí àwọn atúmọ̀ èdè káàkiri ayé, kí wọ́n lè túmọ̀ rẹ̀, kí wọ́n yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa, kí wọ́n sì rí i pé ó dùn-ún kà lédè wọn. Wọ́n máa ń rí i dájú pé àwọn lo “àwọn ọ̀rọ̀ tó péye tó sì jẹ́ òtítọ́” kí wọ́n lè gbé ìtumọ̀ ohun tí a sọ lédè Gẹ̀ẹ́sì yọ dáadáa ní èdè ìbílẹ̀ wọn.​—Oníwàásù 12:10.

Kọ̀ǹpútà ń mú kí iṣẹ́ wọn yára kánkán. A ò lè fi kọ̀ǹpútà rọ́pò àwọn òǹkọ̀wé àtàwọn atúmọ̀ èdè. Àmọ́, iṣẹ́ wọn máa ń yá tí wọ́n bá lo àwọn ìwé atúmọ̀ èdè tó wà lórí kọ̀ǹpútà, àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà tó wà fún èdè wọn àtàwọn ohun tí wọ́n lè fi ṣe ìwádìí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ètò orí kọ̀ǹpútà kan tá a pè ní Multilanguage Electronic Publishing System (ìyẹn MEPS) tó máa jẹ́ ká lè tẹ ọ̀rọ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, ká fi àwòrán sí i, ká sì ṣètò rẹ̀ bó ṣe máa wà lórí ìwé.

Kí nìdí tá a fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ yìí, kódà láwọn èdè tó jẹ́ pé àwọn tó ń sọ ọ́ kò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ? Ìdí ni pé ó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà pé “ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.”​—1 Tímótì 2:​3, 4.

  • Báwo la ṣe ń kọ àwọn ìwé wa?

  • Kí nìdí tá a fi ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí ọ̀pọ̀ èdè?