Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 2

Kí Nìdí Tí A Fi Ń Jẹ́ Orúkọ Náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kí Nìdí Tí A Fi Ń Jẹ́ Orúkọ Náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Nóà

Ábúráhámù àti Sárà

Mósè

Jésù Kristi

Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, jẹ́ orúkọ ẹ̀sìn tuntun kan. Àmọ́, ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ọdún sẹ́yìn, Bíbélì pe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ní “ẹlẹ́rìí” rẹ̀. (Aísáyà 43:10-12) Ṣáájú ọdún 1931, orúkọ tí wọ́n fi mọ̀ wá ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí nìdí tí a fi gba orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Orúkọ náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ Ọlọ́run wa. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ kan sọ pé orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, fara hàn ní àwọn ẹgbẹ̀rún ìgbà nínú Bíbélì. Nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì, wọ́n ti fi àwọn orúkọ oyè bí Olúwa tàbí Ọlọ́run rọ́pò orúkọ yìí. Síbẹ̀, nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ fara han Mósè, ó lo orúkọ tó ń jẹ́ gangan, ìyẹn Jèhófà, ó sì sọ pé: “Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Ẹ́kísódù 3:15) Ọlọ́run tipa báyìí fi hàn pé òun yàtọ̀ sí àwọn ọlọ́run èké. Inú wa dùn pé à ń jẹ́ orúkọ mímọ́ ti Ọlọ́run.

Orúkọ náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn nígbà àtijọ́ jẹ́rìí pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, èyí sì bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ọkùnrin olóòótọ́ náà Ébẹ́lì. Láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún wá ni àwọn èèyàn bíi Nóà, Ábúráhámù, Sárà, Mósè, Dáfídì àti àwọn míì ti dara pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” yìí. (Hébérù 11:4–12:1) Bí ẹnì kan ṣe máa ń ṣe ẹlẹ́rìí ní ilé ẹjọ́ fún ẹni tí kò jẹ̀bí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, lọ́nà kan náà, àwa pẹ̀lú ti pinnu pé a fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run wa.

À ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Bíbélì pe Jésù ní “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́.” (Ìṣípayá 3:14) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé òun ‘jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́rùn’ òun sì ń “jẹ́rìí sí òtítọ́” nípa Ọlọ́run. (Jòhánù 17:26; 18:37) Nítorí náà, àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi gbọ́dọ̀ máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà kí wọ́n sì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ náà. Ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nìyẹn.

  • Kí nìdí tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi gba orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

  • Ìgbà wo ni Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ẹlẹ́rìí lórí ilẹ̀ ayé?

  • Ta ni Ẹlẹ́rìí tí ó tóbi jù lọ tí Jèhófà ní?