Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 16

Kí Ni Ojúṣe Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?

Kí Ni Ojúṣe Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?

Orílẹ̀-èdè Myanmar

Ìpàdé ìjọ

Àwùjọ àwọn tó fẹ́ lọ wàásù

Wọ́n ń ṣàtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba

Bíbélì ṣàlàyé pé àwùjọ méjì ni àwọn ọkùnrin tó ń bójú tó àwọn iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni pín sí, ìyẹn “àwọn alábòójútó àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.” (Fílípì 1:1) Ìwọ̀nba àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló máa ń wà ní ìjọ kọ̀ọ̀kan. Àwọn iṣẹ́ tó ń ṣe wá láǹfààní wo ni àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń ṣe?

Wọ́n ń ran ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lọ́wọ́. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ àwọn ọkùnrin tó ń fi ọ̀wọ́ pàtàkì mú nǹkan tẹ̀mí, wọ́n ṣeé fọkàn tán, wọ́n sì máa ń fara balẹ̀ ṣe nǹkan, àwọn kan lára wọn jẹ́ ọ̀dọ́, àwọn míì sì jẹ́ àgbà. Wọ́n máa ń bójú tó àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn tó ṣe pàtàkì àmọ́ tí kì í ṣe iṣẹ́ àbójútó ìjọ. Èyí jẹ́ kí àwọn alàgbà lè gbájú mọ́ iṣẹ́ kíkọ́ni àti iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn.

Wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó ń ṣeni láǹfààní. A máa ń yan àwọn ìránṣẹ́ òjíṣẹ́ kan láti jẹ́ olùtọ́jú èrò, kí wọ́n máa kí àwọn tó bá wá sí ìpàdé káàbọ̀. Àwọn míì lè máa bójú tó ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, ìwé ìròyìn, àkọsílẹ̀ ìnáwó ìjọ, àwọn míì sì máa ń pín ìpínlẹ̀ ìwàásù fún àwọn ará ìjọ. Wọ́n tún máa ń ṣèrànwọ́ láti ṣàtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn alàgbà lè ní kí wọ́n ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́. Iṣẹ́ yòówù kí wọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti máa ṣe, bí wọ́n ṣe ń ṣe é tinútinú ń mú kí gbogbo èèyàn bọ̀wọ̀ fún wọn.—1 Tímótì 3:13.

Wọ́n ń fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Àwọn ìwà rere tó yẹ Kristẹni tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní la fi ń yàn wọ́n sípò. Wọ́n máa ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ní ìpàdé. Bí wọ́n ṣe ń mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ń jẹ́ kí ìtara wa pọ̀ sí i. Bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ń mú kí ayọ̀ àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀. (Éfésù 4:16) Tó bá yá, àwọn náà lè kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà.

  • Irú èèyàn wo ni àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?

  • Ọ̀nà wo ni àwọn ìránṣẹ́ gbà ń mú kí nǹkan máa lọ déédéé nínú ìjọ?