Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 8

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Múra Dáadáa Nígbà Tá A Bá Ń Lọ sí Àwọn Ìpàdé Wa?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Múra Dáadáa Nígbà Tá A Bá Ń Lọ sí Àwọn Ìpàdé Wa?

Iceland

Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Orílẹ̀-èdè Guinea-Bissau

Orílẹ̀-èdè Philippines

Ǹjẹ́ o ti kíyè sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú àwòrán inú ìwé yìí bí wọ́n ṣe múra dáadáa nígbà tí wọ́n ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ? Kí nìdí tí a fi máa ń fiyè sí aṣọ àti ìmúra wa?

Kí a lè bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run wa. Òótọ́ kan ni pé Ọlọ́run kì í wo inú ọkàn wa nìkan, ó má ń wo ìrísí ara wa pẹ̀lú. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Nígbà tí a bá péjọ láti jọ́sìn Ọlọ́run, ìfẹ́ ọkàn wa ni pé ká bọ̀wọ̀ fún un àti fún àwọn tá a jọ ń sìn ín. Bí a bá fẹ́ lọ síwájú ọba tàbí ààrẹ orílẹ̀-èdè, a máa kíyè sí ìmúra wa nítorí pé èèyàn pàtàkì ni wọ́n. Bákan náà, ọ̀nà tí a gbà múra wá sí ìpàdé ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run, “Ọba ayérayé” àti fún ibi tá a ti ń jọ́sìn rẹ̀.—1 Tímótì 1:17.

Kí a lè fi ìlànà tí à ń tẹ̀ lé hàn. Bíbélì rọ àwa Kristẹni pé kí a máa múra lọ́nà tó fi “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú hàn.” (1 Tímótì 2:9, 10) Mímúra lọ́nà “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà” túmọ̀ sí pé ká má ṣe wọ aṣọ tó lè pe àfiyèsí sí wa, ìyẹn wíwọṣọ lọ́nà ṣekárími, aṣọ tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tàbí èyí tó ṣí ara sílẹ̀. Bákan náà, níní “ìyèkooro èrò inú” ń jẹ́ ká yan aṣọ tó dáa, ká sì yẹra fún aṣọ jákujàku tàbí wíwọṣọ lọ́nà àṣejù. Ìlànà yìí fàyè gba pé kí kálukú wọ aṣọ tó wù ú tó bá sáà ti dáa. Láìsí àní-àní, ìmúra wa tó bójú mu lè “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́,” kí ó sì “yin Ọlọ́run lógo.” (Títù 2:10; 1 Pétérù 2:12) Bí a ṣe ń múra dáadáa nígbà tá a bá ń lọ sí ìpàdé ń mú káwọn èèyàn máa fojú tó dáa wo ìjọsìn Jèhófà.

Má ṣe kọ ìpàdé sílẹ̀ torí pe o kò ní irú aṣọ kan tó o máa wọ̀ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kò dìgbà tí aṣọ wa bá jẹ́ olówó ńlá tàbí tó rí rèǹtè-rente kó tó jẹ́ aṣọ tó dáa, tó mọ́ tónítóní, tó sì bójú mu.

  • Báwo ni ìmúra wa ṣe ṣe pàtàkì tó nígbà tá a bá ń jọ́sìn Ọlọ́run?

  • Àwọn ìlànà wo la máa ń tẹ̀ lé nípa aṣọ àti ìmúra wa?