Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 13

Kí Ni Aṣáájú-Ọ̀nà?

Kí Ni Aṣáájú-Ọ̀nà?

Orílẹ̀-èdè Kánádà

Ìwàásù ilé-dé-ilé

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ìdákẹ́kọ̀ọ́

Ọ̀rọ̀ náà “aṣáájú-ọ̀nà” sábà máa ń tọ́ka sí àwọn tó lọ láti ṣàwárí ìpínlẹ̀ tuntun, kí wọ́n sì la ọ̀nà fún àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn. A lè pe Jésù náà ní aṣáájú-ọ̀nà, torí Ọlọ́run rán an wá sí ayé láti wá ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń fúnni ní ìyè, kí ó sì ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún àwọn èèyàn. (Mátíù 20:28) Lónìí, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa lílo àkókò tó pọ̀ láti máa sọni “di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan láti ṣe iṣẹ́ tí à ń pè ní iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù là ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń kéde ìhìn rere. Àmọ́, àwọn kan ti ṣètò ìgbésí ayé wọn kí wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, tí wọ́n ń lo àádọ́rin [70] wákàtí lóṣooṣù láti máa fi wàásù. Nítorí kí wọ́n bàa lè ṣe iṣẹ́ náà, ọ̀pọ̀ ti dín àkókò tí wọ́n ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn kù. A ti yan àwọn kan láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù tó pọ̀ sí i, wọ́n sì ń fi àádóje [130] wákàtí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ wàásù lóṣooṣù. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà máa ń jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fún àwọn. (Mátíù 6:31-33; 1 Tímótì 6:6-8) Àwọn tí kò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà alákòókò-kíkún lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó bá ṣeé ṣe, nípa lílo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn, ìyẹn ọgbọ̀n wákàtí [30] tàbí àádọ́ta [50] wákàtí lóṣù kan.

Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti èèyàn ló ń mú kí aṣáájú-ọ̀nà máa ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Bíi ti Jésù, a mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. (Máàkù 6:34) Àmọ́, a mọ ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nísinsìnyí, tó máa mú kí wọ́n ní ìrètí pé ọjọ́ ọ̀la á dára. Ìfẹ́ fún aládùúgbò ẹni ló ń mú kí aṣáájú-ọ̀nà máa lo àkókò àti okun rẹ̀ láti sọ ìhìn rere fún àwọn èèyàn. (Mátíù 22:39; 1 Tẹsalóníkà 2:8) Ìyẹn ti mú kí ìgbàgbọ́ aṣáájú-ọ̀nà lágbára, kó sún mọ́ Ọlọ́run, kó sì máa ní ayọ̀ púpọ̀.—Ìṣe 20:35.

  • Kí ni aṣáájú-ọ̀nà?

  • Kí ló mú kí àwọn kan máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà alákòókò-kíkún?